Второзаконие 8 – CARS & YCB

Священное Писание

Второзаконие 8:1-20

Повеление не забывать Вечного

1Вы должны старательно исполнять все повеления, которые я даю вам сегодня, чтобы жить и становиться всё более многочисленными, чтобы войти в землю, которую Вечный клятвенно обещал вашим предкам, и завладеть ею. 2Помни, Исраил, как Вечный, твой Бог, вёл тебя через пустыню все эти сорок лет, смиряя и испытывая тебя, чтобы узнать, что в твоём сердце: будешь ты исполнять Его повеления или нет. 3Он смирял тебя, заставляя тебя голодать, а затем насыщал манной, которой не знал ни ты, ни твои предки, чтобы научить тебя, что не одним хлебом живёт человек, но и каждым словом, исходящим из уст Вечного. 4Твоя одежда не изнашивалась и твои ноги не опухали все эти сорок лет. 5Пусть твоё сердце помнит, что как человек наставляет своего сына, так и Вечный, твой Бог, наставляет тебя.

6Соблюдай повеления Вечного, своего Бога, ходи Его путями и почитай Его. 7Ведь Вечный, твой Бог, вводит тебя в благодатную землю – землю с многоводными реками и водоёмами, с источниками, пробивающимися в долинах и в горах; 8в землю с пшеницей и ячменём, виноградными лозами и инжиром, гранатами, оливковым маслом и мёдом; 9в землю, где хлеба не оскудеют, и ты ни в чём не будешь нуждаться; в землю, где скалы содержат железо, и где из гор ты сможешь добывать медь.

10Когда ты поешь и насытишься, тогда славь Вечного, своего Бога, за ту благодатную землю, которую Он дал тебе. 11Берегись, не забудь Вечного, своего Бога, соблюдай Его повеления, законы и установления, которые я даю тебе сегодня. 12Иначе, когда ты поешь и насытишься, когда построишь хорошие дома и поселишься в них, 13когда твои стада и отары увеличатся, а серебро, золото и всё имущество умножатся, 14твоё сердце возгордится, и ты забудешь Вечного, своего Бога, Который вывел тебя из Египта, из земли рабства. 15Он вёл тебя через огромную и ужасную пустыню, иссохшую и безводную землю с ядовитыми змеями и скорпионами. Он дал тебе воду из кремневой скалы. 16Он кормил тебя манной в пустыне, которую никогда не знали твои отцы, чтобы смирить и испытать тебя и чтобы в конце концов, когда у тебя всё будет благополучно, 17ты не сказал про себя: «Я заработал это богатство своей силой и мощью рук». 18Всегда помни Вечного, своего Бога, потому что это Он даёт тебе возможность приобретать богатство, подтверждая – как это и есть сегодня – Своё священное соглашение, о котором Он клялся твоим предкам.

19Если ты когда-нибудь забудешь Вечного, своего Бога, последуешь другим богам и будешь служить и кланяться им, то – я свидетельствую против тебя сегодня – ты непременно будешь истреблён. 20Подобно народам, которых Вечный истребил перед тобой, будешь истреблён и ты за непослушание Вечному, твоему Богу.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 8:1-20

Má ṣe gbàgbé Olúwa

1Ẹ kíyèsi i láti máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí mo fún un yín lónìí, kí ẹ bá à le yè, kí ẹ sì pọ̀ sí i wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le gba ilẹ̀ náà, tí Olúwa fì búra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín. 2Ẹ rántí bí Olúwa Ọlọ́run yín ti tọ́ ọ yín ṣọ́nà ní gbogbo ọ̀nà ní aginjù fún ogójì ọdún wọ̀nyí láti tẹ orí yín ba àti láti dán an yín wò kí ó ba à le mọ bí ọkàn yín ti rí, bóyá ẹ ó pa òfin rẹ̀ mọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. 38.3: Mt 4.4; Lk 4.4.Ó rẹ̀ yín sílẹ̀ nípa fífi ebi pa yín, Ó sì fi manna bọ́ ọ yín, èyí tí ẹ kò mọ̀, tí àwọn baba yín kò mọ̀, kí ó ba à lè kọ́ ọ yín pé, ènìyàn kò ti ipa oúnjẹ nìkan wà láààyè, bí kò ṣe ohun gbogbo tí ó jáde láti ẹnu Olúwa wá. 4Aṣọ yín kò gbó mọ́ ọn yín lọ́rùn bẹ́ẹ̀ ní ẹsẹ̀ yín kò sì wú, ní ogójì ọdún náà. 5Ẹ mọ̀ ní ọkàn an yín pé, bí baba ti ń kọ́ ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín ń kọ́ ọ yín.

6Nítorí èyí, ẹ gbọdọ̀ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́, nípa rínrìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti bíbẹ̀rù rẹ̀. 7Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ń mú un yín bọ̀ wá sí ilẹ̀ rere ilẹ̀ tí ó kún fún odò àti ibú omi, pẹ̀lú àwọn ìsun tí ń sàn jáde láti orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀. 8Ilẹ̀ tí ó kún fún jéró àti ọkà barle, tí ó sì kún fún àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́, igi pomegiranate, òróró olifi àti oyin. 9Ilẹ̀ tí oúnjẹ kò ti wọ́n, kò sí ohun tí ẹ̀yin yóò ṣe aláìní, ilẹ̀ tí irin ti pọ̀ bí òkúta, ẹ̀yin sì lè wa idẹ jáde láti inú òkè rẹ̀ wá.

10Nígbà tí ẹ bá ti jẹ tí ẹ sì yó tán ẹ yin Olúwa Ọlọ́run yín fún pípèsè ilẹ̀ rere fún un yín. 118.11-16: Ho 13.5,6.Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, nípa kíkùnà láti pa àṣẹ rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti àwọn ìlànà rẹ̀ tí mo ń fún un yín lónìí mọ́. 12Kí ó má ba à jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀, 13nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i, 14nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbéga, tí ẹ̀yin yóò sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá, nínú oko ẹrú. 15Òun ni ó mú un yín la aginjù ẹlẹ́rù ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òǹgbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńláńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta. 16Ó fún yín ní manna láti jẹ nínú aginjù, ohun tí àwọn baba yín kò mọ̀ rí, kí Òun bá à le tẹ orí yín ba kí ó sì lè dán an yín wò, kí ó bá à lè dára fún un yín. 17Ẹ lè rò nínú ara yín pé, “Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún mi.” 18Ṣùgbọ́n ẹ rántí Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fún un yín ní agbára àti lè ní àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì fi mú májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín bí ó ti rí lónìí.

19Bí ẹ bá wá gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn, tí ẹ sì sìn wọ́n, tí ẹ sì foríbalẹ̀ fún wọn, Mo kìlọ̀ fún un yín pé rírun ni ẹ̀yin yóò run. 20Bí àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa parun níwájú u yín, bákan náà ni ẹ ó parun, torí pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín lẹ́nu.