Езекиил 23 – CARSA & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

Езекиил 23:1-49

Вероломные сёстры Огола и Оголива

1Было ко мне слово Вечного:

2– Смертный, были две женщины, дочери одной матери. 3Они с юных лет были блудницами в Египте; в той земле им мяли груди и ласкали девственные соски. 4Старшую звали Огола («её шатёр»), а её сестру – Оголива («Мой шатёр в ней»). Они были Моими и рожали сыновей и дочерей. Огола – это Самария, а Оголива – это Иерусалим.

5Огола стала блудницей, когда ещё была Моей. Она воспылала похотью к своим любовникам-ассирийцам: к воинам, 6одетым в голубое, к наместникам и военачальникам – все они были красивыми молодцами, всадниками на конях. 7Она распутствовала с ассирийской знатью и осквернялась идолами тех, к кому загоралась похотью. 8Она не оставляла распутство, которое началось в Египте, когда во время её юности любовники спали с ней, лаская её соски и изливая на неё похоть.

9Поэтому Я отдал её во власть ассирийцев, к которым она пылала похотью. 10Они раздели её донага, взяли её сыновей и дочерей и убили её мечом. Над ней был исполнен приговор, и она стала позором среди женщин.

11Её сестра Оголива видела это, но в похоти и распутстве становилась развратнее сестры. 12Она тоже пылала похотью к ассирийцам – наместникам и военачальникам, воинам в полном вооружении, всадникам на конях, всем красивым молодцам. 13Я увидел, что и она оскверняла себя; они обе шли по одному пути.

14Но она предалась ещё большему распутству. Она увидела мужчин, нарисованных на стене, изображения вавилонян, запечатлённых красной краской, 15с поясами на бёдрах и роскошными повязками на головах – все они были похожи на вавилонских полководцев, уроженцев Вавилонии. 16Едва увидев их, она воспылала похотью и отправила к ним в Вавилонию послов. 17Вавилоняне пришли к ней на любовное ложе и осквернили её своим блудом. Осквернённая, она отвернулась от них с отвращением. 18Когда же она стала предаваться распутству открыто и обнажаться, Я отвернулся от неё с отвращением, как когда-то от её сестры. 19Но она становилась всё более распутной, вспоминая дни юности, когда она была блудницей в Египте. 20Там она вожделела своих любовников, чьи гениталии были как у ослов, а извержение семени – как у жеребцов. 21Она тосковала по распутству юности, когда в Египте ласкали её соски и мяли её молодые груди.

22Поэтому, Оголива, так говорит Владыка Вечный:

– Я настрою против тебя любовников, от которых ты отвернулась с отвращением, и поведу их на тебя отовсюду – 23вавилонян и всех халдеев, жителей Пекода, Шоа и Коа и с ними всех ассирийцев, красивых молодцев, все они наместники и военачальники, полководцы и сановники, все – всадники на конях. 24Они пойдут на тебя с оружием, колесницами и повозками и множеством народа. Они окружат тебя со всех сторон с большими и малыми щитами и в шлемах. Я доверю им судить тебя, и они будут судить тебя по своим законам. 25Я обращу на тебя Свой ревнивый гнев, и они поступят с тобой в ярости. Они отрежут тебе нос и уши, а твои уцелевшие жители падут от меча. Они возьмут твоих сыновей и дочерей, а уцелевших поглотит огонь. 26Они сорвут с тебя одежды и отнимут твои прекрасные драгоценности. 27Я положу конец распутству и разврату, которым ты предавалась в Египте. Ты больше не будешь ни тосковать о них, ни вспоминать Египет.

28Ведь так говорит Владыка Вечный:

– Смотри, Я отдаю тебя во власть тех, кого ты ненавидишь, тех, от кого ты отвернулась с отвращением. 29Ненавидя тебя, они отнимут всё, ради чего ты трудилась. Они бросят тебя нагой, непокрытой, и откроется весь срам твоего распутства. Твои бесстыдство и разврат 30довели тебя до этого, потому что ты распутничала с народами и осквернялась их идолами. 31Ты пошла по пути твоей сестры, и Я дам тебе в руки её чашу.

32Так говорит Владыка Вечный:

– Ты выпьешь чашу сестры,

глубокую и широкую;

ты станешь посмешищем и позором:

чаша вмещает много.

33Ты будешь полна хмеля и горя,

выпив чашу гибели и разорения –

чашу твоей сестры Самарии.

