2 Летопись 27 – CARSA & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

2 Летопись 27:1-9

Иотам – царь Иудеи

(4 Цар. 15:32-38)

1Иотаму было двадцать пять лет, когда он стал царём, и правил он в Иерусалиме шестнадцать лет. Его мать звали Иеруша, она была дочерью Цадока. 2Он делал то, что было правильным в глазах Вечного, как и его отец Уззия, но в отличие от него, он не вторгался в храм Вечного. А народ продолжал грешить. 3Иотам перестроил Верхние ворота храма Вечного и выполнил большие работы у городской стены на холме Офел. 4Он строил города в иудейских горах и крепости с башнями в лесистых местностях.

5Иотам пошёл войной на царя аммонитян и победил его. Ежегодно в течение трёх лет аммонитяне выплачивали ему три тысячи шестьсот килограммов серебра, тысячу восемьсот тонн27:5 Букв.: «сто талантов… десять тысяч ко́ров». пшеницы и столько же ячменя.

6Иотам стал могущественным царём, потому что жил, во всём повинуясь Вечному, своему Богу.

7Прочие события царствования Иотама, все его войны и другие деяния, записаны в «Книге царей Исраила и Иудеи». 8Ему было двадцать пять лет, когда он стал царём, и правил он в Иерусалиме шестнадцать лет. 9Иотам упокоился со своими предками и был похоронен в Городе Давуда. И царём вместо него стал его сын Ахаз.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 27:1-9

Jotamu ọba Juda

1Jotamu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì di ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìn-dínlógún. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jeruṣa ọmọbìnrin Sadoku. 2Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ussiah ti ṣe, ṣùgbọ́n kìkì wí pé kò wọ ilé Olúwa. Àwọn ènìyàn síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ibi wọn. 3Jotamu sì kọ́ ẹnu-ọ̀nà gíga ilé Olúwa ó sì ṣe iṣẹ́ lórí odi ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ofeli. 4Ó sì kọ́ àwọn ìlú ní Juda òkè àti nínú igbó àti ilé ìṣọ́, ó mọ ilé odi.

5Jotamu sì ṣẹ́ ogun lórí ọba àwọn ará Ammoni ó sì borí wọn. Ní ọdún náà àwọn ará Ammoni wọ́n sì san fún ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà àti ẹgbàárùn-ún òṣùwọ̀n alikama àti ẹgbàárùn-ún barle. Àwọn ará Ammoni gbé e wá ní iye kan náà àti pẹ̀lú ní ọdún kejì àti ní ọdún kẹta.

6Jotamu sì di alágbára nítorí ó rìn ní ọ̀nà tó tọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

7Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jotamu, pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀ pẹ̀lú ohun mìíràn tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti ti Juda. 8Ó sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìn-dínlógún. 927.9: 2Ọb 15.38.Jotamu sì sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Dafidi, Ahasi ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.