2 Летопись 28 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

2 Летопись 28:1-27

Ахаз – царь Иудеи

(4 Цар. 16:1-5)

1Ахазу было двадцать лет, когда он стал царём, и правил он в Иерусалиме шестнадцать лет. В отличие от своего предка Довуда, он не делал того, что было правильным в глазах Вечного. 2Он ходил путями царей Исроила и тоже сделал литых идолов для служения Баалу. 3Он приносил огненные жертвы в долине Бен-Гинном и даже сжигал там своих сыновей по омерзительным обычаям народов, которых Вечный прогнал от исроильтян. 4Ахаз приносил жертвы и возжигал благовония в капищах на возвышенностях, на вершинах холмов и под каждым тенистым деревом.

5Поэтому Вечный, его Бог, отдал его в руки царя Сирии. Сирийцы разбили его, взяли много народа в плен и увели их в Дамаск. Ахаз был отдан также в руки царя Исроила, который нанёс ему тяжёлые потери. 6Пеках, сын Ремалии, убил у Иудеи сто двадцать тысяч доблестных воинов в один день, потому что Иудея оставила Вечного, Бога её предков. 7Зихри, могучий воин ефраимит, убил царского сына Маасею, распорядителя дворца Азрикама и Элкану, второго человека после царя. 8Исроильтяне взяли в плен у своих же братьев в Иудее двести тысяч жён, сыновей и дочерей. Они взяли у них и богатую добычу, которую отправили в Сомарию.

Возвращение иудейских пленников

9Но там был пророк Вечного, которого звали Одед. Он вышел навстречу войску, когда оно возвращалось в Сомарию, и сказал им:

– Вечный, Бог ваших предков, разгневался на Иудею и отдал её вам в руки, но вы истребляли её с яростью, которая достигла небес. 10А теперь вы хотите сделать мужчин и женщин Иудеи и Иерусалима своими рабами. Но разве сами вы не грешили против Вечного, вашего Бога? 11Слушайте же меня! Отпустите своих братьев, которых вы взяли в плен, назад, потому что гнев Вечного воспылал на вас.

12Некоторые из вождей Ефраима – Азария, сын Иоханана, Берехия, сын Мешиллемота, Иехизкия, сын Шаллума, и Амаса, сын Хадлая, – предостерегли тех, кто возвращался с войны.

13– Не ведите сюда этих пленников, – сказали они, – иначе мы станем виновны перед Вечным. Вы что, хотите прибавить к нашим грехам и преступлениям и этот? Наша вина и без того велика, и Его гнев воспылал на Исроил.

14Тогда воины отказались от пленников и добычи перед вождями и всем собранием. 15А те, чьи имена были упомянуты, взяли пленников и всех из них, кто был наг, одели из добычи. Они дали им одежду и обувь, снабдили едой и питьём и помазали целебным маслом. Всех, кто ослаб, они посадили на ослов. Они доставили их к их соплеменникам в Иерихон, город Пальм, и вернулись в Сомарию.

Ахаз просит защиты у ассирийцев

(4 Цар. 16:7-20)

16В то время царь Ахаз послал к царю Ассирии, прося о помощи, 17потому что эдомитяне опять пришли, напали на Иудею и увели пленников, 18а филистимляне опустошали города в предгорьях и на юге Иудеи. Они захватили города и поселились в Бет-Шемеше, Аялоне и Гедероте, а также в Сохо, Тимне и Гимзо и в их окрестных поселениях. 19Вечный унизил Иудею из-за Ахаза, царя Исроила28:19 То есть Иудеи; так же в ст. 23, 27. См. сноску на 12:1., потому что тот развратил Иудею и забыл про верность Вечному. 20К нему пришёл Тиглатпаласар28:20 Это Тиглатпаласар III. Он правил с 745 по 727 гг. до н. э., царь Ассирии, но стал притеснять его, вместо того чтобы помочь. 21Ахаз взял сокровища из храма Вечного, из собственного дворца и дворца вождей и выплатил дань царю Ассирии, но это ему не помогло.

