Иеремия 44 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

Иеремия 44:1-30

Осуждение идолопоклонства

1Слово, которое было к Иеремии об иудеях, живущих в Нижнем Египте – в городах Мигдоле, Тахпанхесе и Мемфисе44:1 Букв.: «Нофе». – и в Верхнем Египте44:1 Букв.: «в Патросе»; также в ст. 15.:

2– Так говорит Вечный, Повелитель Сил, Бог Исроила: Вы видели все невзгоды, которые Я обрушил на Иерусалим и на все города Иудеи. Сегодня они лежат в развалинах, и никто не живёт там 3из-за злодеяний, которые они совершили. Они прогневили Меня, возжигая благовония и поклоняясь чужим богам, которых не знали ни вы, ни ваши предки. 4Снова и снова Я посылал Моих рабов пророков, которые говорили: «Не делайте этой мерзости, которую Я ненавижу!» 5Но они не слушали и не обращали внимания; они не отступали от своих злодеяний и не переставали возжигать благовония чужим богам. 6За это Мой страшный гнев прорвался и заполыхал в городах Иудеи и на улицах Иерусалима, превратив их в заброшенные руины, каковы они и сегодня.

7И теперь так говорит Вечный, Бог Сил, Бог Исроила:

– Зачем вам наводить на себя такую страшную беду? Зачем наводить гибель на мужчин и женщин, детей и младенцев Иудеи, на всех без остатка? 8Зачем вызывать Мой гнев делами своих рук, возжигая благовония чужим богам в Египте, куда вы пришли поселиться? Вы погубите себя и сделаете самих себя предметом проклятий и порицания среди всех народов земли. 9Неужели вы забыли злодеяния, совершённые вашими отцами, злодеяния царей Иудеи и их жён, а также злодеяния ваши и жён ваших в земле Иудеи и на улицах Иерусалима? 10Вплоть до сегодняшнего дня вы не смирились, не боитесь Меня и не живёте по Моему Закону и по Моим установлениям, которые Я дал вам и вашим предкам.

11Поэтому так говорит Вечный, Повелитель Сил, Бог Исроила:

– Я решил обрушить на вас беду и погубить всю Иудею. 12Я заберу уцелевших иудеев, которые решили идти в Египет и поселиться там. Все они погибнут в Египте; они падут от меча или умрут от голода. Все, от малого до великого, умрут от меча или голода. Они станут предметом проклятий и ужаса, порицания и презрения. 13Я накажу живущих в Египте мечом, голодом и мором, как наказал Иерусалим. 14Никто из оставшихся иудеев, пришедших поселиться в Египте, не спасётся и не уцелеет, чтобы вернуться в землю иудейскую, куда они хотели бы вернуться, чтобы жить там; никто, кроме нескольких беженцев, не вернётся.

15Тогда все мужчины, знавшие, что их жёны жгут благовония чужим богам, и все женщины, которые там были, – огромное собрание – и весь народ, живущий в Нижнем и Верхнем Египте, сказали Иеремии:

16– Мы не станем слушать того, что ты говоришь нам от имени Вечного! 17Мы обязательно будем делать всё, о чём дали обеты: возжигать благовония богине неба44:17 См. сноску на 7:18. и совершать ей жертвенные возлияния, как делали и мы, и наши отцы, наши цари, и наши сановники в городах Иудеи и на улицах Иерусалима. Мы тогда ели досыта, жили в благополучии и не видели зла. 18А с тех пор как мы перестали возжигать благовония богине неба и совершать для неё жертвенные возлияния, мы терпим нужду и погибаем от меча и голода.

19А женщины сказали:

– Когда мы возжигали благовония богине неба и совершали ей жертвенные возлияния, разве наши мужья не знали, что мы делаем для неё лепёшки с её изображением и приносим ей жертвенные возлияния?

20Тогда Иеремия сказал всему народу, и мужчинам, и женщинам, которые отвечали ему:

21– Разве Вечный не помнит и не думает о благовониях, которые вы и ваши отцы, ваши цари и сановники и народ страны возжигали в городах Иудеи и на улицах Иерусалима? 22Когда Вечный не мог больше терпеть ваших злодеяний и мерзостей, ваша земля стала предметом проклятий и необитаемой пустыней, какой она остаётся и сегодня. 23За то, что вы возжигали благовония, грешили против Вечного, не слушались Его и не жили по Его Закону, установлениям и заповедям, эта беда и пришла к вам, как вы сами сегодня видите.

