Левит 8 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

Левит 8:1-36

Посвящение Хоруна и его сыновей на служение Вечному

(Исх. 29:1-37)

1Вечный сказал Мусо:

2– Приведи Хоруна и его сыновей, возьми их одеяния, масло для помазания, молодого быка для жертвы за грех, двух баранов и корзину с пресным хлебом 3и собери всё общество к входу в шатёр встречи.

4Мусо сделал, как повелел ему Вечный, и общество собралось к входу в шатёр встречи.

5Мусо сказал собравшимся:

– Это повелел сделать Вечный.

6Мусо вывел Хоруна и его сыновей вперёд и омыл их водой. 7Он облачил Хоруна в рубашку, обвязал его поясом, одел в верхнюю ризу и возложил на него ефод8:7 Ефод – своего рода передник, бывший частью облачения священнослужителя при исполнении им его обязанностей.. Он обвязал его по ефоду украшенным поясом, закрепив на нём ефод. 8Он возложил на него нагрудник, а на нагрудник – священный жребий8:8 Букв.: «урим («свет») и туммим («совершенство»)». С помощью этих предметов определяли волю Всевышнего, но как именно, сегодня не известно.. 9Он надел ему на голову тюрбан и прикрепил к тюрбану спереди золотое украшение, священный венец, как повелел Мусо Вечный.

10Мусо взял масло для помазания и помазал священный шатёр и всё, что в нём. Так он освятил всё это. 11Он семь раз окропил маслом жертвенник, помазав его со всей его утварью и умывальник с его основанием, чтобы освятить их. 12Он возлил масло для помазания на голову Хоруна и помазал его, чтобы освятить. 13Затем он вывел вперёд сыновей Хоруна, надел на них рубашки, обвязал их поясами и надел на них головные уборы, как повелел Мусо Вечный.

14Он привёл молодого быка для жертвы за грех, а Хорун и его сыновья возложили руки ему на голову. 15Мусо заколол быка, взял кровь и пальцем нанёс её на рога жертвенника, чтобы очистить его. Остальную кровь он вылил к основанию жертвенника. Так он освятил жертвенник, чтобы сделать его чистым. 16Ещё Мусо взял весь жир вокруг внутренностей, сальник с печени и обе почки с их жиром и сжёг на жертвеннике. 17Но самого быка – его шкуру, мясо и кишки – он сжёг за лагерем, как повелел Мусо Вечный.

18Мусо привёл барана для всесожжения, а Хорун и его сыновья возложили руки ему на голову. 19Мусо заколол барана и окропил его кровью жертвенник со всех сторон. 20Он разрезал барана на куски и сжёг их вместе с головой и жиром. 21Он вымыл внутренности и голени жертвы и сжёг всего барана на жертвеннике как всесожжение, приятное благоухание, огненную жертву Вечному, как повелел Мусо Вечный.

22Он привёл другого барана, барана для посвящения, а Хорун и его сыновья возложили руки ему на голову. 23Мусо заколол барана, взял кровь и помазал ею мочку правого уха Хоруна, большой палец его правой руки и большой палец правой ноги. 24Мусо вывел вперёд сыновей Хоруна и помазал кровью мочки их правых ушей, большие пальцы их правых рук и большие пальцы правых ног. Он окропил кровью жертвенник со всех сторон. 25Он взял жир, курдюк, весь жир вокруг внутренностей, сальник с печени, обе почки с их жиром и правое бедро. 26Из корзины с пресным хлебом, что была перед Вечным, он взял один пресный хлеб, лепёшку, приготовленную на масле, и корж. Он положил их на жир и правое бедро барана. 27Он вложил всё это в руки Хоруну и его сыновьям и потряс перед Вечным как приношение потрясания. 28Затем Мусо взял это у них из рук и сжёг на жертвеннике, сверху всесожжения, как жертву посвящения, приятное благоухание, огненную жертву Вечному. 29Он взял грудину – свою долю от барана для посвящения – и потряс её перед Вечным как приношение потрясания, как повелел Мусо Вечный.

30Мусо взял масло для помазания и кровь с жертвенника и окропил Хоруна и его одеяния, а также его сыновей с их одеяниями. Так он освятил Хоруна, его сыновей и их одеяния.

31Мусо сказал Хоруну и его сыновьям:

– Сварите мясо у входа в шатёр встречи и ешьте его там с хлебом из корзины для посвящённых хлебов, как я велел, сказав8:31 Или: «как мне было приказано».: «Пусть Хорун и его сыновья едят это». 32Остаток мяса и хлеба сожгите. 33Не уходите от входа в шатёр встречи семь дней, пока не завершатся дни вашего посвящения, потому что ваше посвящение будет длиться семь дней. 34Сделанное сегодня было исполнено по повелению Вечного, чтобы совершить для вас очищение. 35Оставайтесь у входа в шатёр встречи день и ночь в течение семи дней и исполняйте то, что требует Вечный, чтобы вам не умереть, потому что так мне было велено.

36Хорун и его сыновья сделали всё, что повелел через Мусо Вечный.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 8:1-36

Ìfinijoyè àlùfáà Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀

18.1-36: Ek 29.1-37.Olúwa sọ fún Mose pé, 2“Mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, aṣọ wọn, òróró ìtasórí, akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò méjì àti apẹ̀rẹ̀ tí a kó àkàrà aláìwú sínú rẹ̀. 3Kí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn jọ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.” 4Mose sì ṣe bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un, gbogbo ènìyàn sì péjọ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ.

