Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 1

Ìkànìyàn

1Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní aginjù Sinai nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ó wí pé: “Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Israẹli nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ìwọ àti Aaroni ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun. Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan láti inú olúkúlùkù ẹ̀yà kí ó sì wá pẹ̀lú yín, kí olúkúlùkù jẹ́ olórí ilé àwọn baba rẹ̀.

“Orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyí:

“Láti ọ̀dọ̀ Reubeni, Elisuri ọmọ Ṣedeuri;

Láti ọ̀dọ̀ Simeoni, Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai;

Láti ọ̀dọ̀ Juda, Nahiṣoni ọmọ Amminadabu;

Láti ọ̀dọ̀ Isakari, Netaneli ọmọ Ṣuari;

Láti ọ̀dọ̀ Sebuluni, Eliabu ọmọ Heloni;

10 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Josẹfu:

láti ọ̀dọ̀ Efraimu, Eliṣama ọmọ Ammihudu;

Láti ọ̀dọ̀ Manase, Gamalieli ọmọ Pedasuri;

11 Láti ọ̀dọ̀ Benjamini, Abidani ọmọ Gideoni;

12 Láti ọ̀dọ̀ Dani, Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai;

13 Láti ọ̀dọ̀ Aṣeri, Pagieli ọmọ Okanri;

14 Láti ọ̀dọ̀ Gadi, Eliasafu ọmọ Deueli;

15 Láti ọ̀dọ̀ Naftali, Ahira ọmọ Enani.”

16 Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Israẹli.

17 Mose àti Aaroni mú àwọn ènìyàn tí a dárúkọ wọ̀nyí 18 wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Israẹli jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì. Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn. Wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè, 19 gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kà wọ́n nínú aginjù Sinai.

20 Láti ìran Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Israẹli:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn, lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 21 Àwọn tí a kà ní ẹ̀yà Reubeni jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàlélógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (46,500).

22 Láti ìran Simeoni:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà, wọ́n sì to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 23 Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbàá-mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-ọ̀ọ́dúnrún (59,300).

24 Láti ìran Gadi:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ẹbí àti ìdílé wọn. 25 Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Gadi jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀jọ (45,650).

26 Láti ìran Juda:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 27 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlógójì ó-lé-ẹgbẹ̀ta (74,600).

28 Láti ìran Isakari:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 29 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó-lé-irínwó (54,400).

30 Láti ìran Sebuluni:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 31 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (57,400).

32 Láti inú àwọn ọmọ Josẹfu:

Láti ìran Efraimu:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 33 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Efraimu jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).

34 Láti ìran Manase:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 35 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Manase jẹ́ ẹgbàá ẹ́rìndínlógún ó-lé-igba (32,200).

36 Láti ìran Benjamini:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 37 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Benjamini jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tà-dínlógún ó-lé-egbèje (35,400).

38 Láti ìran Dani:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 39 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Dani jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (62,700).

40 Láti ìran Aṣeri:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 41 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).

42 Láti ìran Naftali:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún ó lé, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 43 Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Naftali jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (53,400).

44 Wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí Mose àti Aaroni kà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí méjìlá (12) fún Israẹli, tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ṣojú fún ìdílé rẹ̀. 45 Gbogbo ọmọkùnrin Israẹli tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún (20) sókè, tó sì lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. 46 Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-egbéjì-dínlógún-dínàádọ́ta, (603,550).

47 A kò ka àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ìyókù. 48 Nítorí Olúwa ti sọ fún Mose pé, 49 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ka ẹ̀yà Lefi, tàbí kí o kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli: 50 Dípò èyí yan àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ alábojútó àgọ́ ẹ̀rí, lórí gbogbo ohun èlò àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti àgọ́ ẹ̀rí. Àwọn ni yóò máa gbé àgọ́ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, wọn ó máa mójútó o, kí wọn ó sì máa pàgọ́ yí i ká. 51 Ìgbàkígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, àwọn ọmọ Lefi ni yóò tú palẹ̀, nígbàkígbà tí a bá sì tún pa àgọ́, àwọn ọmọ Lefi náà ni yóò ṣe é. Àlejò tó bá súnmọ́ tòsí ibẹ̀, pípa ni kí ẹ pa á 52 kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn olúkúlùkù ní ibùdó tirẹ̀ lábẹ́ ọ̀págun tirẹ̀. 53 Àwọn ọmọ Lefi yóò jẹ́ alábojútó àti olùtọ́jú àgọ́ ẹ̀rí náà, kí ìbínú má ba à sí lára ìjọ àwọn ọmọ Israẹli; kí àwọn ọmọ Lefi sì máa ṣe ìtọ́jú àgọ́ ẹ̀rí náà.”

54 Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

New Serbian Translation

4 Мојсијева 1

Први попис Израиљаца

1Првога дана другога месеца, друге године након што су изашли из Египта, Господ рече Мојсију у Синајској пустињи, у Шатору од састанка: „Извршите попис све заједнице синова Израиљевих по њиховим породицама и њиховим отачким домовима, према броју имена свих мушкараца, једног по једног. Ти и Арон забележите све у Израиљу по њиховим јединицама, од двадесет година па навише, који су способни за војску. С вама ће бити по један човек из сваког племена, који је главар свог отачког дома.

Ово су имена људи који ће вам помагати:

за Рувимово племе, Елисур, Седијуров син;

за Симеуново племе, Сурисадајев син Саламило;

за Јудино племе, Аминадавов син Насон;

за Исахарово племе, Согаров син Натанаило,

За Завулоново племе, Хелонов син Елијав.

