Римлянам 13 – CARSA & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

Римлянам 13:1-14

О власти

1Каждый человек должен подчиняться существующей власти, потому что нет власти не от Аллаха. Все существующие власти установлены Аллахом. 2Следовательно, тот, кто восстаёт против власти, – восстаёт против установленного Аллахом, и кто так поступает, тот сам на себя навлекает суд. 3Правители страшны не тем, кто делает добро, а тем, кто делает зло. Если хочешь жить без страха перед властью, делай добро и получишь от неё похвалу. 4Представитель власти на службе у Аллаха для твоего блага. Если же ты делаешь зло, то берегись, он не напрасно носит меч. Он – слуга Аллаха, орудие Его гнева, направленное на того, кто делает зло. 5Так что необходимо подчиняться власти не только из страха перед наказанием, но и по совести.

6Вы и налоги платите потому, что стоящие у власти – слуги Аллаха, посвящающие себя своему делу. 7Так что отдавайте всем то, что им надлежит: кому налог – налог, кому пошлину – пошлину, кому уважение – уважение, кому честь – честь.

О братской любви

8Не оставайтесь в долгу ни у кого ни в чём, кроме долга любви друг к другу, потому что любящий ближнего исполнил Закон. 9Вот в чём суть повелений Закона: «Не нарушай супружескую верность», «не убивай», «не кради», «не пожелай чужого»13:9 Исх. 20:13-15, 17; Втор. 5:17-19, 21., и суть любого другого повеления одна – «люби ближнего твоего, как самого себя»13:9 Лев. 19:18.. 10Любовь не причиняет зла ближнему, поэтому любовь и есть исполнение Закона.

Приближение последнего дня

11Вы ведь знаете, какое сейчас время, что настал час пробудиться вам ото сна, потому что наше спасение сейчас гораздо ближе, чем оно было тогда, когда мы только уверовали. 12Ночь приближается к концу, и наступает день. Так давайте же оставим дела тьмы и наденем доспехи света. 13Будем жить достойно, как при свете дня, не предаваясь оргиям, пьянству, разврату, распущенности, вражде и зависти. 14Пусть лучше Повелитель Иса аль-Масих станет вашими доспехами. И не думайте об угождении своей греховной природе и её желаниям.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Romu 13:1-14

Ṣíṣe ìgbọ́ràn sí àwọn aláṣẹ

113.1: Tt 3.1; 1Pt 2.13-14; Òw 8.15; Jh 19.11.Kí olúkúlùkù ọkàn kí ó foríbalẹ̀ fún àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga. Nítorí kò sí àṣẹ kan, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a ti lànà rẹ̀ wá. 2Nítorí ẹni tí ó bá tàpá sí àṣẹ, ó tàpá sí ìlànà Ọlọ́run; àwọn ẹni tí ó ba sì ń tàpá, yóò gba ẹ̀bi fún ara wọn. 313.3: 1Pt 2.14.Nítorí àwọn ìjòyè kò wá láti dẹ́rùbà àwọn tí ń ṣe rere, bí kò ṣe àwọn tó ń ṣe búburú. Ǹjẹ́ ìwọ ha fẹ́ di òmìnira kúrò nínú ẹ̀rù ẹni tó wà ní ipò àṣẹ. Nítorí náà ṣe èyí tó ó dára, ìwọ yóò sì gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. 413.4: 1Tẹ 4.6.Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni i ṣe fún ọ́ sí rere. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń ṣé búburú, máa bẹ̀rù, nítorí kò gbé idà náà lásán. Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní í ṣe, olùgbẹ̀san láti ṣiṣẹ́ ìbínú lára ẹni tí ń ṣe búburú. 5Nítorí náà, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ má tẹríba fún àwọn aláṣẹ, kì í ṣe nítorí ti ìbínú nìkan, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀rí ọkàn pẹ̀lú.

6Nítorí ìdí èyí, ẹ san owó òde pẹ̀lú, nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n, èyí náà ni wọ́n ń bojútó nígbà gbogbo. 713.7: Mt 22.21; Mk 12.17; Lk 20.25.Ẹ san ohun tí ó tọ́ fún ẹni gbogbo: owó òde fún ẹni tí owó òde í ṣe tirẹ̀: owó bodè fún ẹni tí owó bodè í ṣe tirẹ̀: ẹ̀rù fún ẹni tí ẹ̀rù í ṣe tirẹ̀; ọlá fún ẹni tí ọlá í ṣe tirẹ̀.

Ẹ jẹ gbèsè ìfẹ́

813.8: Mt 22.39-40; Ro 13.10; Ga 5.14; Kl 3.14; Jk 2.8.Ẹ má ṣe jẹ ẹnikẹ́ni nígbésè ohun kan, bí kò ṣe pé kí a fẹ́ ọmọ ẹnìkejì ẹni, nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀, ó kó òfin já. 913.9: Ek 20.13-14; De 5.17-18; Le 19.18; Mt 19.19.Àwọn òfin, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò,” bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ ṣọ̀kan nínú òfin kan yìí: “Fẹ́ ẹnìkéjì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.” 1013.10: Mt 22.39-40; Ro 13.8; Ga 5.14; Jk 2.8.Ìfẹ́ kì í ṣe ohun búburú sí ọmọnìkejì rẹ̀: nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin.

Ọjọ́ Olúwa fẹ́rẹ dé

1113.11: Ef 5.14; 1Tẹ 5.6.Àti èyí, bí ẹ̀yin ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsin yìí fún yín láti jí lójú orun: nítorí nísinsin yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ. 1213.12: 1Jh 2.8; Ef 5.11; 1Tẹ 5.8.Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀. 1313.13: 1Tẹ 4.12; Ga 5.19-21.Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmutípara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì í ṣe ní ìjà àti ìlara. 1413.14: Ga 3.27; 5.16.Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.