Второзаконие 10 – CARS & YCB

Священное Писание

Второзаконие 10:1-22

Новые каменные плитки

(Исх. 34:1-9)

1Тогда Вечный сказал мне: «Высеки две каменные плитки, подобные прежним, и поднимись ко Мне на гору. Ещё сделай деревянный сундук10:1 Сундук – см. пояснительный словарь, а также Исх. 25:10-22.. 2Я напишу на плитках слова, что были на тех, которые ты разбил. Затем ты положишь их в сундук».

3Я сделал сундук из дерева акации, вытесал две каменные плитки, подобные прежним, и с ними в руках поднялся на гору. 4Вечный написал на этих плитках то же, что и прежде, десять повелений10:4 Букв.: «десять слов»., которые Он объявил вам на горе, из огня, в день собрания. И Вечный дал их мне. 5Затем я вернулся, спустившись с горы, и положил плитки в сундук, который я сделал, как повелел мне Вечный, они и сейчас там.

Смерть Харуна и служение левитов

6Исраильтяне отправились от колодцев яаканитов10:6 Букв.: «Беэрот-Бене-Яакан». в Мозер. Там Харун умер и был похоронен, а Элеазар, его сын, унаследовал его священство. 7Оттуда они путешествовали в Гудгод, а далее в Иотвату, землю, где много рек. 8В то время Вечный отделил род Леви, чтобы они носили сундук соглашения с Вечным, стояли перед Вечным, служили Ему и благословляли Его именем, что они до сих пор и делают. 9Вот почему у левита нет доли и наследия среди своих братьев; Вечный – вот его наследие, как Вечный, твой Бог, и сказал ему.

10Я пробыл на горе сорок дней и ночей, как и в первый раз, и Вечный снова внял мне. Он не захотел истребить вас. 11«Иди, – сказал мне Вечный, – и веди народ в путь, чтобы они пошли и завладели землёй, которую Я клялся отдать их предкам».

Повеление бояться Вечного

12Итак, Исраил, чего же просит от тебя Вечный, твой Бог, кроме того, чтобы ты боялся Вечного, своего Бога, ходил всеми Его путями, любил Его, служил Ему от всего сердца и от всей души 13и соблюдал повеления и установления Вечного, которые я даю тебе сегодня для твоего же блага?

14Вечному, твоему Богу, принадлежат небеса, даже небеса небес, земля и всё, что на ней. 15И всё-таки Вечный пожелал любить твоих предков и выбрал вас, их потомков, из всех народов, как это и есть сегодня. 16Обрежьте крайнюю плоть вашего сердца10:16 Люди с необрезанными сердцами – образное выражение обозначает людей, непокорных Всевышнему. и больше не упрямьтесь. 17Ведь Вечный, ваш Бог, – это Бог богов и Владыка владык, великий Бог, могучий и грозный, беспристрастный и не берущий взятки. 18Он защищает дело сирот и вдов, любит чужеземцев, кормит и одевает их. 19И вам следует любить чужеземцев, потому что вы сами были чужеземцами в Египте. 20Бойтесь Вечного, вашего Бога, и служите Ему. Будьте верны Ему и клянитесь Его именем. 21Он – ваша хвала; Он – ваш Бог, совершивший для вас великие и страшные чудеса, которые вы видели своими собственными глазами. 22Ваших предков, которые отправились в Египет, было семьдесят человек, а теперь Вечный, ваш Бог, сделал вас многочисленными, и вас так много, как звёзд на небе.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 10:1-22

Wàláà òfin bí i ti ìṣáájú

1Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Gbé wàláà òkúta méjì bí i ti àkọ́kọ́ kí o sì gòkè tọ̀ mí wá. Kí o sì tún fi igi kan àpótí kan. 2Èmi yóò sì kọ ọ̀rọ̀ tí ó wà lára wàláà àkọ́kọ́ tí ìwọ fọ́, sára wàláà wọ̀nyí. Ìwọ yóò sì fi wọ́n sínú àpótí náà.”

3Mo sì kan àpótí náà pẹ̀lú igi kasia, mo sì gbẹ́ wàláà òkúta méjì náà jáde bí i ti ìṣáájú. Mo sì gòkè lọ pẹ̀lú wàláà méjèèjì lọ́wọ́ mí. 4Olúwa tún ohun tí ó ti kọ tẹ́lẹ̀ kọ sórí wàláà wọ̀nyí. Àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó ti sọ fún un yín lórí òkè, láàrín iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀. Olúwa sì fi wọ́n fún mi. 5Mo sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, mo sì ki àwọn wàláà òkúta náà sínú àpótí tí mo ti kàn, bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi, wọ́n sì wà níbẹ̀ di ìsinsin yìí.

6(Àwọn ará Israẹli sì gbéra láti kànga àwọn ará Jaakani dé Mosera. Níbí ni Aaroni kú sí, tí a sì sin ín, Eleasari ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ bí i àlùfáà. 7Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rìn lọ sí Gudgoda, títí dé Jotbata, ilẹ̀ tí o kún fún odò tí ó ń sàn. 8Ní ìgbà yìí ni Olúwa yan àwọn ẹ̀yà Lefi láti máa ru àpótí ẹ̀rí Olúwa, láti máa dúró níwájú Olúwa láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti láti fi orúkọ Olúwa súre bí wọ́n ti ń ṣe títí di òní yìí. 9Ìdí nìyí tí àwọn ẹ̀yà Lefi kò fi ní ìpín tàbí ogún kan láàrín àwọn arákùnrin wọn. Olúwa ni ogún wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run ti sọ fún un yín.)

10Mo tún dúró ní orí òkè náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, bí mo ti ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́, Olúwa sì gbọ́ tèmi ní àkókò yìí bákan náà. Kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láti run yín. 11Olúwa sọ fún mi pé, “Lọ darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọ̀nà wọn, kí wọn bá à lè wọ ilẹ̀ náà, kí wọn sì gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn láti fún wọn.”

Ẹ bẹ̀rù Olúwa

12Nísinsin yìí ìwọ Israẹli, kín ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ọkàn àti àyà rẹ, 13àti láti máa kíyèsi àṣẹ àti ìlànà Olúwa tí mo ń fún ọ lónìí, fún ìre ara à rẹ.

14Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀. 15Síbẹ̀ Olúwa sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀-èdè títí di òní. 16Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, (Ẹ wẹ ọkàn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́) kí ẹ má sì ṣe jẹ́ olórí kunkun mọ́ láti òní lọ. 1710.17: Ap 10.34; Ga 2.6; If 17.14; 19.16.Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojúsàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. 18Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àjèjì, Òun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn. 1910.19: El 22.21; 23.9; Le 19.34.Ẹ gbọdọ̀ fẹ́ràn àwọn àjèjì, torí pé ẹ̀yin pẹ̀lú ti jẹ́ àjèjì rí ní Ejibiti. 20Ẹ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dìímú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀. 21Òun ni ìyìn in yín, Òun sì ni Ọlọ́run yín, tí ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá àti ohun ẹ̀rù, tí ẹ fojú ara yín rí. 2210.22: Ap 7.14.Àádọ́rin (70) péré ni àwọn baba ńlá a yín tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run yín ti mú un yín pọ̀ sí i ní iye bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run.