Деяния 19 – CARS & YCB

Священное Писание

Деяния 19:1-40

Служение Паула в Эфесе

1В то время, когда Аполлос был в Коринфе, Паул, пройдя через горные области, пришёл в Эфес. Там он встретил нескольких учеников.

2– Приняли ли вы Святого Духа, когда поверили? – спросил он их.

– Мы даже и не слышали о том, что существует Святой Дух, – ответили те.

3Тогда Паул спросил:

– Если так, то какой обряд погружения19:3 Или: «обряд омовения»; также в ст. 4 и 5. вы приняли?

– Обряд погружения в воду, который совершал Яхия, – ответили они.

4Паул сказал:

– Обряд погружения в воду, который совершал Яхия, был знаком покаяния. Он призывал народ верить в Того, Кто должен был прийти после него, то есть в Ису.

5Когда они услышали об этом, они приняли обряд погружения в воду в знак единения с Повелителем Исой. 6И когда Паул возложил на них руки, на них сошёл Святой Дух. Они тогда начали говорить другими языками и пророчествовать. 7Всего их было около двенадцати человек.

8Паул три месяца смело говорил в молитвенном доме иудеев, беседуя с людьми о Царстве Всевышнего, и убеждал их. 9Некоторые из них, однако, ожесточались и отказывались верить, перед всеми браня Путь Исы. Тогда Паул оставил их. Он отделил учеников и ежедневно беседовал с ними в школе Тиранна. 10Так продолжалось два года, и все иудеи и греки, жившие в провинции Азия, слышали слово о Повелителе.

11Всевышний совершал через Паула великие чудеса. 12Больным давали прикоснуться к платкам и фартукам, к которым прежде прикасался Паул, и у них проходили болезни, и злые духи выходили из них. 13Некоторые из бродячих иудейских заклинателей тоже попробовали призывать над одержимыми имя Повелителя Исы. Они говорили:

– Заклинаю вас Исой, о Котором возвещает Паул.

14Это делали и семь сыновей Скевы, главного священнослужителя иудеев. 15Но злой дух ответил им:

– Ису я знаю, и Паул мне известен, а вы кто такие?

16И человек, в котором был злой дух, набросился на них с такой силой, что одолел их всех, и они выбежали из дома голые и израненные. 17Когда об этом узнали иудеи и греки, жившие в Эфесе, их охватил страх, и они стали относиться к имени Повелителя Исы с большим почтением. 18Многие из поверивших приходили и открыто признавались в своих делах. 19А многие занимавшиеся прежде волшебством приносили свои колдовские свитки и перед всеми сжигали их. Когда подсчитали общую стоимость всех сожжённых свитков, то она оказалась в пятьдесят тысяч серебряных монет19:19 Букв.: «пятьдесят тысяч драхм». Драхма – древнегреческая серебряная монета, по стоимости примерно равная дневной плате наёмного работника.. 20Так слово о Повелителе распространялось и набирало силу.

Бунт в Эфесе

21После всего этого Паул решил отправиться в Иерусалим через Македонию и Ахаию19:21 Македония и Ахаия – Греция в целом..

– После того как я побываю в Иерусалиме, мне нужно посетить и Рим, – говорил он.

22Он послал в Македонию двух помощников, Тиметея и Эраста, а сам ещё на некоторое время остался в провинции Азия.

23В это время произошёл большой мятеж из-за Пути Исы. 24Человек по имени Деметир, серебряных дел мастер, изготовлял из серебра модели храма богини Артемиды и тем самым давал местным ремесленникам возможность заработать. 25Он созвал их и других подобных мастеров и сказал:

– Вы знаете, что эта работа даёт нам хорошую прибыль. 26Но вы видите и слышите, что этот Паул своими речами ввёл в заблуждение многих людей не только здесь в Эфесе, но и по всей провинции Азия. Он говорит, что боги, сделанные руками человеческими, – это вовсе не боги. 27Это грозит не только тем, что наше ремесло потеряет своё доброе имя, но и тем, что храм великой богини Артемиды уже ничего не будет значить. И сама богиня, которую почитает вся провинция Азия и весь мир, будет лишена божественного величия!

28Услышав это, они в ярости стали кричать:

– Велика Артемида Эфесская!

29Вскоре весь город пришёл в движение. Люди схватили спутников Паула, македонян Гая и Аристарха, и все вместе ринулись в амфитеатр. 30Паул хотел выйти к народу, но ученики ему не позволили. 31Даже некоторые из представителей провинциальной власти, друзья Паула, передали ему просьбу не появляться в амфитеатре.

