Марк 5 – CARS & YCB

Священное Писание

Марк 5:1-43

Изгнание демонов в стадо свиней

(Мат. 8:28-34; Лк. 8:26-37)

1Они переправились на другую сторону озера, в Гадаринскую землю. 2Как только Иса вышел из лодки, навстречу Ему из могильных пещер выскочил человек, одержимый нечистым духом.

3Человек этот жил в могильных пещерах, и никто не мог связать его даже цепями: 4его уже много раз сковывали по рукам и ногам, но он всегда разрывал цепи и разбивал кандалы на ногах. Никто не мог усмирить его. 5Днём и ночью он бродил среди могил и по горам и с диким криком бил себя камнями. 6Увидев Ису издалека, он подбежал к Нему, поклонился 7и закричал во весь голос:

– Что Ты от меня хочешь, Иса, Сын Бога Высочайшего (Царственный Спаситель)? Заклинаю Тебя Всевышним, не мучь меня, – 8потому что Иса говорил ему: «Выйди, нечистый дух, из этого человека».

9Иса спросил:

– Как тебя зовут?

– Меня зовут Полчище5:9 Букв.: «легион» – воинское соединение в римской армии, состоящее примерно из 6 000 человек., – ответил он, – потому что нас много.

10И он настойчиво умолял Ису не выгонять их из тех мест. 11А там у горы в это время паслось большое стадо свиней, 12и нечистые духи попросили Ису:

– Позволь нам войти в этих свиней.

13Иса позволил, и нечистые духи, выйдя из человека, вошли в свиней. Всё стадо, около двух тысяч голов, тут же ринулось с обрыва в озеро и утонуло в нём. 14А свинопасы побежали и рассказали о случившемся в городе и в окрестностях. Сбежался народ посмотреть, что произошло. 15Подойдя к Исе, они увидели, что бывший одержимый, в котором было полчище демонов, сидит одетый и в здравом уме, и их охватил страх. 16Очевидцы же рассказали им, как всё произошло с одержимым и со свиньями. 17Тогда местные жители стали просить Ису покинуть их края. 18Когда Иса садился в лодку, то человек, который был одержим демонами, стал просить, чтобы Он взял его с Собой, 19но Иса отказал ему.

– Ступай домой к своим родным, – сказал Он, – и расскажи им, что сделал для тебя Вечный, и какую милость Он к тебе проявил.

20Тот пошёл и стал рассказывать в области Десяти городов о том, что сделал для него Иса. Его рассказ приводил всех в изумление.

Господство Исы Масиха над болезнью и смертью

(Мат. 9:18-26; Лк. 8:41-56)

21Когда Иса переправился в лодке обратно на другую сторону озера, вокруг Него на берегу собралась большая толпа. 22Тут пришёл Иаир, один из начальников молитвенного дома иудеев. Он, увидев Ису, пал к Его ногам 23и стал умолять:

– Моя маленькая дочь умирает, приди и возложи на неё руки, чтобы она исцелилась и осталась жива.

24Иса пошёл с ним, а за Исой следовала большая толпа и теснила Его со всех сторон. 25Там была женщина, двенадцать лет страдавшая кровотечением. 26Она натерпелась от многих врачей, истратила на лечение всё, что у неё было, но не получила никакой помощи, напротив, ей становилось всё хуже. 27Она слышала об Исе, и поэтому она подошла сзади к Нему сквозь толпу и прикоснулась к Его одежде.

28«Если я хоть к одежде Его прикоснусь, то исцелюсь», – думала она. 29Её кровотечение сразу же остановилось, и она почувствовала, что исцелена. 30А Иса мгновенно почувствовал, что из Него вышла сила.

Он обернулся в толпе и спросил:

– Кто прикоснулся к Моей одежде?

31Ученики ответили Ему:

– Ты же видишь, что толпа теснит Тебя со всех сторон. Что же Ты спрашиваешь, кто к Тебе прикоснулся?

