Исаия 4 – CARSA & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

Исаия 4:1-6

1В тот день семь женщин

ухватятся за одного мужчину и скажут:

– Мы будем есть свой хлеб

и одеваться в свою одежду,

только позволь нам называться твоим именем.

Сними с нас позор незамужества!

Ветвь Вечного

2В тот день Ветвь4:2 Ветвь – одно из имён Исы аль-Масиха (см. также Иер. 23:5-6; Зак. 3:8; 6:12-13; Рим. 15:8-13). Вечного будет прекрасна и прославлена, и плод земли будет гордостью и славой уцелевших в Исраиле. 3Оставшиеся на Сионе и уцелевшие в Иерусалиме будут названы святым народом Аллаха, все, кто записан для жизни в Иерусалиме. 4Вечный отмоет нечистоту женщин Сиона; Он отчистит кровавые пятна с Иерусалима духом суда и духом огня4:4 Также возможно, что здесь говорится о Духе Аллаха, как о несущем суд и огонь.. 5Тогда Вечный сотворит над горой Сион и над всеми, кто соберётся там, облако дыма днём и сияние пылающего огня ночью. Над всей славой Сиона будет покров. 6Он будет убежищем и тенью от дневного зноя, приютом и укрытием от бури и дождя.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 4:1-6

1Ní ọjọ́ náà, obìnrin méje

yóò dì mọ́ ọkùnrin kan

yóò sì wí pé, “Àwa ó máa jẹ oúnjẹ ara wa

a ó sì pèsè aṣọ ara wa;

sá à jẹ́ kí a máa fi orúkọ rẹ̀ pè wá.

Mú ẹ̀gàn wa kúrò!”

Ẹ̀ka Olúwa náà

24.2: Jr 23.5; 33.15; Sk 3.8; 6.12.Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka Olúwa yóò ní ẹwà àti ògo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní Israẹli. 3Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Sioni, àwọn tí o kù ní Jerusalẹmu, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jerusalẹmu. 4Olúwa yóò wẹ ẹ̀gbin àwọn obìnrin Sioni kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí iná. 5Lẹ́yìn náà, Olúwa yóò dá sórí òkè Sioni àti sórí i gbogbo àwọn tí ó péjọpọ̀ síbẹ̀, kurukuru èéfín ní ọ̀sán àti ìtànṣán ọ̀wọ́-iná ní òru, lórí gbogbo ògo yìí ni ààbò yóò wà. 6Èyí ni yóò jẹ́ ààbò àti òjìji kúrò lọ́wọ́ ooru ọ̀sán, àti ààbò òun ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì àti òjò.