Chinese Contemporary Bible (Simplified)

撒迦利亚书 11:1-17

羊群必遭杀戮

1黎巴嫩啊,打开你的门吧,

好让火焰吞噬你的香柏树。

2松树啊,哀号吧,

因为香柏树已经倒下,

挺拔的树木已被毁坏。

巴珊的橡树啊,哀号吧,

因为茂密的树林已被砍倒。

3听啊,牧人在哀号,

因为他们肥美的草场已被毁坏。

听啊,狮子在吼叫,

因为约旦河畔的丛林已被毁坏。

4我的上帝耶和华说:“你去牧养这群待宰的羊吧。 5买羊宰羊的不受惩罚,卖羊的说,‘耶和华当受称颂!我发财了。’它们的牧人不怜悯它们。 6因此,我不再怜悯这地方的居民,我要使他们落在邻人及其君王手中,任这地方被摧毁,必不从敌人手中拯救他们。这是耶和华说的。”

7于是,我牧养这群最困苦的待宰之羊。我拿了两根杖,一根叫“恩惠”,一根叫“联合”,开始牧养羊群。 8我在一个月之内除掉了三个牧人。

然而,我厌烦羊群,他们也厌恶我。 9于是我说:“我不再牧养你们了。要死的就死吧,要灭亡的就灭亡吧,让剩下的互相吞吃吧。” 10然后,我拿起那根叫“恩惠”的杖,把它折断,以废除我与万民所立的约。 11约就在当天废除了,那些注视着我的困苦羊便知道这是上帝的话。

12我对他们说:“你们若认为好,就给我工钱,不然就算了。”于是,他们给了我三十块银子作工钱。 13耶和华对我说:“把这一大笔钱丢给窑户吧,这就是我在他们眼中的价值!”我便把三十块银子丢给圣殿中的窑户。 14我又把那根叫“联合”的杖折断,以断开犹大以色列之间的手足之情。

15耶和华又对我说:“你再拿起愚昧牧人的器具, 16因为我要使一位牧人在地上兴起,他不照顾丧亡的,不寻找失散的,不医治受伤的,不牧养健壮的,反而吃肥羊的肉,撕掉它们的蹄子。

17“丢弃羊群的无用牧人有祸了!

愿刀砍在他的臂膀和右眼上!

愿他的臂膀彻底枯槁,

他的右眼完全失明!”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Sekariah 11:1-17

1Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ sílẹ̀, ìwọ Lebanoni,

kí iná bá lè jẹ igi kedari rẹ run,

2Hu, igi junifa; nítorí igi kedari ṣubú,

nítorí tí a ba àwọn igi tí o lógo jẹ́:

hu, ẹ̀yin igi óákù tí Baṣani,

nítorí gé igbó àjàrà lulẹ̀.

3Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn;

ògo wọn bàjẹ́;

gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìún

nítorí ògo Jordani bàjẹ́.

Olùṣọ́-àgùntàn méjì

4Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run mi wí: “Bọ́ ọ̀wọ́ ẹran àbọ́pa. 5Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi: àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, ‘Ìbùkún ni fún Olúwa, nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀!’ Àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn. 6Nítorí èmi kì yóò ṣàánú fún àwọn ara ilẹ̀ náà mọ́,” ni Olúwa wí, “Ṣí kíyèsi í, èmi yóò fi olúkúlùkù ènìyàn lé aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ ọba rẹ̀, wọn yóò sì fọ́ ilẹ̀ náà, èmi kì yóò sì gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn.”

7Èmi yóò sì bọ́ ẹran àbọ́pa, àní ẹ̀yin òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran. Mo sì mu ọ̀pá méjì sọ́dọ̀; mo pè ọ̀kan ni Oore-ọ̀fẹ́, mo pè èkejì ni Àmùrè; mo sì bọ́ ọ̀wọ́ ẹran náà. 8Olùṣọ́-àgùntàn mẹ́ta ni mo sì gé kúrò ní oṣù kan.

Ọkàn mi sì kórìíra wọn, ọkàn wọn pẹ̀lú sì kórìíra mi. 9Mo sì wí pé, “Èmi kì yóò bọ́ yin: èyí ti ń ku lọ, jẹ́ kí òkú o kú; èyí tí a o ba sì gé kúrò, jẹ́ kí a gé e kúrò; ki olúkúlùkù nínú àwọn ìyókù jẹ́ ẹran-ara ẹnìkejì rẹ̀.”

10Mo sì mu ọ̀pá mi, ti a ń pè ní Oore-ọ̀fẹ́, mo ṣẹ́ si méjì, ki èmi bá lè da májẹ̀mú mi tí mo tí bá gbogbo àwọn ènìyàn náà dá. 11Ó sì dá ni ọjọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran náà tí ó dúró tì mí mọ̀ pé, ọ̀rọ̀ Olúwa ni.

1211.12-13: Mt 26.15; 27.9.Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó ọ̀yà mi.

13Olúwa sì wí fún mi pé, “Sọ ọ sí amọ̀kòkò.” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owó fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìṣúra ní ilé Olúwa.

14Mo sì ṣẹ́ ọ̀pá mi kejì, àní Àmùrè, sí méjì, kí èmi lè ya ìbátan tí ó wà láàrín Juda àti láàrín Israẹli.

15Olúwa sì wí fún mi pé, “Tún mú ohun èlò aṣiwèrè olùṣọ́-àgùntàn kan sọ́dọ̀ rẹ̀. 16Nítorí Èmi o gbé olùṣọ́-àgùntàn kan dìde ni ilẹ̀ náà, tí kí yóò bẹ àwọn tí ó ṣègbé wò, ti kì yóò sì wá èyí tí ó yapa; tí kì yóò ṣe ìtọ́jú èyí tí a pa lára tàbí kí ó bọ́ àwọn tí ara wọn dá pépé: Ṣùgbọ́n òun yóò jẹ ẹran èyí tí ó ni ọ̀rá, àwọn èyí tiwọn fi èékánná wọn ya ara wọn pẹ́rẹpẹ̀rẹ.

17“Ègbé ni fún olùṣọ́-àgùntàn asán náà,

tí ó fi ọ̀wọ́ ẹran sílẹ̀!

Idà yóò gé apá rẹ̀ àti ojú ọ̀tún rẹ̀:

apá rẹ̀ yóò gbẹ pátápátá,

ojú ọ̀tún rẹ̀ yóò sì fọ́ pátápátá!”