3 Царств 14 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

3 Царств 14:1-31

Пророчество Ахии против дома Иеровоама

1В то время Авия, сын Иеровоама, заболел, 2и Иеровоам сказал жене:

– Пойди переоденься, чтобы в тебе нельзя было узнать жену Иеровоама. Потом иди в Шило. Там есть пророк Ахия – тот, кто сказал, что я стану царём этого народа. 3Возьми с собой десять хлебов, несколько лепёшек, кувшин мёда и иди к нему. Он скажет тебе, что будет с мальчиком.

4Жена Иеровоама сделала так, как он говорил, и пошла к дому Ахии в Шило. А Ахия уже не видел, его глаза ослепли от старости. 5Но Вечный сказал Ахии:

– Жена Иеровоама идёт, чтобы спросить тебя о сыне, потому что он заболел. Ответь ей так-то и так-то. Придя, она будет притворяться другой женщиной.

6Когда Ахия услышал у двери звук её шагов, он сказал:

– Входи, жена Иеровоама. Зачем ты притворяешься? У меня для тебя плохие вести. 7Иди, скажи Иеровоаму, что так говорит Вечный, Бог Исроила: «Я возвысил тебя над народом и сделал тебя вождём Моего народа Исроила. 8Я отнял царство у дома Довуда и отдал его тебе, но ты не был подобен Моему рабу Довуду, который исполнял Мои повеления и следовал за Мной от всего сердца, делая лишь то, что правильно в Моих глазах. 9Ты сделал больше зла, чем все, кто жил до тебя. Ты сделал себе других богов, истуканы из металла, вызвав Мой гнев, а ко Мне повернулся спиной. 10Из-за этого Я навожу на твой дом беду. Я истреблю у Иеровоама всякого мужчину – и раба, и свободного. Я буду жечь твой дом, как жгут навоз, пока он не сгорит дотла. 11Тех, кто умрёт у тебя в городе, сожрут псы, а тех, кто умрёт в поле, склюют небесные птицы». Так сказал Вечный!14:10-11 Об исполнении этого пророчества см. 15:29-30.

12А ты возвращайся домой. Когда твоя нога ступит в город, мальчик умрёт. 13Весь Исроил оплачет и похоронит его. Он единственный в доме Иеровоама, кто удостоится погребения потому что он один в его доме, в ком Вечный, Бог Исроила, нашёл что-то доброе.

14Вечный воздвигнет Себе над Исроилом царя, который истребит дом Иеровоама, и это начнётся уже сегодня, и даже сейчас. 15Вечный поразит Исроил, и тот будет как тростник, колеблемый стремительным потоком. Он искоренит Исроил из этой доброй земли, которую Он дал их предкам, и рассеет их за рекой Евфрат, потому что они разгневали Вечного, делая столбы Ашеры14:15 Столбы Ашеры – культовые символы вавилонско-ханонской богини Ашеры. Ашера считалась матерью богов и людей, владычицей моря и всего сущего.. 16Он отдаст Исроил в руки его врагов из-за грехов, которые Иеровоам совершил и к которым он склонил исроильтян.

17Жена Иеровоама встала и пошла в Тирцу. Как только она переступила порог дома, мальчик умер. 18Его похоронили, и весь Исроил оплакивал его, как Вечный и сказал через Своего раба, пророка Ахию.

Смерть Иеровоама

19Прочие события царствования Иеровоама, его войны и то, как он правил, записаны в «Книге летописей царей Исроила». 20Он правил двадцать два года и упокоился со своими предками. И царём вместо него стал его сын Надав.

Реховоам – царь Иудеи

(2 Лет. 12:9-16)

21Реховоам, сын Сулаймона, стал царём в Иудее. Ему был сорок один год, когда он стал царём, и правил он семнадцать лет в Иерусалиме, городе, который Вечный избрал из всех родов Исроила, чтобы пребывать там. Его мать звали Наама, она была аммонитянкой.

