2 Летопись 23 – CARSA & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

2 Летопись 23:1-21

Восстание против Аталии

(4 Цар. 11:4-20)

1На седьмом году правления Аталии Иодай решился действовать. Он заключил союз с сотниками: Азарией, сыном Иерохама, Исмаилом, сыном Иоханана, Азарией, сыном Овида, Маасеей, сыном Адаи, и Элишафатом, сыном Зихри. 2Они прошли по всей Иудее и собрали левитов и глав исраильских семейств из всех городов. Когда они пришли в Иерусалим, 3всё собрание заключило в храме Аллаха соглашение с царём.

Иодай сказал им:

– Вот сын царя! Он должен править, как и обещал Вечный о потомках Давуда. 4И вот что вы должны сделать: треть из вас – священнослужители и левиты, которые заступают на службу по субботам, – должны стеречь двери храма, 5треть из вас – царский дворец, треть – ворота Основания, а весь народ должен находиться во дворах храма Вечного. 6Пусть никто не входит в храм Вечного, кроме священнослужителей и левитов, которые на службе, – они могут войти, потому что освятились, а весь остальной народ должен оставаться снаружи, как и повелел им Вечный. 7Левиты должны встать вокруг царя, каждый с оружием в руках. Всякого, кто войдёт в храм, следует убивать. Будьте при царе, куда бы он ни пошёл.

8Левиты и все мужчины Иудеи сделали всё так, как приказал священнослужитель Иодай. Каждый взял своих людей – и тех, кто заступал на службу в ту субботу, и тех, кто в ту субботу уходил со службы, потому что священнослужитель Иодай не отпустил ни одного из групп священнослужителей. 9Он раздал сотникам копья с большими и маленькими щитами, которые некогда принадлежали царю Давуду и находились в храме Вечного. 10Он поставил всех людей, каждого с оружием в руках, вокруг царя – от южной стороны храма до северной, вокруг жертвенника и храма.

11Иодай и его сыновья вывели сына царя, возложили на него корону, дали ему копию Закона и провозгласили его царём. Его помазали и воскликнули:

– Да здравствует царь!

12Услышав шум народа, бегущего и выкрикивающего приветствия царю, Аталия отправилась к ним в храм Вечного. 13Она посмотрела и увидела: у царской колонны при входе стоял царь! Возле него были начальники отрядов и трубачи, и весь народ страны ликовал и трубил в трубы, а певцы с музыкальными инструментами пели прославляющие песни. Аталия разорвала на себе одежду и закричала:

– Заговор! Заговор!

14Священнослужитель Иодай вызвал сотников, которые распоряжались войском, и сказал им:

– Выведите её за пределы храма и убейте мечом всякого, кто за ней пойдёт.

(Потому что священнослужитель сказал: «Не предавайте её смерти в храме Вечного».)

15Её схватили и привели к входу Конских ворот царского дворца, и там её предали смерти.

16А Иодай заключил соглашение, что он сам, народ и царь будут народом Вечного. 17Весь народ пошёл к храму Баала и разрушил его. Они разбили на куски жертвенники и идолов и убили перед жертвенниками Маттана, жреца Баала.

18Затем Иодай поручил присмотр за храмом Вечного священнослужителям-левитам. Им Давуд определил служение в храме, чтобы они приносили всесожжения Вечному, как написано в Законе Мусы, с радостью и пением, как приказал Давуд. 19Ещё он поставил у ворот храма Вечного привратников, чтобы тот, кто был почему-либо нечист, не мог туда войти.

20Он взял с собой сотников, приближённых царя, правителей и весь народ страны, и они вместе вывели царя из храма Вечного и вошли в царский дворец через Верхние ворота. Они посадили царя на царский престол, 21и весь народ страны ликовал. А город, после того как Аталия была убита мечом, успокоился.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 23:1-21

1Ní ọdún keje, Jehoiada fi agbára rẹ̀ hàn. O dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún kan, Asariah ọmọ Jerohamu, Iṣmaeli ọmọ Jehohanani Asariah ọmọ Obedi, Maaseiah ọmọ Adaiah àti Elisafati ọmọ Sikri. 2Wọ́n lọ sí gbogbo Juda, wọ́n sì pe àwọn ará Lefi àti àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn ará Israẹli láti gbogbo àwọn ìlú jọ. Nígbà tí wọ́n wá sí Jerusalẹmu. 3Gbogbo ìpéjọ náà dá májẹ̀mú pẹ̀lú ọba ní ilé Ọlọ́run.

