Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 1

Ẹ̀dá alààyè àti ògo Olúwa

1Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹrin tí mo di ọmọ ọgbọ̀n ọdún tí mo wà láàrín àwọn ìgbèkùn ní etí odò Kebari, àwọn ọ̀run ṣí sílẹ̀, mo sì rí ìran Ọlọ́run.

Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù—tí ó jẹ́ ọdún karùn-ún ìgbèkùn ọba Jehoiakini— ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ àlùfáà Esekiẹli, ọmọ Busii wá, létí odò Kebari ni ilẹ̀ àwọn ará Babeli. Níbẹ̀ ni ọwọ́ Olúwa ti wà lára rẹ̀.

Mo wò, mo sì rí ìjì tó ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá ìkùùkuu tó nípọn pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná ti n bù yẹ̀rì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rokoṣo tó yí i ká. Àárín iná náà rí bí ìgbà tí irin bá ń bẹ nínú iná, àti láàrín iná náà ni ohun tó dàbí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin wà: Ìrísí wọn jẹ́ ti ènìyàn, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin. Ẹsẹ̀ wọn sì tọ́; àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì rí bí ti ọmọ màlúù, wọ́n sì tàn bí awọ idẹ dídán. Ní abẹ́ ìyẹ́ wọn ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọn ní ọwọ́ ènìyàn. Gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú àti àwọn ìyẹ́, ìyẹ́ wọn kan ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò padà lọ́nà ibi tí ó ń lọ; ṣùgbọ́n wọ́n ń lọ tààrà ni.

10 Báyìí ni ìrísí ojú àwọn ẹ̀dá alààyè yìí: ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú ènìyàn, ní apá ọ̀tún wọn, wọ́n ní ojú kìnnìún ní ìhà ọ̀tún, wọ́n ní ojú màlúù ní ìhà òsì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n sì tún ní ojú ẹyẹ idì. 11 Báyìí ni àpèjúwe ojú wọ́n. Ìyẹ́ wọn gbé sókè; ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ méjì, ìyẹ́ ọ̀kan sì kan ti èkejì ni ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ìyẹ́ méjì tó sì tún bo ara wọn. 12 Olúkúlùkù wọn ń lọ tààrà. Níbikíbi tí èmi bá ń lọ, ni àwọn náà ń lọ, láì wẹ̀yìn bí wọ́n ti ń lọ. 13 Ìrísí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí dàbí ẹyin iná tí ń jó tàbí bí i iná fìtílà. Iná tó ń jó ń lọ sókè lọ sódò láàrín àwọn ẹ̀dá alààyè; iná yìí mọ́lẹ̀ rokoṣo, ó sì ń bù yẹ̀rì yẹ̀rì jáde lára rẹ̀. 14 Àwọn ẹ̀dá alààyè yìí sì ń sáré lọ sókè lọ sódò bí i ìtànṣán àrá.

15 Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè yìí, mo rí kẹ̀kẹ́ ní ilẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí pẹ̀lú ojú rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. 16 Àpèjúwe àti ìrísí àwọn kẹ̀kẹ́ náà nìyìí: kẹ̀kẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rí bákan náà, wọ́n sì ń tàn yinrin yinrin bí i kirisoleti, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kẹ̀kẹ́ yìí rí bí i ìgbà tí a fi kẹ̀kẹ́ bọ kẹ̀kẹ́ nínú. 17 Àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń yí bí wọ́n ti ń yí, wọ́n ń lọ tààrà sí ibi tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè kọjú sí, kẹ̀kẹ́ wọn kò sì yapa bí àwọn ẹ̀dá náà ti n lọ. 18 Àwọn ríìmù wọ́n ga, wọ́n sì ba ni lẹ́rù, àwọn ríìmù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì jẹ́ kìkìdá ojú yíká.

19 Bí àwọn ẹ̀dá bá ń rìn, kẹ̀kẹ́ ẹ̀gbẹ́ wọn náà yóò rìn, bí wọ́n fò sókè, kẹ̀kẹ́ náà yóò fò sókè. 20 Ibikíbi tí ẹ̀mí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ wọn yóò sì bá wọn lọ, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú kẹ̀kẹ́ wọn. 21 Bí àwọn ẹ̀dá yìí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ náà yóò lọ; bí wọ́n bá dúró jẹ́ẹ́ kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni bí àwọn ẹ̀dá yìí bá dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí yóò dìde pẹ̀lú wọn, nítorí pé ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí wà nínú àwọn kẹ̀kẹ́.

22 Ohun tí ó dàbí òfúrufú ràn bo orí àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí, ó ń tàn yinrin yinrin bí i yìnyín, ó sì ba ni lẹ́rù. 23 Ìyẹ́ wọn sì tọ́ lábẹ́ òfúrufú, èkínní sí èkejì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ìyẹ́ méjì méjì tí ó bo ara wọn. 24 Nígbà tí àwọn ẹ̀dá náà gbéra, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn tó bolẹ̀ bí i ríru omi, bí i ohùn Olódùmarè, bí i híhó àwọn jagunjagun. Nígbà tí wọ́n dúró jẹ́ẹ́, wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀.

25 Bí wọ́n ṣe dúró tí wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀, ohùn kan jáde láti inú òfúrufú tó rán bò wọ́n. 26 Lókè àwọ̀ òfúrufú tó borí wọn yìí ni ohun tí ó ní ìrísí ìtẹ́. Ìtẹ́ náà dàbí òkúta safire, lókè ní orí ìtẹ́ ní ohun tó dàbí ènìyàn wà. 27 Láti ibi ìbàdí ènìyàn náà dé òkè, o dàbí irin tí ń kọ yànrànyànràn. O dàbí pe kìkì iná ni, láti ibi ìbàdí rẹ dé ìsàlẹ̀ dàbí iná tó mọ́lẹ̀ yí i ká. 28 Ìmọ́lẹ̀ tó yí i ká yìí dàbí ìrísí òṣùmàrè tó yọ nínú àwọsánmọ̀ ní ọjọ́ òjò, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ tò yí i ká.

