Исход 8 – CARS & YCB

Священное Писание

Исход 8:1-32

1Вечный сказал Мусе:

– Пойди к фараону и скажи ему: Так говорит Вечный: «Отпусти Мой народ поклониться Мне. 2Если ты откажешься, Я наведу на всю твою страну жаб8:2 Скорее всего, это были лягушки, но данный перевод следует традиции и пишет «жабы».. 3Нил будет кишеть жабами. Они вылезут из реки и окажутся в твоём дворце, в спальне, на постели, в домах твоих приближённых и твоего народа8:3 Или: «и на твоём народе»., в твоих тандырах и в квашнях. 4Жабы будут прыгать на тебя, на твой народ и на твоих приближённых».

5Вечный сказал Мусе:

– Скажи Харуну: «Занеси руку с посохом над реками, каналами и прудами и наведи жаб на египетскую землю».

6Харун занёс руку с посохом над водами Египта, и вылезли жабы и заполнили всю землю. 7Но чародеи с помощью колдовства сделали то же самое. Они тоже навели жаб на Египет. 8Фараон позвал Мусу и Харуна и сказал:

– Помолитесь Вечному, чтобы Он избавил от жаб меня и мой народ, и я отпущу исраильтян принести жертву Вечному.

9Муса сказал фараону:

– Я предоставляю тебе честь выбрать, когда мне помолиться за тебя, за твоих приближённых и народ. После этого жабы уйдут от тебя и из твоих дворцов и останутся только в Ниле.

10– Завтра, – сказал фараон.

Муса ответил:

– Будет по-твоему для того, чтобы ты узнал: нет никого, подобного Вечному, нашему Богу. 11Жабы уйдут от тебя и из твоего дворца, от твоих приближённых и народа. Они останутся только в Ниле.

12Муса и Харун ушли от фараона, и Муса воззвал к Вечному о жабах, которых Он навёл на фараона. 13Вечный исполнил просьбу Мусы. Жабы вымерли в домах, во дворах и на полях. 14Их собирали в кучи, и земля начала испускать зловоние. 15Но когда фараон увидел, что пришло облегчение, его сердце исполнилось упрямством, и он опять не послушал Мусу и Харуна, как и говорил Вечный.

Третье наказание: комары

16Вечный сказал Мусе:

– Скажи Харуну: «Подними посох и ударь по пыли на земле: по всему Египту пыль превратится в комаров».

17Они сделали так. Харун поднял руку с посохом, ударил по пыли. Пыль по всему Египту превратилась в комаров. Комары налетели и на людей, и на скот. 18Чародеи попытались с помощью колдовства навести комаров, но не смогли. Комары облепляли людей и скотину. 19И тогда чародеи сказали фараону:

– Это сделал Всевышний.

Но сердце фараона оставалось упрямым. Он не послушал чародеев, как и говорил Вечный.

Четвёртое наказание: мухи

20Вечный сказал Мусе:

– Поднимись завтра рано утром, встань перед фараоном, когда он пойдёт к реке, и скажи ему: Так говорит Вечный: «Отпусти Мой народ поклониться Мне. 21Если не отпустишь, Я пошлю на тебя, на твоих приближённых, на твой народ и в твои дворцы рои мух. Дома египтян наполнятся мухами и вся земля будет покрыта ими. 22Но Я сделаю так, что в земле Гошен, где живёт Мой народ, не будет мух, чтобы ты знал – Я, Вечный, пребываю в той земле. 23Я покажу тебе разницу между Моим и твоим народом. Это знамение будет завтра».

24Вечный так и сделал. Густые рои мух налетели во дворец фараона и в дома его приближённых. Из-за мух погибала вся египетская земля. 25Фараон позвал Мусу и Харуна и сказал:

– Идите, принесите жертву вашему Богу, но только в этой стране, в Египте.