34Ты будешь пить её и осушишь;

разобьёшь её на куски

и будешь терзать себе грудь.

Я так сказал, – возвещает Владыка Вечный.

35Поэтому так говорит Владыка Вечный:

– Так как ты забыла Меня и повернулась ко Мне спиной, то терпи за свои похоть и распутство.

36Вечный сказал мне:

– Смертный, будешь ли судить Оголу и Оголиву? Тогда укажи им на их омерзительные дела. 37Ведь они нарушали супружескую верность, и руки у них в крови. Они распутствовали с идолами и даже детей, которых они Мне родили, они приносили идолам в огненную жертву как пищу. 38Вот что они Мне сделали ещё: в тот же день они оскверняли Моё святилище и нарушали субботы. 39В тот же день, когда они приносили детей в жертву идолам, они входили в Моё святилище и оскверняли его. Вот что они делали в Моём доме.

40Они даже посылали за людьми, которые приходили издалека, и когда те появлялись, ты, Оголива, мылась для них, подводила глаза и надевала драгоценности. 41Ты садилась на красивое ложе, перед которым накрывался стол, и ставила на него Мои благовония и масло.

42У неё раздавались крики праздной толпы. Севеян23:42 Или: «Пьяниц». из пустыни приводили вместе с чернью, и те надевали браслеты на руки этой женщине и её сестре и возлагали прекрасные венцы им на головы. 43Тогда Я сказал об Оголиве, истощённой от распутства: «Пусть они обходятся с ней как с блудницей, потому что она такая и есть». 44И они спали с ней. Они спали с этими блудницами, Оголой и Оголивой, как спят с блудницами. 45Но праведники определят им наказание как женщинам, которые изменяют и проливают кровь, потому что они вероломны и руки у них в крови.

46Так говорит Владыка Вечный:

– Собери против них толпу и предай их ужасу и грабежу. 47Толпа побьёт их камнями и изрубит мечами; их сыновья и дочери будут убиты, а дома сожжены. 48Так Я положу конец разврату в стране, чтобы другие женщины остереглись и не подражали им. 49Вы же, сёстры, понесёте наказание за разврат и за грех идолопоклонства. Тогда вы узнаете, что Я – Владыка Вечный.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 23:1-49

Arábìnrin panṣágà méjì

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 2“Ọmọ ènìyàn, obìnrin méjì wà, ọmọ ìyá kan náà. 3Wọn ń ṣe panṣágà ní Ejibiti, wọn ń ṣe panṣágà láti ìgbà èwe wọn. Ní ilẹ̀ yẹn ni wọn ti fi ọwọ́ pa ọyàn wọn, níbẹ̀ ni wọn sì fọwọ́ pa igbá àyà èwe wọn. 4Èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Ohola, àbúrò rẹ̀ sì ń jẹ́ Oholiba. Tèmi ni wọ́n, wọ́n sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Ohola ni Samaria, Oholiba sì ni Jerusalẹmu.

5“Ohola ń ṣe panṣágà nígbà tí ó sì jẹ́ tèmi; Ó sì ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, àwọn jagunjagun ará Asiria. 6Aṣọ aláró ni a fi wọ̀ wọ́n, àwọn gómìnà àti àwọn balógun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà àwọn tí ń gun ẹṣin. 7O fi ara rẹ̀ fún gbajúmọ̀ ọkùnrin Asiria gẹ́gẹ́ bí panṣágà obìnrin, o fi òrìṣà gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, 8kò fi ìwà panṣágà tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ni Ejibiti sílẹ̀, ní ìgbà èwe rẹ̀ àwọn ọkùnrin n bá a sùn, wọn fi ọwọ́ pa àyà èwe rẹ̀ lára wọn sì ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i.

9“Nítorí náà mo fi i sílẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ará Asiria, tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i. 10Wọ́n bọ́ ọ sí ìhòhò, wọ́n sì gba àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọn sì pa wọn pẹ̀lú idà. Ó di ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ láàrín àwọn obìnrin wọ́n sì fi ìyà jẹ ẹ́.

11“Àbúrò rẹ̀ Oholiba rí èyí, síbẹ̀ nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti panṣágà rẹ̀, Ó ba ara rẹ jẹ́ ju ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ. 12Òun náà ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ará Asiria àwọn gómìnà àti àwọn balógun, jagunjagun nínú aṣọ ogun, àwọn tí ń gun ẹṣin, gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà. 13Mo rí i pé òun náà ba ara rẹ̀ jẹ́; àwọn méjèèjì rìn ojú ọ̀nà kan náà.

