Иешуа 10 – CARS & YCB

Священное Писание

Иешуа 10:1-43

Битва с аморреями. Остановленное солнце

1Когда Адони-Цедек, царь Иерусалима, услышал о том, что Иешуа захватил Гай и полностью уничтожил его, сделав с Гаем и его царём то же, что он сделал с Иерихоном и его царём, и о том, что жители Гаваона заключили с Исраилом мир и живут среди них, 2он очень испугался, потому что Гаваон был такой же большой город, как один из царских городов. Он был больше Гая, и все его жители были храбрыми воинами. 3И Адони-Цедек, царь Иерусалима, послал Гогаму, царю Хеврона, Пираму, царю Иармута, Иафие, царю Лахиша, и Девиру, царю Эглона, весть:

4– Придите и помогите мне напасть на Гаваон, – говорил он, – потому что он заключил мир с Иешуа и исраильтянами.

5Пять аморрейских царей – цари Иерусалима, Хеврона, Иармута, Лахиша и Эглона – объединили силы. Они вышли со всеми своими воинами, расположились станом напротив Гаваона и напали на него. 6Тогда гаваонитяне послали сказать Иешуа в гилгалский лагерь:

– Не оставь своих рабов! Скорее приходи к нам и спаси нас! Помоги нам, потому что все аморрейские цари с нагорий объединили свои силы против нас.

7Иешуа выступил из Гилгала со всем своим войском, со всеми лучшими воинами. 8Вечный сказал Иешуа:

– Не бойся их. Я отдал их в твои руки. Никто из них не сможет противостоять тебе.

9Иешуа шёл из Гилгала всю ночь и захватил своих врагов врасплох. 10Вечный привёл их в смятение перед Исраилом, который разбил их, одержав при Гаваоне великую победу. Исраильтяне гнались за ними по дороге, поднимающейся в Бет-Хорон, и разили их до Азеки и Маккеды. 11Когда аморреи бежали от исраильтян по склону Бет-Хорона в Азеку, Вечный забросал их с неба огромными градинами, и от града погибло больше народа, чем от мечей исраильтян.

12-13Иешуа воззвал к Вечному в тот день, когда Вечный отдал аморреев исраильтянам, и он сказал в присутствии Исраила (как и написано в «Книге Праведного»10:12-13 Букв.: «Книга Иашара». Эта древняя книга, не вошедшая в состав Священного Писания, не сохранилась до наших времён.):

«Стой, солнце, над Гаваоном,

и ты, луна, – над долиною Аялон!»

И солнце остановилось,

и стояла луна,

пока народ не отомстил своим врагам.

Солнце стояло посреди неба и медлило садиться почти целый день. 14Никогда не было такого дня ни прежде, ни потом – дня, когда Вечный послушался человека. Ведь Вечный сражался за Исраил.

15После этого Иешуа вернулся со всем Исраилом в гилгалский лагерь.

Казнь пяти аморрейских царей

16А пять царей бежали и укрылись в пещере в Маккеде. 17Когда Иешуа доложили, что пятерых царей обнаружили прячущимися в пещере в Маккеде, 18он сказал:

– Привалите к входу пещеры большие камни и приставьте к ней стражу. 19Но не останавливайтесь! Преследуйте своих врагов, атакуйте их сзади и не дайте им добраться до своих городов, потому что Вечный, ваш Бог, отдал их в ваши руки.

20Иешуа и исраильтяне истребили их полностью, не оставив в живых почти никого, и лишь немногие уцелевшие добрались до своих укреплённых городов. 21После этого всё войско благополучно вернулось к Иешуа в лагерь в Маккеде, и никто не посмел даже рта раскрыть против исраильтян.

22Иешуа сказал:

– Откройте пещеру и выведите ко мне тех пятерых царей!

23И к нему вывели из пещеры пятерых царей – царей Иерусалима, Хеврона, Иармута, Лахиша и Эглона. 24Когда к Иешуа вывели этих пятерых царей, он призвал всех исраильтян и сказал военачальникам, которые ходили с ним:

– Подойдите и поставьте ваши ноги на шеи этих царей.

Они подошли и поставили ноги на шеи царей.

25Иешуа сказал им:

– Не бойтесь и не теряйте присутствия духа! Будьте тверды и мужественны! Вечный поступит так со всеми врагами, с которыми вы будете воевать.

26Затем Иешуа поразил и умертвил царей и повесил их на пяти деревьях, и они висели на деревьях до вечера. 27На закате Иешуа приказал, и их сняли с деревьев и бросили в пещеру, где они укрывались. К входу в пещеру привалили большие камни, которые там и по сегодняшний день.

28В тот день Иешуа взял Маккеду. Он предал город и его царя мечу и полностью истребил всех жителей. Он никого не оставил в живых. Он сделал с царём Маккеды то же, что и с царём Иерихона.

Захват южных городов

29Затем Иешуа, и с ним весь Исраил, пошёл из Маккеды к Ливне и напал на неё. 30Вечный отдал в руки Исраила и этот город вместе с его царём. Город и всех, кто в нём был, Иешуа предал мечу. Он никого не оставил там в живых. Он сделал с его царём то же, что и с царём Иерихона.

31Затем Иешуа, и с ним весь Исраил, пошёл из Ливны к Лахишу. Он поставил напротив него стан и напал на него. 32Вечный отдал Лахиш Исраилу, и Иешуа взял его на второй день. Город и всех в нём он предал мечу, как он сделал это в Ливне. 33Тем временем Хорам, царь Гезера, пришёл Лахишу на помощь, но Иешуа разбил его и его войско, никого не оставив в живых.

34Затем Иешуа, и с ним весь Исраил, пошёл из Лахиша в Эглон. Они поставили напротив него стан и напали на него. 35Они взяли его в тот же день и предали его мечу. Иешуа полностью истребил всех, кто в нём был, как он сделал это с Лахишем.

36Затем Иешуа, и с ним весь Исраил, пошёл из Эглона в Хеврон и напал на него. 37Исраильтяне взяли город и предали его мечу вместе с его царём, его поселениями и всеми, кто в нём был. Они никого не оставили в живых. Как и в Эглоне, Иешуа полностью уничтожил и город, и всех, кто в нём был.

38Затем Иешуа, и с ним весь Исраил, повернул назад к Девиру и напал на него. 39Они взяли город, его царя и селения и предали их мечу. Они полностью истребили всех, кто в нём был, никого не оставив в живых. Иешуа сделал с Девиром то же, что и с Ливной и её царём и с Хевроном.

40Так Иешуа покорил всю ту область – нагорья и Негев, западные предгорья и горные склоны, и всех её царей. Он никого не оставил в живых. Он полностью истребил всё живое, как повелел Вечный, Бог Исраила. 41Иешуа покорил земли от Кадеш-Барни до Газы и всю область Гошен10:41 Гошен – эту область нужно отличать от Гошена в Египте (см., напр., Нач. 47:27). до Гаваона. 42Всех этих царей и их земли Иешуа взял за один поход, потому что Вечный, Бог Исраила, сражался за Исраил.

43Затем Иешуа и весь Исраил вернулись в гилгалский лагерь.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Joṣua 10:1-43

Òòrùn dúró jẹ́

1Ní báyìí tí Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu gbọ́ pé Joṣua ti gba Ai, tí ó sì ti pa wọ́n pátápátá; tí ó sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, àti bí àwọn ènìyàn Gibeoni ti ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú Israẹli, tí wọ́n sì ń gbé nítòsí wọn. 2Ìbẹ̀rù sì mú òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ torí pé Gibeoni jẹ́ ìlú tí ó ṣe pàtàkì, bí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ọba; ó tóbi ju Ai lọ, gbogbo ọkùnrin rẹ̀ ní ó jẹ́ jagunjagun. 3Nítorí náà Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu bẹ Hohamu ọba Hebroni, Piramu ọba Jarmatu, Jafia ọba Lakiṣi àti Debiri ọba Egloni. Wí pe, 4“Ẹ gòkè wá, kí ẹ sì ràn mi lọ́wọ́ láti kọlu Gibeoni, nítorí tí ó ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Joṣua àti àwọn ará Israẹli.”

5Àwọn ọba Amori márààrún, ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni, kó ara wọn jọ, wọ́n sì gòkè, àwọn àti gbogbo ogun wọn, wọ́n sì dojúkọ Gibeoni, wọ́n sì kọlù ú.

6Àwọn ará Gibeoni sì ránṣẹ́ sí Joṣua ní ibùdó ní Gilgali pé: “Ẹ má ṣe fi ìránṣẹ́ yín sílẹ̀. Ẹ gòkè tọ̀ wà wá ní kánkán kí ẹ sì gbà wá là. Ẹ ràn wá lọ́wọ́, nítorí gbogbo àwọn ọba Amori tí ń gbé ní orílẹ̀-èdè òkè dojú ìjà kọ wá.”

7Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua gòkè lọ láti Gilgali pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, àti akọni nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. 8Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn; Mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn ti yóò lè dojúkọ ọ́.”

9Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wọ́de ogun ní gbogbo òru náà láti Gilgali, Joṣua sì yọ sí wọn lójijì. 10Olúwa mú kí wọn dààmú níwájú àwọn Israẹli, wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Israẹli sì lépa wọn ní ọ̀nà tí ó lọ sí Beti-Horoni, ó sì pa wọ́n dé Aseka, àti Makkeda. 11Bí wọ́n sì tí ń sá ní iwájú Israẹli ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ní ọ̀nà láti Beti-Horoni títí dé Aseka, Olúwa rọ yìnyín ńlá sí wọn láti ọ̀run wá, àwọn tí ó ti ipa yìnyín kú sì pọ̀ ju àwọn tí àwọn ará Israẹli fi idà pa lọ.

12Ní ọjọ́ tí Olúwa fi àwọn ọmọ Amori lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sọ fún Olúwa níwájú àwọn ará Israẹli:

“Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gibeoni,

Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí Àfonífojì Aijaloni.”

13Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn náà sì dúró jẹ́ẹ́,

òṣùpá náà sì dúró,

títí tí ìlú náà fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀,

gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú ìwé Jaṣari.

Oòrùn sì dúró ní agbede-méjì ọ̀run, kò sì wọ̀ ní ìwọ̀n odindi ọjọ́ kan. 14Kò sí ọjọ́ tí o dàbí rẹ̀ ṣáájú tàbí ní ẹ̀yìn rẹ̀, ọjọ́ tí Olúwa gbọ́ ohùn ènìyàn. Dájúdájú Olúwa jà fún Israẹli!

15Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli padà sí ibùdó ní Gilgali.

A pa ọba Amori márùn-ún

16Ní báyìí àwọn ọba Amori márùn-ún ti sálọ, wọ́n sì fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta kan ní Makkeda, 17Nígbà tí wọ́n sọ fún Joṣua pé, a ti rí àwọn ọba márààrún, ti ó fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta ní Makkeda, 18ó sì wí pé, “Ẹ yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò àpáta náà, kí ẹ sì yan àwọn ọkùnrin sí ibẹ̀ láti ṣọ́ ọ. 19Ṣùgbọ́n, ẹ má ṣe dúró! Ẹ lépa àwọn ọ̀tá yín, ẹ kọlù wọ́n láti ẹ̀yìn, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó dé ìlú wọn, nítorí tí Olúwa Ọlọ́run yín tí fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”

20Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli pa wọ́n ní ìpakúpa wọ́n sì pa gbogbo ọmọ-ogun àwọn ọba márààrún run, àyàfi àwọn díẹ̀ tí wọ́n tiraka láti dé ìlú olódi wọn. 21Gbogbo àwọn ọmọ-ogun sì padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní ibùdó ogun ní Makkeda ní àlàáfíà, kò sí àwọn tí ó dábàá láti tún kọlu Israẹli.

22Joṣua sì wí pe, “Ẹ ṣí ẹnu ihò náà, kí ẹ sì mú àwọn ọba márààrún jáde wá fún mi.” 23Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọba márààrún náà kúrò nínú ihò àpáta, àwọn ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni. 24Nígbà tí wọ́n mú àwọn ọba náà tọ Joṣua wá, ó pe gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli, ó sì sọ fún àwọn olórí ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ bí, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín lé ọrùn àwọn ọba wọ̀nyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wá sí iwájú, wọ́n sì gbé ẹsẹ̀ lé ọrùn wọn.

25Joṣua sì sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ ṣe gírí, kí ẹ sì mú àyà le. Báyìí ni Olúwa yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀yin yóò bá jà.” 26Nígbà náà ni Joṣua kọlù wọ́n, ó sì pa àwọn ọba márààrún náà, ó sì so wọ́n rọ̀ ní orí igi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí orí igi títí di ìrọ̀lẹ́.

27Nígbà tí oòrùn wọ̀, Joṣua pàṣẹ, wọ́n sì sọ̀ wọ́n kalẹ̀ kúrò ní orí igi, wọ́n sì gbé wọn jù sí inú ihò àpáta ní ibi tí wọ́n sápamọ́ sí. Wọ́n sì fi òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà, tí ó sì wà níbẹ̀ di òní yìí.

28Ní ọjọ́ náà Joṣua gba Makkeda. Ó sì fi ojú idà kọlu ìlú náà àti ọba rẹ̀, ó sì run gbogbo wọn pátápátá, kò fi ẹnìkan sílẹ̀. Ó sì ṣe sí ọba Makkeda gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí ọba Jeriko.

A ṣẹ́gun àwọn ìlú ìhà gúúsù

29Nígbà náà ní Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Makkeda lọ sí Libina wọ́n sì kọlù ú. 30Olúwa sì fi ìlú náà àti ọba rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́. Ìlú náà àti gbogbo àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni Joṣua fi idà pa. Kò fi ẹnìkan sílẹ̀ ní ibẹ̀: Ó sì ṣe sí ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí ọba Jeriko.

31Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo ará Israẹli, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Libina lọ sí Lakiṣi; ó sì dó tì í, ó sì kọlù ú. 32Olúwa sì fi Lakiṣi lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sì gbà á ní ọjọ́ kejì. Ìlú náà àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀ ní ó fi idà pa gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Libina. 33Ní àkókò yìí, Horamu ọba Geseri gòkè láti ran Lakiṣi lọ́wọ́, ṣùgbọ́n Joṣua ṣẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ títí ti kò fi ku ẹnìkan sílẹ̀.

34Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Lakiṣi lọ sí Egloni; wọ́n sì dó tì í, wọ́n sì kọlù ú. 35Wọ́n gbà á ní ọjọ́ náà, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì run gbogbo ènìyàn ibẹ̀ pátápátá, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí Lakiṣi.

36Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli ṣí láti Egloni lọ sí Hebroni, wọ́n sì kọlù ú. 37Wọ́n gba ìlú náà, wọ́n sì ti idà bọ̀ ọ́, pẹ̀lú ọba rẹ̀, gbogbo ìletò wọn àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀. Wọn kò dá ẹnìkan sí. Gẹ́gẹ́ bí ti Egloni, wọ́n run un pátápátá àti gbogbo ènìyàn inú rẹ̀.

38Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ yí padà, wọ́n sì kọlu Debiri. 39Wọ́n gba ìlú náà, ọba rẹ̀ àti gbogbo ìlú wọn, wọ́n sì fi idà pa wọ́n. Gbogbo ènìyàn inú rẹ̀ ni wọ́n parun pátápátá. Wọn kò sì dá ẹnìkankan sí. Wọ́n ṣe sí Debiri àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọn ti ṣe sí Libina àti ọba rẹ̀ àti sí Hebroni.

40Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣẹ́gun gbogbo agbègbè náà, ìlú òkè, gúúsù, ìlú ẹsẹ̀ òkè ti ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè pẹ̀lú gbogbo ọba, wọn kò dá ẹnìkankan sí. Ó pa gbogbo ohun alààyè run pátápátá, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ti pàṣẹ. 41Joṣua sì ṣẹ́gun wọn láti Kadeṣi-Barnea sí Gasa àti láti gbogbo agbègbè Goṣeni lọ sí Gibeoni. 42Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí àti ilẹ̀ wọn ní Joṣua ṣẹ́gun ní ìwọ́de ogun ẹ̀ẹ̀kan, nítorí tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, jà fún Israẹli.

43Nígbà náà ni Joṣua padà sí ibùdó ní Gilgali pẹ̀lú gbogbo Israẹli.