Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 42

Àwọn yàrá fún àwọn àlùfáà

1Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ìta gbangba ni ìhà àríwá ó sì mú mi wọ àwọn yàrá ni òdìkejì ìta gbangba ilé Ọlọ́run àti ni òdìkejì ògiri ìta ní apá ìhà àríwá. Ilé tí ìlẹ̀kùn rẹ̀ kọjú sí àríwá jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó sì jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú. Méjèèjì ní ogún ìgbọ̀nwọ́ ìpín láti inú ilé ìdájọ́ àti ni ìpín tí ó dojúkọ iwájú ìta ìdájọ́, ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè kọjú sì ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè ní ìdọ́gba mẹ́ta. Ní iwájú àwọn ọ̀nà, yàrá wà nínú tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní ìbú tí ó sì jẹ́ ọgọ́ọ̀rún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. Àwọn ìlẹ̀kùn wọn wà ní apá ìhà àríwá. Nísinsin yìí àwọn yàrá òkè ṣe tóóró, nítorí ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè dàbí ẹni pé ó ní ààyè láti ara wọn ju láti ara àwọn yàrá ti ó wà ní ìsàlẹ̀ tàbí àárín ilé. Àwọn yàrá tí ó wà ní àgbékà kẹta kò ni àwọn òpó gẹ́gẹ́ bí ilé ìdájọ́ ṣe ní; nítorí náà wọ́n kéré ní ààyè ju àwọn tí ó wà ní ìsàlẹ̀ àti àwọn àgbékà ti àárín. Ògiri kan wà ní ìta tí ó ṣe déédé pẹ̀lú àwọn yàrá àti ìta ilé ìdájọ́; a fà á gùn ní iwájú àwọn yàrá ní àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́. Nígbà tí ọ̀wọ́ yàrá ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kángun sí ìta ilé ìdájọ́ jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ọ̀wọ́ ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ tí ó súnmọ́ ibi mímọ́ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. Yàrá ìsàlẹ̀ ni ẹnu-ọ̀nà ní ìhà ìlà-oòrùn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ṣe wọ inú rẹ̀ láti ìta ilé ìdájọ́.

10 Ní ìhà gúúsù lọ sí ìbú ògiri ìta ilé ìdájọ́ tí o ṣe déédé pẹ̀lú àgbàlá ilé Ọlọ́run, ní òdìkejì ògiri ìta ni àwọn yàrá náà wà. 11 Àti ọ̀nà ni iwájú wọn rí gẹ́gẹ́ bí ti ìrí àwọn yàrá tí ó wà ní ọ̀nà àríwá bí wọ́n ti gùn mọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbòòrò mọ àti gbogbo ìjáde wọn sì dàbí ìṣe wọn àti bí ìlẹ̀kùn wọn 12 bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní yàrá tí òun ti ìlẹ̀kùn wọn ní ọ̀nà gúúsù, ìlẹ̀kùn kan wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ojú ọ̀nà tí ó ṣe déédé pẹ̀lú ògiri tí ó gùn dé ìhà ìlà-oòrùn tí ènìyàn ń gba wọ inú àwọn yàrá.

13 Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn yàrá àríwá àti àwọn yàrá gúúsù, tí ó wà níwájú ibi tí a yà sọ́tọ̀ àwọn ni yàrá mímọ́, níbi tí àwọn àlùfáà ti ń súnmọ́ Olúwa yó máa jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ; níbẹ̀ ní wọn o máa gbé ohun mímọ́ jùlọ kà, àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; nítorí ibẹ̀ jẹ́ mímọ́ 14 Níwọ̀n ìgbà tí àwọn àlùfáà bá ti wọ aṣọ funfun ibi mímọ́, wọn kò gbọdọ̀ lọ sí ìta ilé ìdájọ́ àfi tí wọ́n bá bọ àwọn aṣọ tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ ìsin sílẹ̀ ní ibi tí wọn tí lò ó, nítorí wọ́n jẹ́ mímọ́. Wọn gbọdọ̀ wọ aṣọ mìíràn kí wọn tó súnmọ́ ibi tí àwọn ènìyàn yòókù máa ń wà.”