22В этой беде царь Ахаз ещё сильнее нарушил верность Вечному. 23Он принёс жертвы богам Дамаска, думая, что это они разбили его, и говорил: «Раз боги царей Сирии помогли им, стану приносить им жертвы, чтобы они помогли и мне». Но они привели к падению и его, и весь Исроил.

24Ахаз собрал утварь храма Всевышнего и порубил её на куски. Он запер двери храма Вечного и устроил жертвенники на всех углах улиц Иерусалима. 25В каждом городе Иудеи он устроил капища, чтобы приносить жертвы чужим богам, и тем самым гневил Вечного, Бога его предков.

26Прочие события его царствования и все его деяния, от первых до последних, записаны в «Книге царей Иудеи и Исроила». 27Ахаз упокоился со своими предками и был похоронен в Иерусалиме, но не был положен в гробницы царей Исроила. И царём вместо него стал его сын Езекия.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 28:1-27

Ahasi ọba Juda

128.1-4: 2Ọb 16.2-4.Ahasi sì jẹ́ ẹni ogún ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìn-dínlógún. Gẹ́gẹ́ bí i Dafidi baba rẹ̀ kò sì ṣe ohun rere ní ojú Olúwa. 2Ó sì rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli ó sì ṣe ère dídá fún ìsìn Baali 3Ó sì sun ẹbọ ní Àfonífojì Hinnomu, ó sì sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná, gẹ́gẹ́ bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli 4Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní ibi gíga wọ́n nì lórí òkè kékeré àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.

5Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fi lé ọba Siria lọ́wọ́. Àwọn ará Siria sì pa á run, wọ́n sì kó púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wọn wá sí Damasku.

Ó sì tún fi lé ọwọ́ ọba Israẹli pẹ̀lú, ẹni tí ó kó wọn ní ìgbèkùn púpọ̀ tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa. 6Ní ọjọ́ kan Peka, ọmọ Remaliah, pa ọ̀kẹ́ mẹ́fà àwọn ọmọ-ogun ní Juda nítorí Juda ti kọ Olúwa Ọlọ́run baba wọn sílẹ̀. 7Sikri àti Efraimu alágbára sì pa Maaseiah ọmọ ọba, Aṣrikamu ìjòyè tí ó wà ní ìkáwọ́ ilé ọba, àti Elkana igbákejì ọba. 8Àwọn ọmọ Israẹli sì kó ní ìgbèkùn lára àwọn arákùnrin wọn ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn aya wọn, àwọn ọmọkùnrin àti obìnrin wọn sì tún kó ọ̀pọ̀ ìkógun, èyí tí wọn kó padà lọ sí Samaria.

9Ṣùgbọ́n wòlíì Olúwa tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Odedi wà níbẹ̀, ó sì jáde lọ láti lọ pàdé ogun nígbà tí ó padà sí Samaria. Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí Olúwa, Ọlọ́run baba yín bínú sí Juda ó sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin pa wọ́n ní ìpa oró tí ó de òkè ọ̀run. 10Nísinsin yìí, ẹ̀yin ń pète láti mú ọkùnrin àti obìnrin Juda àti Jerusalẹmu ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú yín, ẹ̀yin kò ha jẹ̀bi Olúwa Ọlọ́run yín, àní ẹ̀yin? 11Nísinsin yìí ẹ gbọ́ tèmi! Ẹ rán àwọn ìgbèkùn tí ẹ̀yin ti mú gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹ́wọ̀n padà nítorí ìbínú kíkan Olúwa ń bẹ lórí yín.”

