Езекиил 26 – CARSA & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

Езекиил 26:1-21

Пророчество о Тире

1В одиннадцатом году, в первый день месяца (587 (586) г. до н. э.), было ко мне слово Вечного:

2– Смертный, за то, что Тир, насмехаясь, сказал об Иерусалиме: «Вот! Врата народов разрушены, распахнуты для меня. Он опустошён, и теперь я буду благоденствовать», 3Владыка Вечный говорит: «Я твой противник, Тир. Я подниму против тебя многие народы, подобно тому, как море вздымает волны. 4Они сломают твои стены и разрушат твои башни, а Я вымету из тебя пыль и сделаю голой скалой. 5Посреди моря ты станешь местом, где раскидывают рыбацкие сети, потому что Я так сказал, – возвещает Владыка Вечный. Ты будешь разграблен народами, 6а твои селения на земле будут преданы мечу. Тогда ты узнаешь, что Я – Вечный».

7Ведь так говорит Владыка Вечный: «Смотрите, Я веду с севера на Тир Навуходоносора, царя Вавилона, царя царей, с конями и колесницами, всадниками и огромным, могучим войском. 8Он опустошит твои селения на земле мечом. Он возведёт против тебя осадные валы, сделает насыпь у твоих стен и обратит против тебя щиты. 9Он прикажет бить в твои стены таранами и разрушить твои башни кирками. 10Коней у него будет так много, что поднятая ими пыль покроет тебя. Твои стены дрогнут от топота его боевых коней, повозок и колесниц, когда он войдёт в твои ворота, как входят в город, стены которого были пробиты. 11Копыта его коней будут попирать твои улицы. Он перебьёт твоих жителей мечом, и твои мощные колонны рухнут на землю. 12Твои богатства разграбят, твои товары расхитят. Твои стены сломают, роскошные дома разрушат, а камни, дерево и мусор бросят в море. 13Я положу конец твоим шумным песням, и музыка твоих арф смолкнет. 14Я сделаю тебя голой скалой; ты станешь местом, где раскидывают рыбацкие сети. Ты никогда не будешь вновь отстроен, потому что Я, Вечный, так сказал», – возвещает Владыка Вечный.

15Так говорит Тиру Владыка Вечный:

– Неужели побережье не вздрогнет от шума твоего падения, когда застонут раненые, когда в тебе начнётся резня? 16Тогда властители побережья сойдут с престолов, сбросят мантии и снимут расшитые одежды. Охваченные трепетом, они будут сидеть на земле, вздрагивая каждый миг и ужасаясь твоей доле. 17Они поднимут о тебе плач; они скажут тебе:

«Как сгинул ты, славный город,

мореходами населённый!

Ты был силою на морях,

ты и твои горожане,

что наводили страх

на всё побережье.

18Ныне, в день твоего падения,

содрогаются берега;

острова, что на море,

ужасаются твоей гибели».

19Так говорит Владыка Вечный:

– Когда Я сделаю тебя опустошённым городом, подобным тем городам, где никто больше не живёт, когда Я сомкну над тобой океанскую бездну, и её великие воды покроют тебя, 20тогда Я сведу тебя с теми, кто спускается в пропасть, к тем, кто жил в древности. Я поселю тебя в нижнем мире, среди вековечных развалин, с теми, кто спускается в пропасть, чтобы ты больше не был населён и не занял места26:20 Или: «…населён, и Я дам красоту». на земле живых. 21Я пошлю тебе страшный конец, и тебя не станет. Тебя будут искать, но не найдут, – возвещает Владыка Вечный.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 26:1-21

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Tire

126.1–28.19: Isa 23; Jl 3.4-8; Am 1.9-10; Sk 9.3-4.Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kọ́kànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn, nítorí pé Tire sọ nípa Jerusalẹmu pé, ‘Háà! A fọ́ èyí tí í ṣe bodè àwọn orílẹ̀-èdè, a yí i padà sí mi, èmi yóò di kíkún, òun yóò sì di ahoro,’ 3nítorí náà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, èmí dojúkọ ọ́ ìwọ Tire, Èmi yóò sì jẹ́ kí orílẹ̀-èdè púpọ̀ dìde sí ọ, gẹ́gẹ́ bí Òkun tí ru sókè. 4Wọn yóò wó odi Tire lulẹ̀, wọn yóò sì wo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀; Èmi yóò sì ha erùpẹ̀ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orí àpáta. 5Yóò sì jẹ́ ibi nína àwọ̀n tí wọn fi ń pẹja sí láàrín Òkun, ní Olúwa Olódùmarè wí. Yóò di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè. 6Ìlú tí ó tẹ̀dó sí, ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó fi idà sọ ọ́ di ahoro. Nígbà náà ní wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.