26Но Муса сказал:

– Так делать нельзя. Наши жертвоприношения Вечному, нашему Богу, для египтян – мерзость. Если мы станем совершать обряд жертвоприношения, который противен им, у них на глазах, то они забьют нас камнями. 27Нет, чтобы принести жертву Вечному, нашему Богу, как Он велел, нам нужно удалиться на три дня в пустыню.

28Фараон сказал:

– Я отпущу вас принести жертву Вечному, вашему Богу, в пустыню, но только не уходите далеко. Помолитесь и обо мне.

29Муса ответил:

– Как только я уйду от тебя, я помолюсь Вечному, и завтра мухи оставят тебя, твоих приближённых и народ. Но и ты больше не обманывай, не отпуская народ принести жертву Вечному.

30Муса ушёл от фараона и помолился Вечному. 31Вечный сделал то, что просил Муса: избавил фараона, его приближённых и народ от мух. Ни одной мухи не осталось. 32Но и на этот раз сердце фараона осталось упрямым, и он не отпустил народ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 8:1-32

1Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Padà tọ Farao lọ kí ó sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni Olúwa wí: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn ó bá à lè sìn mi. 2Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn ó lọ, èmi yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀pọ̀lọ́ kọlu gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ. 3Odò Naili yóò kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀pọ̀lọ́. Wọn yóò gòkè wá sí ààfin rẹ, àti yàrá rẹ ni orí ibùsùn rẹ. Wọn yóò gòkè wá sí ilé àwọn ìjòyè rẹ àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ, àti sí ibi ìdáná rẹ, àti sí inú ìkòkò ìyẹ̀fun rẹ. 4Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóò gun ara rẹ àti ara àwọn ìjòyè rẹ, àti ara gbogbo àwọn ènìyàn rẹ.’ ”

5Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni, ‘Kí ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde pẹ̀lú ọ̀pá sí orí àwọn odò kéékèèkéé àti odò ńlá, àti sí orí àwọn àbàtà kí ó sì mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ gòkè wá sí ilẹ̀ Ejibiti.’ ”

6Ní ìgbà náà ni Aaroni sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí àwọn omi Ejibiti, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ sì wá, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀. 7Ṣùgbọ́n àwọn onídán ilẹ̀ Ejibiti ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn. Àwọn náà mú kí ọ̀pọ̀lọ́ gún wá sí orí ilẹ̀ Ejibiti.

8Farao ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì sọ fún wọn pé, “Gbàdúrà sí Olúwa kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí kúrò lọ́dọ̀ mi àti lára àwọn ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ kí ó lọ láti rú ẹbọ sí Olúwa.”

9Mose sọ fún Farao pé, “Jọ̀wọ́ sọ fún mi ìgbà ti èmi yóò gbàdúrà fún ọ àti àwọn ìjòyè rẹ àti fún àwọn ènìyàn rẹ, kí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí bá lè lọ lọ́dọ̀ rẹ àti ní àwọn ilé yín tí wọn yóò sì wà nínú odò Naili nìkan.”

10Farao wí pé, “Ni ọ̀la.”

Mose sì dáhùn pé, “Yóò sì rí bí ìwọ ti sọ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé kò sí ẹni bí Olúwa Ọlọ́run wa. 11Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóò fi ìwọ àti àwọn ilé yín àti ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, wọn yóò sì wà nínú Naili nìkan.”

12Lẹ́yìn tí Mose àti Aaroni tí kúrò ní iwájú Farao, Mose gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sókè sí Olúwa nípa àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí ó ti rán sí Farao. 13Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose tí béèrè. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ sì kú nínú ilé àti ní ìta, gbangba àti nínú oko. 14Wọ́n sì kó wọn jọ ni òkìtì òkìtì gbogbo ilẹ̀ sì ń rùn. 15Ṣùgbọ́n ni ìgbà tí Farao rí pé ìtura dé, ó sé ọkàn rẹ̀ le kò sì fetí sí Mose àti Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí.

