以斯帖记 7 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

以斯帖记 7:1-10

哈曼被处死

1王带着哈曼去赴以斯帖王后的宴席。 2在这第二次宴会中,王在席间又问以斯帖:“以斯帖王后啊,你要什么?我必赐给你。你有何要求?就是半壁江山,也必为你成就。” 3以斯帖回答说:“我若得到王的恩宠,王若愿意,就请王把我的性命和我本族人的性命赐给我——这是我所求的。 4因为我和我本族的人都被卖了,我们将被铲除、杀光、灭尽。如果只是卖我们为奴为婢,我会闭口不语,因为那样的痛苦不值得来打扰王7:4 因为那样的痛苦不值得来打扰王”或译“但王的损失,敌人无法补偿”。。” 5亚哈随鲁王问以斯帖王后:“谁敢这样做?他在哪里?” 6以斯帖回答说:“敌人和仇家就是这恶人哈曼!”哈曼在王和王后面前十分惊恐。

7王大怒,离席去了御花园。哈曼见王定意要惩罚他,便留下来求以斯帖王后饶命。 8王从御花园回到席上,见哈曼伏在以斯帖所靠的榻上,便说:“他竟敢在宫中当着我的面侮辱王后吗?”王这话一出口,便有人蒙了哈曼的脸。 9服侍王的太监哈波拿说:“哈曼为那救驾有功的末底改做了一个二十三米高的木架,如今正立在哈曼家里。”王说:“把哈曼吊在上面!” 10于是,哈曼被吊在他为末底改预备的木架上,王的怒气这才平息。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esteri 7:1-10

Síso Hamani rọ̀

1Ọba àti Hamani sì lọ sí àpèjẹ pẹ̀lú Esteri ayaba, 27.2: Mk 6.23.Bí wọ́n sì ṣe ń mu wáìnì ní ọjọ́ kejì yìí, ọba sì tún béèrè pé, “Esteri ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọba à mi, n ó fi fún ọ.”

3Nígbà náà ni ayaba Esteri dáhùn, “Bí èmi bá rí ojúrere rẹ, ìwọ ọba, bí ó bá sì tẹ́ ọláńlá à rẹ lọ́rùn, fún mi ní ẹ̀mí mi, èyí ni ẹ̀bẹ̀ mi. Kí o sì pa àwọn ènìyàn mi mọ́—èyí ni ìbéèrè mi. 4Nítorí a ti ta èmi àti àwọn ènìyàn mi fún àwọn tí yóò pa wá run, à ti ṣe ìdájọ́ wa fún pípa àti píparẹ́. Bí a bá tilẹ̀ tà wá bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ǹ bá dákẹ́, nítorí irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ kò tó èyí tí à ń yọ ọba lẹ́nu sí.”

5Ọba Ahaswerusi bi Esteri ayaba léèrè pé, “Ta a ni ẹni náà? Níbo ni ẹni náà wà tí kò bẹ̀rù láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀?”

6Esteri sọ wí pé, “Alátakò àti ọ̀tá náà ni Hamani aláìníláárí yìí.”

Nígbà náà ni Hamani wárìrì níwájú ọba àti ayaba. 7Ọba sì dìde pẹ̀lú ìbínú, ó fi wáìnì sílẹ̀ ó sì jáde lọ sí àgbàlá ààfin. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hamani, ti rí i dájú pé ọba ti pinnu láti pa òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ Esteri ayaba nítorí ẹ̀mí rẹ̀.

8Bí ọba ṣe padà dé láti àgbàlá ààfin wá sí gbọ̀ngàn àsè náà, Hamani ṣubú sórí àga tí Esteri ayaba fẹ̀yìn tì.

Ọba sì pariwo pé, “Yóò ha tún tẹ́ ayaba níbí yìí, nínú ilé, ní ojú mi bí?”

Ní kété tí ọba sọ ọ̀rọ̀ yìí jáde, wọ́n da aṣọ bo Hamani lójú. 9Nígbà náà Harbona ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà tó ń dúró níwájú ọba, sọ wí pé, “igi tí ó ga tó ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà marunlélaadọrin ni Hamani ti rì sí ẹ̀gbẹ́ ilé e rẹ̀. Ó ṣe é fún Mordekai, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọba.”

Ọba wí pé, ẹ so ó rọ̀ sórí i rẹ́! 10Wọ́n sì so Hamani sórí igi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún Mordekai, ìbínú ọba sì rọ̀.