5Mose sì sọ fún ìjọ ènìyàn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa ti pàṣẹ pé kí á ṣe.” 6Nígbà náà ni Mose mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá síwájú, ó sì fi omi wẹ̀ wọ́n. 7Ó sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Aaroni, ó fi àmùrè dì í, ó wọ̀ ọ́ ní efodu; aṣọ ìgúnwà, ó sì tún wọ̀ ọ́ ni aṣọ ìlekè oyè àlùfáà tí ó ní ìgbànú tí a ṣe ọnà dáradára sí. 8Ó fi ìgbàyà sí àyà rẹ̀, ó sì fi Urimu àti Tumimu sí ibi ìgbàyà náà. 9Ó dé e ní fìlà, ó sì fi àwo wúrà tí í ṣe adé mímọ́ síwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

10Mose sì fi òróró ìtasórí ya àgọ́ àti ohun gbogbo tó wà nínú rẹ̀ sí mímọ́. 11Ó wọ́n díẹ̀ nínú òróró yìí sórí pẹpẹ lẹ́ẹ̀méje, ó ta òróró sórí pẹpẹ àti gbogbo ohun èlò àti agbada pẹ̀lú ohun tó gbé agbada yìí dúró láti lè yà á sí mímọ́, 12ó da díẹ̀ lára òróró ìtasórí yìí sórí Aaroni, ó sì yà á sí mímọ́. 13Lẹ́yìn èyí ló mú àwọn ọmọ Aaroni wá síwájú, ó sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n, ó fi àmùrè dìwọ́n lára, ó fi fìlà dé wọn lórí gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

14Ó sì mú akọ màlúù wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí ẹran náà. 15Mose pa akọ màlúù náà, ó sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí gbogbo ìwo pẹpẹ láti wẹ pẹpẹ náà mọ́. Ó da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ní ó ṣe yà á sí mímọ́ láti ṣe ètùtù fún un. 16Mose tún mú gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, ó sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ. 17Ṣùgbọ́n akọ màlúù yìí pẹ̀lú awọ àti ara ẹran àti ìgbẹ́ rẹ̀ ní ó sun lẹ́yìn ibùdó gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún Mose.

18Lẹ́yìn náà ló mú àgbò wá fún ẹbọ sísun Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà. 19Mose sì pa àgbò náà, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ náà ká. 20Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, Mose sì sun orí àti àwọn ègé àti ọ̀rá rẹ̀. 21Ó fi omi fọ gbogbo nǹkan inú àti ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sun odidi àgbò náà lórí pẹpẹ bí ẹbọ sísun òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa gẹ́gẹ́ bí Olúwa tí pàṣẹ fún Mose.

22Ó sì mú àgbò kejì wa, èyí ni àgbò ìfinijoyè àlùfáà, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé e lórí. 23Mose sì pa àgbò náà, ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀, ó tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni, sórí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti ti ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀. 24Mose sì tún mú àwọn ọmọ Aaroni wá síwájú, ó sì mú ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ ó fi sí etí ọ̀tún wọn, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ yí pẹpẹ náà ká. 25Ó mú ọ̀rá ẹran náà, ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára nǹkan inú àti èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn pẹ̀lú itan ọ̀tún. 26Lẹ́yìn náà ló mú àkàrà aláìwú sí, èyí tó wà níwájú Olúwa àti àkàrà tí a fi òróró ṣe, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì kó gbogbo rẹ̀ sórí ọ̀rá àti itan ọ̀tún ẹran náà. 27Ó kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí lé Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa. 28Lẹ́yìn náà, Mose gba gbogbo rẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó sì sun wọn lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìfinijoyè àlùfáà òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa. 29Mose sì mú igẹ̀ ẹran náà, èyí tó jẹ́ ìpín rẹ̀ nínú àgbò fún ìfinijoyè, ó sì fì í níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, bi Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

30Mose sì mú díẹ̀ lára òróró ìtasórí àti díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ láti orí pẹpẹ, ó wọ́n sára àwọn ọmọ Aaroni àti aṣọ rẹ̀, ó sì tún wọ́n sára àwọn ọmọ Aaroni àti aṣọ wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Mose ya Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ wọn sí mímọ́.

31Mose sì sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ se ẹran náà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀ pẹ̀lú àkàrà tí a mú láti inú apẹ̀rẹ̀ ọrẹ ìfinijoyè àlùfáà gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ pé, ‘Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó jẹ ẹ́.’ 32Kí ẹ fi iná sun ìyókù àkàrà àti ẹran náà. 33Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje, títí tí ọjọ́ ìfinijoyè àlùfáà yín yóò fi pé, nítorí pé ìfinijoyè àlùfáà yín yóò gba ọjọ́ méje gbáko. 34Ohun tí a ṣe lónìí jẹ́ ohun tí Olúwa ti pàṣẹ láti ṣe ètùtù fún yín. 35Ẹ gbọdọ̀ wà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé lọ́sàn án àti lóru fún ọjọ́ méje kí ẹ sì ṣe ohun tí Olúwa fẹ́, kí ẹ má ba à kú, nítorí ohun tí Olúwa pàṣẹ fún mi ni èyí.”

36Báyìí ni Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ohun gbogbo tí Olúwa pàṣẹ láti ẹnu Mose.