Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

3 Johanu

Alàgbà,

Sì Gaiusi, olùfẹ́, ẹni tí mo fẹ́ nínú òtítọ́.

Olùfẹ́, èmi ń gbàdúrà pé nínú ohun gbogbo kí o lè máa dára fún ọ, kí o sì máa wà ni ìlera, àní bí o tí dára fún ọkàn rẹ. Nítorí mo yọ̀ gidigidi, nígbà tí àwọn arákùnrin dé tí wọn sì jẹ́rìí sí ìwà òtítọ́ inú rẹ̀, àní bí ìwọ tí ń rìn nínú òtítọ́. Èmi ni ayọ̀ tí ó tayọ, láti máa gbọ́ pé, àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.

Olùfẹ́, ìwọ ń ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún àwọn tí ń ṣe ará, àti pàápàá fún àwọn tí ń ṣe àlejò. Tí wọn ń jẹ́rìí sí ìfẹ́ rẹ̀ níwájú ìjọ: bí ìwọ bá ń pèsè fún wọn ní ọ̀nà àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó tí yẹ nínú Ọlọ́run. Nítorí pé, nítorí iṣẹ́ Kristi ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgba ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn aláìkọlà. Nítorí náà, ó yẹ kí àwa fi inú rere gba irú àwọn wọ̀nyí, kí àwa lè jẹ́ alábáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú òtítọ́.

Èmi kọ̀wé sí ìjọ: ṣùgbọ́n Diotirefe, ẹni tí ó fẹ́ láti jẹ́ ẹni pàtàkì jùlọ, kò gbà wá. 10 Nítorí náà bí mo bá dé, èmi yóò mú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ṣe wá sì ìrántí rẹ, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ búburú àti ìsọkúsọ sí wa: èyí kò sì tún tẹ́ ẹ lọ́rùn, síbẹ̀ òun fúnrarẹ̀ kọ̀ láti gba àwọn ará, àwọn tí ó sì ń fẹ́ gbà wọ́n, ó ń dá wọn lẹ́kun, ó sì ń lé wọn kúrò nínú ìjọ.

11 Olùfẹ́, má ṣe ṣe àfarawé ohun tí í ṣe ibi bí kò ṣe ohun tí ṣe rere. Ẹni tí ó bá ń ṣe rere ti Ọlọ́run ni; ẹni tí ó ba ń ṣe búburú kò rí Ọlọ́run. 12 Demetriusi ní ẹ̀rí rere lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn àti ní ti òtítọ́ fúnrarẹ̀ pẹ̀lú; nítòótọ́, àwa pẹ̀lú sì gba ẹ̀rí rẹ̀ jẹ́; ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí wa.

13 Èmí ní ohun púpọ̀ láti kọ sínú ìwé sí ọ, ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ fi kálàmù àti tawada kọ wọ́n sínú ìwé. 14 Mo ni ìrètí láti rí ọ láìpẹ́, tí àwa yóò sì sọ̀rọ̀ lójúkojú.

15 Àlàáfíà fún ọ.

Àwọn ọ̀rẹ́ wa tó wà níbí kí ọ. Kí àwọn ọ̀rẹ́ wa tó wà lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

Neno: Bibilia Takatifu

3 Yohana

Kutoka Kwa Mzee. Kwa mpendwa wangu Gayo, nimpendaye katika kweli. Mpendwa, ninakuombea ufanikiwe katika mambo yote na kwamba uwe na afya njema ya mwili; kwa maana najua roho yako ni salama. Nilifurahi sana walipokuja ndugu kadhaa wakashuhudia jinsi ulivyo mwaminifu katika kweli na jinsi unavyoendelea kuishi katika kweli. Hakuna kitu kinachonifurahisha zaidi kuliko kusi kia kwamba watoto wangu wanafuata kweli.

Uaminifu Wa Gayo

Mpendwa, wewe umekuwa mwaminifu kwa yote unayowatendea hao ndugu, ingawaje wao ni wageni kwako. Wamelishuhudia kanisa kuhusu upendo wako. Tafadhali wasaidie waendelee na safari yao kwa namna itakayompendeza Mungu. Kwa maana wanasafiri kwa ajili ya Bwana na wamekataa kupokea cho chote kutoka kwa watu wasiomjua Mungu . Kwa hiyo tunawajibu wa kuwasaidia watu wa namna hiyo ili tuwe watenda kazi pamoja nao kwa ajili ya kweli.

Diotrefe Na Demetrio

Niliandika barua kwa hilo kanisa; lakini Diotrefe apendaye kujiweka mbele kama kiongozi wao, hatambui mamlaka yangu. 10 Kwa hiyo nitakapokuja nitaeleza mambo anayofanya; na kuhusu maneno maovu anayosema juu yangu. Wala hatosheki na hayo bali anakataa kuwakaribisha ndugu. Pia anawazuia wale ambao wanataka kuwakarib isha na anawafukuza kutoka katika kanisa. 11 Mpendwa, usiige ubaya bali iga wema. Atendaye mema ni wa Mungu. Atendaye uovu hajapata kumwona Mungu. 12 Demetrio anashuhudiwa wema na kila mtu na hata kweli yenyewe inamshuhudia. Mimi pia ninamshuhudia wema, na wewe unajua kwamba ushuhuda wangu ni wa kweli.

Salamu Za Mwisho

13 Ninayo mengi ya kukuandikia, lakini afadhali nisitumie kalamu na wino. 14 Natarajia kukuona karibuni na tutaongea uso kwa uso.