24Потом Иеремия сказал всему народу и женщинам:

– Слушайте слово Вечного, весь народ Иудеи, живущий в Египте. 25Так говорит Вечный, Повелитель Сил, Бог Исроила: «Вы с вашими жёнами совершили на деле то, что обещали, говоря: „Мы непременно будем исполнять свои обеты, которые мы дали, возжигая благовония и совершая жертвенные возлияния богине неба“. Давайте же, делайте, что обещали! Исполняйте свои обеты!» 26Но выслушай слово Вечного, весь народ Иудеи, живущий в Египте: «Клянусь Своим великим именем, – говорит Вечный, – что никому из иудеев, живущих во всём Египте, не будет впредь дано призывать Моё имя и клясться: „Верно, как и то, что жив Владыка Вечный“. 27Я буду наблюдать за ними, чтобы причинить им зло, а не благо; иудеи в Египте будут умирать от меча и голода, пока все не погибнут. 28Тех же, кто спасётся от меча и вернётся из Египта в землю иудейскую, будет очень мало. Тогда весь оставшийся народ Иудеи, который пришёл в Египет, чтобы поселиться там, узнает, чьё слово сбудется, Моё или их.

29Вот вам знамение того, – возвещает Вечный, – что Я накажу вас в этом краю, чтобы вы знали, что Мои угрозы причинить вам зло непременно сбудутся. 30Так говорит Вечный: Я отдам фараона Хофру44:30 Хофра (Априй) правил Египтом с 589 по 570 гг. до н. э. и был свергнут и убит своими врагами., египетского царя, в руки его врагов, которые ищут его смерти, как отдал Я Цедекию, царя Иудеи, в руки Навуходоносора, царя Вавилона, врага, который хотел убить его».

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 44:1-30

Àjálù nítorí ṣinṣin òrìṣà

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá nípa àwọn Júù tí ń gbé ní ìsàlẹ̀ Ejibiti ní Migdoli, Tafanesi àti Memfisi àti ní apá òkè Ejibiti: 2“Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Wo ibi tí mo mú bá Jerusalẹmu àti gbogbo ìlú Juda. Lónìí, wọ́n wà ní ìyapa àti ìparun. 3Nítorí pé ibi tí wọ́n ti ṣe. Wọ́n mú mi bínú nípa tùràrí fínfín àti nípa bíbọ àwọn òrìṣà, yálà èyí tí ìwọ tàbí àwọn baba rẹ kò mọ̀. 4Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní mo rán wòlíì mi, èyí tí ó wí báyìí pé, ‘Má ṣe àwọn ohun ìríra yìí tí èmi kórìíra.’ 5Ṣùgbọ́n wọn kò fetísílẹ̀ láti fi ọkàn si. Wọn kò sì yípadà kúrò nínú búburú wọn tàbí dáwọ́ ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà dúró. 6Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Juda àti òpópó Jerusalẹmu àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí.

7“Báyìí tún ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: Kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Juda ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan? 8Èéṣe tí ẹ fi mú mi bínú pẹ̀lú ohun tí ọwọ́ yín ṣe pẹ̀lú ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà Ejibiti, níbi tí ẹ wá láti máa gbé? Ẹ̀ ò pa ara yín run, ẹ̀ ó sì sọ ara yín di ẹni ìfiré àti ẹ̀gàn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè ayé gbogbo. 9Ṣé ẹ̀yin ti gbàgbé ibi tí àwọn baba ńlá yín àti àwọn ọba; àwọn ayaba Juda, àti àwọn ibi tí ẹ ti ṣe àti àwọn ìyàwó yín ní ilẹ̀ Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu? 10Láti ìgbà náà sí àkókò yìí, wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ tàbí fi ìtẹríba hàn tàbí kí wọn ó tẹ̀lé òfin àti àṣẹ tí mo pa fún un yín àti àwọn baba yín.

11“Fún ìdí èyí, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn Israẹli wí: Mo ti pinnu láti mú ibi wá sí orí yín àti láti pa Juda run. 12Èmi yóò sì mú àwọn èérún tí ó kù ní Juda, tí wọ́n ṣetán láti lọ Ejibiti. Wọn yóò ṣubú pẹ̀lú idà tàbí kí wọn kú pẹ̀lú ìyàn láti orí ọmọdé títí dé àgbà ni wọn yóò kú láti ọwọ́ ìyàn tàbí idà. Wọn yóò di ẹni ìfiré àti ìparun, ẹni ẹ̀kọ̀ àti ẹni ẹ̀gàn. 13Èmi yóò fi ìyà jẹ ẹni tí ó bá ń gbé ní Ejibiti pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn bí mo ṣe fi ìyà jẹ Jerusalẹmu. 14Kò sí èyí tí ó kéré jù nínú Juda tí ó kù, tí ó ń gbé ilẹ̀ Ejibiti tí yóò sá àsálà padà sórí ilẹ̀ Juda, èyí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti padà sí, àti láti máa gbé; àyàfi àwọn aṣàtìpó mélòó kan.”

