Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 1

Àṣẹ láti jáde kúrò ní Horebu

1Wọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Mose sọ fún gbogbo Israẹli ní aginjù, aginjù ìlà-oòrùn Jordani, ni Arabah: ní òdìkejì Ṣufi, ní àárín Parani àti Tofeli, Labani, Haserotu àti Disahabu. (Ọjọ́ mọ́kànlá ni ó gbà láti rin ìrìnàjò láti Horebu dé Kadeṣi-Barnea, bí a bá gba ọ̀nà òkè Seiri.)

Ní ìgbà tí ó pé ogójì ọdún, ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kọ́kànlá, Mose sọ ohun gbogbo tí Ọlọ́run pàṣẹ nípa àwọn ọmọ Israẹli fún wọn. Èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣẹ́gun Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni, àti Ogu ọba Baṣani ni ó ṣẹ́gun ní Edrei, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu.

Ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani tí ó wà nínú ilẹ̀ Moabu ni Mose bẹ̀rẹ̀ sísọ àsọyé òfin wọ̀nyí wí pé:

Olúwa Ọlọ́run wa bá wa sọ̀rọ̀ ní Horebu pé, “Ẹ ti dúró ní orí òkè yìí pẹ́ tó. Ẹ yípadà kí ẹ sì tẹ̀síwájú ní ìrìnàjò yín lọ sí ilẹ̀ òkè àwọn ará Amori: Ẹ tọ gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń gbé Arabah lọ ní aginjù, ní àwọn orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní gúúsù àti ní etí Òkun, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani àti lọ sí Lebanoni, títí fi dé odò ńlá Eufurate. Wò ó, èmi tí fi ilẹ̀ yí fún un yín: Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí Olúwa ti búra wí pé òun yóò fún àwọn baba yín: fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu, àti fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn.”

Yíyan àwọn olórí

Mo wí fún un yín nígbà náà pé, “Èmi nìkan kò lè dá ẹrù u yín gbé. 10 Olúwa Ọlọ́run yín ti sọ yín di púpọ̀ lónìí, ẹ̀yin sì ti pọ̀ bí ìràwọ̀ ní ojú ọ̀run. 11 Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín sọ yín di púpọ̀ ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún sí i, kí ó sì bùkún un yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí. 12 Báwo ni èmi nìkan ṣe lè máa ru àjàgà àti ìṣòro yín àti èdè-àìyedè yín? 13 Ẹ yan àwọn ọlọ́gbọ́n, olóye àti àwọn ẹni àpọ́nlé, láti inú ẹ̀yà yín kọ̀ọ̀kan, èmi yóò sì fi wọ́n ṣe olórí yín.”

14 Ẹ̀yin sì dá mi lóhùn wí pé, “Ohun tí ìwọ ti gbèrò láti ṣe nì dára.”

15 Bẹ́ẹ̀ ni mo yan olórí àwọn ẹ̀yà yín, àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin, ẹni àpọ́nlé, mo sì fi jẹ olórí yín: olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀yà yín. 16 Mo sì kìlọ̀ fún àwọn onídàájọ́ yín nígbà náà pé: Ẹ gbọ́ èdè-àìyedè tí ó wà láàrín àwọn ènìyàn an yín kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ òdodo, bóyá ẹjọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ láàrín Israẹli sí Israẹli ni tàbí láàrín Israẹli kan sí àlejò. 17 Ẹ má sì ṣe ojúsàájú ní ìdájọ́: Ẹ ṣe ìdájọ́ ẹni ńlá àti kékeré bákan náà. Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹnikẹ́ni torí pé ti Ọlọ́run ni ìdájọ́. Ẹjọ́ tí ó bá le jù fún un yín ni kí ẹ mú wá fún mi. Èmi yóò sì gbọ́ ọ. 18 Nígbà náà ni èmi yóò sọ ohun tí ẹ ó ṣe fún un yín.

A rán àwọn Ayọ́lẹ̀wò jáde

19 Nígbà náà ní a gbéra láti Horebu, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún wá, a sì la àwọn ilẹ̀ lókè Amori kọjá lọ dé gbogbo aginjù ńlá tí ó ba ni lẹ́rù nì tí ẹ̀yin ti rí, bẹ́ẹ̀ ni a sì dé Kadeṣi-Barnea. 20 Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ ti dé ilẹ̀ òkè àwọn ará Amori, èyí tí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa. 21 Ẹ kíyèsi i, Olúwa Ọlọ́run yín ló ni ilẹ̀ náà. Ẹ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín tí sọ fún un yín. Ẹ má bẹ̀rù, Ẹ má sì ṣe fòyà.”

