3 Царств 17 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

3 Царств 17:1-24

Ильёс предсказывает засуху

1Ильёс из Тишбы, что в Галааде, сказал Ахаву:

– Верно, как и то, что жив Вечный, Бог Исроила, Которому я служу, – в эти годы не будет ни росы, ни дождя, разве только по моему слову.

2И к Ильёсу было слово Вечного:

3– Уходи отсюда, иди на восток и спрячься у реки Керит, что к востоку от Иордана. 4Из реки ты будешь пить, а кормить тебя Я повелел во́ронам.

5И он сделал, как сказал ему Вечный. Он пошёл к реке Керит, что к востоку от Иордана, и остался там. 6Вороны приносили ему хлеб и мясо утром и вечером, а пил он из реки.

Ильёс и вдова из Сарепты

7Через некоторое время река пересохла, потому что в стране не было дождя. 8Тогда к пророку было слово Вечного:

9– Теперь ступай в Сарепту17:9 Сарепта – финикийский город, находившийся на территории современного государства Ливан. А значит пророк должен был покинуть пределы Исроила., что близ Сидона, и живи там. Я повелел одной вдове кормить тебя.

10И он пошёл в Сарепту. Когда он подошёл к воротам города, там была вдова, которая собирала дрова. Он позвал её и сказал:

– Принеси мне в сосуде немного воды попить.

11Когда она пошла, он окликнул её и сказал:

– Принеси мне и кусок хлеба.

12– Верно, как и то, что жив Вечный, твой Бог, – ответила она, – у меня нет хлеба – лишь пригоршня муки в кадке да немного масла в кувшине. Вот возьму пару поленьев и пойду, приготовлю из этой муки еду для себя и для сына. Съедим это, а потом умрём.

13Ильёс сказал ей:

– Не бойся. Иди домой и сделай так, как сказала. Но сперва сделай для меня из того, что у тебя есть, маленькую лепёшку и принеси мне, а потом приготовь что-нибудь для себя и своего сына. 14Ведь так говорит Вечный, Бог Исроила: «Мука в кадке не переведётся и масло в кувшине не кончится до того дня, когда Вечный пошлёт на землю дождь».

15Она пошла и сделала так, как сказал ей Ильёс. И каждый день у неё, у Ильёса и у её семьи была пища. 16Мука в кадке не переводилась и масло в кувшине не кончалось – по слову Вечного, сказанному Ильёсом.

Воскрешение сына вдовы

17Через некоторое время сын той женщины, хозяйки дома, заболел. Ему становилось всё хуже и хуже, и наконец он перестал дышать. 18Тогда она сказала Ильёсу:

– Что у тебя против меня, человек Всевышнего? Ты пришёл, чтобы напомнить мне о моём грехе и убить моего сына?

19– Дай мне своего сына, – ответил ей Ильёс.

Он взял его у неё из рук, отнёс в верхнюю комнату, где он жил, и положил его на постель. 20Затем он воззвал к Вечному:

– Вечный, Бог мой, неужели Ты наведёшь беду и на вдову, у которой я живу, умертвив её сына?

21Он простирался над мальчиком трижды и взывал к Вечному:

– Вечный, Бог мой, пусть жизнь этого мальчика вернётся к нему!

22Вечный услышал мольбу Ильёса, и жизнь мальчика вернулась к нему, и он ожил. 23Ильёс взял мальчика и отнёс его вниз из своей комнаты в дом. Он отдал его матери и сказал:

– Смотри, твой сын жив!

24Женщина сказала Ильёсу:

– Теперь я знаю, что ты пророк и что слово Вечного, сказанное тобой, истинно.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Ọba 17:1-24

Elijah kéde ọ̀dá

117.1: If 11.6.Elijah ará Tiṣibi láti Tiṣbi ní Gileadi wí fún Ahabu pé, “Bí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, kì yóò sí ìrì tàbí òjò ní ọdún díẹ̀ tí ń bọ̀ bí kò ṣe nípa ọ̀rọ̀ mi.”

2Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Elijah wá pé: 3“Kúrò níhìn-ín, kọjú sí ìhà ìlà-oòrùn, kí o sì fi ara rẹ pamọ́ níbi odò Keriti, tí ń bẹ níwájú Jordani. 4Ìwọ yóò mu nínú odò náà, mo sì ti pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò láti máa bọ́ ọ níbẹ̀.”

5Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un. Ó sì lọ sí ẹ̀bá odò Keriti, tí ń bẹ níwájú Jordani, ó sì dúró síbẹ̀. 6Àwọn ẹyẹ ìwò sì mú àkàrà àti ẹran wá fún un ní òwúrọ̀, àti àkàrà àti ẹran ní alẹ́, ó sì ń mu nínú odò náà.

Elijah àti opó Sarefati

7Ó sì ṣe lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, odò náà sì gbẹ nítorí kò sí òjò ní ilẹ̀ náà. 817.8-16: Lk 4.25,26.Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá wí pé: 9“Lọ nísinsin yìí sí Sarefati ti Sidoni, kí o sì dúró síbẹ̀. Èmi ti pàṣẹ fún obìnrin opó kan níbẹ̀ láti máa bọ́ ọ.” 10Bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sí Sarefati. Nígbà tí ó sì dé ibodè ìlú náà, obìnrin opó kan ń ṣa igi jọ níbẹ̀. Ó sì ké sí i, ó sì béèrè pé, “Ǹjẹ́ o lè bu omi díẹ̀ fún mi wá nínú ohun èlò kí èmi kí ó lè mu?” 11Bí ó sì ti ń lọ bù ú wá, ó ké sí i pé, “Jọ̀ ọ́, mú òkèlè oúnjẹ díẹ̀ fún mi wá lọ́wọ́ rẹ.”

12Obìnrin opó náà sì dá a lóhùn wí pé, “Bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti wà, èmi kò ní àkàrà: bí kò ṣe ìkúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìkòkò àti òróró díẹ̀ nínú kólòbó. Èmi ń ṣa igi díẹ̀ jọ láti kó lọ ilé, kí èmi kí ó sì pèsè rẹ̀ fún mi àti fún ọmọ mi, kí àwa lè jẹ ẹ́: kí a sì kú.”

13Elijah sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Lọ, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí. Ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ṣe àkàrà kékeré kan fún mi nínú rẹ̀ ná, kí o sì mú fún mi wá, lẹ́yìn náà, kí o ṣe tìrẹ àti ti ọmọ rẹ. 14Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Ìkòkò ìyẹ̀fun náà kì yóò ṣófo, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró náà kì yóò gbẹ, títí di ọjọ́ tí Olúwa yóò rọ òjò sí orí ilẹ̀.’ ”

15Ó sì lọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Elijah ti sọ fún un. Oúnjẹ sì wà fún Elijah àti obìnrin náà àti ilé rẹ̀ ní ojoojúmọ́. 16Nítorí ìkòkò ìyẹ̀fun náà kò ṣófo, kólòbó òróró náà kò gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti ipa Elijah sọ.

17Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọmọ obìnrin tí ó ni ilé náà ṣe àìsàn, àìsàn náà sì le tó bẹ́ẹ̀, tí ó fi kú. 1817.18: Mt 8.29; Mk 1.24; Jh 2.4.Obìnrin náà sì wí fún Elijah pé, “Kí lo ní sí mi, ènìyàn Ọlọ́run? Ìwọ ha tọ̀ mí wá láti mú ẹ̀ṣẹ̀ mi wá sí ìrántí, àti láti pa mí ní ọmọ?”

19Elijah sì wí fún un pé, “Gbé ọmọ rẹ fún mi.” Ó sì yọ ọ́ jáde ní àyà rẹ̀, ó sì gbé e lọ sí iyàrá òkè ilé níbi tí òun ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn tirẹ̀. 20Nígbà náà ni ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ ha mú ibi wá bá opó náà pẹ̀lú lọ́dọ̀ ẹni tí èmi ń ṣe àtìpó, nípa pípa ọmọ rẹ̀?” 21Nígbà náà ni ó sì na ara rẹ̀ lórí ọmọdé náà ní ẹ̀ẹ̀mẹta, ó sì ké pe Olúwa pé, “Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọdé yìí kí ó tún padà tọ̀ ọ́ wá!”

22Olúwa sì gbọ́ igbe Elijah, ẹ̀mí ọmọdé náà sì tún padà tọ̀ ọ́ wá, ó sì sọjí. 23Elijah sì mú ọmọdé náà, ó sì gbé e sọ̀kalẹ̀ láti inú yàrá òkè náà wá sínú ilé. Ó sì fi lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́; Elijah sì wí pé, “Wò ó, ọmọ rẹ yè!”

24Obìnrin náà sì wí fún Elijah pé, “Nísinsin yìí mo mọ̀ pé ènìyàn Ọlọ́run ni ìwọ ń ṣe, àti pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa ní ẹnu rẹ.”