Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Filemoni

Ìkíni

Èmi Paulu, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìhìnrere Jesu Kristi àti Timotiu arákùnrin wa.

Sí Filemoni ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábáṣiṣẹ́ wa, sí Affia arábìnrin wa, sí Arkippu ẹni tó jẹ́ jagunjagun fún àgbélébùú náà àti sí ìjọ àwọn Kristiani tí ó ń pàdé nínú ilé rẹ:

Oore-Ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi.

Ọpẹ́ àti Àdúrà

Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi, nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jesu Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́. Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ́ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọingbọin, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kristi wá. Ìfẹ́ rẹ ti fún mi ní ayọ̀ púpọ̀ àti ìgboyà, nítorí ìwọ, arákùnrin ti tu ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ lára.

Paulu bẹ̀bẹ̀ fún Onesimu

Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú Kristi mo ní ìgboyà púpọ̀ láti pàṣẹ ohun ti ó yẹ kí ó ṣe fún ọ, Síbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́. Èmi gẹ́gẹ́ bí Paulu, arúgbó, àti nísinsin yìí òǹdè Jesu Kristi. 10 Èmí bẹ̀ ọ́ nítorí ọmọ mi Onesimu, ẹni tí ó di ọmọ nígbà tí mo wà nínú ìdè. 11 Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá.

12 Èmi rán an nísinsin yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. 13 Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó ba à dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìhìnrere 14 ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá láìgba ìyọ̀ǹda ní ọwọ́ rẹ, kí oore tí ìwọ bá ṣe má ba à jẹ́ ìfipámúniṣe bí kò ṣe ìfìfẹ́ṣe. 15 Bóyá ìdí rẹ̀ tí òun fi yẹra kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀ ni pé kí ìwọ kí ó lè gbà á padà sọ́dọ̀ títí láé; 16 Kì í wá ṣe bí ẹrú mọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni ti ó sàn ju ẹrú lọ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. Ó ṣọ̀wọ́n fún mi jọjọ, ṣùgbọ́n ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù nípa ti ara àti gẹ́gẹ́ bí arákùnrin nínú Olúwa.

17 Nítorí náà bí ìwọ bá kà mí sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tẹ́wọ́ gbà á bí ìwọ yóò ti tẹ́wọ́ gbà mí. 18 Bí ó bá ti ṣe ọ́ ní ibi kan tàbí jẹ ọ́ ní gbèsè ohun kan, kà á sí mi lọ́rùn. 19 Èmi Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ìwé yìí; èmi yóò san án padà láì tilẹ̀ ní í sọ nípa pé ìwọ pàápàá jẹ mi ní gbèsè ara rẹ. 20 Èmi ń fẹ́, arákùnrin, pé kí èmi kí ó lè ni àǹfààní kan láti ọ̀dọ̀ rẹ nínú Olúwa; fi ayọ̀ rẹ kún ọkàn mi nínú Kristi. 21 Ìgbẹ́kẹ̀lé ti mo ní pé ìwọ yóò gbọ́rọ̀, ni mo fi kọ ìwé yìí ránṣẹ́ sí ọ. Mo mọ̀ dájú pé ìwọ yóò ṣe ju bí mo ti béèrè lọ.

22 Ó ku ohun kan: Ṣe ìtọ́jú iyàrá àlejò rẹ sílẹ̀ fún mi, nítorí mo ní ìgbàgbọ́ pé a óò tú mi sílẹ̀ fún yín ní ìdáhùn sí àdúrà yín.

23 Epafira, òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi nínú Kristi Jesu kí ọ. 24 Marku kí ọ pẹ̀lú Aristarku, Dema àti Luku, àwọn alábáṣiṣẹ́ mi.

25 Kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín.

Nkwa Asem

Filemon

Nkyia

Saa nhoma yi fi Paulo a esiane Kristo Yesu nti, ɔyɛ odeduani no ne yɛn nuabarima Timoteo nkyɛn. Yɛde kɔma yɛn adamfo ne yɛn yɔnko Filemon ne asafo a wohyia wɔ wo fi no ne yɛn nuabea Apia ne yɛn yɔnko sraani Arkipo no.