22 Nígbà náà ni gbogbo yín tọ̀ mí wá wí pé, “Jẹ́ kí a yan àwọn ayọ́lẹ̀wò láti yọ́ ilẹ̀ náà wò fún wa, kí wọn sì fún wa ní ìròyìn àwọn ọ̀nà tí a ó gbà àti àwọn ìlú tí a ó bá pàdé.”

23 Èrò náà sì dára lójú mi, torí èyí ni mo ṣe yan àwọn ènìyàn méjìlá nínú yín, ẹnìkan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. 24 Wọ́n sì gòkè lọ sí ilẹ̀ òkè náà, wọ́n sì wá sí Àfonífojì Eṣkolu, wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò. 25 Wọ́n sì mú lára èso ilẹ̀ náà wá fún wa pé, “Ilẹ̀ tí ó dára ni Olúwa Ọlọ́run wa fún wa.”

Ìṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa

26 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́ gòkè lọ; ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run yín. 27 Ẹ kùn nínú àgọ́ ọ yín, ẹ sì wí pé, “Olúwa kórìíra wa, torí èyí ló fi mú wa jáde láti Ejibiti láti fi wá lé àwọn ará Amori lọ́wọ́ láti pa wá run. 28 Níbo la ó lọ? Àwọn arákùnrin wa ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa nípa sísọ pé, ‘Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga jù wá lọ; àwọn ìlú náà tóbi jọjọ bẹ́ẹ̀ ni odi wọn ga kan ọ̀run. A tilẹ̀ rí àwọn òmíràn (ìran Anaki) níbẹ̀.’ ”

29 Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ má ṣojo, ẹ kò sì gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn. 30 Olúwa Ọlọ́run yín, tí ń ṣáájú yín yóò jà fún un yín; bí ó ti ṣe fún un yín ní Ejibiti lójú ẹ̀yin tìkára yín 31 àti ní aginjù. Níbẹ̀ ni ẹ ti rí i bí Olúwa Ọlọ́run yín ti gbé yín, bí baba ti í gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ lọ títí ẹ fi padà dé ibí yìí.”

32 Pẹ̀lú gbogbo èyí tí mo wí, ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run yín, 33 tí ń ṣáájú u yín lọ ní gbogbo ọ̀nà yín, nípa fífi iná ṣe amọ̀nà yín ní òru àti ìkùùkuu ní ọ̀sán, láti fi àwọn ibi tí ẹ lè tẹ̀dó sí hàn yín àti àwọn ọ̀nà tí ẹ ó rìn.

34 Nígbà tí Olúwa gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra wí pé: 35 “Kò sí ọ̀kan nínú ìran búburú yìí tí yóò dé ilẹ̀ rere tí mo ti búra láti fún àwọn baba ńlá a yín. 36 Bí kò ṣe Kalebu ọmọ Jefunne. Òun ni yóò wọ̀ ọ́. Èmi yóò sì fún òun àti àwọn ìran rẹ̀ ní ilẹ̀ náà tí ó ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ̀; torí pé ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀lé Olúwa.”

37 Torí i tiyín ni Olúwa fi bínú sí mi wí pé, “Ìwọ náà kì yóò wọ ibẹ̀ bákan náà, 38 ṣùgbọ́n Joṣua ọmọ Nuni tí ń ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ ni yóò wọ ibẹ̀. Mú un, ní ọkàn le torí pé, òun yóò ṣáájú àwọn ọmọ Israẹli láti gba ilẹ̀ náà. 39 Àwọn èwe yín tí ẹ sọ pé wọn yóò kó lẹ́rú. Àwọn ọmọ yín tí ko tí ì mọ rere yàtọ̀ sí búburú ni yóò wọ ilẹ̀ náà. 40 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, ẹ yí padà sí aginjù tí ó wà ní ọ̀nà tí ó lọ sí Òkun pupa.”

41 Nígbà náà ni ẹ fèsì wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí Olúwa. A ó sì gòkè lọ láti jà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún wa.” Torí náà gbogbo yín ẹ mú ohun ìjà a yín, ẹ rò pé ó rọrùn láti gòkè lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè olókè náà.