32Собравшиеся были в замешательстве, потому что одни кричали одно, другие – другое. Большинство же вообще не знало, зачем они собрались. 33Из толпы вытолкнули вперёд Искандера – это сделали иудеи. Искандер жестом призвал народ к тишине, чтобы сказать защитную речь. 34Но когда все узнали, что он иудей, то стали в один голос кричать:

– Велика Артемида Эфесская!

И кричали около двух часов. 35Тогда к народу вышел один из начальников города. Он успокоил их и сказал:

– Эфесяне, разве не известно всему миру, что город Эфес – хранитель храма великой Артемиды и её изображения, упавшего с небес? 36Это неопровержимый факт. Поэтому вы должны успокоиться и не поступать опрометчиво. 37Вы привели сюда этих людей, хотя ни один из них не обокрал храма и не оскорбил нашей богини. 38Если у Деметира и у других мастеров на кого-либо есть жалоба, то у нас для этого существуют суд и власти. Туда вы можете приносить обвинения друг на друга. 39Если у вас есть ещё какие-либо вопросы, то представьте их на рассмотрение законного собрания. 40Есть опасность, что после сегодняшних событий нас могут обвинить в мятеже, и в таком случае нам нечем будет оправдаться, так как для этого сборища нет никаких оснований.

С этими словами он распустил собрание.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìṣe àwọn Aposteli 19:1-41

Paulu ní Efesu

1Nígbà ti Apollo wà ni Kọrinti, ti Paulu kọjá lọ sí apá òkè ìlú, ó sì wá sí Efesu: o sì rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kan; 2o wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ha gba Ẹ̀mí Mímọ́ náà nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́?”

Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò gbọ́ rárá pé Ẹ̀mí Mímọ́ kan wà.”

3Ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ irú bamitiisi wo ni a bamitiisi yín sí?”

Wọ́n sì wí pé, “Sí bamitiisi tí Johanu.”

4Paulu sí wí pé, “Nítòótọ́, ní Johanu fi bamitiisi tí ìrònúpìwàdà bamitiisi, ó ń wí fún àwọn ènìyàn pé, kí wọ́n gba ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́, èyí sì ni Kristi Jesu.” 5Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, a bamitiisi wọn lórúkọ Jesu Olúwa. 6Nígbà tí Paulu sì gbé ọwọ́ lé wọn, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn: wọ́n sì ń fọ́ èdè mìíràn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. 7Iye àwọn ọkùnrin náà gbogbo tó méjìlá.

8Nígbà tí ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni oṣù mẹ́ta, ó ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó sì ń yí wọn lọ́kàn padà sí nǹkan tí i ṣe tí ìjọba Ọlọ́run. 9Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoojúmọ́ ni ilé ìwé Tirannusi. 10Èyí n lọ bẹ́ẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì; tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ń gbé Asia gbọ́ ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki.

11Ọlọ́run sì tí ọwọ́ Paulu ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìyanu, 12tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń mú aṣọ àti aṣọ ìnuwọ́ rẹ̀ tọ àwọn ọlọkùnrùn lọ, ààrùn sì fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí búburú sì jáde kúrò lára wọn.

13Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan n lọ káàkiri láti máa le ẹ̀mí èṣù jáde, wọn dáwọ́lé àdábọwọ́ ara wọn, láti pé orúkọ Jesu Olúwa sí àwọn tí ó ni ẹ̀mí búburú, wí pé, “Àwa fi orúkọ Jesu tí Paulu ń wàásù fi yín bú.” 14Àwọn méje kan sì wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹnìkan tí a ń pè ni Sikẹfa, tí í ṣe olórí àlùfáà gíga láàrín àwọn Júù. 15Ẹ̀mí búburú náà sì dáhùn, ó ní “Jesu èmi mọ̀ ọ́n, mo sì mọ Paulu pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin?” 16Nígbà tí ọkùnrin tí ẹ̀mí búburú náà wà lára rẹ̀ sì fò mọ́ wọn, ó pa kúúrù mọ́ wọn, ó sì borí wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sá jáde kúrò ní ilé náà ní ìhòhò pẹ̀lú ni ìfarapa.

17Ìròyìn yìí sì di mí mọ̀ fún gbogbo àwọn Júù àti àwọn ará Giriki pẹ̀lú tí ó ṣe àtìpó ní Efesu; ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn, a sì gbé orúkọ Jesu Olúwa ga. 18Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ sì wá, wọ́n jẹ́wọ́, wọ́n sì fi iṣẹ́ wọn hàn. 19Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí ń ṣe alálúpàyídà ni ó kó ìwé wọn jọ, wọ́n dáná sun wọ́n lójú gbogbo ènìyàn. Wọ́n sì ṣírò iye wọn, wọ́n sì rí i, ó jẹ́ ẹgbàá-mẹ́dọ́gbọ̀n ìwọ̀n fàdákà. 20Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa gbèrú tí o sí gbilẹ̀ si í gidigidi.

