Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Juda

Juda, ìránṣẹ́ Jesu Kristi àti arákùnrin Jakọbu,

Sí àwọn tí a pè, olùfẹ́ nínú Ọlọ́run Baba, tí a pamọ́ fún Jesu Kristi:

Kí àánú, àlàáfíà àti ìfẹ́ kí ó máa jẹ́ tiyín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

Ẹ̀ṣẹ̀ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi tòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmí ní ìtara láti kọ̀wé sí i yín nípa ìgbàlà tí í ṣe ti gbogbo ènìyàn, n kò gbọdọ̀ má kọ̀wé sí yín, kí ń sì gbà yín ní ìyànjú láti máa jà fitafita fún ìgbàgbọ́, tí a ti fi lé àwọn ènìyàn mímọ́ lọ́wọ́ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. Nítorí àwọn ènìyàn kan ń bẹ tí wọ́n ń yọ́ wọlé, àwọn ẹni tí a ti yàn láti ìgbà àtijọ́ sí ẹ̀bi yìí, àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, tí ń yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wa padà sí wọ̀bìà, tí wọn sì ń sẹ́ Olúwa wa kan ṣoṣo náà, àní, Jesu Kristi Olúwa.

Nítòótọ́, ẹ ti mọ nǹkan wọ̀nyí ní ẹ̀ẹ̀kan rí, mo fẹ́ rán an yín létí pé, lẹ́yìn tí Olúwa ti gba àwọn kan là láti ilẹ̀ Ejibiti wá, lẹ́yìn náà ni ó run àwọn tí kò gbàgbọ́. Àti àwọn angẹli tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìsàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá nì. Àní bí Sodomu àti Gomorra, àti àwọn ìlú agbègbè wọn, ti fi ara wọn fún àgbèrè ṣíṣe, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ará àjèjì lẹ́yìn, àwọn ni ó fi lélẹ̀ bí àpẹẹrẹ, àwọn tí ó ń jìyà iná àìnípẹ̀kun.

Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjòyè, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búburú sí àwọn ọlọ́lá. Ṣùgbọ́n Mikaeli, olórí àwọn angẹli, nígbà tí ó ń bá Èṣù jiyàn nítorí òkú Mose, kò sọ ọ̀rọ̀-òdì sí i; Ṣùgbọ́n ó wí pé, “Olúwa bá ọ wí.” 10 Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí n sọ̀rọ̀-òdì sí ohun gbogbo ti kò yé wọn: ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí wọn mọ̀ nípa èrò ara ni, bí ẹranko tí kò ní ìyè, nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n di ẹni ìparun.

11 Ègbé ni fún wọn! Nítorí tí wọ́n ti rìn ní ọ̀nà Kaini, wọ́n sì fi ìwọra súré sínú ìṣìnà Balaamu nítorí ère, wọn ṣègbé nínú ìṣọ̀tẹ̀ Kora.

12 Àwọn wọ̀nyí ní ó jẹ́ àbàwọ́n nínú àsè ìfẹ́ yín, nígbà tí wọ́n ń bá yín jẹ àsè, àwọn olùṣọ́-àgùntàn ti ń bọ́ ara wọn láìbẹ̀rù. Wọ́n jẹ́ ìkùùkuu láìrọ òjò, tí a ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ gbá kiri; àwọn igi aláìléso ní àkókò èso, wọ́n kú lẹ́ẹ̀méjì, a sì fà wọ́n tú tigbòǹgbò tigbòǹgbò. 13 Wọ́n jẹ́ ìjì líle ti ń ru ní ojú omi Òkun, ti ń hó ìfófó ìtìjú wọn jáde; alárìnkiri ìràwọ̀, àwọn tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè láéláé.

14 Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ni Enoku, ẹni keje láti ọ̀dọ̀ Adamu, sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn pé “Kíyèsi i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn rẹ̀ mímọ́, 15 láti ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn, láti dá gbogbo àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run lẹ́bi ní ti gbogbo iṣẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run wọn, ti wọ́n ti fi àìwà-bí-Ọlọ́run ṣe, àti ní ti gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìwà-bí-Ọlọ́run ti sọ sí i.” 16 Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní àwọn ti ń kùn, àwọn aláròyé, ti ń rìn nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn; wọn ń gbéraga nípa ara wọn, wọ́n sì ń ṣátá àwọn ènìyàn mìíràn fún èrè ara wọn.

Ìpè fún ìdúró ṣinṣin

17 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti sọ ṣáájú láti ọwọ́ àwọn aposteli Olúwa wa Jesu Kristi. 18 Bí wọn ti wí fún yín pé, “Nígbà ìkẹyìn àwọn ẹlẹ́gàn yóò wà, tí wọn yóò máa rìn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run ti ara wọn.” 19 Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn ẹni tí ń ya ara wọn sí ọ̀tọ̀, àwọn ẹni ti ara, tí wọn kò ni Ẹ̀mí.

20 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, olùfẹ́, ti ẹ ń gbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín tí ó mọ́ jùlọ, ti ẹ ń gbàdúrà nínú Ẹ̀mí Mímọ́. 21 Ẹ máa pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ̀yin ti ń retí àánú Olúwa wa Jesu Kristi tí yóò mú yín dé ìyè àìnípẹ̀kun.

22 Ẹ máa ṣàánú fún àwọn tí ń ṣe iyèméjì. 23 Ẹ máa gba àwọn ẹlòmíràn là, nípa fífà wọ́n yọ kúrò nínú iná; kí ẹ sì máa ṣàánú pẹ̀lú ìbẹ̀rù kí ẹ sì kórìíra ẹ̀wù tí ara ti sọ di èérí.

Orin ìyìn sí Ọlọ́run

24 Ǹjẹ́ mo fi yín lé ẹni tí o lè pa yín mọ́ kúrò nínú ìkọ̀sẹ̀, tí o sì lè mú yín wá síwájú ògo rẹ̀ láìlábùkù pẹ̀lú ayọ̀ ńlá lọ́wọ́— 25 tí Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n nìkan ṣoṣo, Olùgbàlà wa, ní ògo àti ọláńlá, ìjọba àti agbára, nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, kí gbogbo ayé tó wà, nísinsin yìí àti títí láéláé! Àmín.

Nkwa Asem

Yuda

Yesu Kristo somfo Yuda a ɔyɛ Yakobo ne nua na ɔkyerɛw krataa yi. De kɔmaa wɔn a Onyankopɔn afrɛ wɔn na wɔte Agya Onyankopɔn dɔ ne Yesu Kristo banbɔ mu.

Mmɔborɔhunu ne ɔdɔ a ɛdɔɔso nka mo.

Atoro adiyifo

Me nnamfonom, na merebɔ mmɔden akyerɛw mo afa nkwagye a yɛn nyinaa te mu no ho. Nanso ɛsɛ sɛ mekyerɛw mo wɔ asɛm foforo ho na moyere mo ho gyina nokware a Onyankopɔn de ama ne nkurɔfo afebɔɔ a ɛnsɛ sɛ wɔsesa mu nna nyinaa no akyi pintinn. Nnipa bi awiawia wɔn ho abɛfra yɛn mu, a wɔkyea asɛm a ɛfa yɛn Nyankopɔn adom no ho, yi wɔn ho ano wɔ wɔn bɔne ho, nam so po Yesu Kristo a ɔno nko ara na ɔyɛ Wura ne yɛn Awurade no. Kyerɛwsɛm no aka wɔn afobu a aba wɔn so no ho asɛm dedaw.

Ɛwom sɛ munim eyinom dedaw, nanso mepɛ sɛ mekae mo adwene wɔ ogye a Awurade gyee Israelfo fii Misraim asase so na akyiri yi, ɔsɛee wɔn a na wonnye asɛm no nni no ho. Monkae abɔfo a na wɔtra wɔn tumi na wogyaw wɔn atenae no. Woguu wɔn nkɔnsɔnkɔnsɔn wɔ sum kabii mu a Onyankopɔn de wɔn asie retwɛn da kɛse no na wabu wɔn atɛn. Monkae Sodom ne Gomora ne nkurow a na atwa wɔn ho ahyia no sɛ, na emu nnipa no yɛ aguamanfo, na wɔde wɔn agu ogya a ennum da no mu, de retwe wɔn aso de abɔ obiara kɔkɔ.

