4 Царств 13 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

4 Царств 13:1-25

Иоахаз – царь Исроила

1На двадцать третьем году правления иудейского царя Иоаша, сына Охозии, царём Исроила стал Иоахаз, сын Иеву, и правил в Сомарии семнадцать лет. 2Он делал зло в глазах Вечного, следуя грехам Иеровоама, сына Невата, к которым тот склонил Исроил, и не отворачивался от них. 3Гнев Вечного вспыхнул на Исроил, и долгое время Он держал их во власти Хазаила, царя Сирии, и его сына Бен-Адада13:3 Это Бен-Адад III, правивший Сирией в начале VIII в. до н. э..

4Но Иоахаз взмолился Вечному, и Вечный услышал его, ведь Он видел, как жестоко царь Сирии притесняет Исроил. 5Вечный дал Исроилу избавителя, и Исроил вышел из-под власти Сирии. Исроильтяне стали жить в мире, как и прежде. 6И всё же они не отвернулись от грехов дома Иеровоама, к которым тот склонил Исроил, но оставались в них. Да и столб Ашеры13:6 Столб Ашеры – культовый символ вавилонско-ханонской богини Ашеры. Ашера считалась матерью богов и людей, владычицей моря и всего сущего. продолжал стоять в Сомарии.

7От войска Иоахаза не осталось ничего, кроме пятидесяти всадников, десяти колесниц и десяти тысяч пеших воинов, потому что царь Сирии истребил остальных, уподобив их пыли во время молотьбы.

8Прочие события царствования Иоахаза, всё, что он сделал, и его свершения записаны в «Книге летописей царей Исроила». 9Иоахаз упокоился со своими предками и был похоронен в Сомарии. И царём вместо него стал его сын Иоаш.

Иоаш – царь Исроила

10На тридцать седьмом году правления Иоаша, царя Иудеи, царём Исроила стал Иоаш, сын Иоахаза, и правил в Сомарии шестнадцать лет. 11Он делал зло в глазах Вечного и не отвернулся ни от одного из грехов Иеровоама, сына Невата, к которым тот склонил Исроил. Он оставался в них.

12Прочие события царствования Иоаша, всё, что он сделал, и его свершения, включая войну против Амасии, царя Иудеи, записаны в «Книге летописей царей Исроила».

13Иоаш упокоился со своими предками, и Иеровоам сменил его на престоле. Иоаш был похоронен в Сомарии с царями Исроила.

Смерть Елисея

14Елисей был смертельно болен. Иоаш, царь Исроила, пришёл навестить его и плакал над ним.

– Отец мой! Отец мой! – восклицал он. – Колесница и конница Исроила!

15Елисей сказал:

– Достань лук и стрелы, – и он сделал это.

16– Возьми лук в руки, – сказал он царю Исроила.

Когда тот взял лук, Елисей положил руки на руки царя Исроила.

17– Открой восточное окно, – сказал он, и тот открыл его.

– Стреляй! – сказал Елисей, и тот выстрелил.

– Стрела победы Вечного, стрела победы над Сирией! – сказал Елисей. – Ты будешь бить сирийцев при городе Афеке, пока не разобьёшь их.

18Затем он сказал:

– Возьми стрелы, – и царь взял их.

Елисей сказал ему:

– Бей ими по земле.

Он ударил три раза и остановился.

19Пророк разгневался на него и сказал:

– Ты должен был бы ударить по земле пять или шесть раз, тогда ты побил бы Сирию полностью. А теперь ты разобьёшь её только три раза.

20Елисей умер и был похоронен.

Позже разбойники из Моава повадились вторгаться в страну каждую весну. 21Однажды во время похорон одного человека исроильтяне увидели банду разбойников и бросили покойника в гробницу Елисея. Когда мёртвое тело коснулось костей Елисея, тот человек ожил и встал на ноги.

Исполнение последнего пророчества Елисея

22Хазаил, царь Сирии, притеснял Исроил во все дни царствования Иоахаза. 23Но Вечный был милостив к ним, жалел их и заботился о них ради священного соглашения с Иброхимом, Исхоком и Якубом. Он и теперь не хотел истребить их или прогнать от Себя.

24Хазаил, царь Сирии, умер, и его сын Бен-Адад стал царём вместо него. 25И Иоаш, сын Иоахаза, отнял у Бен-Адада, сына Хазаила, те города, которые тот отвоевал у его отца Иоахаза. Три раза Иоаш разбивал его и возвращал исроильские города.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 13:1-25

Jehoahasi ọba Israẹli

1Ní ọdún kẹtàlélógún ti Joaṣi ọmọ ọba Ahasiah ti Juda, Jehoahasi ọmọ Jehu di ọba Israẹli ní Samaria. Ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́tà-dínlógún. 2Ó ṣe búburú níwájú Olúwa nípa títẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá, kò sì yípadà kúrò nínú wọn. 3Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Israẹli, àti fún ìgbà pípẹ́, ó fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ agbára ọba Hasaeli ọba Siria àti Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀.