22Люди Иудеи делали зло в глазах Вечного. Своими грехами они возбудили Его ревнивый гнев сильнее, чем их отцы. 23Они тоже устроили у себя капища на возвышенностях, священные камни и столбы Ашеры на каждом высоком холме и под каждым тенистым деревом. 24В стране были даже храмовые блудники14:24 Храмовые блудники – имеются в виду мужчины, занимавшиеся культовой проституцией, которая была неотъемлемой частью весьма распространённых в те дни языческих культов плодородия., ведь народ перенял все отвратительные обычаи тех народов, которых Вечный прогнал от исроильтян.

25На пятом году правления царя Реховоама царь Египта Сусаким14:25 Сусаким – фараон Шешонк I, основатель XXII (ливийской) династии, правил с 950 по 929 гг. до н. э. напал на Иерусалим. 26Он унёс сокровища храма Вечного и сокровища царского дворца. Он забрал всё, включая и все золотые щиты, которые сделал Сулаймон. 27Царь Реховоам сделал вместо них щиты из бронзы и вверил их начальникам стражи, что охраняла вход в царский дворец. 28Всякий раз, когда царь шёл в храм Вечного, стража несла щиты, а после возвращала их в комнату стражи.

29Прочие события царствования Реховоама и всё, что он сделал, записано в «Книге летописей царей Иудеи». 30Между Реховоамом и Иеровоамом всё время шла война. 31Реховоам упокоился со своими предками и был похоронен с ними в Городе Довуда. Его мать звали Наама, она была аммонитянкой. И царём вместо него стал его сын Авия.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Ọba 14:1-31

Ahijah sọtẹ́lẹ̀ fún Jeroboamu

1Ní àkókò náà Abijah ọmọ Jeroboamu sì ṣàìsàn, 2Jeroboamu sì wí fún aya rẹ̀ pé, “Lọ, sì pa ara rẹ dà, kí wọn kí ó má ba à mọ̀ ọ́n ní aya Jeroboamu. Nígbà náà ni kí o lọ sí Ṣilo. Ahijah wòlíì wà níbẹ̀; ẹni tí ó sọ fún mi pé, èmi yóò jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn yìí. 3Mú ìṣù àkàrà mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, àti àkàrà wẹ́wẹ́ àti ìgò oyin, kí o sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Òun yóò sì sọ fún ọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin náà.” 4Bẹ́ẹ̀ ni aya Jeroboamu sì ṣe bí ó ti wí, ó sì lọ sí ilé Ahijah ní Ṣilo.

Ahijah kò sì ríran; ojú rẹ̀ ti fọ́ nítorí ogbó rẹ̀. 5Ṣùgbọ́n Olúwa ti sọ fún Ahijah pé, “Kíyèsi i, aya Jeroboamu ń bọ̀ wá béèrè nípa ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí ó ṣàìsàn, báyìí báyìí ni kí ìwọ kí ó wí fún un. Nígbà tí ó bá dé, yóò ṣe ara rẹ̀ bí ẹlòmíràn.”

6Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí, nígbà tí Ahijah sì gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ ní ẹnu-ọ̀nà, ó sì wí pé, “Wọlé wá, aya Jeroboamu. Kí ló dé tí ìwọ fi ṣe ara rẹ bí ẹlòmíràn? A ti fi iṣẹ́ búburú rán mi sí ọ. 7Lọ, sọ fún Jeroboamu pé báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí; Èmi sì gbé ọ ga láti inú àwọn ènìyàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí lórí Israẹli ènìyàn mi. 8Mo fa ìjọba náà ya kúrò ní ilé Dafidi, mo sì fi fún ọ ṣùgbọ́n, ìwọ kò dàbí Dafidi ìránṣẹ́ mi, tí ó pa àṣẹ mi mọ́, tí ó sì tọ̀ mí lẹ́yìn tọkàntọkàn rẹ̀, láti ṣe kìkì èyí tí ó tọ́ ní ojú mi. 9Ìwọ sì ti ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú rẹ lọ. Ìwọ sì ti ṣe àwọn ọlọ́run mìíràn fún ara rẹ, àwọn òrìṣà tí a gbẹ́; o sì ti mú mi bínú, o sì ti gbé mi sọ sí ẹ̀yìn rẹ.

