2 Летопись 8 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

2 Летопись 8:1-18

Другие дела Сулаймона

(3 Цар. 9:10-28)

1По истечении двадцати лет, в которые Сулаймон строил храм Вечного и свой дворец, 2Сулаймон отстроил и города, которые дал ему Хирам, и поселил в них исроильтян. 3Затем Сулаймон пошёл к Хамат-Цове и захватил его. 4Ещё он построил Тадмор в пустыне и все города для хранения запасов, которые он основал в Хамате. 5Он заново отстроил Верхний Бет-Хорон и Нижний Бет-Хорон, сделав их городами-крепостями со стенами и воротами на засовах. 6Он также отстроил Баалат, все другие города для хранения запасов и все города для своих колесниц и коней8:6 Или: «колесничих»; или: «всадников».. Сулаймон построил всё, что ему хотелось построить в Иерусалиме, на Ливане и во всех землях, которыми он правил.

7-8Оставшихся в стране неисроильтян – потомков хеттов, аморреев, перизеев, хивеев и иевусеев, – которых исроильтяне не истребили, Сулаймон использовал как рабскую силу, как это есть и до сегодняшнего дня. 9Но исроильтян Сулаймон не обращал в рабов, выполняющих его работы, они были его воинами, военачальниками и начальниками его колесниц и колесничих. 10Ещё они были у него главными начальниками – двести пятьдесят начальников, наделённых властью над людьми8:10 См. сноску на 2:2..

11Сулаймон переселил дочь фараона из Города Довуда во дворец, который он для неё построил, ведь он сказал: «Моя жена не должна жить во дворце Довуда, царя Исроила, потому что святы места, куда вносили сундук Вечного».

12На жертвеннике Вечного, который он построил напротив притвора храма, Сулаймон возносил Вечному всесожжения, 13по установлениям каждого дня о приношениях, данным Мусо, по субботам, в праздник Новолуния и в три ежегодных праздника – в праздник Пресных хлебов, в праздник Жатвы и в праздник Шалашей8:13 См. таблицы: «Праздники в Исроиле» и «Жертвоприношения в Исроиле» на странице ##.. 14По приказу своего отца Довуда он назначил группы священнослужителей для несения службы и левитов, чтобы они возносили хвалу Вечному и помогали священнослужителям выполнять то, что требовалось по установлениям каждого дня. Ещё он поставил привратников по группам у каждых ворот, потому что так повелел Довуд, человек Всевышнего. 15Повеления царя священнослужителям и левитам о чём бы то ни было, включая указания о хранении сокровищ, были исполнены в точности.

16Вся работа Сулаймона со дня, когда было заложено основание храма Вечного, до дня, когда он был достроен, была выполнена. Итак, храм Вечного был завершён.

17Тогда Сулаймон отправился в Эцион-Гевер и Елат, города на морском побережье, что в земле Эдома. 18Хирам прислал ему корабли, которые вели его слуги, знавшие море. Вместе с людьми Сулаймона, они отплыли в Офир и привезли оттуда шестнадцать тысяч двести килограммов8:18 Букв.: «четыреста пятьдесят талантов». золота, которое и доставили царю Сулаймону.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 8:1-18

Àwọn iṣẹ́ Solomoni mìíràn

18.1-18: 1Ọb 9.10-28.Lẹ́yìn ogún ọdún lásìkò ìgbà tí Solomoni kọ́ ilé Olúwa àti ilé òun fúnrarẹ̀. 2Solomoni tún ìlú tí Hiramu ti fi fún un kọ́, ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jọ níbẹ̀ kí wọn kí ó lè máa gbé nínú ibẹ̀. 3Nígbà náà Solomoni lọ sí Hamati-Ṣoba ó sì borí rẹ̀. 4Ó sì tún kọ́ Tadmori ní aginjù àti gbogbo ìlú ìṣúra tí ó ti kọ́ ní Hamati. 5Ó sì tún kọ́ òkè Beti-Horoni àti ìsàlẹ̀ Beti-Horoni gẹ́gẹ́ bí ìlú olódi, pẹ̀lú ògiri àti pẹ̀lú ìlẹ̀kùn àti ọ̀pá ìdábùú. 6Àti gẹ́gẹ́ bí Baalati àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti gbogbo ìlú fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti fún àwọn ẹṣin rẹ̀ ohunkóhun tí ó bá yẹ ní kókó ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo àyíká agbègbè tí ó ń darí.

7Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kúrò láti ara àwọn ará Hiti, ará Amori, ará Peresi, ará Hifi àti ará Jebusi àwọn ènìyàn wọ̀nyí wọn kì í ṣe àwọn ará Israẹli, 8Èyí ni wí pé, àwọn ọmọ wọn tí ó kù sílé ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò parun àwọn ni Solomoni bu iṣẹ́ ìrú fún títí di òní yìí. 9Ṣùgbọ́n Solomoni kò mú ọmọ ọ̀dọ̀ lára àwọn ọmọ Israẹli, wọn jẹ́ ọ̀gágun rẹ̀, olùdarí àwọn oníkẹ̀kẹ́ àti olùdarí kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. 10Wọ́n sì tún jẹ́ olórí aláṣẹ fún ọba Solomoni, àádọ́ta ó-lé-nígba àwọn alákòóso lórí àwọn ènìyàn (250).

11Solomoni gbé ọmọbìnrin Farao sókè láti ìlú Dafidi lọ sí ibi tí ó ti kọ́ fún un, nítorí ó wí pé “Aya mi kò gbọdọ̀ gbé nínú ilé Dafidi ọba Israẹli nítorí ibi tí àpótí ẹ̀rí Olúwa bá tí wọ̀, ibi mímọ́ ni.”

12Lórí pẹpẹ Olúwa tí ó ti kọ́ níwájú ìloro náà, Solomoni sì rú ẹbọ sísun sí Olúwa, 13nípa ìlànà ojoojúmọ́ fún ẹbọ rírú tí a pàṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mose wá fún ọjọ́ ìsinmi, oṣù tuntun àti lẹ́rìn mẹ́ta lọ́dún, ní àjọ àìwúkàrà, ní àjọ ọ̀sẹ̀ méje àti àjọ àgọ́. 14Ní pípamọ́ pẹ̀lú ìlànà baba rẹ̀ Dafidi, ó sì yan ipa àwọn àlùfáà fún iṣẹ́ wọn àti àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ adarí láti máa yin àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìlànà ojoojúmọ́. Ó sì tún yàn àwọn olùṣọ́nà nípa pípín sí olúkúlùkù ẹnu-ọ̀nà, nítorí èyí ni Dafidi ènìyàn Ọlọ́run ti paláṣẹ. 15Wọn kò sì yà kúrò nínú àṣẹ ọba sí àwọn àlùfáà tàbí sí àwọn ọmọ Lefi, nínú ohunkóhun, àti pẹ̀lú ti ìṣúra.

16Gbogbo iṣẹ́ Solomoni ni a gbé jáde láti ọjọ́ ìfi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ ìparí. Bẹ́ẹ̀ ni ilé Olúwa sì parí.

17Nígbà náà ni Solomoni lọ sí Esioni-Geberi àti Elati ní Edomu létí òkun. 18Hiramu sì fi ọ̀kọ̀ ránṣẹ́ sì i nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó mòye Òkun. Èyí pẹ̀lú àwọn ènìyàn Solomoni, lọ sí Ofiri wọ́n sì gbé àádọ́ta irínwó tálẹ́ǹtì wúrà wá, padà èyí tí wọ́n sì mú tọ ọba Solomoni wá.