21Ǹjẹ́ bí nǹkan wọ̀nyí tí parí tan, Paulu pinnu nínú ọkàn rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kọjá ní Makedonia àti Akaia, òun ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wí pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo bá dé ibẹ̀, èmi kò lè ṣàìmá dé Romu pẹ̀lú.” 22Nígbà tí ó sì tí rán méjì nínú àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un lọ sí Makedonia, Timotiu àti Erastu, òun tìkára rẹ̀ dúró díẹ̀ ní ilẹ̀ Asia.

Ìrúkèrúdò ní Efesu

23Ní àkókò náà ìrúkèrúdò díẹ̀ kan wà nítorí ọ̀nà náà. 24Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Demetriusi, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé òrìṣà fún Artemisi, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà; 25Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọnà bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nípa iṣẹ́ ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa. 26Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Efesu nìkan ṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ jẹ́ gbogbo Asia ni Paulu yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run. 27Kì í sì ṣe pé kìkì iṣẹ́ ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí asán; ṣùgbọ́n tẹmpili Artemisi òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọláńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Asia àti gbogbo ayé ń bọ.”

28Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n kún fún ìbínú, wọ́n kígbe, wí pé, “Òrìṣà ńlá ni Artemisi ti ará Efesu!” 29Gbogbo ìlú náà sì kún fún ìrúkèrúdò: wọ́n sì fi ọkàn kan rọ́ wọn sí inú ilé ìṣeré, wọ́n sì mú Gaiu àti Aristarku ara Makedonia, àwọn ẹlẹgbẹ́ Paulu nínú ìrìnàjò. 30Nígbà ti Paulu sì ń fẹ́ wọ àárín àwọn ènìyàn lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kọ̀ fún un. 31Àwọn olórí kan ara Asia, tí i ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ránṣẹ́ sí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe fi ara rẹ̀ wéwu nínú ilé ìṣeré náà.

32Ǹjẹ́ àwọn kan ń wí ohun kan, àwọn mìíràn ń wí òmíràn: nítorí àjọ di rúdurùdu; ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò sì mọ̀ ìdí ohun tí wọ́n tilẹ̀ fi péjọpọ̀. 33Àwọn kan nínú àwùjọ Júù ti Aleksanderu síwájú, wọn si pàṣẹ fun láti sọ̀rọ̀. Ó juwọ́ sí wọn láti dákẹ́ kí ó ba lè wí tẹnu rẹ̀ fun àwọn ènìyàn. 34Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Júù ni, gbogbo wọn ni ohùn kan, bẹ̀rẹ̀ sí kígbe fún bi wákàtí méjì pé, “Òrìṣà ńlá ni Artemisi tí ará Efesu!”

35Nígbà tí akọ̀wé ìlú sì mú kí ìjọ ènìyàn dákẹ́, “Ẹ̀yin ará Efesu, ta ni ẹni tí ó wà tí kò mọ̀ pé, ìlú Efesu ní í ṣe olùsìn Artemisi òrìṣà ńlá, àti tí ère tí ó ti ọ̀dọ̀ Jupiteri bọ́ sílẹ̀? 36Ǹjẹ́ bi a kò tilẹ̀ sọ̀rọ̀-òdì sí nǹkan wọ̀nyí, ó yẹ kí ẹ dákẹ́, kí ẹ̀yin má ṣe fi ìkanra ṣe ohunkóhun. 37Nítorí ti ẹ̀yin mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wá, wọn kò ja ilé òrìṣà lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀-òdì sí òrìṣà wa. 38Ǹjẹ́ nítorí náà tí Demetriusi, àti àwọn oníṣẹ́-ọnà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ bá ní gbólóhùn asọ̀ kan sí ẹnikẹ́ni, ilé ẹjọ́ ṣí sílẹ̀, àwọn onídàájọ́ sì ń bẹ: jẹ́ kí wọn lọ fi ara wọn sùn. 39Ṣùgbọ́n bí ẹ ba ń wádìí ohun kan nípa ọ̀ràn mìíràn, a ó parí rẹ̀ ni àjọ tí ó tọ́. 40Nítorí àwa ṣa wà nínú ewu, nítorí rògbòdìyàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ lónìí yìí; kò ṣáá ní ìdí kan tí rògbòdìyàn yìí fi bẹ́ sílẹ̀, nítorí èyí àwa kì yóò lè dáhùn fún ìwọ́jọ yìí.” 41Nígbà tí ó sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tan, ó tú ìjọ náà ká.