Езекиил 24 – CARSA & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

Езекиил 24:1-27

Притча о котле

1В девятом году, в десятый день десятого месяца (15 января 588 г. до н. э.), было ко мне слово Вечного:

2– Смертный, запиши этот день, сегодняшний день, потому что царь Вавилона в этот день осадил Иерусалим. 3Поведай этому мятежному народу притчу. Скажи им: Так говорит Владыка Вечный:

«Поставь котёл;

поставь и налей воды.

4Брось в него мясо,

хорошее мясо – окорок и лопатку, –

и наполни лучшими из костей.

5Возьми отборных овец;

разложи под котлом дрова;

пусть он кипит,

и пусть в нём сварятся кости».

6Ведь так говорит Владыка Вечный:

«Горе кровавому городу,

котлу проржавевшему,

чья ржавчина не отчистилась!

Опустошите его,

выбрасывая из него кусок за куском,

не выбирая по жребию.

7Жители его проливали невинную кровь;

они проливали её на голые камни,

а не на землю,

где её покрыла бы пыль.

8Пробуждая для мести Мой гнев,

Я оставил ту кровь на голой скале,

где её нельзя будет скрыть».

9Поэтому так говорит Владыка Вечный:

«Горе кровавому городу!

Я тоже сложу много дров для костра.

10Подложи дров,

разведи огонь,

развари мясо,

добавь приправу,

и пусть обуглятся кости.

11Поставь котёл на угли пустым,

чтобы он разогрелся,

и медь его раскалилась,

чтобы грязь его в нём расплавилась,

и ржавчина отгорела.

12Нет, впустую Я утомлял Себя:

не сошла глубокая ржавчина

даже с помощью огня».

13– Твоя нечистота – это распутство. Когда Я пытался очистить тебя, ты не очистился, а теперь ты не очистишься до тех пор, пока Мой гнев на тебя не утихнет.

14Я, Вечный, сказал это. Настало время Мне действовать. Я не буду сдерживаться, щадить и сожалеть. Ты будешь судим по твоим путям и делам, – возвещает Владыка Вечный.

Смерть жены Езекиила

15Было ко мне слово Вечного:

16– Смертный, Я одним ударом отниму у тебя усладу твоих глаз. Но не скорби, не сетуй и не проливай слёз. 17Стони тихо, не устраивай плача по умершим. Не следуй ритуалам: не снимай головной убор и сандалии, не закрывай нижнюю часть лица и не ешь пищу плакальщиков.

18Утром я говорил с народом, а вечером у меня умерла жена. На следующее утро я исполнил то, что мне было велено. 19Тогда люди спросили меня:

– Не скажешь ли, какое значение имеет для нас то, что ты не скорбишь?

20Я сказал им:

– Было ко мне слово Вечного: 21Скажи исраильтянам: Так говорит Владыка Вечный: «Я оскверню Своё святилище – крепость, которой вы гордитесь, усладу ваших глаз, которой жаждут ваши сердца. Оставленные вами сыновья и дочери падут от меча». 22Вы будете делать так, как делал я. Вы не будете закрывать нижнюю часть лица и есть пищу плакальщиков. 23На головах у вас будут головные повязки, а на ногах – сандалии. Вы не будете ни скорбеть, ни сетовать, но станете чахнуть из-за своих грехов24:23 Или: «в своих грехах». и тихо стонать.

24– Езекиил будет вам знамением: вы будете делать так, как делал он. Когда это сбудется, вы узнаете, что Я – Владыка Вечный.

25А что до тебя, смертный, то в день, когда Я отниму у них твердыню, их ликование и славу, усладу их глаз, к которой стремятся их сердца, и их сыновей и дочерей, 26в тот самый день придёт уцелевший, чтобы рассказать тебе новости. 27Тогда твои уста откроются. Ты заговоришь с ним и не будешь больше хранить молчание. Ты будешь для них знамением, и они узнают, что Я – Вечный.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 24:1-27

Ìkòkò ìdáná náà

1Ní ọdún kẹsànán, oṣù kẹwàá, ọjọ́ kẹwàá, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn, kọ ọjọ́ náà sílẹ̀, ọjọ́ náà gan an, nítorí ọba Babeli náà ti da ojú ti Jerusalẹmu ní ọjọ́ yìí gan an. 3Sì pa òwe yìí fún ilé ọlọ́tẹ̀ náà, sọ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Gbé ìkòkò ìdáná náà ka iná:

Gbé e ka iná kí o sì da omi sí i nínú.

4Kó àwọn ègé ẹran tí a gé náà sínú rẹ̀,

gbogbo àwọn ègé ẹran tí ó tóbi, itan àti apá.

Kó àwọn egungun tí ó dára jù sínú rẹ̀

5Mú àwọn tí ó jọjú nínú agbo ẹran.

Kó àwọn egungun sí abẹ́ ẹ rẹ̀;

sì jẹ́ kí ó hó dáradára

sì jẹ́ kí àwọn egungun náà bọ̀ nínú rẹ̀.

