1 Летопись 17 – CARSA & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

1 Летопись 17:1-27

Обещание Аллаха Давуду

(2 Цар. 7:1-17)

1После того как Давуд поселился в своём дворце, он сказал пророку Нафану:

– Смотри, я живу во дворце из кедра, а сундук соглашения с Вечным стоит в шатре.

2Нафан ответил Давуду:

– Иди и делай то, что у тебя на сердце, потому что Аллах с тобой.

3В ту ночь к Нафану было слово Аллаха:

4– Пойди и скажи Моему рабу Давуду: Так говорит Вечный: «Не ты построишь Мне дом для обитания. 5Я не жил в доме с того дня, как вывел Исраил из Египта, и до сегодняшнего дня, но обитал в шатре и переходил с места на место. 6Где бы Я ни ходил со всеми исраильтянами, разве Я когда-либо говорил кому-нибудь из их судей17:6 В период после завоевания Ханаана и до восшествия на престол царей Аллах ставил вождей, называемых судьями, которые защищали и управляли исраильским народом. Об этом можно прочитать в книге Судей., которым Я повелел пасти Мой народ: „Почему вы не построили Мне дом из кедра?“»

7Итак, скажи Моему рабу Давуду: Так говорит Вечный, Повелитель Сил: «Я взял тебя, когда ты смотрел и ухаживал на пастбище за овцами, чтобы ты стал правителем Моего народа Исраила. 8Я был с тобой, куда бы ты ни ходил, и сокрушил перед тобой всех твоих врагов. Я сделаю твоё имя великим, подобным именам великих людей земли. 9Я устрою место для Своего народа Исраила и укореню его, чтобы у него был свой дом и чтобы никто его больше не тревожил. Нечестивые люди не будут больше притеснять его, как прежде, 10с того времени, как Я поставил судей над Своим народом Исраилом. Я смирю всех твоих врагов.

Я объявляю тебе, что Сам устрою твой дом. 11Когда твои дни завершатся, и ты отойдёшь к своим предкам, Я возведу на престол твоего потомка, одного из твоих сыновей, и упрочу его царство. 12Он построит Мне дом, а Я упрочу его престол навеки. 13Я буду назван его Отцом, а он Мне сыном наречётся. Я не отниму от него Своей любви, как отнял её от твоего предшественника. 14Я поставлю его над Своим домом и Своим царством навечно, и его престол будет установлен навеки»17:13-14 Эти слова также являются пророчеством об Исе аль-Масихе (см. Лк. 1:32; Рим. 1:3-4; Евр. 1:5)..

15Нафан передал Давуду все слова этого откровения.

Молитва Давуда

(2 Цар. 7:18-29)

16Тогда царь Давуд вошёл, сел перед Вечным и сказал:

– Кто я, о Вечный Бог, и что такое моя семья, что Ты так возвеличил меня? 17И словно этого не было достаточно в Твоих глазах, Аллах, Ты ещё рассказал о будущем дома Твоего раба. Ты открыл мне то, что человек желает знать, о Вечный Бог. 18Что ещё может сказать Тебе Давуд за прославление Твоего раба? Ведь Ты знаешь Своего раба, 19о Вечный! Ради Своего раба и по Своей воле Ты совершил это великое дело и дал все эти великие обещания.

20Нет подобного Тебе, Вечный, и нет Бога, кроме Тебя, как слышали мы своими ушами. 21И кто подобен Исраилу, единственному народу на земле, который Всевышний выкупил Себе, чтобы сделать Своим народом? Чтобы все узнали имя Твоё, Ты совершил великие и ужасные дела, выкупив Свой народ из Египта и изгнав перед ним другие народы. 22Ты сделал Исраил Своим собственным народом навеки, и Ты, о Вечный, стал его Богом.

23И теперь, Вечный, пусть обещание, которое Ты дал о Своём рабе и его доме, утвердится навеки, и сделай, как Ты обещал. 24Пусть пребудет и возвеличится Твоё имя вовеки, чтобы люди говорили: «Вечный, Повелитель Сил, Бог Исраила, есть Бог над Исраилом!» И дом Твоего раба Давуда утвердится перед Тобой.

25Так как Ты, мой Бог, открыл Своему рабу, что устроишь его дом, то раб Твой нашёл в себе смелость молиться перед Тобой. 26Вечный, Ты – Бог! Ты обещал Своему рабу это благо. 27Пусть же станет Тебе угодно благословлять дом Твоего раба, чтобы он был перед Тобой вечно. Ведь Ты, Вечный, благословил его, и он будет благословен навеки!

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 17:1-27

Ìlérí Ọlọ́run sí Dafidi

117.1-27: 2Sa 7.1-29.Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti fi ìdí kalẹ̀ sínú ààfin rẹ̀, ó sọ fún Natani wòlíì pé, “Èmi nìyí, tí ń gbé inú òpépé (igi) ààfin kedari nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa wà lábẹ́ àgọ́.”

2Natani dá Dafidi lóhùn pé, “Ohunkóhun tí o bá ní lọ́kàn, ṣe é nítorí tí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.”

3Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Natani wá, wí pé:

4“Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé. 5Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé. 6Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Israẹli rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkan kan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Israẹli, tí èmí pàṣẹ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yin kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kedari kọ́ fún mi?” ’

7“Nígbà náà, sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi mú ọ kúrò ní pápá oko tútù wá, àní kúrò lẹ́yìn agbo àgùntàn, kí ìwọ kí ó lè máa ṣe olórí àwọn ènìyàn mi Israẹli. 8Èmi ti wà pẹ̀lú rẹ ní, ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmí sì ti gé gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ. Nísinsin yìí Èmi yóò mú kí orúkọ rẹ kí ó dàbí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá jùlọ tí ó wà ní ayé. 9Èmi yóò sì pèsè ààyè kan fún àwọn ènìyàn mi Israẹli, kí wọn kí ó lè ní ilé tiwọn, kí a má sì ṣe dààmú wọn mọ́. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò ni wọ́n lára mọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀. 10Bí wọ́n sì ti ṣe láti ìgbà tí mo ti yan àwọn aṣáájú lórí àwọn ènìyàn mi Israẹli. Èmi pẹ̀lú yóò ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀tá yín.

“ ‘Èmi sọ fún yín pé Olúwa yóò kọ́ ilé kan fún yín: 11Nígbà ti ọjọ́ rẹ bá kọjá, tí ìwọ bá lọ láti lọ bá àwọn baba à rẹ, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ sókè láti rọ́pò rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ tìrẹ, Èmi yóò sì fìdí ìjọba rẹ̀ kalẹ̀. 12Òun ni ẹni tí yóò kọ́ ilé fún mi, èmi yóò sí fi ìdí ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ títí láé. 13Èmi yóò jẹ́ baba rẹ̀, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi. Èmi kì yóò mú ìfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ láéláé gẹ́gẹ́ bí mo ṣe mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú rẹ̀. 14Èmi yóò gbé e ka orí ilé mi àti ìjọba mi títí láé; ìtẹ́ rẹ̀ ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.’ ”

15Natani ròyìn fún Dafidi gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti ìfihàn yí.

Àdúrà Dafidi

16Nígbà náà, ọba Dafidi wọlé lọ, ó sì jókòó níwájú Olúwa ó sì wí pé:

“Ta ni èmi, Olúwa Ọlọ́run, àti ki ni ìdílé mi, tí ìwọ mú mi dé ibí? 17Pẹ̀lú bí ẹni pé èyí kò tó lójú rẹ, Ọlọ́run. Ìwọ ti sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ iwájú ilé ìránṣẹ́ rẹ. Ìwọ ti wò mí bí ẹni pé èmi ni ẹni gbígbéga jù láàrín àwọn ọkùnrin Olúwa Ọlọ́run.

18“Kí ni ohun tí Dafidi tún lè sọ nítorí ọlá tí o bù fún ìránṣẹ́ rẹ? Nítorí tí ìwọ mọ ìránṣẹ́ rẹ, 19Olúwa. Nítorí ti ìránṣẹ́ rẹ àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ rẹ, ìwọ ti ṣe ohun ńlá yìí àti láti fi gbogbo ìlérí ńlá yìí hàn.

20“Kò sí ẹnìkan bí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan àfi ìwọ, gẹ́gẹ́ bí à ti gbọ́ pẹ̀lú etí ara wa. 21Pẹ̀lú ta ni ó dàbí àwọn ènìyàn rẹ Israẹli—orílẹ̀-èdè kan ní ayé, tí Ọlọ́run jáde lọ láti ra àwọn ènìyàn kan padà fún ara rẹ̀, àti láti lè ṣe orúkọ fún ara à rẹ, àti láti ṣe ohun ńlá àti ọwọ́ ìyanu nípa lílé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀, ẹni tí ó gbàlà láti Ejibiti? 22Ìwọ ṣe àwọn ènìyàn rẹ Israẹli ní tìrẹ láéláé ìwọ Olúwa sì ti di Ọlọ́run wọn.

23“Nísinsin yìí, Olúwa, Jẹ́ kí ìlérí tí ìwọ ti ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ àti ilé rẹ̀ di fífi ìdí múlẹ̀ títí láé. Ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe ìlérí. 24Kí ó lè di fífi ìdí múlẹ̀ àti kí orúkọ rẹ di gbígbéga títí láé. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin yóò wí pé, ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni Ọlọ́run Israẹli.’ Ilé ìránṣẹ́ rẹ Dafidi sì ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ.

25“Ìwọ, Ọlọ́run mi, ti fihan ìránṣẹ́ rẹ pé, ìwọ yóò kọ́ ilé fún un. Bẹ́ẹ̀ ni ìránṣẹ́ rẹ ti ní ìgboyà láti gbàdúrà sí ọ. 26Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run. Ìwọ ti fi ìlérí dídára yìí fún ìránṣẹ́ rẹ. 27Nísinsin yìí ó ti tẹ́ ọ lọ́rùn láti bùkún ilé ìránṣẹ́ rẹ kí ó lè tẹ̀síwájú ní ojú rẹ; nítorí ìwọ, Olúwa, ti bùkún un, a ó sì bùkún un títí láéláé.”