Исход 2 – CARS & YCB

Священное Писание

Исход 2:1-25

Рождение пророка Мусы

1Один человек из рода Леви взял себе жену из того же рода. 2Она забеременела и родила сына. Увидев, какой это красивый ребёнок, она прятала его три месяца, 3а когда не смогла больше прятать, взяла тростниковую корзину и покрыла её смолой и дёгтем. Она положила в неё младенца и поставила её среди тростника на берегу Нила. 4Сестра младенца встала поодаль, чтобы увидеть, что с ним случится. 5Дочь фараона спустилась к Нилу купаться, а её служанки ходили по берегу. Она увидела корзину среди тростника и послала за ней рабыню. 6Открыв корзину, дочь фараона увидела младенца. Он плакал, и она пожалела его.

– Это один из еврейских детей, – сказала она.

7Тогда сестра младенца подошла и спросила у дочери фараона:

– Может, пойти и привести кормилицу из евреек, чтобы она вскормила для тебя младенца?

8– Да, пойди, – ответила та.

Девочка пошла и привела мать младенца.

9Дочь фараона сказала ей:

– Возьми этого младенца и вскорми его для меня, а я тебе заплачу за это.

Женщина взяла младенца и вскормила его. 10Когда ребёнок подрос, она отвела его к дочери фараона, и та усыновила мальчика. Она назвала его Муса («вытащить»)2:10 О переводе имён и названий см. приложение VI., говоря: «Я вытащила его из воды».

Бегство Мусы в Мадиан

11Однажды, когда Муса уже вырос, он пошёл к своим соплеменникам и увидел, какую тяжёлую работу они делают. Он увидел, как египтянин бьёт еврея – его соплеменника. 12Оглянувшись вокруг и увидев, что никого нет, Муса убил египтянина и спрятал его тело в песке.

13На следующий день он увидел двух дерущихся евреев. Он спросил обидчика:

– Зачем ты бьёшь своего соплеменника?

14Тот ответил:

– Кто поставил тебя начальником и судьёй над нами? Не думаешь ли ты убить и меня, как убил египтянина?

Муса испугался и подумал: «Должно быть, то, что я сделал, стало известно».

15Услышав об этом, фараон хотел казнить Мусу, но Муса убежал от него и поселился в стране мадианитян. Однажды, когда он сидел у колодца, 16семь дочерей мадианского жреца пришли начерпать воды, чтобы наполнить поилки и напоить отару отца. 17Но пришли пастухи и отогнали их, тогда Муса встал, защитил дочерей жреца и напоил их овец.

18Когда девушки вернулись к своему отцу Иофору2:18 Букв.: «Рагуил». Рагуил – второе имя Иофора., тот спросил:

– Почему вы сегодня так рано вернулись?

19Они ответили:

– Какой-то египтянин защитил нас от пастухов. Он даже начерпал нам воды и напоил отару овец.

20– Где же он? – спросил отец у дочерей. – Почему вы оставили его? Пригласите его поесть с нами.

21Муса решил остаться у этого человека, и тот отдал свою дочь Ципору Мусе в жёны. 22Она родила сына, и Муса назвал его Гершом («чужестранец там»), говоря: «Я стал поселенцем в чужой земле».

23Спустя долгое время царь Египта умер. Исраильтяне стонали в рабстве и взывали о помощи. Вопль об их рабской доле дошёл до Всевышнего, 24и Всевышний, услышав их стоны, вспомнил Своё соглашение с Ибрахимом, Исхаком и Якубом. 25Всевышний посмотрел на исраильтян и пожалел их.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 2:1-25

Ìbí Mose

1Ó sì ṣe, ọkùnrin ará ilé Lefi kan fẹ́ ọmọbìnrin ará Lefi kan ni ìyàwó. 22.2: Ap 7.20; Hb 11.23.Obìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbà tí ó rí í pé ọmọ náà rẹwà, ó gbé ọmọ náà pamọ́ fún oṣù mẹ́ta. 3Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé papirusi hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà àti òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà. Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú eèsún ni etí odò Naili. 4Arábìnrin rẹ̀ dúró ni òkèèrè láti wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà.

52.5,10: Ap 7.21.Nígbà náà ni ọmọbìnrin Farao sọ̀kalẹ̀ wá sí etí odò Naili láti wẹ̀, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ń rìn ni etí bèbè odò. Ó sì ri apẹ̀rẹ̀ náà ni àárín eèsún, ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin kan láti lọ gbé e wá, 6ó ṣí i, ó sì rí ọmọ náà. Ọmọ náà ń sọkún, àánú ọmọ náà sì ṣe é. Ó wí pé “Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Heberu ni èyí.”

7Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin Farao pé “Ṣé kí èmi lọ wá ọ̀kan lára àwọn obìnrin Heberu wá fún ọ láti bá ọ tọ́jú ọmọ náà?”

8Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni; lọ.” Arábìnrin náà sì lọ, ó sì pe ìyá ọmọ náà wá, 9Ọmọbìnrin Farao sì wí fún un pé, “Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ” Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀. 10Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin Farao wá, ó sì di ọmọ rẹ̀. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mose, ó wí pé “Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi.”

Mose sálọ sí Midiani

112.11: Ap 7.23; Hb 11.24.Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Mose ti dàgbà, ó jáde lọ sí ibi ti àwọn ènìyàn rẹ̀ wà, ó ń wò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ líle wọn, O ri ará Ejibiti tí ń lu ará Heberu, ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. 122.12: Ap 7.24.Ó wo ìhín, ó wo ọ̀hún, nígbà tí kò rí ẹnìkankan, ni ó bá pa ará Ejibiti náà, ó sì bò ó mọ́ inú iyanrìn. 13Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará Heberu méjì tí wọ́n ń jà. Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé “Èéṣe tí ìwọ fi ń lu Heberu arákùnrin rẹ?”

142.14: Ap 7.27,28.Ọkùnrin náà sì dáhùn pé “Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa? Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti?” Nígbà náà ni ẹ̀rù ba Mose, ó sì wí pé, “lóòótọ́ ni ọ̀ràn yìí ti di mí mọ̀.”

152.15,22: Ap 7.29.Nígbà ti Farao sì gbọ́ nípa èyí, ó wá ọ̀nà láti pa Mose, ṣùgbọ́n Mose sá kúrò ní àrọ́wọ́tó o Farao, ó lọ sí Midiani láti máa gbé, nígbà tí ó dé bẹ̀, ó jókòó ni ẹ̀bá a kànga kan. 16Ó sì ṣe, àlùfáà Midiani kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn. 17Àwọn darandaran kan wá, wọ́n sì lé wọn sẹ́yìn, ṣùgbọ́n Mose dìde láti gbà wọ́n sílẹ̀ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ẹran wọn ní omi.

18Nígbà ti àwọn ọmọbìnrin náà padà dé ọ̀dọ̀ Reueli baba wọn, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé “Èéṣe tí ẹ̀yin fi tètè dé ni òní?”

19Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ará Ejibiti kan ni ó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn darandaran, ó tilẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti fa omi àti láti fún agbo ẹran ní omi.”

20Ó sọ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, “Níbo ni ó wà? Èéṣe ti ẹ fi fi ọkùnrin náà sílẹ̀? Ẹ pè é wá jẹun.”

21Mose gbà láti dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ẹni tí o fi Sippora, ọmọbìnrin rẹ̀ fún Mose láti fi ṣe aya. 22Ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Gerṣomu, ó wí pé “Èmi ń ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”

23Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ọba Ejibiti kú. Àwọn ará Israẹli ń kérora ní oko ẹrú wọn, wọ́n ń ké fún ìrànlọ́wọ́ nítorí oko ẹrú tí wọ́n wà, igbe wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. 242.24: Ap 7.34.Ọlọ́run gbọ́ igbe wọn, Ó sì rántí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Abrahamu, Isaaki àti pẹ̀lú Jakọbu. 25Nítorí náà, Ọlọ́run bojú wo àwọn ará Israẹli, Ó sì wà láti gbà wọ́n sílẹ̀.