Езекиил 36 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

Езекиил 36:1-38

Суд и восстановление на горах Исроила

1– Смертный, пророчествуй горам Исроила и скажи: «Слушайте слово Вечного, горы Исроила. 2Так говорит Владыка Вечный: За то, что враг говорил о вас: „Ага! Древние вершины стали нашим достоянием“, 3пророчествуй и скажи: Так говорит Владыка Вечный: Так как они разоряли и обирали вас со всех сторон так, что вы стали достоянием прочих народов и подверглись сплетням и злословию, 4слушайте, горы Исроила, слово Владыки Вечного. Так говорит Владыка Вечный горам и холмам, ущельям и долинам, заброшенным развалинам и обезлюдевшим городам, которые стали добычей и предметом насмешек для прочих народов вокруг вас, – 5так говорит Владыка Вечный: В пылающей ревности Я говорил против прочих народов и против всего Эдома. С ликованием и презрением они завладели Моей землёй, чтобы разорять её пастбища».

6Поэтому пророчествуй же о земле Исроила и скажи горам и холмам, ущельям и долинам: Так говорит Владыка Вечный: «Я говорю в порыве гнева и объятый ревностью, потому что вам приходится терпеть оскорбления от народов». 7Поэтому так говорит Владыка Вечный: «Клянусь с поднятой рукой, что народы, окружающие вас, тоже подвергнутся оскорблениям. 8Но вы, горы Исроила, распустите ветви и будете приносить плоды для Моего народа Исроила, потому что он скоро вернётся. 9Я забочусь о вас, Я смотрю на вас милостиво; вы будете вспаханы и засеяны, 10а Я умножу ваших жителей, весь народ Исроила. Города заселятся, и развалины будут отстроены. 11Я умножу на вас людей и скот; они будут плодовиты и размножатся. Я поселю на вас людей, как и прежде, и сделаю вам ещё больше добра, чем раньше. Тогда вы узнаете, что Я – Вечный. 12Я приведу на вас людей – Мой народ Исроил. Они будут владеть вами, вы станете их наследием и не будете больше лишать их детей».

13Так говорит Владыка Вечный: «Так как вам говорят: „Вы пожираете людей и отнимаете детей у своего народа“, 14вы больше не будете пожирать людей и отнимать у своего народа детей, – возвещает Владыка Вечный. – 15Я больше не дам вам услышать оскорбления народов; вы больше не будете ни терпеть позор от других народов, ни отнимать детей у своего народа», – возвещает Владыка Вечный.

16И снова было ко мне слово Вечного:

17– Смертный, когда народ Исроила жил на своей земле, он осквернил её своим поведением и делами. Поведение народа было для Меня подобно нечистоте женщины во время месячных. 18За то, что люди проливали кровь на этой земле и оскверняли её своими идолами, Я излил на них гнев. 19Я рассеял их среди народов, и они были разбросаны по странам; Я судил их по их поведению и делам. 20И куда бы они ни пришли, они бесславили Моё святое имя, потому что народы говорили о них: «Это народ Вечного, который принудили уйти из Его земли». 21И Я пожалел Своё святое имя, которое исроильтяне обесславили среди народов, к которым пришли.

22Поэтому скажи исроильтянам: Так говорит Владыка Вечный: «Не ради вас, исроильтян, сделаю Я это, а ради Моего святого имени, которое вы обесславили среди народов, к которым пришли. 23Я покажу святость Моего великого имени, которое было обесславлено среди народов, имени, которое вы обесславили у них. И народы узнают, что Я – Вечный, – возвещает Владыка Вечный, – когда Я через вас покажу Свою святость у них на глазах. 24Я выведу вас из народов, соберу из всех стран и приведу в вашу землю. 25Я окроплю вас чистой водой, и вы очиститесь; Я очищу вас от всякой скверны и от всех ваших идолов. 26Я дам вам новое сердце и вложу в вас новый дух. Я заберу у вас сердце из камня и дам вам сердце из плоти. 27Я вложу в вас Моего Духа, чтобы вы следовали Моим установлениям и тщательно исполняли Мои законы. 28Вы будете жить на земле, которую Я отдал вашим предкам. Вы будете Моим народом, а Я буду вашим Богом. 29Я спасу вас от всякой скверны. Я дам вам зерно и умножу его; Я не наведу на вас голод. 30Я умножу плоды на деревьях и урожай в поле, чтобы вы больше не терпели из-за голода позор среди народов. 31Вы вспомните свои неправедные пути и злодеяния и станете гнушаться себя из-за своих грехов и мерзостей. 32Я хочу, чтобы вы знали: Я делаю это не ради вас, – возвещает Владыка Вечный. – Стыдитесь и ужасайтесь своих злодеяний, народ Исроила!»