4Nígbà náà Jehoahasi kígbe ó wá ojúrere Olúwa, Olúwa sì tẹ́tí sí i. Nítorí ó rí bí ọba Siria ti ń ni Israẹli lára gidigidi. 5Olúwa pèsè Olùgbàlà fún Israẹli, wọ́n sì sá kúrò lọ́wọ́ agbára Siria. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli gbé nínú ilé ara wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀. 6Ṣùgbọ́n wọn kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jeroboamu, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá, wọ́n tẹ̀síwájú nínú rẹ̀, ère òrìṣà Aṣerah sì wà síbẹ̀ ní Samaria pẹ̀lú.

7Kò sí ohùn kan tí wọ́n fi sílẹ̀ ní ti ọmọ-ogun Jehoahasi àyàfi àádọ́ta ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, kẹ̀kẹ́ mẹ́wàá, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣẹ̀, nítorí ọba Siria ti pa ìyókù run, ó sì ṣe wọ́n bí eruku nígbà pípa ọkà.

8Fún ti ìyókù ìṣe Jehoahasi fún ìgbà, tí ó fi jẹ ọba, gbogbo ohun tí ó ṣe àti àṣeyọrí rẹ̀ ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli? 9Jehoahasi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sí Samaria. Jehoaṣi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Jehoaṣi ọba Israẹli

10Ní ọdún kẹtà-dínlógójì tí Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi di ọba Israẹli ní Samaria ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́rìn-dínlógún. 11Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati èyí tí ó ti ti Israẹli láti fà. Ó sì tẹ̀síwájú nínú wọn.

12Fún ti ìyókù iṣẹ́ Jehoaṣi fún ìgbà tí ó fi jẹ ọba, gbogbo ohun tí ó ṣe, pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀ pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Amasiah ọba Juda, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli? 13Jehoaṣi sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. Jeroboamu sì rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́. A sin Jehoaṣi sí Samaria pẹ̀lú àwọn ọba Israẹli.

14Nísinsin yìí, Eliṣa ń jìyà lọ́wọ́ àìsàn, lọ́wọ́ èyí tí ó sì kú. Jehoaṣi ọba Israẹli lọ láti lọ wò ó, ó sì sọkún lórí rẹ̀. “Baba mi! Baba mi!” Ó sọkún. “Àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin Israẹli!”

15Eliṣa wí pé, “Mú ọrun kan àti àwọn ọfà,” ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. 16“Mú ọrun ní ọwọ́ rẹ.” Ó wí fún ọba Israẹli. Nígbà tí ó ti mú u, Eliṣa mú ọwọ́ rẹ̀ lé ọwọ́ ọba.

17“Ṣí fèrèsé apá ìlà-oòrùn,” ó wí, pẹ̀lú ó sì ṣí i: “Ta á!” Eliṣa wí, ó sì ta á. “Ọfà ìṣẹ́gun Olúwa; ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria!” Eliṣa kéde. “Ìwọ yóò pa àwọn ará Siria run pátápátá ní Afeki.”

18Nígbà náà ó wí pé, “Mú àwọn ọfà náà,” ọba sì mú wọn. Eliṣa wí fún un pé, “Lu ilẹ̀.” Ó lù ú lẹ́ẹ̀mẹ́ta, ó sì dáwọ́ dúró. 19Ènìyàn Ọlọ́run sì bínú sí i, ó sì wí pé, “Ìwọ kò bá ti lu ilẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀márùnún tàbí ní ẹ̀ẹ̀mẹ́fà; Nígbà náà, ìwọ kò bá ti ṣẹ́gun Siria àti pa á run pátápátá ṣùgbọ́n Nísinsin yìí ìwọ yóò ṣẹ́gun rẹ̀ ní ẹ̀mẹ́ta péré.”

20Eliṣa kú a sì sin ín.

Ẹgbẹ́ Àwọn ará Moabu máa ń wọ orílẹ̀-èdè ní gbogbo àmọ́dún. 21Bí àwọn ọmọ Israẹli kan ti ń sin òkú ọkùnrin kan, lójijì wọ́n rí ẹgbẹ́ àwọn oníjadì: Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Eliṣa. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan egungun Eliṣa, ó padà wá sí ayé, ó sì dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀.

22Hasaeli ọba Siria ni Israẹli lára ní gbogbo àkókò tí Jehoahasi fi jẹ ọba. 23Ṣùgbọ́n Olúwa ṣàánú fún wọn ó sì ní ìyọ́nú, ó sì fiyèsí wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu. Títí di ọjọ́ òní, kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti pa wọ́n run tàbí lé wọn lọ níwájú rẹ̀.

24Hasaeli ọba Siria kú, Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 25Nígbà náà, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi gbà padà kúrò lọ́wọ́ Beni-Hadadi ọmọ Hasaeli àwọn ìlú tí ó ti gbà nínú ogun látọ̀dọ̀ baba rẹ̀ Jehoahasi. Ní ẹ̀ẹ̀mẹta, Jehoaṣi ṣẹ́gun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó gba ìlú àwọn ọmọ Israẹli padà.