以斯拉记 5 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

以斯拉记 5:1-17

1那时,先知哈该易多的子孙撒迦利亚以色列上帝的名,向犹大耶路撒冷犹大人宣讲上帝的话。 2于是,撒拉铁的儿子所罗巴伯约萨达的儿子耶书亚开始在耶路撒冷重建上帝的殿,上帝的先知在他们身边帮助他们。

3当时,河西总督达乃示他·波斯乃及其同僚来问他们:“谁批准你们重建这殿、修复这墙的?” 4又问道:“建造这殿的人们叫什么名字。” 5然而,上帝看顾犹太人的长老,工程没有被叫停,直到事情呈报给大流士王、收到王的回谕后才停止。

6河西的官员们——河西总督达乃示他·波斯乃及其同僚上奏大流士王, 7奏章如下:

“愿大流士王一切平安! 8王该知道,我们去了犹大省,到了伟大上帝的殿。人们正在用大石建殿,木料已经安在墙里,工程进展迅速、顺利。 9我们问那些长老,‘谁批准你们重建这殿、修复这墙的?’ 10我们又问他们的名字,好记下他们首领的名字禀告王。

11“他们回答说,‘我们是天地之上帝的仆人,我们正在重建这座多年前由以色列的一位伟大君王建造的殿。 12但因为我们的祖先触怒了天上的上帝,上帝把他们交在迦勒底人——巴比伦尼布甲尼撒的手中,他摧毁了这殿,把他们掳到巴比伦13然而,巴比伦塞鲁士在其统治元年,降旨重建这座上帝的殿。 14尼布甲尼撒王曾掳去耶路撒冷上帝殿里的金银器皿,放在巴比伦神庙里,塞鲁士王从巴比伦神庙取出这些器皿,交给他委派做省长的设巴萨15吩咐他把这些器皿带去,重新陈设在耶路撒冷的殿里,在旧址上重建上帝的殿。 16于是,这位设巴萨就在耶路撒冷为上帝的殿立了根基,从那时到如今,殿一直在重建中,还没有竣工。’

17“现在,王若愿意,请查阅巴比伦的王室记录,看看塞鲁士王是否降旨重建耶路撒冷的上帝之殿。王对此事如何决断,请告知我们。”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esra 5:1-17

Lẹ́tà Tatenai sí Dariusi

15.1: Hg 1.1; Sk 1.1.Nígbà náà wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, láti ìran Iddo, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ará Júù ní Juda àti Jerusalẹmu ní orúkọ Ọlọ́run Israẹli tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bẹ lára wọn. 2Nígbà náà Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti Jeṣua ọmọ Josadaki gbáradì fún iṣẹ́ àti tún ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu kọ́. Àwọn wòlíì Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, tí wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́.

3Ní àkókò náà Tatenai, baálẹ̀ ti agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹgbẹgbẹ́ wọn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n sì béèrè pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ àti láti tún odi yìí mọ?” 4Wọ́n sì tún béèrè pé, “Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí?” 5Ṣùgbọ́n ojú Ọlọ́run wọn wà lára àwọn àgbàgbà Júù, wọn kò sì dá wọn dúró títí ìròyìn yóò fi dè ọ̀dọ̀ Dariusi kí wọ́n sì gba èsì tí àkọsílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.

6Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Tatenai, olórí agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn. Àwọn olóyè ti agbègbè Eufurate, fi ránṣẹ́ sí ọba Dariusi. 7Ìròyìn tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i kà báyìí pé:

Sí ọba Dariusi:

Àlàáfíà fún un yín.

8Kí ọba kí ó mọ̀ pé a lọ sí ẹ̀kún Juda, sí tẹmpili Ọlọ́run tí ó tóbi. Àwọn ènìyàn náà ń kọ́ ọ pẹ̀lú àwọn òkúta ńláńlá àti pẹ̀lú fífi àwọn igi sí ara ògiri. Wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àìsimi, ó sì ń ní ìtẹ̀síwájú kíákíá lábẹ́ ìṣàkóso wọn.

9A bi àwọn àgbàgbà, a sì fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún ilé Olúwa yìí kọ́ àti láti tún odi rẹ̀ mọ?” 10A sì tún béèrè orúkọ wọn pẹ̀lú, kí a lè kọ àwọn orúkọ àwọn olórí wọn sílẹ̀ kí ẹ ba à le mọ ọ́n.

11Èyí ni ìdáhùn tí wọ́n fún wa:

“Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, àwa sì ń tún tẹmpili ilé Olúwa tí a ti kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kọ́, èyí tí ọba olókìkí kan ní Israẹli kọ́, tí ó sì parí i rẹ̀. 12Ṣùgbọ́n nítorí tí àwọn baba wa mú Ọlọ́run ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadnessari ti Kaldea, ọba Babeli lọ́wọ́, ẹni tí ó run tẹmpili Olúwa yìí tí ó sì kó àwọn ènìyàn náà padà sí Babeli.

135.13: Es 1.1; 6.3.“Ṣùgbọ́n ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba Kirusi ọba Babeli, ọba Kirusi pàṣẹ pé kí a tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́. 14Òun tilẹ̀ kò jáde láti inú tẹmpili ní babeli fàdákà àti ohun èlò wúrà ilé Ọlọ́run, èyí tí Nebukadnessari kó láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu wá sí inú tẹmpili ní Babeli. Ọba Kirusi kó wọn fún ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣeṣbassari, ẹni tí ó ti yàn gẹ́gẹ́ bí i baálẹ̀, 15ó sì sọ fún un pé, ‘Kó àwọn ohun èlò yìí kí o lọ, kí o sì kó wọn sí inú ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, kí ẹ sì tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ipò o rẹ̀.’

16“Nígbà náà ni Ṣeṣbassari náà wá, ó sí fi ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run tí ó wá ní Jerusalẹmu lélẹ̀, láti ìgbà náà àní títí di ìsinsin yìí ni o ti n bẹ ní kíkọ́ ṣùgbọ́n, kò sí tí ì parí tán.”

17Nísinsin yìí tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí ní ilé ìṣúra ọba ní Babeli láti rí bí ọba Kirusi fi àṣẹ lélẹ̀ lóòótọ́ láti tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́ ní Jerusalẹmu. Nígbà náà jẹ́ kí ọba kó fi ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sí wa.