14“Ṣùgbọ́n ó tẹ̀síwájú nínú ṣíṣe panṣágà. O ri àwòrán àwọn ọkùnrin lára ògiri, àwòrán àwọn ara Kaldea àwòrán pupa, 15pẹ̀lú ìgbànú ni ìdí wọn àti àwọn ìgbàrí ni orí wọn; gbogbo wọn dàbí olórí kẹ̀kẹ́ ogun Babeli ọmọ ìlú Kaldea. 16Ní kété tí ó rí wọn, ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí wọn, ó sì rán oníṣẹ́ sí wọn ni Kaldea. 17Àwọn ará Babeli wá sọ́dọ̀ rẹ̀, lórí ibùsùn ìfẹ́, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn, wọ́n bà á jẹ́. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bà á jẹ́ tán, ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn ní ìtìjú. 18Nígbà tí ó tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ panṣágà rẹ̀ ní gbangba wọ́n sì tú u sí ìhòhò, mo yí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ìtìjú, gẹ́gẹ́ bí mo ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. 19Síbẹ̀síbẹ̀ ó ń pọ̀ sí i nínú ìdàpọ̀ rẹ̀ bí ó ti ń rántí ìgbà èwe rẹ̀ tí ó jẹ́ panṣágà ní Ejibiti. 20Nítorí ó fẹ́ olùfẹ́ àwọn olùfẹ́ wọn ní àfẹ́jù, tí àwọn tí nǹkan ọkùnrin wọn dàbí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ẹni tí ìtújáde ara wọn dàbí ti àwọn ẹṣin. 21Báyìí ni ìwọ pe ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìgbà èwe rẹ wá sí ìrántí, ní ti rírin orí ọmú rẹ láti ọwọ́ àwọn ará Ejibiti, fún ọmú ìgbà èwe rẹ.

22“Nítorí náà, Oholiba, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò gbé olólùfẹ́ rẹ dìde sí ọ, àwọn tí o kẹ́yìn si ní ìtìjú, èmi yóò sì mú wọn dojúkọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà 23àwọn ará Babeli àti gbogbo ara Kaldea àwọn ọkùnrin Pekodi àti Ṣoa àti Koa àti gbogbo ará Asiria pẹ̀lú wọn, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà, gbogbo àwọn gómìnà àti balógun, olórí oníkẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn onípò gíga, gbogbo àwọn tí ń gun ẹṣin. 24Wọn yóò wa dojúkọ ọ pẹ̀lú ohun ìjà, kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹrù àti pẹ̀lú ìwọ́jọpọ̀ ènìyàn; wọn yóò mú ìdúró wọn lòdì sí ọ ní gbogbo ọ̀nà pẹ̀lú asà ńlá àti kékeré pẹ̀lú àṣíborí. Èmi yóò yí ọ padà sí wọn fun ìjìyà, wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ gẹ́gẹ́ bí wọn tí tó. 25Èmi yóò sì dojú ìbínú owú mi kọ ọ́, wọn yóò sì fìyà jẹ ọ́ ní ìrunú. Wọ́n yóò gé àwọn imú àti àwọn etí yín kúrò, àwọn tí ó kù nínú yín yóò ti ipá idà ṣubú. Wọn yóò mú àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin yín lọ, àwọn tí o kù nínú yín ni iná yóò jórun. 26Wọn yóò sì kó àwọn aṣọ àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye yín. 27Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti iṣẹ́ panṣágà tí ẹ bẹ̀rẹ̀ ni Ejibiti. Ẹ̀yin kò ní wo àwọn nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú ìpòùngbẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rántí Ejibiti mọ.

28“Nítorí báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò fi ọ lé ọwọ́ àwọn tí ó kórìíra, lọ́wọ́ àwọn ẹni tí ọkàn rẹ ti ṣí kúrò. 29Wọn yóò fìyà jẹ ọ́ pẹ̀lú ìkórìíra, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tí o ṣiṣẹ́ fún lọ. Wọn yóò fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòhò goloto, ìtìjú iṣẹ́ panṣágà rẹ ni yóò farahàn. Ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti panṣágà rẹ. 30Èmi yóò ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí sí ọ, nítorí ìwọ ti bá àwọn kèfèrí ṣe àgbèrè lọ, o sì fi àwọn òrìṣà wọn ba ara rẹ̀ jẹ́. 31Ìwọ ti rin ọ̀nà ti ẹ̀gbọ́n rẹ rìn; Èmi yóò sì fi ago rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.

