4 Царств 24 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

4 Царств 24:1-20

1Во время царствования Иоакима в страну вторгся царь Вавилона Навуходоносор24:1 Навуходоносор II, самый великий царь Нововавилонской империи, правил с 605 по 562 гг. до н. э., и Иоаким стал подвластным ему на три года, но потом передумал и восстал против Навуходоносора. 2Вечный насылал на Иоакима вавилонских, сирийских, моавских и аммонитских разбойников. Он посылал их губить Иудею, по слову Вечного, сказанному Его рабами пророками. 3Конечно, всё это произошло с Иудеей по воле Вечного, чтобы удалить их от Него из-за грехов Манассы и всего, что тот сделал, 4в том числе и за невинную кровь. Ведь он наполнил Иерусалим невинной кровью, и Вечный не желал прощать.

5Прочие события царствования Иоакима и всё, что он сделал, записано в «Книге летописей царей Иудеи». 6Иоаким упокоился со своими предками. И царём вместо него стал его сын Иехония.

7Царь Египта не выходил больше из своей страны, потому что царь Вавилона захватил все его земли от речки на границе Египта до реки Евфрат.

Иехония – царь Иудеи

(2 Лет. 36:9-10)

8Иехонии было восемнадцать лет, когда он стал царём, и правил он в Иерусалиме три месяца. Его мать звали Нехушта, она была дочерью Элнафана, родом из Иерусалима. 9Иехония делал зло в глазах Вечного, во всём уподобляясь своему отцу.

10В то время военачальники Навуходоносора, царя Вавилона, двинулись на Иерусалим и осадили город. 11Сам Навуходоносор подошёл к городу, когда его осаждали военачальники. 12И Иехония, царь Иудеи, вместе с матерью, приближёнными, полководцами и придворными сдался ему.

На восьмом году своего правления царь Вавилона взял Иехонию в плен. 13Как и говорил Вечный, Навуходоносор забрал все сокровища из храма Вечного и из царского дворца и порубил на куски всю золотую утварь, которую сделал для храма Вечного царь Исроила Сулаймон. 14Он увёл в плен весь Иерусалим: всех полководцев и воинов, всех ремесленников и кузнецов – десять тысяч человек общим счётом. Оставлен был лишь бедный люд страны. 15Навуходоносор увёл Иехонию пленным в Вавилон. Он увёл из Иерусалима в Вавилон мать царя, его жён, его придворных и знатных людей страны. 16Ещё царь Вавилона привёл пленниками в Вавилон всё войско из семи тысяч воинов, сильных и готовых к бою, и тысячи ремесленников и кузнецов. 17Он сделал Маттанию, дядю Иехонии, царём вместо него и дал ему новое имя – Цедекия.

Цедекия – царь Иудеи

(2 Лет. 36:11-14; Иер. 52:1-3)

18Цедекии был двадцать один год, когда он стал царём, и правил он в Иерусалиме одиннадцать лет. Его мать звали Хамуталь, она была дочерью Иеремии из Ливны. 19Цедекия делал зло в глазах Вечного, во всём уподобляясь Иоакиму. 20Иерусалим и Иудея так разгневали Вечного, что Он прогнал их от Себя.

Падение Иерусалима

(2 Лет. 36:15-20; Иер. 39:1-10; 52:4-27)

Цедекия восстал против царя Вавилона.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 24:1-20

1Nígbà ìjọba Jehoiakimu, Nebukadnessari ọba Babeli gbógun sí ilẹ̀ náà, Jehoiakimu sì di ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà náà ó yí ọkàn rẹ̀ padà ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadnessari. 2Olúwa sì rán àwọn ará Babeli, àwọn ará Aramu, àwọn ará Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni. Ó rán wọn láti pa Juda run, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì. 3Nítòótọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ sí Juda gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, láti mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Manase àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe. 4Àti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí a ta sílẹ̀ nítorí ó ti kún Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí Olúwa kò sì fẹ́ láti dáríjì.

5Ní ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ọba Juda? 6Jehoiakimu sùn pẹ̀lú baba rẹ̀, Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

7Ọba Ejibiti kò sì tún jáde ní ìlú rẹ̀ mọ́, nítorí ọba Babeli ti gba gbogbo agbègbè rẹ̀ láti odò Ejibiti lọ sí odò Eufurate.

Jehoiakini ọba Juda

824.8-17: 2Ki 36.9-10.Jehoiakini jẹ́ ẹni ọdún méjì-dínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Nehuṣita ọmọbìnrin Elnatani; ó wá láti Jerusalẹmu. 9Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe.

10Ní àkókò náà àwọn ìránṣẹ́ Nebukadnessari ọba Babeli gbé ogun wá Jerusalẹmu, wọ́n sì gbé dó ti ìlú náà, 11Nebukadnessari ọba Babeli fúnrarẹ̀ wá sókè sí ìlú nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ fi ogun dó tì í. 12Jehoiakini ọba Juda àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn ìjòyè gbogbo wọn sì jọ̀wọ́ ara wọn fún un.

Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀ ti ọba Babeli ó mú Jehoiakini ẹlẹ́wọ̀n. 13Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Nebukadnessari kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé Olúwa àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún Olúwa. 14Ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn gbogbo Jerusalẹmu: gbogbo ìjòyè àti àwọn akọni alágbára ọkùnrin, àti gbogbo oníṣọ̀nà àti ọlọ́nà tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbàárùn-ún ún, àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà nìkan ni ó kù.

15Nebukadnessari mú Jehoiakini ní ìgbèkùn lọ sí Babeli. Ó sì tún mú ìyá ọba láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, ìyàwó rẹ̀ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn olórí ilé náà. 16Àti gbogbo àwọn ọkùnrin ọlọ́lá tí ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) alágbára ọkùnrin, àti àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ, ẹgbẹ̀rún (1,000), gbogbo àwọn alágbára tí ó yẹ fún ogun ni ọba Babeli kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli 17Ọba Babeli sì mú Mattaniah arákùnrin baba Jehoiakini, jẹ ọba ní ìlú rẹ̀ ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Sedekiah.

Sedekiah ọba Juda

1824.18–25.21: 2Ki 36.11-21; Jr 52.1-27.Sedekiah jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlá. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali ọmọbìnrin Jeremiah; ó sì wá láti Libina. 19Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe. 20Nítorí tí ìbínú Olúwa, ni gbogbo èyí ṣe ṣẹ sí Jerusalẹmu, àti Juda, ní òpin ó ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.

Ìṣubú Jerusalẹmu

Nísinsin yìí Sedekiah sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babeli.