Báyìí ni ìrísí ògo Olúwa. Nígbà tí mo rí i, mo dojúbolẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn ẹnìkan tó ń sọ̀rọ̀.

New American Standard Bible

Ezekiel 1

The Vision of Four Figures

1Now it came about in the thirtieth year, on the fifth day of the fourth month, while I was by the river Chebar among the exiles, the heavens were opened and I saw [a]visions of God. (On the fifth of the month [b]in the fifth year of King Jehoiachin’s exile, the word of the Lord came expressly to Ezekiel the priest, son of Buzi, in the land of the Chaldeans by the river Chebar; and there the hand of the Lord came upon him.)

As I looked, behold, a storm wind was coming from the north, a great cloud with fire flashing forth continually and a bright light around it, and in its midst something like glowing metal in the midst of the fire. Within it there were figures resembling four living beings. And this was their appearance: they had human form. Each of them had four faces and four wings. Their legs were straight and [c]their feet were like a calf’s hoof, and they gleamed like burnished bronze. Under their wings on their four sides were human hands. As for the faces and wings of the four of them, their wings touched one another; their faces did not turn when they moved, each went straight forward. 10 As for the form of their faces, each had the face of a man; [d]all four had the face of a lion on the right and the face of a bull on the left, and [e]all four had the face of an eagle. 11 Such were their faces. Their wings were spread out above; each had two touching another being, and two covering their bodies. 12 And each went straight forward; wherever the spirit was about to go, they would go, without turning as they went. 13 [f]In the midst of the living beings there was something that looked like burning coals of fire, [g]like torches darting back and forth among the living beings. The fire was bright, and lightning was [h]flashing from the fire. 14 And the living beings ran to and fro like bolts of lightning.

15 Now as I looked at the living beings, behold, there was one wheel on the earth beside the living beings, [i]for each of the four of them. 16 The appearance of the wheels and their workmanship was like [j]sparkling beryl, and all four of them had the same form, their appearance and workmanship being as if [k]one wheel were within another. 17 Whenever they [l]moved, they [m]moved in any of their four [n]directions without turning as they [o]moved. 18 As for their rims they were lofty and awesome, and the rims of all four of them were full of eyes round about. 19 Whenever the living beings [p]moved, the wheels [q]moved with them. And whenever the living beings rose from the earth, the wheels rose also. 20 Wherever the spirit was about to go, they would go in that direction[r]. And the wheels rose close beside them; for the spirit of the living [s]beings was in the wheels. 21 Whenever those went, these went; and whenever those stood still, these stood still. And whenever those rose from the earth, the wheels rose close beside them; for the spirit of the living [t]beings was in the wheels.

Vision of Divine Glory

22 Now over the heads of the living [u]beings there was something like an expanse, like the awesome gleam of [v]crystal, spread out over their heads. 23 Under the expanse their wings were stretched out straight, one toward the other; each one also had two wings covering its body on the one side and on the other. 24 I also heard the sound of their wings like the sound of abundant waters as they went, like the voice of [w]the Almighty, a sound of tumult like the sound of an army camp; whenever they stood still, they dropped their wings. 25 And there came a voice from above the expanse that was over their heads; whenever they stood still, they dropped their wings.

26 Now above the expanse that was over their heads there was something resembling a throne, like [x]lapis lazuli in appearance; and on that which resembled a throne, high up, was a figure with the appearance of a man. 27 Then I [y]noticed from the appearance of His loins and upward something like [z]glowing metal that looked like fire all around within it, and from the appearance of His loins and downward I saw something like fire; and there was a radiance around Him. 28 As the appearance of the rainbow [aa]in the clouds on a rainy day, so was the appearance of the surrounding radiance. Such was the appearance of the likeness of the glory of the Lord. And when I saw it, I fell on my face and heard a voice speaking.

Notas al pie

 1. Ezekiel 1:1 Some ancient mss and versions read a vision
 2. Ezekiel 1:2 Lit it was
 3. Ezekiel 1:7 Lit the soles of their feet
 4. Ezekiel 1:10 Lit the four of them
 5. Ezekiel 1:10 Lit the four of them
 6. Ezekiel 1:13 So with some ancient versions; Heb as the likeness of the living beings
 7. Ezekiel 1:13 Lit like the appearance of
 8. Ezekiel 1:13 Lit coming out
 9. Ezekiel 1:15 Lit for his four faces
 10. Ezekiel 1:16 Lit the look of beryl
 11. Ezekiel 1:16 Lit the wheel in the midst of the wheel
 12. Ezekiel 1:17 Lit went
 13. Ezekiel 1:17 Lit went
 14. Ezekiel 1:17 Lit sides
 15. Ezekiel 1:17 Lit went
 16. Ezekiel 1:19 Lit went
 17. Ezekiel 1:19 Lit went
 18. Ezekiel 1:20 M.T. adds the spirit to go
 19. Ezekiel 1:20 M.T. reads being
 20. Ezekiel 1:21 M.T. reads being
 21. Ezekiel 1:22 So some ancient mss and versions; M.T. reads being
 22. Ezekiel 1:22 Or ice
 23. Ezekiel 1:24 Heb Shaddai
 24. Ezekiel 1:26 Heb eben-sappir
 25. Ezekiel 1:27 Lit saw
 26. Ezekiel 1:27 Or electrum
 27. Ezekiel 1:28 Lit which occurs in