15Lẹ́yìn èyí, gbogbo àwọn ọkùnrin tí ẹ bá mọ̀ pé, ìyàwó wọn sun tùràrí sí àwọn òrìṣà pẹ̀lú àwọn obìnrin tí ó bá wá àwọn ènìyàn púpọ̀, pàápàá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní òkè àti ìsàlẹ̀ Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni a wí fún Jeremiah. 16“Wọn sì wí pé: Àwa kò ní fetísílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí o bá bá wa sọ ní orúkọ Olúwa. 17Dájúdájú; à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe: A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run; à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ni àwọn ìgboro Jerusalẹmu. Nígbà naà àwa ní oúnjẹ púpọ̀ a sì ṣe rere a kò sì rí ibi 18Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí a ti dáwọ́ tùràrí sísun sí Ayaba Ọ̀run àti láti da ẹbọ ohun mímu fún un, àwa ti ṣaláìní ohun gbogbo, a sì run nípa idà àti nípa ìyàn.”

19Àwọn obìnrin náà fi kún un pé, “Nígbà tí à ń jó tùràrí sí ayaba ọ̀run, tí a sì ń fi ohun mímu rú ẹbọ si; ǹjẹ́ àwọn ọkọ wa kò mọ pé àwa ń ṣe àkàrà bí i, àwòrán rẹ, àti wí pé à ń da ọtí si gẹ́gẹ́ bi ohun ìrúbọ?”

20Wàyí o, Jeremiah sọ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, ọkùnrin àti obìnrin, tí wọn sì ń dáhùn pé, 21“Ṣe Ọlọ́run kò rántí ẹbọ sísun ní ìlú Juda àti àwọn ìgboro Jerusalẹmu láti ọ̀dọ̀ rẹ àti ọ̀dọ̀ àwọn baba rẹ, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn ìlú. 22Nígbà tí Ọlọ́run kò lè fi ara da ìwà búburú yín àti àwọn nǹkan ìríra gbogbo tí ẹ ṣe, ilẹ̀ yín sì di ohun ìfiré àti ìkọ̀sílẹ̀, láìsí olùgbé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà lónìí. 23Nítorí pé ẹ ti sun ẹbọ, tí ẹ sì ti ṣẹ̀ sí Olúwa àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, àti pé ẹ kò sì tẹ̀lé òfin rẹ̀ àti àwọn àṣẹ. Ibi náà yóò wá sórí rẹ àti bí o ṣe rí i.”

24Nígbà náà ni Jeremiah dáhùn pẹ̀lú obìnrin náà pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ọmọ Juda tí ó wà ní Ejibiti. 25Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Ìwọ àti àwọn Ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ ṣẹ lórí sísun tùràrí àti dída ẹbọ ohun mímu sí orí ère Ayaba Ọ̀run.’

“Tẹ̀síwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ. 26Ṣùgbọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè, gbogbo ẹ̀yin Júù tí ń gbé ilẹ̀ Ejibiti, mo gégùn ún: ‘Mo búra pẹ̀lú títóbi orúkọ mi,’ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ‘wí pé, kò sí ẹnikẹ́ni láti Juda tí ń gbé ibikíbi ní Ejibiti ni tí ó gbọdọ̀ ké pe orúkọ mi tàbí búra. “Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó dá wa ti wà láààyè.” 27Nítorí náà, èmi ó ṣọ wọ́n fún ibi, kì í ṣe fún rere. Àti gbogbo àwọn ọkùnrin Juda tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti ni a ó parun pẹ̀lú idà àti ìyàn títí tí gbogbo wọn yóò fi tán. 28Àwọn tí ó bá sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìparun idà àti pípadà sí ilẹ̀ Juda láti Ejibiti yóò kéré níye. Gbogbo àwọn tí ó bá kú ní ilẹ̀ Juda, tí ó wá gbé ilẹ̀ Ejibiti yóò mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóò dúró yálà tèmi tàbí tiyín.

29“ ‘Èyí ni yóò jẹ́ ààmì fún un yín pé èmi yóò fi ìyà jẹ yín níbi tí Olúwa ti sọ láti lè jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìjìyà mi tí mo sọ pé ẹ̀ ó jẹ yóò ṣẹ.’ 30Báyìí ni Olúwa wí: ‘Èmi yóò fi Farao Hofira ọba Ejibiti lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́, èyí tí ó lè pa ayé rẹ́; gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekiah ọba Juda lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́ ọ̀tá tó ń lépa ẹ̀mí rẹ̀.’ ”