32“Èyí yìí ní ohun ti Olúwa Olódùmarè:

“Ìwọ yóò mu nínú ago ẹ̀gbọ́n rẹ,

ago tí ó tóbi tí ó sì jinnú:

yóò mú ìfiṣẹ̀sín àti ìfiṣe ẹlẹ́yà wá,

nítorí tí ago náà gba nǹkan púpọ̀.

33Ìwọ yóò mu àmupara àti ìbànújẹ́,

ago ìparun àti ìsọdahoro

ago ẹ̀gbọ́n rẹ Samaria.

34Ìwọ yóò mú un ni àmugbẹ;

ìwọ yóò sì fọ sí wẹ́wẹ́

ìwọ yóò sì fa ọmú rẹ̀ ya.

Èmi ti sọ̀rọ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.

35“Nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Níwọ́n bí ìwọ ti gbàgbé mi, tí ìwọ sì ti fi mi sí ẹ̀yìn rẹ, ìwọ gbọdọ̀ gba àbájáde ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti panṣágà rẹ.”

36Olúwa sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ń jẹ́ ìwọ yóò ṣe ìdájọ́ Ohola àti Oholiba? Nítorí náà dojúkọ wọn nípa ìkórìíra tí wọn ń ṣe, 37nítorí wọn ti dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn. Wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà pẹ̀lú àwọn òrìṣà wọn; kódà wọ́n fi àwọn ọmọ wọn tí wọn bí fún ni ṣe ìrúbọ, gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún wọn. 38Bákan náà ni wọ́n ti ṣe èyí náà sí mi: Ní àkókò kan náà wọn ba ibi mímọ́ mi jẹ́, wọ́n sì lo ọjọ́ ìsinmi mi ní àìmọ́. 39Ní ọjọ́ náà gan an wọ́n fi àwọn ọmọ wọn rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà, wọn wọ ibi mímọ́ mi lọ wọn sì lò ó ní ìlòkulò. Ìyẹn ní wọn ṣe ní ilé mi.

40“Wọn tilẹ̀ rán oníṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn, nígbà tí wọ́n dé, ìwọ wẹ ara rẹ fún wọn, ìwọ kún ojú rẹ, ìwọ sì fi ọ̀ṣọ́ iyebíye sára, 41Ìwọ jókòó lórí ibùsùn ti o lẹ́wà, pẹ̀lú tábìlì tí a tẹ́ ní iwájú rẹ lórí, èyí tí o gbé tùràrí àti òróró tí ó jẹ́ tèmi kà.

42“Ariwo ìjọ ènìyàn tí kò bìkítà wà ní àyíká rẹ̀; a mú àwọn ara Sabeani láti aginjù pẹ̀lú àwọn ọkùnrin láti ara àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ sí àwọn ọwọ́ obìnrin náà àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, adé dáradára sì wà ní orí wọn. 43Lẹ́yìn náà mo sọ̀rọ̀ nípa èyí tí ó lo ara rẹ̀ sá nípa panṣágà ṣíṣe, ‘Nísinsin yìí jẹ kí wọn lo o bí panṣágà, nítorí gbogbo ohun tí ó jẹ́ nìyẹn.’ 44Wọn ba sùn bí ọkùnrin ti bá panṣágà sùn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sùn pẹ̀lú obìnrin onífẹ̀kúfẹ̀ẹ́, Ohola àti Oholiba. 45Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin olódodo yóò pàṣẹ pé kí wọ́n fi ìyà jẹ àwọn obìnrin tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè tí ó sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ nítorí pé panṣágà ni wọ́n ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn.

46“Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Mú àgbájọ àwọn ènìyànkénìyàn wá sọ́dọ̀ wọn ki ó sì fi wọn lé ọwọ́ ìpayà àti ìkógun. 47Àwọn ènìyànkénìyàn náà yóò sọ wọ́n ni òkúta, yóò sì gé wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà wọn; wọn ó sì pa àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n ó sì jó àwọn ilé wọn kanlẹ̀.

48“Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ni ilẹ̀ náà, kí gbogbo àwọn obìnrin le gba ìkìlọ̀ kí wọn kí ó ma sì ṣe fi ara wé ọ. 49Ìwọ yóò sì jìyà fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì gba àbájáde àwọn ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà tí o dá. Nígbà náà ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.”