7“Nítorí báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, láti ìhà àríwá ni èmi yóò ti mú Nebukadnessari ọba Babeli, ọba àwọn ọba, dìde sí Tire pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun. 8Yóò sì fi idà sá àwọn ọmọbìnrin rẹ ní oko, yóò sì kọ́ odi tì ọ́, yóò sì mọ òkìtì tì ọ́, yóò sì gbé apata sókè sí ọ. 9Yóò sì gbé ẹ̀rọ ogun tí odi rẹ, yóò sì fi ohun èlò ogun wó ilé ìṣọ́ rẹ palẹ̀. 10Àwọn ẹṣin rẹ̀ yóò pọ̀ dé bí pé wọn yóò fi eruku bò ọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn ògiri rẹ yóò mì tìtì fún igbe àwọn ẹṣin ogun kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kẹ̀kẹ́ ogun nígbà tí ó bá wọ ẹnu-ọ̀nà odi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń wọ ìlú láti inú àwọn ògiri rẹ̀ ti ó di fífọ́ pátápátá. 11Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin rẹ̀ ni yóò fi tẹ gbogbo òpópónà rẹ mọ́lẹ̀; yóò fi idà pa àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọ̀wọ́n rẹ ti o lágbára yóò wó palẹ̀. 12Wọn yóò kó ọrọ̀ rẹ, wọn yóò sì fi òwò rẹ ṣe ìjẹ ogun; wọn yóò sì wó odi rẹ lulẹ̀, wọn yóò sì ba àwọn ilé rẹ dídára jẹ́, wọn yóò sì kó àwọn òkúta rẹ̀, àti igi ìtì ìkọ́lé rẹ̀, àti erùpẹ̀ rẹ̀, dà sí inú Òkun. 1326.13: If 18.22.Èmi yóò sì mú ariwo orin rẹ̀ dákẹ́ àti ìró dùùrù orin rẹ̀ ni a kì yóò gbọ́ mọ́. 14Èmi yóò sọ ọ di àpáta lásán, ìwọ yóò sì di ibi tí a ń sá àwọ̀n ẹja sí. A kì yóò sì tún ọ mọ nítorí èmi Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ ní Olúwa Olódùmarè wí.

15“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí Tire: Ǹjẹ́ àwọn erékùṣù kì yóò ha wárìrì nípa ìṣubú rẹ, nígbà tí ìkórìíra ìpalára àti rírẹ́ni lọ́run bá ń ṣẹlẹ̀ ní inú rẹ? 1626.16-17: If 18.9-10.Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ-aládé etí Òkun yóò sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn da, tì wọn yóò sì bọ́ àwọn aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ kúrò. Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jókòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́. 17Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé:

“ ‘Báwo ni a ṣe pa ọ́ run, ìwọ ìlú olókìkí

ìwọ tí àwọn èrò okun ti gbé inú rẹ̀!

Ìwọ jẹ alágbára lórí okun gbogbo

òun àti àwọn olùgbé inú rẹ̀;

ìwọ gbé ẹ̀rù rẹ

lórí gbogbo olùgbé ibẹ̀.

18Nísinsin yìí erékùṣù wárìrì

ní ọjọ́ ìṣubú rẹ;

erékùṣù tí ó wà nínú Òkun

ni ẹ̀rù bà torí ìṣubú rẹ.’

19“Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ahoro, gẹ́gẹ́ bi àwọn ìlú tí a kò gbé inú wọn mọ́, àti nígbà tí èmi yóò mú ibú agbami Òkun wá sí orí rẹ, omi ńlá yóò sì bò ọ́, 20nígbà tí èmi yóò mú ọ wálẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, pẹ̀lú àwọn ènìyàn àtijọ́. Èmi yóò sì gbé ọ lọ si bi ìsàlẹ̀, ní ibi ahoro àtijọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, ìwọ kì yóò sì padà gbé inú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì gbé ògo kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè. 21Èmi yóò ṣe ọ ní ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́. Bí a tilẹ̀ wá ọ, síbẹ̀ a kì yóò tún rí ọ mọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.”