Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 1

Àkọsílẹ̀ ìwé ìran Jesu Kristi

1Ìwé ìran Jesu Kristi, ẹni tí í ṣe ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu:

Abrahamu ni baba Isaaki;

Isaaki ni baba Jakọbu;

Jakọbu ni baba Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀,

Juda ni baba Peresi àti Sera,

Tamari sì ni ìyá rẹ̀,

Peresi ni baba Hesroni:

Hesroni ni baba Ramu;

Ramu ni baba Amminadabu;

Amminadabu ni baba Nahiṣoni;

Nahiṣoni ni baba Salmoni;

Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀;

Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀;

Obedi sì ni baba Jese;

Jese ni baba Dafidi ọba.

Dafidi ni baba Solomoni, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Uriah tẹ́lẹ̀ rí.

Solomoni ni baba Rehoboamu,

Rehoboamu ni baba Abijah,

Abijah ni baba Asa,

Asa ni baba Jehoṣafati;

Jehoṣafati ni baba Jehoramu;

Jehoramu ni baba Ussiah;

Ussiah ni baba Jotamu;

Jotamu ni baba Ahaṣi;

Ahaṣi ni baba Hesekiah;

10 Hesekiah ni baba Manase;

Manase ni baba Amoni;

Amoni ni baba Josiah;

11 Josiah sì ni baba Jekoniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Babeli.

12 Lẹ́yìn ìkólọ sí Babeli:

Jekoniah ni baba Ṣealitieli;

Ṣealitieli ni baba Serubbabeli;

13 Serubbabeli ni baba Abihudi;

Abihudi ni baba Eliakimu;

Eliakimu ni baba Asori;

14 Asori ni baba Sadoku;

Sadoku ni baba Akimu;

Akimu ni baba Elihudi;

15 Elihudi ni baba Eleasari;

Eleasari ni baba Mattani;

Mattani ni baba Jakọbu;

16 Jakọbu ni baba Josẹfu, ẹni tí ń ṣe ọkọ Maria, ìyá Jesu, ẹni tí í ṣe Kristi.

17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́ ìran mẹ́rìnlá láti orí Abrahamu dé orí Dafidi, ìran mẹ́rìnlá á láti orí Dafidi títí dé ìkólọ sí Babeli, àti ìran mẹ́rìnlá láti ìkólọ títí dé orí Kristi.

Ìtàn ibí Jesu Kristi

18 Bí a ṣe bí Jesu Kristi nìyìí: Ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrín Maria ìyá rẹ̀ àti Josẹfu, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́. 19 Nítorí Josẹfu ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòtítọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójútì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.

20 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, angẹli Olúwa yọ sí i ní ojú àlá, ó wí pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má fòyà láti fi Maria ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni. 21 Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

22 Gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì ṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ èyí tí a sọ láti ẹnu wòlíì rẹ̀ wá pé: 23 “Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli,” èyí tí ó túmọ̀ sí, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.”

24 Nígbà tí Josẹfu jí lójú oorun rẹ̀, òun ṣe gẹ́gẹ́ bí angẹli Olúwa ti pàṣẹ fún un. Ó mú Maria wá sílé rẹ̀ ní aya. 25 Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ ọ́n títí tí ó fi bí ọmọkùnrin, òun sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

马太福音 1

耶稣基督的家谱

1耶稣基督是亚伯拉罕的子孙、大卫的后裔,以下是祂的家谱:

亚伯拉罕生以撒,

以撒生雅各,

雅各生犹大和他的兄弟,

犹大和她玛生法勒斯和谢拉,

法勒斯生希斯仑[a]

希斯仑生兰,

兰生亚米拿达,

亚米拿达生拿顺,

拿顺生撒门,

撒门和喇合生波阿斯,

波阿斯和路得生俄备得,

俄备得生耶西,

耶西生大卫王。

大卫和乌利亚的妻子生所罗门,

所罗门生罗波安,

罗波安生亚比雅,

亚比雅生亚撒,

亚撒生约沙法,

约沙法生约兰,

约兰生乌西雅,

乌西雅生约坦,

约坦生亚哈斯,

亚哈斯生希西迦,

10 希西迦生玛拿西,

玛拿西生亚们,

亚们生约西亚,

11 约西亚生耶哥尼雅和他的兄弟,

那时以色列人被掳往巴比伦。

12 被掳到巴比伦以后,

耶哥尼雅生撒拉铁,

撒拉铁生所罗巴伯,

13 所罗巴伯生亚比玉,

亚比玉生以利亚敬,

以利亚敬生亚所,

14 亚所生撒督,

撒督生亚金,

亚金生以律,

15 以律生以利亚撒,

以利亚撒生马但,

马但生雅各,

16 雅各生约瑟。

约瑟就是玛丽亚的丈夫,

那被称为基督[b]的耶稣就是玛丽亚生的。

17 这样,从亚伯拉罕到大卫共有十四代,从大卫到被掳至巴比伦也是十四代,从被掳至巴比伦到基督降生也是十四代。

耶稣的降生

18 以下是耶稣基督降生的经过。

耶稣的母亲玛丽亚和约瑟订了婚,还没有成亲就从圣灵怀了孕。 19 约瑟是个义人,不愿公开地羞辱她,便决定暗中和她解除婚约。 20 他正在考虑这事的时候,主的一位天使在梦中向他显现,说:“大卫的后裔约瑟,不要怕,把玛丽亚娶过来,因为她所怀的孕是从圣灵来的。 21 她将生一个儿子,你要给祂取名叫耶稣[c],因为祂要把自己的子民从罪恶中救出来。”

22 这一切应验了主借着先知所说的话: 23 “必有童贞女怀孕生子,祂的名字要叫以马内利,意思是‘上帝与我们同在’。” 24 约瑟醒来,就遵从主的天使的吩咐和玛丽亚结婚, 25 只是在她生下孩子之前没有与她同房。约瑟给孩子取名叫耶稣。

Notas al pie

  1. 1:3 ”希腊文是“亚兰”。
  2. 1:16 基督”意思是“受膏者”。
  3. 1:21 耶稣”意思是“救主”。