3 Царств 13 – CARS & YCB

Священное Писание

3 Царств 13:1-34

1Когда Иеровоам стоял у жертвенника, чтобы возжечь благовония, из Иудеи в Вефиль, по слову Вечного, пришёл пророк. 2Он крикнул жертвеннику по слову Вечного:

– Жертвенник, жертвенник! Так говорит Вечный: родится дому Давуда сын по имени Иосия. На тебе принесёт он в жертву тех самых жрецов капищ, которые возжигают на тебе благовония, и сожжёт на тебе человеческие кости13:2 См. 4 Цар. 23:15-20, где описывается исполнение этого пророчества..

3В тот же день пророк дал знамение:

– Вот знамение того, что это возвестил Вечный: этот жертвенник расколется, а пепел на нём будет рассыпан.

4Услышав то, что пророк прокричал жертвеннику Вефиля, царь Иеровоам протянул руку от жертвенника и сказал:

– Возьмите его!

Но рука, которую он протянул к тому человеку, иссохла, и он не мог повернуть её к себе. 5А жертвенник раскололся, и пепел с него рассыпался согласно знамению, что пророк дал по слову Вечного.

6Тогда царь сказал пророку:

– Прошу, помолись Вечному, твоему Богу, пусть Он смилуется надо мной и исцелит мне руку.

Пророк помолился Вечному, и рука царя выздоровела и стала как прежде. 7Царь сказал пророку:

– Пойдём ко мне в дом, подкрепись, а я одарю тебя.

8Но пророк ответил царю:

– Даже если бы ты давал мне половину твоего добра, я не пошёл бы с тобой и не стал бы ни есть здесь хлеба, ни пить воды. 9Ведь словом Вечного мне было велено: «Не ешь хлеба, не пей воды и не возвращайся тем путём, по которому идёшь».

10И он пошёл другой дорогой, чтобы не возвращаться тем путём, по которому пришёл в Вефиль.

Непослушание пророка

11А в Вефиле жил один старый пророк, сыновья которого пришли и рассказали ему обо всём, что совершил там в тот день иудейский пророк. Они передали отцу и то, что он сказал царю.

12Отец спросил их:

– Какой дорогой он пошёл?

И сыновья показали ему, какой дорогой пошёл пророк из Иудеи. 13Он сказал сыновьям:

– Оседлайте мне осла.

И когда они оседлали ему осла, он сел на него 14и поехал за тем пророком. Он нашёл его сидящим под дубом и спросил:

– Ты ли пророк, который пришёл из Иудеи?

– Я, – ответил тот.

15Тогда старый пророк сказал ему:

– Пойдём ко мне в дом, поешь.

16Но иудейский пророк ответил:

– Я не могу вернуться с тобой и не могу здесь ни есть хлеба, ни пить воды, 17потому что Вечный повелел мне: «Не ешь там хлеба, не пей воды и не возвращайся тем путём, по которому идёшь туда».

18Старый пророк ответил:

– Я такой же пророк, как и ты. И ангел сказал мне по слову Вечного: «Верни его к себе домой, чтобы он поел хлеба и попил воды».

(А это была ложь.)

19И пророк из Иудеи возвратился с ним, ел и пил у него дома. 20Пока они ещё сидели за столом, к старому пророку, который возвратил его, было слово Вечного. 21Он закричал пророку, который пришёл из Иудеи:

– Так говорит Вечный: «Ты не послушался слова Вечного и нарушил повеление, которое дал тебе Вечный, твой Бог. 22Ты вернулся, ел хлеб и пил воду там, где Он запретил тебе есть и пить. Поэтому твоё тело не будет погребено в гробнице твоих отцов».

23Когда иудейский пророк поел и попил, пророк, который возвратил его, оседлал для него осла. 24Иудейский пророк уехал из города, но по дороге на него напал лев и растерзал его. Его тело лежало брошенным на дороге, а возле него стояли осёл и лев. 25Люди, что проходили мимо, увидели лежащее тело и льва, стоящего возле тела. Они пошли и рассказали об этом в том городе, где жил старый пророк. 26Когда пророк, который возвратил его с пути, услышал об этом, он сказал:

– Это тот пророк, который не послушался слова Вечного. Вечный отдал его льву, который растерзал и умертвил его, как Вечный и говорил ему.

27Пророк сказал сыновьям:

– Оседлайте мне осла, – и они сделали это.

