Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 28

Àjíǹde rẹ̀

1 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, bí ilẹ̀ ti ń mọ́, Maria Magdalene àti Maria kejì lọ sí ibojì.

Wọ́n rí i pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹ̀ tí ó mú gbogbo ilẹ̀ mì tìtì. Nítorí angẹli Olúwa ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó ti yí òkúta ibojì kúrò. Ó sì jókòó lé e lórí. Ojú rẹ̀ tàn bí mọ̀nàmọ́ná. Aṣọ rẹ̀ sì jẹ́ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́, wọ́n sì wárìrì wọn sì dàbí òkú.

Nígbà náà ni angẹli náà wí fún àwọn obìnrin náà pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé ẹ̀yin ń wá Jesu tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Ṣùgbọ́n kò sí níhìn-ín. Nítorí pé ó ti jíǹde, gẹ́gẹ́ bí òun ti wí. Ẹ wọlé wá wo ibi ti wọ́n tẹ́ ẹ sí. Nísinsin yìí, Ẹ lọ kíákíá láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, ‘Ó ti jíǹde kúrò nínú òkú. Àti pé òun ń lọ sí Galili síwájú yín, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò gbé rí i,’ wò ó, o ti sọ fún yin.”

Àwọn obìnrin náà sáré kúrò ní ibojì pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ayọ̀ ńlá. Wọ́n sáré láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn nípa ìròyìn tí angẹli náà fi fún wọn. Bí wọ́n ti ń sáré lọ lójijì Jesu pàdé wọn. Ó wí pé, “Àlàáfíà” Wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọ́n gbá a ní ẹsẹ̀ mú. Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un. 10 Nígbà náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arákùnrin mi pé, ‘Kí wọ́n lọ tààrà sí Galili níbẹ̀ ni wọn yóò gbé rí mi.’ ”

Àwọn olùṣọ́ ròyìn

11 Bí àwọn obìnrin náà sì ti ń lọ sí ìlú, díẹ̀ nínú àwọn olùṣọ́ tí wọ́n ti ń ṣọ́ ibojì lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 12 Wọ́n sì pe ìpàdé àwọn àgbàgbà Júù. Wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn olùṣọ́. 13 Wọ́n wí pé, “Ẹ sọ fún àwọn ènìyàn pé, ‘Gbogbo yín sùn nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá lóru láti jí òkú rẹ̀.’ 14 Bí Pilatu bá sì mọ̀ nípa rẹ̀, àwa yóò ṣe àlàyé tí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn fún un, tí ọ̀rọ̀ náà kì yóò fi lè kó bá yín.” 15 Àwọn olùṣọ́ sì gba owó náà. Wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti darí wọn. Ìtàn yìí sì tàn ká kíákíá láàrín àwọn Júù. Wọ́n sì gba ìtàn náà gbọ́ títí di òní yìí.

Jesu pín iṣẹ́ ńlá fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

16 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ́kànlá náà lọ sí Galili ní orí òkè níbi tí Jesu sọ pé wọn yóò ti rí òun. 17 Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ṣe iyèméjì bóyá Jesu ni tàbí òun kọ́. 18 Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi. 19 Nítorí náà, Ẹ lọ, ẹ sọ wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ máa bamitiisi wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti Ẹ̀mí Mímọ́. 20 Ẹ kọ́ wọn láti máa kíyèsi ohun gbogbo èyí tí mo ti pàṣẹ fún yín. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín ní ìgbà gbogbo títí tí ó fi dé òpin ayé.”

New Living Translation

Matthew 28

The Resurrection

1Early on Sunday morning,[a] as the new day was dawning, Mary Magdalene and the other Mary went out to visit the tomb.

Suddenly there was a great earthquake! For an angel of the Lord came down from heaven, rolled aside the stone, and sat on it. His face shone like lightning, and his clothing was as white as snow. The guards shook with fear when they saw him, and they fell into a dead faint.

Then the angel spoke to the women. “Don’t be afraid!” he said. “I know you are looking for Jesus, who was crucified. He isn’t here! He is risen from the dead, just as he said would happen. Come, see where his body was lying. And now, go quickly and tell his disciples that he has risen from the dead, and he is going ahead of you to Galilee. You will see him there. Remember what I have told you.”

The women ran quickly from the tomb. They were very frightened but also filled with great joy, and they rushed to give the disciples the angel’s message. And as they went, Jesus met them and greeted them. And they ran to him, grasped his feet, and worshiped him. 10 Then Jesus said to them, “Don’t be afraid! Go tell my brothers to leave for Galilee, and they will see me there.”

The Report of the Guard

11 As the women were on their way, some of the guards went into the city and told the leading priests what had happened. 12 A meeting with the elders was called, and they decided to give the soldiers a large bribe. 13 They told the soldiers, “You must say, ‘Jesus’ disciples came during the night while we were sleeping, and they stole his body.’ 14 If the governor hears about it, we’ll stand up for you so you won’t get in trouble.” 15 So the guards accepted the bribe and said what they were told to say. Their story spread widely among the Jews, and they still tell it today.

The Great Commission

16 Then the eleven disciples left for Galilee, going to the mountain where Jesus had told them to go. 17 When they saw him, they worshiped him—but some of them doubted!

18 Jesus came and told his disciples, “I have been given all authority in heaven and on earth. 19 Therefore, go and make disciples of all the nations,[b] baptizing them in the name of the Father and the Son and the Holy Spirit. 20 Teach these new disciples to obey all the commands I have given you. And be sure of this: I am with you always, even to the end of the age.”

Notas al pie

  1. 28:1 Greek After the Sabbath, on the first day of the week.
  2. 28:19 Or all peoples.