42 Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún mi pé, “Sọ fún wọn, ‘Ẹ má ṣe gòkè lọ láti jà torí pé èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín. Àwọn ọ̀tá a yín yóò sì ṣẹ́gun yín.’ ”

43 Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbọ́, ẹ̀yin ṣọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa, pẹ̀lú ìgbéraga yín, ẹ gòkè lọ sí ìlú olókè náà. 44 Àwọn ará Amori tí ń gbé ní àwọn òkè náà, dojúkọ yín bí àgbájọpọ̀ oyin. Wọ́n sì lù yín bolẹ̀ láti Seiri títí dé Horma. 45 Ẹ padà, ẹ sì sọkún níwájú Olúwa, òun kò sì fetí sí igbe ẹkún yín, Ó sì kọ etí dídi sí i yín. 46 Báyìí ni ẹ sì dúró ní Kadeṣi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ṣe.

Bibelen på hverdagsdansk

5 Mosebog 1

Indledning

1I denne bog er de ord nedskrevet, som Moses talte til Israels folk, mens de opholdt sig på Moabs ubeboede sletter øst for Jordanfloden, omkranset af byerne Suf, Paran, Tofel, Laban, Hatzerot og Di-Zahab. Stedet ligger 11 dagsrejser fra Horebs bjerg[a] via Kadesh-Barnea og Seirs bjerge, og det var nu 40 år siden, israelitterne rejste fra Egypten. På den første dag i den 11. måned i det 40. år holdt Moses følgende tale. Det var efter, at han havde overvundet amoritterkongen Sihon fra Heshbon og i Edrei havde slået kong Og af Bashan fra Ashtarot. I talen nævnes de love, som Herren havde befalet ham at give videre til Israels folk.

Tilbageblik på vandringen fra Sinai til det lovede land

„Herren, vores Gud, talte til os ved Horebs bjerg,” begyndte Moses. „Dengang sagde han til os: ‚Nu er det på tide, at I forlader dette bjerg og går ind og erobrer amoritternes bjergland og nabofolkenes landområder i Arabadalen[b], i Negev ørkenen, i kana’anæernes højland, bakkeskråningerne mod vest og kystområderne, ja helt op til Eufratfloden mod nord, inklusive Libanons land. Gå ind og tag hele det land i besiddelse, som jeg lovede jeres forfædre, Abraham, Isak og Jakob.’

Dengang sagde jeg til Israels folk: ‚Jeg kan ikke bære så stort et ansvar alene. 10 Herren har gjort jer til et stort folk, så talrige som stjernerne på himlen. 11 Må Herren, jeres fædres Gud, gøre jer 1000 gange så talrige, som I er nu, og velsigne jer, sådan som han har lovet. 12 Men det er en uoverkommelig opgave for mig at være alene om at afgøre jeres retssager og stridsspørgsmål. 13 Derfor skal hver enkelt stamme udvælge nogle vise, erfarne og forstandige mænd, som jeg kan indsætte som jeres ledere.’

14 Det forslag accepterede de, 15 hvorefter jeg indsatte de mænd, der blev valgt, som dommere og administrative ledere, nogle med ansvar for 1000, andre med ansvar for 100, for 50 eller for 10. 16 Jeg indprentede dem, at alle skulle være lige for loven, også de fremmede, og at de skulle lade begge parter komme til orde og derefter dømme retfærdigt. 17 ‚Når I afsiger dom,’ forklarede jeg dem, ‚skal alle behandles ens, hvad enten de er rige eller fattige. Sørg for at yde alle samme retfærdighed. I må ikke frygte for nogen, for I dømmer på Guds vegne, og hvis en sag er for vanskelig til, at I kan træffe en afgørelse, skal I komme til mig med den, så jeg kan overtage den.’ 18 Ved den lejlighed gav jeg også folket instrukser vedrørende mange andre ting.

19 På Herrens befaling forlod vi så Horeb og rejste gennem den store og forfærdelige ørken, som I selv har oplevet eller hørt om, indtil vi nåede til Kadesh-Barnea på grænsen til amoritternes land. 20 Da sagde jeg til folket: ‚Nu er vi kommet til det land, som Herren, vores Gud, vil give os, 21 og han vil hjælpe os med at erobre det. Vær derfor ikke bange, men vær ved godt mod og gør, som han har befalet jer at gøre.’