Kòròrò bo ilẹ̀

16Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni, ‘Na ọ̀pá rẹ jáde kí ó sì lu eruku ilẹ̀,’ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti ni erùpẹ̀ ilẹ̀ yóò ti di kòkòrò-kantíkantí.” (Kòkòrò kan tí ó ní ìyẹ́ méjì tí ó ṣì ń ta ni) 17Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, Nígbà tí Aaroni na ọwọ́ rẹ́ jáde pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó sì lu eruku ilẹ̀, kòkòrò-kantíkantí sì wà lára àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko wọn. Gbogbo eruku jákèjádò ilẹ̀ Ejibiti ni ó di kòkòrò-kantíkantí. 18Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn onídán gbìdánwò láti da kòkòrò-kantíkantí pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, wọn kò le è ṣé.

Nígbà tí kòkòrò-kantíkantí sì wà lára àwọn ẹranko wọn, 198.19: Lk 11.20.àwọn onídán sì sọ fún Farao pé, “Ìka Ọlọ́run ni èyí.” Ṣùgbọ́n àyà Farao sì yigbì, kò sì fetísílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.

Àwọn eṣinṣin bo ilẹ̀

20Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí o sì ko Farao lójú bí ó ṣe ń lọ sí odò, kí o sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni Olúwa sọ: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó bá à lè sìn Mi. 21Bí ìwọ kò bá jẹ́ kí àwọn ènìyàn Mi kí ó lọ, èmi yóò rán ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sí ara rẹ àti sí ara àwọn ìjòyè rẹ, àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ̀, sí àwọn ilẹ̀ rẹ̀. Gbogbo ilé àwọn ará Ejibiti ni yóò kún fún eṣinṣin àti orí ilẹ̀ tí wọ́n wà pẹ̀lú.

22“ ‘Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ náà, Èmi yóò ya ilẹ̀ Goṣeni sọ́tọ̀, níbi tí àwọn ènìyàn mi ń gbé, ọ̀wọ́ eṣinṣin kankan ki yóò dé ibẹ̀. Kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, èmi ni Olúwa, mo wà ni ilẹ̀ yìí. 23Èmi yóò pààlà sáàárín àwọn ènìyàn mi àti àwọn ènìyàn rẹ. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí yóò ṣẹlẹ̀ ni ọ̀la.’ ”

24Olúwa sì ṣe èyí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sì ya wọ ààfin Farao àti sí ilé àwọn ìjòyè rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ Ejibiti bàjẹ́ pẹ̀lú ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ̀n-ọn-nì.

25Nígbà náà ni Farao ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ kí ẹ sì rú ẹbọ sí Ọlọ́run yín ní ilẹ̀ yìí.”

26Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Èyí ló tọ́, ẹbọ tí a ó rú sí Olúwa Ọlọ́run wa yóò jẹ́ ohun ìríra sí àwọn ará ilẹ̀ Ejibiti. Bí a bá ṣe ìrúbọ ti yóò jẹ́ ìríra ni ojú wọn ṣé wọn, ó ní sọ òkúta lù wá? 27A gbọdọ̀ lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú aginjù láti rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wa.”

28Nígbà náà ni Farao wí pé, “Èmi yóò jẹ́ ki ẹ lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín nínú aginjù, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rìn jìnnà jù. Ẹ gbàdúrà fún mi.”

29Mose dáhùn ó wí pé, “Bí èmi bá ti kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa, àwọn ọ̀wọ́ eṣinṣin yóò fi Farao, àwọn ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ ní ọ̀la ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ìdánilójú wa pé Farao kò tún ni lo ẹ̀tàn láti má jẹ́ kí àwọn ènìyàn kí ó lọ rú ẹbọ sí Olúwa.”

30Nígbà náà ni Mose kúrò ni ọ̀dọ̀ Farao, ó sì gbàdúrà sí Olúwa; 31Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ti béèrè: Àwọn ọ̀wọ́ eṣinṣin kúrò lára Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀ àti lára àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú, eṣinṣin kan kò sì ṣẹ́kù. 32Ṣùgbọ́n ni àkókò yìí náà, Farao sé ọkàn rẹ le, kò sì jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ.