Второзаконие 13 – CARST & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

Второзаконие 13:1-18

1Если пророк или толкователь снов появится среди вас и предскажет знамение или чудо, 2и если это знамение или чудо сбудется, и он скажет: «Обратитесь к другим богам (богам, которых вы не знали) и служите им», 3то вы не должны слушать того пророка или толкователя снов. Это Вечный, ваш Бог, испытывает вас, чтобы узнать, любите ли вы Его всем сердцем и всей душой. 4Вы должны следовать только за Вечным, вашим Богом, и только Его вы должны чтить. Храните Его повеления и слушайтесь Его; служите Ему и храните Ему верность. 5А тот пророк или толкователь снов должен быть предан смерти, потому что он призывал к отступничеству от Вечного, вашего Бога, Который вывел вас из Египта, из земли рабства. Этот пророк или толкователь снов пытался сбить тебя, Исроил, с пути, которым повелел тебе идти Вечный, твой Бог. Очисти себя от этого зла.

6Если кто-нибудь, даже твой родной брат13:6 Букв.: «брат твой, сын матери твоей»., или сын, или дочь, или любимая жена, или твой ближайший друг станут тайно искушать тебя, говоря: «Пойдём, чтобы служить другим богам» (богам, которых не знал ни ты, ни твои предки, 7богам народов, которые живут вокруг тебя, далеко или близко, от одного конца земли до другого), 8то не уступай этому человеку и не слушай его. Не жалей его. Не щади и не покрывай. 9Ты непременно должен убить его. Ты первым должен кинуть в него камень, а потом и все остальные. 10Забей его камнями до смерти, потому что он пытался увести тебя от Всевышнего, твоего Бога, Который вывел тебя из Египта, из земли рабства. 11Тогда весь Исроил услышит об этом и испугается, и никто не станет делать впредь такого зла среди вас.

12Если ты услышишь об одном из городов, которые Вечный, твой Бог, даёт тебе для жизни, 13что там появились негодяи, сбившие с пути его жителей, которые говорят: «Пойдём и будем служить другим богам» (богам, которых ты не знал), 14то ты должен подробно расспросить, всё проверить и расследовать это. И если это правда, и ты сможешь доказать, что такая мерзость была сделана среди вас, 15то ты непременно должен предать мечу всех живущих в том городе. Истреби его полностью: и народ, и скот. 16Всё богатство этого города собери посередине площади и сожги город со всем добром без остатка, как всесожжение Вечному, твоему Богу. Он должен остаться в руинах навсегда и никогда не должен быть отстроен вновь. 17Ни одной из тех проклятых вещей не должно остаться у тебя в руках, чтобы Вечный не обрушил на тебя Свой пылающий гнев. И тогда Он окажет тебе милость, пожалеет тебя и сделает твой народ более многочисленным, как Он клялся твоим предкам. 18Потому что ты слушаешься Вечного, своего Бога, хранишь все Его повеления, которые я даю тебе сегодня, и поступаешь правильно в Его глазах.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 13:1-18

Sí sin àwọn ọlọ́run mìíràn

1Bí wòlíì tàbí alásọtẹ́lẹ̀ nípa àlá lílá bá farahàn láàrín yín, tí ó sì ń kéde iṣẹ́ ààmì tàbí iṣẹ́ ìyanu, 2bí iṣẹ́ ààmì tàbí iṣẹ́ ìyanu tí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ bá ṣẹ tí òun sì wí pé, “ẹ wá ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn” (àwọn ọlọ́run tí ẹ kò mọ̀ rí) “kí ẹ sì jẹ́ kí a máa sìn wọ́n,” 3ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ wòlíì tàbí àlá náà, Olúwa Ọlọ́run yín ń dán an yín wò ni, láti mọ̀ bóyá ẹ fẹ́ràn rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn an yín. 4Olúwa Ọlọ́run yín ni kí ẹ tẹ̀lé, Òun ni kí ẹ bu ọlá fún, ẹ pa òfin rẹ̀ mọ́ kí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀: ẹ sìn ín, kí ẹ sì dìímú ṣinṣin. 5Wòlíì náà tàbí alálàá náà ni kí ẹ pa, nítorí pé wàásù ìṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú yín jáde láti Ejibiti wá, tí ó sì rà yín padà lóko ẹrú. Ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lójú ọ̀nà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín láti máa rìn. Ẹ gbọdọ̀ yọ ibi náà kúrò láàrín yín.

6Bí arákùnrin tìrẹ gan an ọmọ ìyá rẹ tàbí ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí obìnrin, aya tí o fẹ́ràn jù, tàbí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ bá tàn ọ́ jẹ níkọ̀kọ̀ wí pé jẹ́ kí a lọ sin ọlọ́run mìíràn, (ọlọ́run tí ìwọ tàbí baba rẹ kò mọ̀ 7ọlọ́run (òrìṣà) àwọn tí ó wà láyìíká yín, yálà wọ́n jìnnà tàbí wọ́n wà nítòsí, láti òpin ilẹ̀ kan dé òmíràn.) 8Má ṣe fetí sí i, má sì dá sí i, má ṣe dáàbò bò ó. 9Ṣùgbọ́n pípa ni kí o pa á. Ọwọ́ rẹ ni yóò kọ́kọ́ wà lára rẹ̀ láti pa á, lẹ́yìn náà ọwọ́ gbogbo ènìyàn. 10Sọ ọ́ ní òkúta pa nítorí pé ó gbìyànjú láti fà ọ́ kúrò lẹ́yìn Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó mú ọ jáde ti Ejibiti wá kúrò ní oko ẹrú. 11Gbogbo Israẹli yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, kò sì sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí yóò dán irú ibi bẹ́ẹ̀ wò mọ́.

12Bí ẹ̀yin bá gbọ́ tí a sọ nípa èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín láti máa gbé, 13pé àwọn ènìyàn búburú, ti farahàn láàrín yín, tí ó sì ti mú kí àwọn ènìyàn ìlú wọn ṣìnà lọ, tí wọ́n wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sin ọlọ́run mìíràn,” (àwọn ọlọ́run tí ẹ kò mọ̀.) 14Kí ẹ wádìí, ẹ béèrè, kí ẹ sì tọpinpin ọ̀rọ̀ náà dájúṣáká, bí ó bá jẹ́ òtítọ́ ni, tí ó sì hàn dájú pé ìwà ìríra yìí ti ṣẹlẹ̀ láàrín yín. 15Gbogbo àwọn tí ó ń gbé ìlú náà ni kí ẹ fi idà run pátápátá. Ẹ run ún pátápátá, àti ènìyàn àti ẹran ọ̀sìn inú rẹ̀. 16Ẹ kó gbogbo ìkógun ìlú náà, sí àárín gbogbo ènìyàn, kí ẹ sun ìlú náà àti gbogbo ìkógun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun sí Olúwa Ọlọ́run rẹ. Ó gbọdọ̀ wà ní píparun láéláé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ tún un kọ. 17A kò gbọdọ̀ rí ọ̀kan nínú àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun wọ̀n-ọn-nì lọ́wọ́ yín, kí Olúwa ba à le yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀, yóò sì ṣàánú fún un yín, yóò sì bá a yín kẹ́dùn, yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i, bí ó ti fì búra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá yín. 18Nítorí pé ẹ̀yin gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ̀yin sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tí mo ń fún un yín lónìí yìí, tí ẹ̀yin sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ̀.