32Но Иса обводил толпу взглядом, чтобы увидеть ту, которая это сделала. 33Женщина, дрожа от страха и зная, что с ней произошло, подошла, пала к Его ногам и рассказала всю правду. 34Тогда Иса сказал ей:

– Дочь Моя, твоя вера исцелила тебя. Иди с миром и будь здорова от своего недуга.

35Пока Иса ещё говорил, пришли люди из дома Иаира, начальника молитвенного дома, и передали:

– Твоя дочь умерла, зачем ещё беспокоить Учителя?

36Но Иса, не обращая внимания на их слова, сказал начальнику молитвенного дома:

– Не бойся, только верь!

37Он не позволил идти с Ним никому, кроме Петира, Якуба и Иохана, брата Якуба. 38Когда они вошли в дом начальника, Он увидел смятение. Люди плакали и причитали. 39Иса вошёл в дом и спросил их:

– Почему вы так скорбите и плачете? Девочка не умерла, она спит.

40Над Ним начали смеяться. Но Иса велел всем выйти, а Сам с отцом и матерью девочки и Своими спутниками вошёл в комнату, где она лежала. 41Взяв её за руку, Иса сказал:

– Талета, куми!

Это значит: «Девочка, говорю тебе: встань!»

42Девочка сразу встала и начала ходить (ей было лет двенадцать). Все были сильно удивлены. 43Но Иса строго наказал им, чтобы никто не узнал о случившемся, а девочку велел покормить.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Marku 5:1-43

Ìwòsàn ọkùnrin ẹlẹ́mìí èṣù

15.1-20: Mt 8.28-34; Lk 8.26-39.Wọ́n lọ sí apá kejì adágún ní ẹ̀bá ilẹ̀ àwọn ará Gadara. 2Bí Jesu sì ti ń ti inú ọkọ̀ ojú omi jáde. Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ jáde ti ibojì wá pàdé rẹ̀. 3Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ibojì, kò sí ẹni tí ó lè dè é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n kò le dè é. 4Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọ́n ti ń fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹsẹ̀ rẹ̀. Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀. 5Tọ̀sán tòru láàrín àwọn ibojì àti ní àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara tí ó sì ń fi òkúta ya ara rẹ̀.

6Nígbà tí ó sì rí Jesu látòkèrè, ó sì sáré lọ láti pàdé rẹ̀. Ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 75.7: Ap 16.17; Hb 7.1; Mk 1.24.Ó sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tèmi tìrẹ, Jesu Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.” 8Nítorí tí Ó wí fún un pé, “Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́!”

9Jesu sì bi í léèrè pé, “Kí ni orúkọ rẹ?”

Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì dáhùn wí pé, “Ligioni, nítorí àwa pọ̀.” 10Nígbà náà ni ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jesu gidigidi, kí ó má ṣe rán àwọn jáde kúrò ní agbègbè náà.

11Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá kan sì ń jẹ lẹ́bàá òkè. 12Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ Jesu pé, “Rán wa lọ sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ wọ̀n-ọn-nì kí àwa le è wọ inú wọn lọ.” 13Jesu fún wọn láààyè, àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà tí ó tó ìwọ̀n ẹgbàá sì túká lọ́gán, wọ́n sì sáré lọ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè rọ́ sínú Òkun, wọ́n sì ṣègbé.

14Àwọn olùtọ́jú ẹran wọ̀nyí sì sálọ sí àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèkéé, wọ́n sì ń tan ìròyìn náà ká bí wọ́n ti ń sáré. Àwọn ènìyàn sì tú jáde láti fojú gán-án-ní ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀. 15Nígbà tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkùnrin náà, ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù, tí ó jókòó níbẹ̀, ó wọ aṣọ ìyè rẹ sì bọ̀ sípò, ẹ̀rù sì bà wọ́n. 16Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sì ń ròyìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin ẹlẹ́mìí àìmọ́, wọ́n si sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà pẹ̀lú. 17Nígbà náà, àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ Jesu pé kí ó fi agbègbè àwọn sílẹ̀.

