Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 1

1Èyí ni ọ̀rọ̀ Jeremiah ọmọ Hilkiah ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà ní Anatoti ní agbègbè ilẹ̀ Benjamini. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá ní ọdún kẹtàlá ní àkókò ìjọba Josiah ọmọ Amoni ọba Juda, Àti títí dé àsìkò Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, títí dé oṣù karùn-ún ọdún kọkànlá Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, nígbà tí àwọn ará Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn.

Ìpè Jeremiah

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé,

Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́n,
    kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀.
    Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè.

Mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀.”

Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe sọ pé, ‘Ọmọdé lásán ni mí.’ O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.” Olúwa sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́.

Olúwa sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsin yìí mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ 10 Wò ó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, láti wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti máa kọ́, àti láti máa gbìn.

11 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ mí wá wí pé:

“Kí ni o rí Jeremiah?”

Mo sì dáhùn wí pé “Mo rí ẹ̀ka igi almondi.”

12 Olúwa sì wí fún mi pé, “Ó ti rí i bí ó ṣe yẹ, nítorí pé mo ti ń ṣọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúṣẹ.”

13 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ̀kejì pé, “Kí ni o rí?” Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá.

14 Olúwa, sì wí fún mi pé, “Láti apá àríwá ni a ó ti mu ìdààmú wá sórí gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà. 15 Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè àríwá níjà,” ni Olúwa wí.

Àwọn ọba wọn yóò wá
    gbé ìtẹ́ wọn ró ní ojú ọ̀nà àbáwọlé
Jerusalẹmu. Wọn ó sì dìde sí gbogbo
    àyíká wọn àti sí gbogbo àwọn
    ìlú Juda.
16 Èmi yóò sì kéde ìdájọ́ mi lórí àwọn ènìyàn mi
    nítorí ìwà búburú wọn nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀,
nípa rírúbọ sí ọlọ́run mìíràn
    àti sínsin àwọn ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe.

17 “Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pàṣẹ fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n dẹ́rùbà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn. 18 Ní òní èmi ti sọ ọ́ di ìlú alágbára, òpó irin àti odi idẹ sí àwọn ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. 19 Wọn yóò dojú ìjà kọ ọ́, wọn kì yóò borí rẹ, nítorí wí pé èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì gbà ọ́,” ni Olúwa wí.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

耶利米书 1

1希勒迦的儿子耶利米是便雅悯境内亚拿突城的一位祭司,以下是他的话。 犹大王亚们的儿子约西亚执政第十三年,耶和华的话传给了耶利米。 从犹大王约西亚的儿子约雅敬开始执政,一直到约西亚的另一个儿子西底迦做犹大王的第十一年五月,就是耶路撒冷的居民被掳之日,耶和华的话常常传给耶利米。

耶利米蒙召

耶和华对我说:
“我还没有使你在母腹中成形,就认识你;
你还未出生,我已使你圣洁,
立你做万国的先知。”

我回答说:“主耶和华啊,我太年轻,不懂得怎样说话。” 耶和华却说:

“不要说你太年轻,
我派你去谁那里,
你就去谁那里;
我吩咐你说什么,
你就说什么。
谁也不要怕,
因为我与你同在,
我必拯救你。
这是耶和华说的。”

然后,耶和华伸手摸我的口,对我说:“看啊,我已把我的话放在你口中。 10 今日,我派你到列邦列国去拔掉、拆除、毁灭、推翻、建造和栽植。”

两个异象

11 耶和华又对我说:“耶利米,你看见什么?”我说:“我看见一根杏树枝。” 12 耶和华说:“不错。我必实现我说过的话。”

13 耶和华又对我说:“你看见什么?”我回答说:“我看见一锅煮沸的水,从北方倾倒下来。” 14 耶和华说:“不错。因为有灾祸要从北方降临到这地方的一切居民。 15 我要召来北方各国,他们要在耶路撒冷的城门自立王位,攻打耶路撒冷周围的城墙和犹大各城邑。这是耶和华说的。 16 我要审判他们,因为他们犯罪作恶,背弃我,给别的神明烧香,又跪拜自己制造的神像。 17 现在,你要做好准备,去把我吩咐你的话告诉他们。不要惧怕他们,不然我将使你在他们面前充满恐惧。 18 看啊,今天我已使你成为坚城、铁柱、铜墙,来对抗整个犹大,对抗犹大的君王、首领、祭司和境内的众民。 19 他们必攻击你,但绝不能胜过你,因为我与你同在,我必拯救你。这是耶和华说的。”