22 De svarede: ‚Lad os først sende nogle spioner ind i landet, så vi kan se, hvilken rute der er den bedste, og hvilke byer vi først skal indtage.’

23 Jeg gik ind på forslaget og udvalgte 12 spioner, en fra hver stamme. 24 De drog ind i bjerglandet og nåede til Eshkoldalen, som de undersøgte grundigt. 25 Derfra vendte de tilbage med noget af landets frugt. De var enige om, at det var et godt og frugtbart land, som Herren, vores Gud, ville give os. 26 Men folket turde alligevel ikke gå ind i landet og satte sig dermed op imod Herrens befaling.

27 I stedet begyndte de at beklage sig i deres telte. ‚Herren hader os,’ klagede de. ‚Han har ført os den lange vej fra Egypten, men kun for at udlevere os til amoritterne, så de kan slå os ihjel. 28 Hvad er det dog, vi har indladt os på?’ Spionerne tog modet fra folket ved at berette om landets indfødte, der var langt højere og stærkere end os, og om deres befæstede byer, hvis mure nåede til himlen! De fortalte tilmed, at de havde set anakitiske[c] kæmper i landet.

29 Men jeg opfordrede dem til ikke at være bange. 30 ‚Det er Herren, jeres Gud, som er jeres leder,’ sagde jeg. ‚Han vil gå foran jer og gøre store undere for øjnene af jer, nøjagtig som han gjorde i Egypten. 31 Har I allerede glemt, hvordan han bar jer på sine arme hele vejen gennem ørkenen som en far, der bærer sin søn?’

32 Men folket ville stadig ikke adlyde. De nægtede at tro på Herren, deres Gud, 33 som førte dem fra sted til sted ved hjælp af en sky om dagen og en ildsky om natten og viste dem de bedste steder at slå lejr i ørkenen.

34 Da blev Herren vred over deres beklagelser. Han svor, 35 at ikke en eneste af hele den ulydige og vantro generation skulle få lov at opleve det gode land, han havde lovet deres forfædre, 36 undtagen Kaleb, der som belønning for sin tro og lydighed fik lovning på den jord, han som en af de 12 spioner havde betrådt.

37 Selv mig blev Herren vred på, og det var folkets skyld. Herren sagde til mig: ‚Heller ikke du får lov at komme ind i landet, 38 men din medhjælper Josva skal i dit sted føre folket ind. Derfor skal du styrke og opmuntre ham til at overtage din plads. 39 Jeg vil senere give landet til de børn, som man påstod ville blive taget til fange og gjort til slaver, 40 men I skal nu vende om og gå tilbage gennem ørkenen mod Det Røde Hav.’

41 Så kom de straks på andre tanker: ‚Vi har syndet imod Herren!’ sagde de. ‚Men nu vil vi gerne gå ind i landet og kæmpe, sådan som Herren, vores Gud, har sagt.’ Derpå greb de til våben i den tro, at de med lethed kunne erobre hele området.

42 Men Herren sagde til mig: ‚Sig til dem, at de skal lade være, for jeg har ikke i sinde at hjælpe dem, og de vil blive hugget ned af deres fjender.’

43 Jeg fortalte dem, hvad Herren havde sagt, men de ville stadig ikke høre efter. De trodsede Herrens ord og rykkede ind i bjerglandet. 44 Amoritterne gik til modangreb og jagtede dem som bier, så der lå faldne hele vejen fra Seir til Horma. 45 De, der vendte hjem, græd for Herrens ansigt, men nu var det Herren, der ikke ville lytte til dem. 46 Derfor var de tvunget til at blive i Kadesh i længere tid.

Notas al pie

  1. 1,2 I 5. Mosebog og til dels i 2. Mosebog omtales Guds bjerg i Sinaiørkenen som Horebs bjerg i stedet for Sinaibjerget.
  2. 1,7 Araba er navnet på den del af Rift Valley, som går fra Eilat ved Det Røde Hav til Libanons bjerge. Gennem denne dalsænkning flyder Jordanfloden og her ligger Galilæasøen og Det Døde Hav.
  3. 1,28 Anakitterne var en slægt af kæmper, der nedstammede fra Anak, jf. 4.Mos. 13,22.