18Bí Jesu ti ń wọ inú ọkọ̀ ojú omi lọ, ọkùnrin náà tí ó ti ní ẹ̀mí àìmọ́ tẹ́lẹ̀ bẹ̀ Ẹ́ pé kí òun lè bá a lọ. 19Jesu kò gbà fún un, ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Lọ sí ilé sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sì sọ fún wọn bí Ọlọ́run ti ṣe ohun ńlá fún ọ, àti bí ó sì ti ṣàánú fún ọ.” 205.20: Mk 7.31.Nítorí naà, ọkùnrin yìí padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ní Dekapoli nípa ohun ńlá tí Jesu ṣe fún un. Ẹnu sì ya gbogbo ènìyàn.

Òkú ọmọbìnrin kan àti obìnrin aláìsàn

215.21-43: Mt 9.18-26; Lk 8.40-56.Nígbà tí Jesu sì ti inú ọkọ̀ rékọjá sí apá kejì Òkun, ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọ yí i ká ní etí Òkun. 225.22: Lk 13.14; Ap 13.15; 18.8,17.Ọ̀kan nínú àwọn olórí Sinagọgu tí à ń pè ni Jairu wá sọ́dọ̀ Jesu, nígbà tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 235.23: Mk 6.5; 7.32; 8.23; Ap 9.17; 28.8.Ó sì bẹ̀ ẹ́ gidigidi pé, “Ọmọbìnrin mi wà lójú ikú, mo bẹ̀ ọ́, wá fi ọwọ́ rẹ lé e, kí ara rẹ̀ lè dá, kí ó sì yè.” 24Jesu sì ń bá a lọ.

Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn. 25Obìnrin kan sì wà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá. 26Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i. 27Nígbà tí ó sì gbúròó iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe, ìdí nìyìí tí ó fi wá sẹ́yìn rẹ̀, láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. 28Nítorí ti ó rò ní ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à lè fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.” 29Ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì gbẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun sì mọ̀ lára rẹ̀ pé, a mú òun láradá kúrò nínú ààrùn náà.

305.30: Lk 5.17.Lọ́gán, Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé agbára jáde lára òun. Ó yípadà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì béèrè, “Ta ni ó fi ọwọ́ kan aṣọ mi?”

31Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó rọ̀gbà yí ọ ká, ìwọ sì tún ń béèrè ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn ọ́?”

32Síbẹ̀, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí wò yíká láti rí ẹni náà, tí ó fi ọwọ́ kan òun. 33Nígbà náà, obìnrin náà kún fún ìbẹ̀rù àti ìwárìrì nítorí ó ti mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun. Ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo òtítọ́ fún un. 345.34: Lk 7.50; Mk 10.52.Jesu sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá: Máa lọ ní àlàáfíà, ìwọ sì ti sàn nínú ààrùn rẹ.”

35Bí Jesu sì ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ dé láti ilé Jairu olórí Sinagọgu wá, wọ́n wí fún un pé, ọmọbìnrin rẹ ti kú, àti pé kí wọn má ṣe yọ Jesu lẹ́nu láti wá, nítorí ó ti pẹ́ jù.

36Ṣùgbọ́n bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jairu pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbàgbọ́ nìkan.”

375.37: Mk 9.2; 13.3.Nígbà náà, Jesu dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jairu, bí kò ṣe Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin Jakọbu. 38Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jesu rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún. 39Ó wọ inú ilé lọ, o sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohùnréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.” 40Wọ́n sì fi í rẹ́rìn-ín.

Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí. 415.41: Lk 7.14; Ap 9.40.Ó gbá a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Talita kuumi” (tí ó túmọ̀ sí, ọmọdébìnrin, dìde dúró). 42Lẹ́sẹ̀kan náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì bà wọ́n, ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi. 435.43: Mk 1.43-44; 7.36.Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó sì wí fún wọn kí wọn fún ọmọbìnrin náà ní oúnjẹ.