2 Коринфянам 10 – CARSA & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

2 Коринфянам 10:1-18

Паул говорит в защиту своего служения

1Я, Паул, который, как вы говорите, всегда так робок, когда нахожусь у вас, и так смел вдали от вас, обращаюсь сейчас к вам в кротости и смирении аль-Масиха. 2Прошу вас, не вынуждайте меня, когда я буду у вас, быть смелым и строгим по отношению к тем, кто считает, что мы совершаем служение из-за каких-то человеческих соображений. 3Хотя мы и живём в этом мире, мы не воюем так, как этот мир воюет. 4Мы сражаемся не обычным оружием, которое используется в этом мире, но оружием Всевышнего, которое способно разрушить самые неприступные духовные твердыни. Мы опровергаем ложные доводы 5и сокрушаем надменность тех, кто ведёт борьбу против познания Аллаха. Мы берём в плен каждую мысль, чтобы сделать её послушной аль-Масиху. 6Мы готовы наказать тех, кто упорствует в непослушании аль-Масиху, как только остальные докажут нам своё послушание и преданность.

7Вы смотрите на вещи поверхностно10:7 Или: «Так смотрите же на то, что и так лежит на поверхности».. И тот, кто гордится своими особыми взаимоотношениями с аль-Масихом, тот должен знать, что и мы принадлежим аль-Масиху так же, как и он. 8Даже если бы я стал ещё больше хвалиться той властью, которую Повелитель дал нам для созидания, а не для разрушения, мне не пришлось бы стыдиться.

9Пусть никто не думает, будто я только хочу запугать вас своими посланиями. 10Некоторые говорят, что в посланиях-то я строг и силён, но когда я присутствую лично, то я слаб, а мои слова слишком незначительны. 11Пусть те, кто так говорит, знают, что каковы мы в посланиях, таковы будем и на деле, когда придём к вам.

12Мы не хотим уподобляться тем из вас, кто сам возвышает себя, или сравнивать себя с ними. Они поступают глупо, сравнивая и соизмеряя себя с самими же собой. 13А мы не будем преувеличивать собственную значимость, но будем отстаивать свои права в тех пределах, что даны нам Аллахом, а сюда входит и наша работа среди вас. 14Ведь мы не выходим за эти пределы, как если бы мы не приходили к вам, но мы на самом деле были первыми, кто принёс вам Радостную Весть об аль-Масихе. 15Мы не хвалимся без меры, потому что наш труд – это наша, а не чужая заслуга. Мы надеемся, что ваша вера будет расти, а вместе с тем будут расширяться и пределы нашей деятельности у вас. 16И тогда мы сможем идти дальше и там возвещать Радостную Весть, а не хвалиться тем, что сделано другими в их собственных пределах. 17«Тот, кто хвалится, пусть хвалится Вечным Повелителем»10:17 Иер. 9:24.. 18Ведь не тот достоин одобрения, кто сам себя хвалит, а тот, кого хвалит Повелитель.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kọrinti 10:1-18

Paulu gbèjà iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀

110.1: 2Kọ 10.10.Ṣùgbọ́n èmi Paulu fúnra mi fi inú tútù àti ìwà pẹ̀lẹ́ Kristi bẹ̀ yín, èmi ẹni ìrẹ̀lẹ̀ lójú yín nígbà tí mo wà láàrín yín, ṣùgbọ́n nígbà tí èmi kò sí, mo di ẹni ìgboyà sí yín. 210.2: 2Kọ 13.2,10; 1Kọ 4.21.Ṣùgbọ́n èmi bẹ̀ yín pé nígbà tí mo wà láàrín yín, kí èmi ba à lè lo ìgboyà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé náà, eléyìí tí mo ti fọkàn sí láti fi dojúkọ àwọn kan, ti ń funra sí wa bí ẹni tí ń rìn nípa ìlànà ti ayé yìí. 3Nítorí pé, bí àwa tilẹ̀ n gbé nínú ayé, ṣùgbọ́n àwa kò jagun nípa ti ara. 4Nítorí ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n ó lágbára nínú Ọlọ́run láti wó ibi gíga palẹ̀. 5Àwa ń sọ gbogbo èrò àti gbogbo ohun gíga ti ń gbe ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ́run kalẹ̀, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbèkùn wá sí ìtẹríba fún Kristi. 610.6: 2Kọ 2.9.Àwa sì ti murá tan láti jẹ gbogbo àìgbọ́ràn ní yà, nígbà tí ìgbọ́ràn yín bá pé.

710.7: 1Kọ 1.12.Ẹ̀yin sì ń wo nǹkan gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fihàn lóde. Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìgboyà nínú ara rẹ̀, ti Kristi ni òun, kí ó tún rò lẹ́ẹ̀kan si pé, bí òun ti jẹ́ ti Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwa pẹ̀lú jẹ́ ti Kristi. 8Nítorí bí mo tilẹ̀ ń ṣògo bí ó ti wù mi nítorí agbára, tí Olúwa ti fi fún wá fún ìdàgbàsókè, dípò fífà yín ṣubú, ojú kí yóò tì mí. 9Kí ó má ṣe dàbí ẹni pé èmi ń fi ìwé kíkọ dẹ́rùbà yín. 1010.10: 1Kọ 2.3.Nítorí wọ́n wí pé, “Ìwé rẹ wúwo, wọn sì lágbára; ṣùgbọ́n ní ti ara ìrísí rẹ̀ jẹ aláìlera, ọ̀rọ̀ rẹ kò níláárí.” 11Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé, irú ẹni tí àwa jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ nípa ìwé kíkọ nígbà tí àwa kò sí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa sì jẹ́ nínú iṣẹ́ pẹ̀lú nígbà ti àwa bá wà.

12Nítorí pé àwa kò dáṣà láti ka ara wa mọ́, tàbí láti fi ara wa wé àwọn mìíràn nínú wọn tí ń yin ara wọn; ṣùgbọ́n àwọn fúnrawọn jẹ́ aláìlóye bí wọn ti ń fi ara wọn díwọ̀n ara wọ́n, tí wọ́n sì ń fi ara wọn wé ara wọn. 13Ṣùgbọ́n àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, ṣùgbọ́n nípa ààlà ìwọ̀n tí Ọlọ́run ti pín fún wa, èyí tí ó mú kí ó ṣe é ṣe láti dé ọ̀dọ̀ yín. 14Nítorí àwa kò nawọ́ wa rékọjá rárá, bí ẹni pé àwa kò dé ọ̀dọ̀ yín: nítorí àwa tilẹ̀ dé ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú nínú ìhìnrere Kristi. 1510.15: Ro 15.20.Àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, èyí nì, lórí iṣẹ́ ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí ààlà wa, àwa ó dí gbígbéga lọ́dọ̀ yín sí i lọ́pọ̀lọpọ̀. 16Kí a bá à lè wàásù ìhìnrere ní àwọn ìlú tí ń bẹ níwájú yín, kí a má sì ṣògo nínú ààlà ẹlòmíràn nípa ohun tí ó wà ní àrọ́wọ́tó. 1710.17: Jr 9.24.“Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.” 18Nítorí kì í ṣe ẹni tí ń yin ara rẹ̀ ni ó ní ìtẹ́wọ́gbà, bí kò ṣe ẹni tí Olúwa bá yìn.