6“ ‘Nítorí báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà,

fún ìkòkò náà tí èérí rẹ̀ wà nínú rẹ̀,

tí èérí kò dà kúrò lójú rẹ̀!

Mú ẹran náà jáde ní ekìrí ekìrí

má ṣe ṣà wọ́n mú.

7“ ‘Nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ wà ní àárín rẹ̀;

à á sí orí àpáta kan lásán

kò dà á sí orí ilẹ̀,

níbi ti erùpẹ̀ yóò ti bò ó

8Láti bá à le jẹ́ kí ìbínú kí ó dé láti gbẹ̀san

mo da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí orí àpáta kan lásán,

kí o ma bà á wà ni bíbò.

9“ ‘Nítorí náà báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà!

Èmi pàápàá yóò jẹ́ kí òkìtì iná náà tóbi.

10Nítorí náà kó igi náà jọ sí i,

kí o sì fi iná sí i.

Ṣe ẹran náà dáradára,

fi tùràrí dùn ún;

kí o sì jẹ́ kí egungun náà jóná.

11Lẹ́yìn náà gbé òfìfo ìkòkò náà lórí ẹyin iná

kí idẹ rẹ̀ lè gbóná, kí ó lè pọ́n

àti ki ìfófó rẹ̀ le di yíyọ́ nínú rẹ̀

kí èérí rẹ̀ le jó dànù.

12Ó ti ba gbogbo akitiyan jẹ:

èérí rẹ̀ kò sì jáde kúrò lára rẹ̀,

èérí náà gan an yóò wà nínú iná.

13“ ‘Nísinsin yìí èérí rẹ̀ ni ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà. Nítorí mo gbìyànjú láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò sì mọ́ kúrò nínú ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, a kì yóò sì tún wẹ̀ ọ mọ́ kúrò nínú èérí rẹ, títí èmi yóò fi jẹ́ kí ìbínú mi balẹ̀ sórí rẹ̀.

14“ ‘Èmi Olúwa ni ó sọ ọ́, yóò sì ṣe, èmi yóò sì ṣe é. Èmi kì yóò padà sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá sí i, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọkàn mi padà; gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ, ni wọn yóò dá ọ lẹ́jọ́, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

Ìyàwó Esekiẹli kú

15Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá pé: 16“Ọmọ ènìyàn, kíyèsi i, mo mú ìfẹ́ ojú rẹ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, nípa lílù kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ gbààwẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sọkún, bẹ́ẹ̀ ni omijé ojú rẹ kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀. 17Má ṣe sọkún, má ṣe gbààwẹ̀ fún òkú. Wé ọ̀já sí orí rẹ, sì bọ bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ: má ṣe bo ètè ìsàlẹ̀ rẹ, ma ṣe jẹ oúnjẹ tí àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà.”

18Báyìí ni mo sọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn ní òwúrọ̀, ní àṣálẹ́ ìyàwó mi sì kú. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, mo ṣe bí a ti pàṣẹ fún mi.

19Lẹ́yìn náà àwọn ènìyàn bi mí léèrè pé, “Ṣe o kò ni sọ fún wa ohun ti nǹkan wọ̀nyí ní láti ṣe pẹ̀lú wa?”

20Mo sọ báyìí fún wọn pé, “Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 21Sọ fún ilé Israẹli, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, èmi yóò sọ ibi mímọ́ mi di ibi àìmọ́ tayọ agbára yín, ìfẹ́ ojú yín, ìkáàánú yín, àti ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin tí ẹ̀yin fi sílẹ̀ sẹ́yìn yóò ṣubú nípa idà. 22Ẹyin yóò sì ṣe bí mo ti ṣe. Ẹ̀yin kì yóò bo ìsàlẹ̀ ojú yín tàbí jẹ oúnjẹ ti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà. 23Ẹ̀yin yóò fi àwọn ọ̀já wé àwọn orí yín àti àwọn bàtà ni ẹsẹ̀ yín, ẹ̀yin kì yóò ṣọ̀fọ̀ tàbí sọkún, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò ṣòfò dànù nítorí àwọn àìṣedéédéé yín, ẹ̀yin yóò sì máa kérora láàrín ara yín. 24Esekiẹli yóò jẹ ààmì fún un yín; ẹ̀yin yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.’

25“Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ, Ọmọ ènìyàn, kì yóò ha jẹ́ pé, ní ọjọ́ náà, nígbà ti mo bá gba agbára wọn, ayọ̀ wọn àti ògo wọn, ìfẹ́ ojú wọn, ohun tí wọn gbé ọkàn wọn lé, àti àwọn ọmọ ọkùnrin wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ obìnrin wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn, 26ní ọjọ́ náà ẹni tí ó bá sálà yóò tọ̀ ọ́ wá láti sọ ìròyìn náà fún ọ 27Ní ọjọ́ náà ẹnu rẹ yóò sì ṣí; ìwọ yóò sọ̀rọ̀, ìwọ kì yóò sì yadi mọ́. Báyìí ìwọ yóò jẹ́ ààmì fún wọn; wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ní Olúwa.”