33Так говорит Владыка Вечный: «В день, когда Я очищу вас от ваших грехов, Я вновь заселю ваши города, и развалины будут отстроены. 34Опустошённую землю начнут возделывать; она не будет больше лежать в запустении перед взором прохожих. 35Они станут говорить: „Эта земля, бывшая в запустении, стала похожа на Эдемский сад. Города, которые лежали в развалинах, безлюдные и разрушенные, ныне укреплены и заселены“. 36И народы, которые останутся вокруг вас, узнают, что Я, Вечный, отстроил то, что было разрушено, и насадил там, где было погублено. Я, Вечный, сказал это и исполню».

37Так говорит Владыка Вечный: «Я снова отвечу на мольбы исроильтян и сделаю для них следующее: умножу людей, как овец, 38как овец для жертвоприношения в Иерусалиме в установленные праздники, и разрушенные города наполнятся толпами людей. Тогда они узнают, что Я – Вечный».

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 36:1-38

Àsọtẹ́lẹ̀ kan sí àwọn òkè Israẹli

1“Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn òkè gíga Israẹli kí o sì wí pé, ‘Ẹ̀yin òkè gíga Israẹli gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 2Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Àwọn ọ̀tá sọ nípa yín pé, “Háà! Àwọn ibi gíga ìgbàanì ti di ohun ìní wa.” ’ 3Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé wọn sọ ọ di ahoro, tí wọn sì ń dọdẹ rẹ ní gbogbo ọ̀nà kí ìwọ kí ó lè di ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù, àti ohun ti àwọn ènìyàn ń sọ ọ̀rọ̀ ìríra àti ìdíbàjẹ́ sí, 4nítorí náà, Ẹ̀yin òkè gíga Israẹli gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè: Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn òkè gíga àti àwọn òkè kéékèèkéé, fún Àfonífojì ńlá àti Àfonífojì kéékèèkéé, fún àwọn ibi ìsọdahoro ìparun àti fún àwọn ìlú tí a ti kọ̀sílẹ̀ tí a ti kó tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù ní àyíká sì fi ṣe ẹlẹ́yà, 5èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ìgbóná ọkàn ní mo sọ̀rọ̀ sí àwọn kèfèrí yòókù, àti sí Edomu, nítorí pẹ̀lú ìbínú àti ìjowú ní ọkàn wọn ni wọ́n sọ ilé mi di ohun ìní wọn, kí wọn kí o lè kó pápá oko tútù rẹ̀.’ 6Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli náà kí o sì sọ sí àwọn òkè gíga náà àti àwọn òkè kéékèèkéé, sí àwọn Àfonífojì ńlá àti sí àwọn Àfonífojì kéékèèkéé: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi sọ̀rọ̀ nínú ìrunú owú mi nítorí pé ìwọ ti jìyà ìfiṣẹ̀sín àwọn orílẹ̀-èdè. 7Nítorí náà, Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi ṣe ìbúra nípa nína ọwọ́ mi sókè pé; àwọn orílẹ̀-èdè àyíká rẹ náà yóò jìyà ìfiṣẹ̀sín.

8“ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ, òkè gíga Israẹli, yóò mú ẹ̀ka àti èso fún àwọn ènìyàn mi Israẹli, nítorí wọn yóò wá sílé ní àìpẹ́ yìí. 9Èmi ń ṣe àníyàn fún ọ, èmi yóò sì fi rere wọ̀ ọ́; àwa yóò tu ọ́, àwa yóò sì gbìn ọ́, 10èmi yóò sì sọ iye àwọn ènìyàn di púpọ̀ nínú rẹ àti gbogbo ilé Israẹli. Àwọn ìlú yóò di ibùgbé, a yóò sì tún àwọn ibi ìparun kọ́. 11Èmi yóò sọ iye ènìyàn àti ẹran dì púpọ̀ nínú yín, wọn yóò sì so èso, wọn yóò sì di púpọ̀ yanturu. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn máa gbé nínú rẹ bí ti àtẹ̀yìnwá, èmi yóò sì mú kí o ṣe rere ju ìgbà àtijọ́ lọ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ pé èmi ni Olúwa. 12Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn, àní àwọn ènìyàn Israẹli, rìn lórí rẹ̀. Wọn yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì di ogún ìní wọn; ìwọ kì yóò sì gba àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ wọn mọ́.

13“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé àwọn ènìyàn sọ fún ọ pé, “Ìwọ pa àwọn ènìyàn run, ìwọ sì gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ wọn,” 14nítorí náà ìwọ kì yóò pa àwọn ènìyàn run tàbí mú kì orílẹ̀-èdè di aláìlọ́mọ mọ́, ni Olúwa Olódùmarè wí. 15Èmi kì yóò mú ki ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́, ìwọ kì yóò jìyà ọ̀rọ̀ ìfiṣẹ̀sín láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tàbí mú kí orílẹ̀-èdè rẹ ṣubú, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

16Síwájú sí i ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 17“Ọmọ ènìyàn, nígbà tí àwọn ènìyàn Israẹli: ń gbé ní ilẹ̀ wọn, wọ́n bà á jẹ́ nípa ìwà àti ìṣe wọn. Ìwà wọn dàbí nǹkan àkókò àwọn obìnrin ni ojú mi. 18Nítorí náà mo tú ìbínú mi jáde sórí wọn nítorí wọn ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ti fi ère wọn ba a jẹ́. 19Mo tú wọn ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, a sì fọ́n wọn ká sí àwọn ìlú; mo ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà àti ìṣe wọn. 20Gbogbo ibi tí wọ́n lọ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè ni wọn ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́, nítorí tí a sọ nípa wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn Olúwa, síbẹ̀ wọn ní láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀.’ 21Orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mi lógún, èyí tí ilé Israẹli sọ di aláìmọ́ ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lọ.

22“Nítorí náà, sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kì í ṣe nítorí rẹ, ìwọ ilé Israẹli, ni èmi yóò ṣe ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mímọ́ mi, èyí ti ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti lọ. 23Èmi yóò fi jíjẹ́ mímọ́ orúkọ ńlá mi, èyí tí a ti sọ di aláìmọ́ hàn ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè, orúkọ tí ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ni àárín wọn. Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ni Olúwa Olódùmarè wí, nígbà tí mo bá fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ yín ni iwájú wọn.

24“ ‘Nítorí èmi yóò mú yín jáde kúrò ni àwọn orílẹ̀-èdè náà; Èmi yóò ṣà yín jọ kúrò ní gbogbo àwọn ìlú náà; Èmi yóò sì mú yín padà sí ilẹ̀ ẹ̀yin tìkára yín. 25Èmi yóò wọ́n omi tó mọ́ sí yín lára ẹ̀yin yóò sì mọ́; Èmi yóò sì fọ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ìwà èérí yin gbogbo àti kúrò nínú gbogbo òrìṣà yin. 26Èmi yóò fún yín ni ọkàn tuntun, èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú yín; Èmi yóò sì mú ọkàn òkúta kúrò nínú yín, èmi yóò sì fi ọkàn ẹran fún yín. 27Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, èmi yóò sì mú ki ẹ tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ẹ sì fiyèsí àti pa òfin mi mọ́. 28Ẹ̀yin yóò sì máa gbé ilẹ̀ náà tí mo ti fi fún àwọn baba ńlá yín; ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín. 29Èmi yóò sì gbà yín kúrò nínú gbogbo ìwà àìmọ́ yín. Èmi yóò pèsè ọkà, èmi yóò sì mú kí ó pọ̀ yanturu, èmi kì yóò sì mú ìyàn wá sí orí yín. 30Èmi yóò sọ èso àwọn igi yín àti ohun ọ̀gbìn oko yín di púpọ̀, nítorí kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jìyà ìdójútì mọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà nítorí ìyàn. 3136.31: El 6.9; 20.43.Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rántí àwọn ọ̀nà búburú àti àwọn ìwà ìkà yín, ẹ̀yin yóò sì kórìíra ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ìwà tí kò bójúmu. 32Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ń kò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí yín, ni Olúwa Olódùmarè wí. Jẹ kí ojú kí ó tì yín, kí ẹ sì gba ẹ̀tẹ́ nítorí ìwà yín ẹ̀yin ilé Israẹli!

33“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ tí mo wẹ̀ yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn ìlú yín, wọn yóò sì ṣe àtúnkọ́ ìwólulẹ̀. 34Ilẹ̀ ahoro náà ní àwa yóò tún kọ́ ti kì yóò wà ní ahoro lójú àwọn tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá mọ́. 35Wọn yóò sọ wí pé, “Ilẹ̀ yìí tí ó ti wà ní ahoro tẹ́lẹ̀ ti dàbí ọgbà Edeni; àwọn ìlú tí ó wà ní wíwó lulẹ̀, ahoro tí a ti parun, ni àwa yóò mọdi sí tí yóò sì wà fún gbígbé ni ìsinsin yìí.” 36Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká yín tí ó kù yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti tún àwọn ohun tí ó bàjẹ́ kọ́, mo sì ti tún ohun tí ó di ìṣòfo gbìn. Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi yóò sì ṣe e?’

37“Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò yí sí ilé Israẹli, èmi yóò sì ṣe èyí fún wọn. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn yín pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí àgùntàn, 38Kí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran fún ìrúbọ ní Jerusalẹmu ní àsìkò àjọ̀dún tí a yàn. Ìlú ti a parun yóò wá kún fún agbo àwọn ènìyàn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”