Jehoiada wí fún wọn pé, “Ọmọkùnrin ọba yóò jẹ ọba, bí Olúwa ti ṣèlérí nípa àwọn ìran Dafidi. 4Nísinsin yìí èyí ni ohun tí ó yẹ kí ó ṣe: Ìdámẹ́ta àlùfáà yín àti àwọn ará Lefi tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi ni kí ó bojútó àwọn ìlẹ̀kùn. 5Ìdámẹ́ta yín níbi ààfin ọba àti ìdámẹ́ta níbi ẹnu odi ìdásílẹ̀ àti gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí ó wà ní àgbàlá ààfin ilé Olúwa. 6Kò sí ẹnìkan tí ó gbọdọ̀ wọ inú ilé Olúwa yàtọ̀ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi tí a rán ní iṣẹ́ ìsìn. Wọ́n lè wọlé nítorí tí a ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí wọn ó sọ ohun tí Olúwa ti yàn fún wọn. 7Àwọn ará Lefi gbọdọ̀ wà ní ìdúró ṣinṣin yí ọba ká. Olúkúlùkù pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé Olúwa ni kí ẹ pa. Ẹ dúró ti ọba níbikíbi tí ó bá lọ.”

8Àwọn ará Lefi àti gbogbo ọkùnrin Juda ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada àlùfáà ti paláṣẹ. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀, àwọn tí wọ́n lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n ń kúrò ní ibi iṣẹ́. Nítorí Jehoiada àlùfáà kò ì tí tú ìpín kankan sílẹ̀. 9Jehoiada àlùfáà, sì fi ọ̀kọ̀ àti asà, àti apata wọ̀n-ọn-nì, tí ó jẹ́ ti ọba Dafidi tí wọn wà ní ilé Ọlọ́run, fún àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún. 10Ó sì to gbogbo àwọn ènìyàn ti ọba káàkiri, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, láti apá ọ̀tún ilé náà títí dé apá òsì ilé náà, lẹ́bàá pẹpẹ àti lẹ́bàá ilé náà.

11Jehoiada àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mú ọmọkùnrin ọba jáde wá wọ́n sì gbé adé sórí rẹ̀; Wọ́n mú ẹ̀dà májẹ̀mú kan fún un. Wọ́n sì kéde rẹ̀ lọ́ba. Wọ́n fi ààmì òróró yàn án, wọ́n sì kígbe pé, “Kí ọba kí ó pẹ́!”

12Nígbà tí Ataliah gbọ́ igbe àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sáré tí wọ́n ń kígbe ọba, ó lọ sí ọ̀dọ̀ wọn ní ilé Olúwa. 13Ó sì wò, sì kíyèsi, ọba dúró ní ibùdó rẹ̀ ní ẹ̀bá ẹnu-ọ̀nà, àti àwọn balógun àti àwọn afùnpè lọ́dọ̀ ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, wọ́n sì fọn ìpè, àti àwọn akọrin pẹ̀lú ohun èlò ìyìn. Nígbà náà ni Ataliah fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì kégbe wí pé, “Ọ̀tẹ̀! Ọ̀tẹ̀!”

14Jehoiada àlùfáà mú àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, tí ó wà ní àbojútó àwọn ọ̀wọ́ ogun, ó sì wá wí fún wọn pé: “Mú un jáde wá láàrín àwọn ọgbà, kí a sì fi idà pa ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí tí àlùfáà ti wí pé, “Má ṣe pa á nínú ilé Olúwa.” 15Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi ipá mú un kí ó tó dé ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ti Ẹnu Ẹṣin ilé ọba, wọ́n sì ti pa á níbẹ̀.

16Nígbà náà ni Jehoiada, dá májẹ̀mú pé òun àti àwọn ènìyàn àti ọba yóò jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run. 17Gbogbo àwọn ènìyàn lọ sí ilé Baali, wọ́n sì fà á ya lulẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti àwọn òrìṣà, wọ́n sì pa Mattani àlùfáà Baali níwájú àwọn pẹpẹ.

18Nígbà náà, Jehoiada tẹ àwòrán ilé Olúwa sí ọwọ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ẹni tí Dafidi ti fi ṣe iṣẹ́ ní ilé Olúwa láti tẹ ẹbọ sísun ti Olúwa bí a ti kọ ọ́ nínú òfin Mose, pẹ̀lú ayọ̀ àti orin kíkọ, gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti pàṣẹ. 19Ó mú àwọn olùṣọ́nà wà ni ipò ìdúró ní ẹnu odi ilé Olúwa kí ẹni aláìmọ́ nínú ohunkóhun kó má ba à wọlé.

20Ó mú pẹ̀lú rẹ̀ àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, Àwọn ẹni ọlá, àwọn olórí àwọn ènìyàn àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. Ó sì mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé Olúwa. Wọ́n lọ sínú ààfin láti ẹnu òde ti òkè. Wọ́n sì fi ọba jókòó lórí ìtẹ́. 21Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì ń yọ̀. Ìlú naà sì dákẹ́ rọ́rọ́. Nítorí tí a pa Ataliah pẹ̀lú idà.