28Он вышел и нашёл тело, лежавшее на дороге, возле которого стояли осёл и лев. Лев же не съел тела и не растерзал осла. 29Пророк поднял тело иудейского пророка, положил его на осла и привёз обратно в город, чтобы оплакать и похоронить его. 30Он положил тело в свою гробницу и оплакивал его, восклицая:

– О, мой брат!

31Похоронив его, он сказал сыновьям:

– Когда я умру, похороните меня в гробнице, где погребён иудейский пророк, положите мои кости рядом с его костями13:31 В некоторых рукописях присутствуют слова: «чтобы мои кости сохранились с его костями».. 32Ведь то, что он возвестил по слову Вечного против жертвенника Вефиля и против всех капищ на возвышенностях в городах Самарии, непременно исполнится.

Упорство Иеровоама

33Но даже после этого Иеровоам не переменил своего злого пути, и снова назначил из народа жрецов для капищ на возвышенностях. Он посвящал в жрецы для капищ любого, кто хотел. 34Таков был грех дома Иеровоама, что вёл к его падению и к искоренению с лица земли.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Ọba 13:1-34

Ènìyàn Ọlọ́run kan láti Juda

1Sì kíyèsi i, ènìyàn Ọlọ́run kan wá láti Juda sí Beteli nípa ọ̀rọ̀ Olúwa, bì Jeroboamu sì ti dúró lẹ́bàá a pẹpẹ láti fi tùràrí jóná. 2Ó sì kígbe sí pẹpẹ náà nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé, “Pẹpẹ! Pẹpẹ! Báyìí ni Olúwa wí: ‘A ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josiah ní ilé Dafidi. Lórí rẹ ni yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga wọ̀n-ọn-nì tí ń fi tùràrí lórí rẹ̀ rú ẹbọ, a ó sì sun egungun ènìyàn lórí rẹ.’ ” 3Ní ọjọ́ kan náà ènìyàn Ọlọ́run sì fún wọn ní ààmì kan wí pé: “Èyí ni ààmì tí Olúwa ti kéde: kíyèsi i, pẹpẹ náà yóò ya, eérú tí ń bẹ lórí rẹ̀ yóò sì dànù.”

4Nígbà tí Jeroboamu ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run, tí ó kígbe sí pẹpẹ náà ní Beteli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde nínú pẹpẹ, ó sì wí pé, “Ẹ mú un” ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ tí ó nà sí i sì kákò, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le fà á padà mọ́. 5Lẹ́sẹ̀kan náà, pẹpẹ ya, eérú náà sì dànù kúrò lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ààmì tí ènìyàn Ọlọ́run ti fi fún un nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.

6Nígbà náà ní ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì gbàdúrà fún mi kí ọwọ́ mi lè padà bọ̀ sípò.” Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa, ọwọ́ ọba sì padà bọ̀ sípò, ó sì padà sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.

7Ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Wá bá mi lọ ilé, kí o sì wá nǹkan jẹ, èmi yóò sì fi ẹ̀bùn fún ọ.”

8Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run náà dá ọba lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá tilẹ̀ fún mi ní ìdajì ìní rẹ, Èmi kì yóò lọ pẹ̀lú rẹ tàbí kí èmi jẹ oúnjẹ tàbí mu omi ní ibí yìí. 9Nítorí a ti pa á láṣẹ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi tàbí padà ní ọ̀nà náà tí o gbà wá.’ ” 10Bẹ́ẹ̀ ni ó gba ọ̀nà mìíràn, kò sì padà gba ọ̀nà tí ó gbà wá sí Beteli.

11Wòlíì àgbà kan wà tí ń gbé Beteli, ẹni tí àwọn ọmọ rẹ̀ dé, tí ó sì ròyìn gbogbo ohun tí ènìyàn Ọlọ́run náà ti ṣe ní Beteli ní ọjọ́ náà fún un. Wọ́n sì tún sọ fún baba wọn ohun tí ó sọ fún ọba. 12Baba wọn sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ọ̀nà wo ni ó gbà?” Àwọn ọmọ rẹ̀ sì fi ọ̀nà tí ènìyàn Ọlọ́run láti Juda gbà hàn án. 13Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún un tán, ó sì gùn ún. 14Ó sì tẹ̀lé ènìyàn Ọlọ́run náà lẹ́yìn. Ó sì rí i tí ó jókòó lábẹ́ igi óákù kan, ó sì wí fún un pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti Juda wá bí?”

