Узайр 6 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

Узайр 6:1-22

Указ царя Дария

1Царь Дарий дал повеление, и в архивах, что хранились в сокровищнице в Вавилоне, устроили поиск. 2Но нашёлся свиток в крепости Екбатаны, что в провинции Мидия, и в нём было написано:

Памятная запись:

3В первый год правления царя Куруша, царь отдал повеление о храме Всевышнего в Иерусалиме:

Пусть храм – место, где приносятся жертвы и сжигаются всесожжения, – будет отстроен, и пусть будут заложены его основания. Пусть он будет тридцать метров в высоту и тридцать метров6:3 Букв.: «шестьдесят локтей». в ширину, 4с тремя рядами из больших камней и одним – из дерева. Расходы пусть будут оплачены из царской казны. 5А ещё, пусть золотые и серебряные вещи дома Всевышнего, которые Навуходоносор забрал из Иерусалимского храма и принёс в Вавилон, вернутся на своё место в Иерусалимский храм и пусть их поместят в доме Всевышнего.

6Итак, Таттенай, наместник провинции за Евфратом, Шетар-Бознай и вы, их сподвижники, чиновники этой провинции, держитесь подальше. 7Не вмешивайтесь в работу над этим храмом Всевышнего. Пусть иудейский наместник и старейшины иудеев отстраивают этот дом Всевышнего на его прежнем месте.

8Более того, я даю повеление о том, чем вы должны помогать этим старейшинам иудеев в постройке этого дома Всевышнего: расходы этих людей следует полностью оплатить из царской казны, из доходов провинции за Евфратом, чтобы работа не останавливалась. 9Всё, что бы ни потребовалось: тельцы, бараны, ягнята для всесожжений Богу небесному, пшеница, соль, вино и масло, как скажут священнослужители из Иерусалима, должно выдаваться им ежедневно без промедления, 10чтобы они могли приносить жертвы, угодные Богу небесному, и молиться о благополучии царя и его сыновей.

11Я даю и такое повеление, что если кто-нибудь изменит этот указ, то пусть из его дома вынут кол и посадят его на него. Пусть его дом за это преступление будет превращён в груду развалин. 12Пусть Бог, Которого там почитают, низложит всякого царя или народ, которые поднимут руку, чтобы изменить этот указ или разрушить этот Иерусалимский храм.

Так повелел я, Дарий. Да будет исполнено это со всем усердием.

Завершение строительства храма и его освящение

13И наместник провинции за Евфратом Таттенай, Шетар-Бознай и их сподвижники со всем старанием исполнили то, что повелел царь Дарий. 14И старейшины иудеев продолжали строить и преуспевали в то самое время, когда пророчествовали пророки Аггей и Закария, внук Иддо. Они завершили строительство храма по повелению Бога Исроила и указам Куруша, Дария и Артаксеркса, царей Персии. 15Строительство храма было завершено на третий день месяца адара, в шестой год правления царя Дария (12 марта 515 г. до н. э.).

16И весь народ Исроила – священнослужители, левиты и все остальные, возвратившиеся из плена, – радостно отпраздновали освящение дома Всевышнего. 17Для освящения этого дома Всевышнего они принесли в жертву сто быков, двести баранов, четыреста ягнят и в жертву за грех всего Исроила – двенадцать козлов, по одному за каждый исроильский род. 18Затем они назначили для служения Всевышнему в Иерусалиме священнослужителей по их отделениям и левитов по их группам, как предписано в Тавроте, книге Мусо.

Праздник Освобождения

19В четырнадцатый день первого месяца (21 апреля 515 г. до н. э.) возвратившиеся из плена отметили праздник Освобождения6:19 Праздник Освобождения – этот праздник отмечался в память об избавлении иудейского народа под руководством пророка Мусо из Египетского рабства (см. Исх. 12; 13:17-22; 14; Втор. 16:1-8).. 20Священнослужители и левиты очистились, и все были ритуально чисты. Левиты закололи ягнёнка, предназначенного в жертву на праздник Освобождения для всех возвратившихся из плена, для своих собратьев-священнослужителей и для самих себя. 21И исроильтяне, вернувшиеся из плена, ели вместе со всеми теми, кто удалился от нечистых обычаев своих соседей-язычников, чтобы прибегать к помощи Вечного, Бога Исроила. 22Семь дней они радостно отмечали праздник Пресных хлебов6:22 Праздник Пресных хлебов – этот праздник шёл сразу же за праздником Освобождения и длился семь дней. В эти дни предписывалось есть только пресный хлеб (см. Исх. 12:15-20; 13:3-10; Лев. 23:6-8; Чис. 28:17-25)., потому что Вечный наполнил их радостью, расположив к ним царя Ассирии6:22 Персидский царь Дарий назван здесь царём Ассирии потому, что Персия завоевала Вавилонскую империю, которая, в свою очередь, завоевала Ассирию. так, что тот стал помогать им в работе над домом Всевышнего, Бога Исроила.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esra 6:1-22

Dariusi rí ìwé àṣẹ Sairusi

1Nígbà náà ni ọba Dariusi pàṣẹ, wọ́n sì wá inú ilé ìfí-nǹkan-pamọ́-sí ní ilé ìṣúra ní Babeli. 2A rí ìwé kíká kan ní Ekbatana ibi kíkó ìwé sí ní ilé olódi agbègbè Media, wọ̀nyí ni ohun tí a kọ sínú rẹ̀:

Ìwé ìrántí:

36.3: Es 1.1; 5.13.Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba ọba Kirusi, ọba pa àṣẹ kan nípa tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu:

Jẹ́ kí a tún tẹmpili ibi tí a ti ń rú onírúurú ẹbọ kọ́, kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ni gíga àti fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ àádọ́rùn-ún ẹsẹ̀ bàtà, 4pẹ̀lú ipele òkúta ńláńlá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ipele pákó kan, kí a san owó rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra ọba. 5Sì jẹ́ kí wúrà àti àwọn ohun èlò fàdákà ti ilé Ọlọ́run, tí Nebukadnessari kó láti ilé Olúwa ní Jerusalẹmu tí ó sì kó lọ sí Babeli, di dídápadà sí ààyè wọn nínú tẹmpili ní Jerusalẹmu; kí a kó wọn sí inú ilé Ọlọ́run.

6Nítorí náà, kí ìwọ, Tatenai baálẹ̀ agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹlẹgbẹ́ yín, àwọn ìjòyè ti agbègbè náà kúrò níbẹ̀. 7Ẹ fi iṣẹ́ ilé Ọlọ́run yìí lọ́rùn sílẹ̀ láì dí i lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí baálẹ̀ àwọn Júù àti àwọn àgbàgbà Júù tún ilé Ọlọ́run yín kọ́ sí ipò rẹ̀.

8Síwájú sí i, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe fún àwọn àgbàgbà Júù wọ̀nyí lórí kíkọ́ ilé Ọlọ́run yìí:

Gbogbo ìnáwó àwọn ọkùnrin yìí ni kí ẹ san lẹ́kùnrẹ́rẹ́ lára ìṣúra ti ọba, láti ibi àkójọpọ̀ owó ìlú ti agbègbè Eufurate kí iṣẹ́ náà má bà dúró. 9Ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́—àwọn ọ̀dọ́ akọ màlúù, àwọn àgbò, ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, àti jéró, iyọ̀, wáìnì àti òróró, bí àwọn àlùfáà ní Jerusalẹmu ti béèrè ni ẹ gbọdọ̀ fún wọn lójoojúmọ́ láìyẹ̀. 10Kí wọn lè rú àwọn ẹbọ tí ó tẹ́ Ọlọ́run ọ̀run lọ́rùn kí wọ́n sì gbàdúrà fún àlàáfíà ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀:

11Síwájú sí i, mo pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá yí àṣẹ yìí padà, kí fa igi àjà ilé rẹ̀ yọ jáde, kí a sì gbe dúró, kí a sì fi òun náà kọ́ sí orí rẹ̀ kí ó wo ilé rẹ̀ palẹ̀ a ó sì sọ ọ́ di ààtàn. 12Kí Ọlọ́run, tí ó ti jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ibẹ̀, kí ó pa gbogbo ọba àti orílẹ̀-èdè rún tí ó bá gbé ọwọ́ sókè láti yí àṣẹ yìí padà tàbí láti wó tẹmpili yìí tí ó wà ní Jerusalẹmu run.

Èmi Dariusi n pàṣẹ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mímúṣẹ láìyí ohunkóhun padà.

Píparí àti yíya tẹmpili sí mímọ́

13Nígbà náà, nítorí àṣẹ tí ọba Dariusi pa, Tatenai, Baálẹ̀ ti agbègbè Eufurate, àti Ṣetar-bosnai pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pa á mọ́ láìyí ọ̀kan padà. 14Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbàgbà Júù tẹ̀síwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, ìran Iddo. Wọ́n parí kíkọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run Israẹli àti àwọn àṣẹ Kirusi, Dariusi àti Artasasta àwọn ọba Persia pọ̀. 15A parí ilé Olúwa ní ọjọ́ kẹta, oṣù Addari (oṣù kejì) ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dariusi.

16Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Israẹli—àwọn àlùfáà, àwọn Lefi àti àwọn ìgbèkùn tí ó padà, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀. 17Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù (100), ọgọ́rùn-ún méjì àgbò (200) àti ọgọ́ọ̀rún mẹ́rin akọ ọ̀dọ́-àgùntàn (400), àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli, àgbò méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Israẹli. 18Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpín wọ́n àti àwọn Lefi sì ẹgbẹẹgbẹ́ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mose.

Àjọ ìrékọjá

19Ní ọjọ́ kẹrìnlá ti oṣù Nísàn (oṣù kẹrin), àwọn tí a kó ní ìgbèkùn ṣe ayẹyẹ àjọ ìrékọjá. 20Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì jẹ́ mímọ́. Àwọn ará Lefi pa ọ̀dọ́-àgùntàn ti àjọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn, fún àwọn àlùfáà arákùnrin wọn àti fún ara wọn. 21Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó ti dé láti ìgbèkùn jẹ ẹ́ lápapọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ti ya ara wọn kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ àìmọ́ ti àwọn kèfèrí aládùúgbò wọn láti wá Olúwa Ọlọ́run Israẹli. 22Fún ọjọ́ méje, wọ́n ṣe ayẹyẹ àkàrà àìwú pẹ̀lú àjẹtì àkàrà. Nítorí tí Olúwa ti kún wọn pẹ̀lú ayọ̀ nípa yíyí ọkàn ọba Asiria padà, tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.