以斯拉记 1 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

以斯拉记 1:1-11

塞鲁士下令犹太人回国

1波斯塞鲁士元年,耶和华为要应验祂借耶利米所说的话,就感动波斯塞鲁士,使他下诏通告全国:

2波斯塞鲁士如此说,‘天上的上帝耶和华已把天下万国都赐给我,祂吩咐我在犹大耶路撒冷为祂建造殿宇。 3你们当中凡是耶和华的子民,都可以去犹大耶路撒冷,为住在耶路撒冷以色列的上帝耶和华建殿,愿上帝与他们同在! 4凡留下不回国的人,无论住在哪里,都要用金银、财物和牲畜帮助同区那些将要回国的人,此外还要为耶路撒冷的上帝的殿献上自愿献的礼物。’”

5于是,犹大便雅悯的族长、祭司和利未人——所有被上帝感动的人都准备上耶路撒冷重建耶和华的殿。 6他们周围的人除了献上自愿献的礼物外,还拿出银器、金子、财物、牲畜和珍宝来支持他们。 7巴比伦尼布甲尼撒曾从耶路撒冷耶和华的殿里带回珍贵的器皿,放在自己神明的庙里。波斯塞鲁士将这些器皿取出来, 8派财政大臣米提利达如数交给犹大的首领设巴萨9三十个金盘、一千个银盘、二十九把刀、 10三十个金碗、四百一十个次等银碗及一千件其他器皿, 11共有五千四百件金银器皿。被掳者从巴比伦耶路撒冷时,设巴萨把这些器皿一并带去。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esra 1:1-11

Kirusi ran àwọn tí a kó nígbèkùn lọ́wọ́ láti padà

11.1-3: Es 5.13; 6.3; 2Ki 36.22,23.Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi, ọba Persia, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí Jeremiah sọ ṣẹ, Olúwa ru ọkàn Kirusi ọba Persia sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbègbè ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé:

2“Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé:

“ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili Olúwa fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda. 3Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda, láti kọ́ tẹmpili Olúwa Ọlọ́run Israẹli, Ọlọ́run tí ó wà ní Jerusalẹmu. 4Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni náà bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.’ ”

5Nígbà náà àwọn olórí ìdílé Juda àti Benjamini àti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi—olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run ti fọwọ́ tọ́ ọkàn rẹ̀—múra láti gòkè lọ láti kọ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. 6Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún si gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá.

7Ní àfikún, ọba Kirusi mú àwọn ohun èlò tí ó jẹ́ ti ilé Olúwa jáde wá, tí Nebukadnessari ti kó lọ láti Jerusalẹmu tí ó sì ti kó sí ilé òrìṣà rẹ̀. 8Kirusi ọba Persia pàṣẹ fún Mitredati olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣeṣbassari ìjòyè Juda.

9Èyí ni iye wọn:

Ọgbọ̀n àwo wúrà 30Ẹgbẹ̀rún àwo fàdákà 1,000Àwo ìrúbọ fàdákà mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n 2910Ọgbọ̀n àdému wúrà 30Irínwó ó-lé-mẹ́wàá oríṣìí àdému fàdákà mìíràn 410Ẹgbẹ̀rún kan àwọn ohun èlò mìíràn 1,000

11Gbogbo ohun èlò wúrà àti ti fàdákà ní àpapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó-lé-irínwó (5,400).

Ṣeṣbassari kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí wá pẹ̀lú àwọn ìgbèkùn tí ó gòkè wá láti Babeli sí Jerusalẹmu.