10“ ‘Nítorí èyí, Èmi yóò mú ibi wá sí ilé Jeroboamu. Èmi yóò ké gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ Jeroboamu, àti ọmọ ọ̀dọ̀ àti òmìnira ní Israẹli. Èmi yóò mú ilé Jeroboamu kúrò bí ènìyàn ti ń kó ìgbẹ́ kúrò, títí gbogbo rẹ̀ yóò fi tán. 11Ajá yóò jẹ ẹni Jeroboamu tí ó bá kú ní ìlú, àti ẹni tí ó bá kú ní igbó ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ. Olúwa ti sọ ọ́!’

12“Ní ti ìwọ, padà lọ ilé, nígbà tí o bá sì fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ ìlú, ọmọ náà yóò kú. 13Gbogbo Israẹli yóò sì ṣọ̀fọ̀ fún un, wọn yóò sì sin ín. Òun nìkan ni a ó sì sin nínú ẹni tí ń ṣe ti Jeroboamu, nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ nìkan ni a ti rí ohun rere díẹ̀ sípa Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ní ilé Jeroboamu.

14Olúwa yóò gbé ọba kan dìde fúnrarẹ̀ lórí Israẹli tí yóò ké ilé Jeroboamu kúrò. Ọjọ́ náà nìyìí! Kí ni? Àní nísinsin yìí. 15Olúwa yóò kọlu Israẹli, yóò sì dàbí koríko ti ń mì nínú omi. Yóò sì fa Israẹli tu kúrò ní ilẹ̀ rere yìí, tí ó ti fi fún àwọn baba wọn, yóò sì fọ́n wọn ká kọjá odò Eufurate, nítorí wọ́n ti rú ìbínú Olúwa nípa ṣíṣe ère Aṣerah. 16Yóò sì kọ Israẹli sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu ti ṣẹ̀ àti tí ó mú Israẹli ṣẹ̀.”

17Nígbà náà ni aya Jeroboamu sì dìde, ó sì lọ, ó sì lọ sí Tirsa. Bí ó sì ti fi ẹsẹ̀ tẹ ìloro ilé, ọmọdé náà sì kú. 18Wọ́n sì sin ín, gbogbo Israẹli sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí láti ẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀, Ahijah wòlíì.

19Ìyókù ìṣe Jeroboamu, bí ó ti jagun, àti bí ó ti jẹ ọba, ni a kọ sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli. 20Jeroboamu sì jẹ ọba fún ọdún méjìlélógún, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Nadabu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Rehoboamu ọba Juda

21Rehoboamu ọmọ Solomoni sì jẹ ọba ní Juda. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní ọdún mọ́kànlélógún ní Jerusalẹmu, ìlú tí Olúwa ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Naama, ará Ammoni.

22Juda sì ṣe búburú níwájú Olúwa nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí wọ́n ti dá, wọ́n sì mú u jowú ju gbogbo èyí tí baba wọn ti ṣe lọ. 23Wọ́n sì tún kọ́ ibi gíga fún ara wọn, àti ère òkúta àti òpó Aṣerah lórí gbogbo òkè gíga, àti lábẹ́ gbogbo igi tútù. 24Àwọn tí wọn jẹ́ ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà wà ní ilẹ̀ náà, àwọn ènìyàn náà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli.

2514.25-31: 2Ki 12.1-16.Ó sì ṣe ní ọdún karùn-ún Rehoboamu, Ṣiṣaki ọba Ejibiti kọlu Jerusalẹmu. 26Ó sì kó ìṣúra ilé Olúwa lọ àti ìṣúra ilé ọba. Gbogbo rẹ̀ ni ó kó lọ, pẹ̀lú asà wúrà tí Solomoni ti ṣe. 27Rehoboamu ọba sì ṣe asà idẹ ní ipò wọn, ó sì fi wọ́n sí ọwọ́ olórí àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlẹ̀kùn ilé ọba. 28Nígbàkígbà tí ọba bá sì lọ sí ilé Olúwa Wọ́n á rù wọ́n, wọ́n á sì mú wọn padà sínú yàrá olùṣọ́.

29Ní ti ìyókù ìṣe Rehoboamu, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda bí? 30Ogun sì wà láàrín Rehoboamu àti Jeroboamu ní ọjọ́ wọn gbogbo. 31Rehoboamu sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní Ìlú Dafidi. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Naama; ará Ammoni. Abijah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.