Chinese Contemporary Bible (Simplified)

传道书 10

1死苍蝇会使芬芳的膏油发臭,
同样,一点点愚昧足以毁掉智慧和尊荣。
智者的心引导他走正路,
愚人的心带领他入歧途。[a]
愚人走路时也无知,
并向众人显出他的愚昧。
如果当权的人向你大发雷霆,
不要因此就离开岗位,
因为平心静气能避免大错。
我发现日光之下有一件可悲的事,
似乎是掌权者所犯的错误:
愚人身居许多高位,
富人却屈居在下。
我曾看见奴仆骑在马上,
王子却像奴仆一样步行。
挖掘陷阱的,自己必掉在其中;
拆围墙的,必被蛇咬;
开凿石头的,必被砸伤;
劈木头的,必有危险。
10 斧头钝了若不磨利,
用起来必多费力气,
但智慧能助人成功。
11 弄蛇人行法术之前,
若先被蛇咬,
行法术还有什么用呢?
12 智者口出恩言,
愚人的话毁灭自己。
13 愚人开口是愚昧,
闭口是邪恶狂妄。
14 愚人高谈阔论,
其实无人知道将来的事,
人死后,谁能告诉他世间的事呢?
15 愚人因劳碌而筋疲力尽,
连进城的路也认不出来。
16 一国之君若年幼无知,
他的臣宰从早到晚只顾宴乐,
那国就有祸了!
17 一国之君若英明尊贵,
他的臣宰为了强身健体而节制饮食,
不酗酒宴乐,那国就有福了!
18 屋顶因人懒惰而坍塌,
房间因人游手好闲而漏雨。
19 宴席带来欢笑,
酒使人开怀,
钱使人万事亨通。
20 不可咒诅君王,
连这样的意念都不可有,
也不可在卧室里咒诅富豪,
因为天空的飞鸟会通风报信,
有翅膀的会把事情四处传开。

Notas al pie

  1. 10:2 这一节希伯来文是“智者的心在右,愚人的心在左。”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Oniwaasu 10

1Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún òróró ìkunra ní òórùn búburú,
    bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀.
Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa ṣí sí ohun tí ó tọ̀nà,
    ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ sí ohun tí kò dára.
Kódà bí ó ti ṣe ń rìn láàrín ọ̀nà,
    òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́n
    a sì máa fihan gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó.
Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ,
    ma ṣe fi ààyè rẹ sílẹ̀;
    ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ le è tú àṣìṣe ńlá.

Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn,
    irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso.
A gbé aṣiwèrè sí ọ̀pọ̀ ipò tí ó ga jùlọ,
    nígbà tí ọlọ́rọ̀ gba àwọn ààyè tí ó kéré jùlọ.
Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin,
    nígbà tí ọmọ-aládé ń fi ẹsẹ̀ rìn bí ẹrú.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀;
    ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán an.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbe òkúta le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn;
    ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn.

10 Bí àáké bá kú
    tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́n;
yóò nílò agbára púpọ̀
    ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá.

11 Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀,
    kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.

12 Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́
    ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnrarẹ̀ ni yóò parun.
13 Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀;
    ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìsínwín búburú.
14     Wèrè a sì máa ṣàfikún ọ̀rọ̀.

Kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ó ń bọ̀
    ta ni ó le è sọ fún un ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀?

15 Iṣẹ́ aṣiwèrè a máa dá a lágara
    kò sì mọ ojú ọ̀nà sí ìlú.

16 Ègbé ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ tí ọba ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀
    àti tí àwọn ọmọ-aládé ń ṣe àsè ní òwúrọ̀.
17 Ìbùkún ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ èyí tí ọba rẹ̀ jẹ́
    ọmọ ọlọ́lá, àti tí àwọn ọmọ-aládé ń jẹun ní àsìkò tí ó yẹ,
    fún ìlera, tí kì í ṣe fún ìmutípara.

18 Bí ènìyàn bá ń lọ́ra, àjà ilé a máa jì
    bí ọwọ́ rẹ̀ bá ń ṣe ọ̀lẹ, ilé a máa jó.

19 Ẹ̀rín rínrín ni a ṣe àsè fún,
    wáìnì a máa mú ayé dùn,
    ṣùgbọ́n owó ni ìdáhùn sí ohun gbogbo.

20 Ma ṣe bú ọba, kódà nínú èrò rẹ,
    tàbí kí o ṣépè fún ọlọ́rọ̀ ní ibi ibùsùn rẹ,
nítorí pé ẹyẹ ojú ọ̀run le è gbé ọ̀rọ̀ rẹ
    ẹyẹ tí ó sì ní ìyẹ́ apá le è fi ẹjọ́ ohun tí o sọ sùn.