Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Sekariah 4

Ọ̀pá fìtílà wúrà àti àwọn igi olifi méjì

1Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì tún dé, ó sì jí mi, bí ọkùnrin tí a jí lójú oorun rẹ̀, Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?”

Mo sì wí pé, “Mo wò, sì kíyèsi i, ọ̀pá fìtílà tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ wúrà, pẹ̀lú àwokòtò rẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú fìtílà méje rẹ̀ lórí rẹ̀, àti ẹnu méje fún fìtílà méjèèje, tí ó wà lórí rẹ̀: Igi olifi méjì sì wà létí rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwokòtò náà, àti èkejì ní apá òsì rẹ̀.”

Mo sì dáhùn mo sì wí fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé, “Kín ni wọ̀nyí, olúwa mi?”

Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”

Mo sì wí pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n, olúwa mi.”

Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Serubbabeli tó wí pé: ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa Ẹ̀mí mi,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

“Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubbabeli: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún fun! Ọlọ́run bùkún fun!’ ”

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé: “Ọwọ́ Serubbabeli ni a ti ṣe ìpìlẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀; ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín.

10 “Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ nígbà ti wọ́n bá rí okùn ìwọ̀n nì lọ́wọ́ Serubbabeli.

“(Àwọn méje wọ̀nyí ni àwọn ojú Olúwa, tí ó ń sáré síhìn-ín sọ́hùn-ún ní gbogbo ayé.)”

11 Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn igi olifi méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀?”

12 Mo sì tún dáhùn, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn ẹ̀ka méjì igi olifi wọ̀nyí jásí, tí ń tú òróró wúrà jáde nínú ara wọn láti ẹnu ọ̀pá oníhò wúrà méjì.”

13 Ó sì dáhùn, ó wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”

Mo sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa à mi.”

14 Ó sì wí pé, “Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti Olúwa gbogbo ayé.”

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

撒迦利亚书 4

金灯台和橄榄树

1那位与我说话的天使又来唤醒我,像唤醒睡觉的人一样。 他问我:“你看见了什么?”

我说:“我看见一个纯金的灯台,上面有一个油碗,灯台上有七盏灯,每盏灯有七个灯芯。 灯台旁边有两棵橄榄树,左右各一棵。” 我问与我说话的天使:“主啊,这是什么意思?” 他说:“你不知道吗?”我说:“主啊,我不知道。”

他对我说:“这是耶和华对所罗巴伯讲的话。万军之耶和华说,‘不靠权势,不靠才能,乃靠我的灵。 大山啊,你算什么?你必在所罗巴伯面前化为平地。他必搬出那块封殿顶的石头,伴随着欢呼声——愿恩典、恩典归于这殿!’”

耶和华的话又传给了我,说: “所罗巴伯的手奠立这殿的根基,他的手也必完成这项工程。那时你便知道是万军之耶和华差遣我到你们这里来的。 10 谁敢藐视这微不足道的日子?人们看见所罗巴伯手中拿着线锤时,就必欢喜。

“这七盏灯是耶和华遍察天下的眼睛。”

11 我又问天使:“灯台左右的两棵橄榄树是什么意思?” 12 然后我又问道:“流出橄榄油的两个金管旁边的两根橄榄枝是什么意思?” 13 他说:“你不知道吗?”我说:“主啊,我不知道。” 14 他说:“这是侍立在天下之主旁边的两位受膏者。”