Saa nnipa no nam saa kwan koro no ara so soso dae ma wɔyɛ bɔne tia wɔn nipadua. Wɔtew Onyankopɔn tumi atua, na wɔayaw anuonyamfo a wɔwɔ soro no. Ɔbɔfo panyin Mikael mpo nyɛɛ saa da. Bere a Mikael ne ɔbonsam repere Mose amu so a akasakasa sii wɔn ntam no mpo, wantew ɔbonsam atua, na mmom asɛm a ɔkae ara ne sɛ, “Awurade nka w’anim.” 10 Nanso saa nnipa yi tew nneɛma a wɔnte ase ho atua. Na nneɛma a wonim kwa sɛ nkekaboa no, saa nneɛma koro no ara na ɛsɛe wɔn.

11 Wonnue! Ɔkwan a Kain faa so no ara so na wɔnam. Sikanibere nti, wɔde wɔn ho ahyɛ mfomso a Bileam yɛe no bi ase. Wɔayɛ dɔm sɛnea Kora yɛɛ dɔm no nam so ma wɔasɛe wɔn sɛ ɔno.

12 Wɔte sɛ nkekae fi a ɛwɔ wo nua aduan a ɔne wo di mu a wɔmfɛre ho. Wɔn ani ku wɔn ara wɔn ho. Na wɔte sɛ omununkum a esi na mframa bɔ no nanso osu ntɔ. Wɔte sɛ nnua a ɛnsow aba asusow mu. Wɔte sɛ nnua a wɔatutu ne ntini ama awu koraa.

13 Wɔte sɛ ɛpo asorɔkye a ano yɛ den a, wɔn aniwude a wɔyɛ no huru sɛ ahuru. Wɔte sɛ okyin nsoromma, a Onyankopɔn de wɔn asie esum kabii mu afebɔɔ.

14 Henok, Adam aseni a ɔto no so asia na ɔhyɛɛ saa nnipa yi ho nkɔm teteete se, “Hwɛ, Awurade ne n’abɔfo Kronkron mpempem bɛba, 15 na wɔabebu mo nyinaa atɛn na wɔabu nnebɔneyɛfo nyinaa atɛn wɔ wɔn bɔne a wɔayɛ ne nsɛm a wɔaka atia Onyankopɔn no ho.” 16 Bere biara, saa nnipa yi nwiinwii na wɔde so nso to afoforo so. Wodi wɔn akɔnnɔ akyi. Wɔhoahoa wɔn ho na wotu afoforo aso sɛnea ɛbɛyɛ a wɔbɛba abedi wɔn akyi.

Kɔkɔbɔ

17 Me nnamfonom, monkae. Monkae nsɛm a tete no asomafo no ka faa Awurade Yesu Krsito ho. 18 Wɔkae se, “Sɛ awiei no du a, nnipa a wodi mo ho fɛw bɛba, wɔn a wodi wɔn akɔnnɔ akyi.” 19 Eyinom ne nnipa a wɔnam wɔn akɔnnɔ so de mpaepaemu ba no. Na wonni Honhom no wɔ wɔn mu.

20 Enti mo a moyɛ me nnamfonom, mitu mo fo sɛ, monkɔ so mmia mo gyidi mu. Mommɔ mpae wɔ Honhom Kronkron no tumi mu, 21 na montena Onyankopɔn dɔ mu bere a moretwɛn yɛn Awurade Yesu Krsito wɔ n’ahummɔbɔ mu ama wama mo nkwa a enni awiei no.

22 Munhu akyinnyegyefo mmɔbɔ. 23 Montwe wɔn mfi ogya mu nnye wɔn nkwa. Momfa suro nhu ebinom mmɔbɔ, na munkyi atade a bɔne nkekae akeka mu.

24 Na nea obetumi aso mo mu na moanhintiw, na ɔde mo asi n’anuonyam anim sɛ nnipa a wonni dɛm wɔ ahosan mu no, 25 Onyankopɔn koro a ɔnam yɛn Awurade Yesu Kristo so yɛ yɛn Agyenkwa no, ɔno na anuonyam ne kɛseyɛ ne ahoɔden ne tumi nka no mmere a atwam ne nnɛ ne daa nyinaa. Amen.