Adom ne asomdwoe a efi yɛn Agya Nyankopɔn ne Awurade Yesu Kristo nka mo.

Onua Filemon, bere biara a mebɔ mpae no, mebɔ bi ma wo na meda me Nyankopɔn nso ase. Mete dɔ a wodɔ Onyankopɔn nkurɔfo ne gyidi a wowɔ wɔ Awurade Yesu mu no. Me mpaebɔ ne sɛ, baako a yɛne wo ayɛ sɛ gyidifo no bɛma yɛn ntease a emu dɔ wɔ nhyira biara a yenya fi Kristo mu no mu. Onua pa, wo dɔ no ama me anigye na ahyɛ me nkuran nso. Woakanyan Onyankopɔn nkurɔfo.

Eyi nti, mitumi de akokoduru kasa kyerɛ wo sɛ wo nua wɔ Kristo mu, hyɛ wo ma woyɛ nea ɛsɛ sɛ woyɛ. Ɔdɔ so na menam de saa asɛm yi to w’anim. Ɛwom sɛ me Paulo a meyɛ Kristo Yesu nanmusini na mprempren, ne nti meyɛ odeduani no, na meyɛ nea mereyɛ yi. 10 Enti migyina Onesimo a ɔyɛ me ba wɔ Kristo mu ananmu bisa, efisɛ, bere a meda afiase no, na ɔyɛ me ba honhom mu. 11 Bere bi a atwam no na ne ho nni mfaso ma wo nanso mprempren de, ne ho wɔ mfaso ma me ne wo. 12 Merema no asan n’akyi aba wo nkyɛn mprempren ara. Me koma ka ba a ɔreba no ho.

13 Esiane Asɛmpa no nti, mepɛ sɛ ɔtena me nkyɛn bere a meda afiase yi sɛnea ɛbɛyɛ a obesi w’ananmu aboa me. 14 Nanso mempɛ sɛ mehyɛ wo sɛ boa me. Mmom, mepɛ sɛ wo ara wufi wo pɛ mu boa me. Ɛno nti, merenyɛ biribiara gye sɛ wopene so.

15 Ebia na Onesimo twee ne ho kakra na akyiri yi wabedi nna wo nkyɛn. 16 Mprempren ɔnyɛ ɔsomfo kɛkɛ efisɛ, ɔkyɛn ɔsomfo. Ɔyɛ onua pa wɔ Kristo mu. Ɔsom bo ma me. Saa ara nso na ɔbɛsom bo ama wo sɛ ɔsomfo ne onua wɔ Awurade mu.

17 Enti sɛ wudwen me ho sɛ wo fafafo a, saa ara nso na gye no awaawaatuu sɛnea wubegye me no ara. 18 Sɛ wayɛ wo biribi anaasɛ ɔde wo ka bi a, dan ma me. 19 Ɛha de, me ara mede me nsa bɛhyɛ ase sɛ: Me Paulo, metua wo ka. Ɛnsɛ sɛ mekae wo sɛ wo nkwa gyina me so. 20 Enti, me nua, mesrɛ wo sɛ, Awurade nti, yɛ me saa adɔe yi; ka me koma hyew sɛ wo nua wɔ Kristo mu.

21 Mewɔ anidaso sɛ, nea merekyerɛw wo yi, wobɛyɛ ama aboro nea merebisa wo yi so.

22 Afei pɛ ɔdan ma me efisɛ, minim sɛ Onyankopɔn betie mo mpaebɔ ama mabɛka mo ho bio.

23 Epafra a Kristo Yesu nti ɔne me da afiase no kyia wo.

24 Saa ara nso na Marko, Aristako, Dema ne Luka nso kyia wo.

25 Awurade Kristo adom nka mo nyinaa.