15 Nígbà tí o parí nǹkan tí ó wà nínú ilé Ọlọ́run tán, o mú mi jáde lọ sí ọ̀nà tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn, ó sì wọn agbègbè náà yípo: 16 Ó wọn ìhà ìlà-oòrùn pẹ̀lú ọ̀pá-ìwọ̀n nǹkan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́. 17 Ó wọn ìhà àríwá; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá-ìwọ̀n nǹkan. 18 O wọn ìhà gúúsù; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá wíwọ̀n nǹkan. 19 Lẹ́yìn èyí ni ó wà yí padà sí ìhà ìwọ̀-oòrùn o sì wọ̀n-ọ́n: ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá wíwọ̀n. 20 Báyìí ní ó wọ̀n-ọ́n ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ó ní ògiri kan yípo rẹ̀, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, láti ya ibi mímọ́ sọ́tọ̀ kúrò ní ibi àìmọ́.

New Living Translation

Ezekiel 42

Rooms for the Priests

1Then the man led me out of the Temple courtyard by way of the north gateway. We entered the outer courtyard and came to a group of rooms against the north wall of the inner courtyard. This structure, whose entrance opened toward the north, was 175 feet[a] long and 87 1⁄2 feet[b] wide. One block of rooms overlooked the 35-foot[c] width of the inner courtyard. Another block of rooms looked out onto the pavement of the outer courtyard. The two blocks were built three levels high and stood across from each other. Between the two blocks of rooms ran a walkway 17 1⁄2 feet[d] wide. It extended the entire 175 feet of the complex,[e] and all the doors faced north. Each of the two upper levels of rooms was narrower than the one beneath it because the upper levels had to allow space for walkways in front of them. Since there were three levels and they did not have supporting columns as in the courtyards, each of the upper levels was set back from the level beneath it. There was an outer wall that separated the rooms from the outer courtyard; it was 87 1⁄2 feet long. This wall added length to the outer block of rooms, which extended for only 87 1⁄2 feet, while the inner block—the rooms toward the Temple—extended for 175 feet. There was an eastern entrance from the outer courtyard to these rooms.

10 On the south[f] side of the Temple there were two blocks of rooms just south of the inner courtyard between the Temple and the outer courtyard. These rooms were arranged just like the rooms on the north. 11 There was a walkway between the two blocks of rooms just like the complex on the north side of the Temple. This complex of rooms was the same length and width as the other one, and it had the same entrances and doors. The dimensions of each were identical. 12 So there was an entrance in the wall facing the doors of the inner block of rooms, and another on the east at the end of the interior walkway.

13 Then the man told me, “These rooms that overlook the Temple from the north and south are holy. Here the priests who offer sacrifices to the Lord will eat the most holy offerings. And because these rooms are holy, they will be used to store the sacred offerings—the grain offerings, sin offerings, and guilt offerings. 14 When the priests leave the sanctuary, they must not go directly to the outer courtyard. They must first take off the clothes they wore while ministering, because these clothes are holy. They must put on other clothes before entering the parts of the building complex open to the public.”

15 When the man had finished measuring the inside of the Temple area, he led me out through the east gateway to measure the entire perimeter. 16 He measured the east side with his measuring rod, and it was 875 feet long.[g] 17 Then he measured the north side, and it was also 875 feet. 18 The south side was also 875 feet, 19 and the west side was also 875 feet. 20 So the area was 875 feet on each side with a wall all around it to separate what was holy from what was common.

Notas al pie

  1. 42:2a Hebrew 100 cubits [53 meters]; also in 42:8.
  2. 42:2b Hebrew 50 cubits [26.5 meters]; also in 42:7, 8.
  3. 42:3 Hebrew 20[-cubit] [10.6-meter].
  4. 42:4a Hebrew 10 cubits [5.3 meters].
  5. 42:4b As in Greek and Syriac versions, which read Its length was 100 cubits [53 meters]; Hebrew reads and a passage 1 cubit [21 inches or 53 centimeters] wide.
  6. 42:10 As in Greek version; Hebrew reads east.
  7. 42:16 As in 45:2 and in Greek version at 42:17, which reads 500 cubits [265 meters]; Hebrew reads 500 rods [5,250 feet or 1,590 meters]; similarly in 42:17, 18, 19, 20.