10 За Јосифове синове:

Амијудов син Елисама, за Јефремово племе,

и Фадасуров син Гамалило, за Манасијино племе.

11 За Венијаминово племе, Гадеонијев син Авидан;

12 за Даново племе, Амисадајев син Ахијезер;

13 за Асирово племе, Ехранов син Фагаило;

14 за Гадово племе, Деуелов син Елисаф;

15 за Нефталимово племе, Енанов син Ахиреј.“

16 Ови су били изабрани од заједнице, кнезови својих отачких племена, главари Израиљевих хиљада.

17 Мојсије и Арон су узели ове људе који су били одређени по имену, 18 па су сабрали сву заједницу првога дана другог месеца. Они су се, један по један, уписали у своја родословља, по својим породицама, по својим отачким домовима, и по својим именима, од двадесет година па навише, 19 као што је Господ заповедио Мојсију. Тако их је пописао у Синајској пустињи.

20 Од потомака Рувима, Израиљевог првенца, појединачно су били пописани сви мушкарци од двадесет година па навише, способни за војску, по својим родословима, по својим породицама и својим отачким домовима. 21 Из Рувимовог племена било је пописано четрдесет шест хиљада пет стотина.

22 Од Симеунових потомака, појединачно су били пописани сви мушкарци способни за војску од двадесет година па навише, по својим родословима, по својим породицама и својим отачким домовима. 23 Из Симеуновог племена било је пописано педесет девет хиљада три стотине.

24 Од Гадових потомака, појединачно су били пописани сви мушкарци способни за војску од двадесет година па навише, по својим родословима, по својим породицама и својим отачким домовима. 25 Из Гадовог племена било је пописано четрдесет пет хиљада шест стотина педесет.

26 Од Јудиних потомака, појединачно су били пописани сви мушкарци способни за војску од двадесет година па навише, по својим родословима, по својим породицама и својим отачким домовима. 27 Из Јудиног племена било је пописано седамдесет четири хиљаде шест стотина.

28 Од Исахарових потомака, појединачно су били пописани сви мушкарци од двадесет година па навише, способни за војску, по својим родословима, по својим породицама и својим отачким домовима. 29 Из Исахаровог племена било је пописано педесет четири хиљаде четири стотине.

30 Од Завулонових потомака, појединачно су били пописани сви мушкарци од двадесет година па навише, способни за војску, по својим родословима, по својим породицама и својим отачким домовима. 31 Из Завулоновог племена било је пописано педесет седам хиљада четири стотине.

32 Од Јосифових потомака: од Јефремових потомака, појединачно су били пописани сви мушкарци од двадесет година па навише, способни за војску, по својим родословима, по својим породицама и својим отачким домовима. 33 Из Јефремовог племена било је пописано четрдесет хиљада пет стотина.

34 Од Манасијиних потомака, појединачно су били пописани сви мушкарци од двадесет година па навише способни за војску, по својим родословима, по својим породицама и својим отачким домовима. 35 Из Манасијиног племена било је пописано тридесет две хиљаде две стотине.

36 Од Венијаминових потомака, појединачно су били пописани сви мушкарци од двадесет година па навише, способни за војску, по својим родословима, по својим породицама и својим отачким домовима. 37 Из Венијаминовог племена било је пописано тридесет пет хиљада четири стотине.

38 Од Данових потомака, појединачно су били пописани сви мушкарци од двадесет година па навише, способни за војску, по својим родословима, по својим породицама и својим отачким домовима. 39 Из Дановог племена било је пописано шездесет две хиљаде седам стотина.

40 Од Асирових потомака, појединачно су били пописани сви мушкарци од двадесет година па навише, способни за војску, по својим родословима, по својим породицама и својим отачким домовима. 41 Из Асировог племена било је пописано четрдесет једна хиљада пет стотина.

42 Од Нефталимових потомака, појединачно су били пописани сви мушкарци од двадесет година па навише, способни за војску, по својим родословима, по својим породицама и својим отачким домовима. 43 Из Нефталимовог племена било је пописано педесет три хиљаде четири стотине.

44 Ови пописани су били они које је пописао Мојсије са Ароном, уз помоћ дванаест кнезова, по један човек на сваки отачки дом. 45 Сви Израиљци, који су били уписани у своје отачке домове, од двадесет година па навише, били су способни за војску у Израиљу. 46 Свих пописаних било је шест стотина три хиљаде пет стотина педесет.

47 Ипак, међу њих се нису водили Левити према свом предачком племену. 48 Наиме, Господ је рекао Мојсију: 49 „Нека се Левијево племе не пописује, и нека се не пописују са осталим Израиљцима. 50 Него, постави Левите над Пребивалиштем сведочанства, и над свом опремом и свим што му припада. Они ће носити Пребивалиште са свом опремом, служити у њему, и логоровати око Пребивалишта. 51 Кад Пребивалиште крене, нека га Левити раставе, а кад се Пребивалиште заустави, нека га Левити подигну. Ако му се приближи туђинац, нека се погуби. 52 Остали Израиљци нека логорују сваки у своме табору, код своје заставе, и по својим четама. 53 Левити нека логорују око Пребивалишта сведочанства, да не би плануо гнев на израиљску заједницу. Зато нека чувају стражу код Пребивалишта сведочанства.“

54 Израиљци учине све онако како је Господ заповедио Мојсију. Баш тако су учинили.