12Lẹ́yìn náà, díẹ̀ nínú àwọn olórí ní Efraimu, Asariah ọmọ Jehohanani, Bẹrẹkiah ọmọ Meṣilemoti, Jehiskiah ọmọ Ṣallumu, àti Amasa ọmọ Hadlai, dìde sí àwọn tí o ti ogun náà bọ̀. 13Wọn si wí pé “Ìwọ kò gbọdọ̀ mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n wá síbí,” “tàbí àwa ti jẹ̀bi níwájú Olúwa, ṣe ẹ̀yin ń gbèrò láti fi kún ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀bi wa ni: nítorí tí ẹ̀bi wa ti tóbi púpọ̀, ìbínú rẹ̀ kíkan sì wà lórí Israẹli.”

14Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ológun tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti ìkógun sílẹ̀ níwájú àwọn ìjòyè àti gbogbo ìjọ ènìyàn. 15Àwọn ọkùnrin tí a pè pẹ̀lú orúkọ náà sì dìde, wọn sì mú àwọn ìgbèkùn náà, wọ́n sì fi ìkógun náà wọ̀ gbogbo àwọn tí ó wà ní ìhòhò nínú wọn, wọ́n sì wọ̀ wọ́n ní aṣọ, wọ́n sì bọ̀ wọ́n ní bàtà, wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ àti ohun mímu, wọ́n sì fi òróró kùn wọ́n ní ara, wọ́n sì kó gbogbo àwọn tí ó jẹ́ aláìlera nínú wọ́n sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kó wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Jeriko, ìlú ọ̀pẹ, wọ́n sì padà sí Samaria.

16Ní àkókò ìgbà náà, ọba Ahasi ránṣẹ́ sí ọba Asiria fún ìrànlọ́wọ́. 17Àwọn ará Edomu sì tún padà wá láti kọlu Juda kí wọn sì kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ. 18Nígbà tí àwọn ará Filistini sì ti jagun ní ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n nì àti síhà gúúsù Juda. Wọ́n ṣẹ́gun wọ́n sì gba Beti-Ṣemeṣi, Aijaloni àti Gederoti, àti Soko, Timna, a ri Gimiso, pẹ̀lú ìletò wọn. 19Olúwa sì rẹ Juda sílẹ̀ nítorí Ahasi ọba Israẹli, nítorí ó sọ Juda di aláìní ìrànlọ́wọ́, ó sì ṣe ìrékọjá gidigidi sí Olúwa. 20Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fún ní ìpọ́njú dípò ìrànlọ́wọ́. 21Ahasi mú díẹ̀ nínú ìní ilé Olúwa àti láti ilé ọba àti láti ọ̀dọ̀ ọba ó sì fi wọ́n fún ọba Asiria: ṣùgbọ́n èyí kò ràn wọ́n lọ́wọ́.

22Ní àkókò ìpọ́njú rẹ̀ ọba Ahasi sì di aláìṣòótọ́ sí Olúwa. 23Ó sì rú ẹbọ sí òrìṣà àwọn Damasku, ẹni tí ó ṣẹ́gun wọn, nítorí ó rò wí pé, “Nítorí àwọn òrìṣà àwọn ọba Siria ti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọn kí ó bà lè ràn mí lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n àwọn ni ìparun rẹ̀ àti ti gbogbo Israẹli.

24Ahasi sì kó gbogbo ohun èlò láti ilé Olúwa jọ ó sì kó wọn lọ. Ó sì ti ìlẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tẹ́ pẹpẹ fún ara rẹ̀ ní gbogbo igun Jerusalẹmu. 25Ní gbogbo ìlú Juda ó sì kọ́ ibi gíga láti sun ẹbọ fún àwọn ọlọ́run mìíràn. Kí ó sì mú Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn bínú.

26Ìyókù iṣẹ́ ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Juda àti ti Israẹli. 2728.27: 2Ọb 16.20.Ahasi sì sùn pẹ̀lú àwọn Baba rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Jerusalẹmu ṣùgbọ́n wọn kò mú un wá sínú àwọn isà òkú àwọn ọba Israẹli. Hesekiah ọmọ rẹ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.