Ó sì dá a lóhùn pé, “Èmi ni.”

15Nígbà náà ni wòlíì náà sì wí fún un pé, “Bá mi lọ ilé, kí o sì jẹun.”

16Ènìyàn Ọlọ́run náà sì wí pé, “Èmi kò le padà sẹ́yìn tàbí bá ọ lọ ilé, tàbí kí èmi kí ó jẹ oúnjẹ tàbí mu omi pẹ̀lú rẹ níhìn-ín. 17A ti sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi níhìn-ín tàbí kí o padà lọ nípa ọ̀nà tí ìwọ bá wá.’ ”

18Wòlíì àgbà náà sì wí fún un pé, “Wòlíì ni èmi náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìwọ. Angẹli sì sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa pé: ‘Mú un padà wá sí ilé rẹ, kí ó lè jẹ oúnjẹ àti kí ó lè mu omi.’ ” (Ṣùgbọ́n ó purọ́ fún un ni.) 19Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà sì padà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì jẹ oúnjẹ ó sì mu omi ní ilé rẹ̀.

20Bí wọ́n sì ti jókòó ti tábìlì, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ wòlíì tí ó mú un padà wá pé; 21Ó sì kígbe sí ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti Juda wá wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ ti ba ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ́, ìwọ kò sì pa àṣẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́. 22Ìwọ padà, ìwọ sì ti jẹ oúnjẹ, ìwọ sì ti mu omi níbi tí ó ti sọ fún ọ pé kí ìwọ kí ó má ṣe jẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Nítorí náà, a kì yóò sin òkú rẹ sínú ibojì àwọn baba rẹ.’ ”

23Nígbà tí ènìyàn Ọlọ́run sì ti jẹun tán àti mu omi tan, wòlíì tí ó ti mú u padà sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún un. 24Bí ó sì ti ń lọ ní ọ̀nà rẹ̀, kìnnìún kan pàdé rẹ̀ ní ọ̀nà, ó sì pa á, a sì gbé òkú rẹ̀ sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró tì í lẹ́gbẹ̀ẹ́. 25Àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá sì rí pé ó gbé òkú náà sọ sí ojú ọ̀nà, kìnnìún náà sì dúró ti òkú náà; wọ́n sì wá, wọ́n sì sọ ọ́ ní ìlú tí wòlíì àgbà náà ń gbé.

26Nígbà tí wòlíì tí ó mú un padà wá láti ọ̀nà rẹ̀ sì gbọ́ èyí, ó sì wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run náà ni tí ó ba ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ́. Olúwa sì ti fi lé kìnnìún lọ́wọ́, tí ó sì fà á ya, tí ó sì pa á, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti kìlọ̀ fún un.”

27Wòlíì náà sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi,” wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. 28Nígbà náà ni ó sì jáde lọ, ó sì rí òkú náà tí a gbé sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kìnnìún náà kò sì jẹ òkú náà, tàbí fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ya. 29Nígbà náà ni wòlíì náà gbé òkú ènìyàn Ọlọ́run náà, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì gbé e padà wá sí ìlú ara rẹ̀ láti ṣọ̀fọ̀ fún un àti láti sin ín. 30Nígbà náà ni ó gbé òkú náà sínú ibojì ara rẹ̀, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ó ṣe, arákùnrin mi!”

31Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú rẹ̀ tán, ó sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Nígbà tí mo bá kú, ẹ sin mí ní ibojì níbi tí a sin ènìyàn Ọlọ́run sí; ẹ tẹ́ egungun mi lẹ́bàá egungun rẹ̀. 32Nítorí iṣẹ́ tí ó jẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Olúwa sí pẹpẹ tí ó wà ní Beteli àti sí gbogbo ojúbọ lórí ibi gíga tí ń bẹ ní àwọn ìlú Samaria yóò wá sí ìmúṣẹ dájúdájú.”

33Lẹ́yìn nǹkan yìí, Jeroboamu kò padà kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún yan àwọn àlùfáà sí i fún àwọn ibi gíga nínú gbogbo àwọn ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di àlùfáà, a yà á sọ́tọ̀ fún ibi gíga wọ̀nyí. 34Èyí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jeroboamu, èyí tí ó yọrí sí ìṣubú rẹ̀, a sì pa á run kúrò lórí ilẹ̀.