Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Tẹsalonika 1

1Paulu, Sila àti Timotiu,

Sí ìjọ Tẹsalonika, nínú Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi Olúwa:

Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jesu Kristi Olúwa.

Àdúrà àti ìdúpẹ́

Ó yẹ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, nítorí pé ìgbàgbọ́ yín ń dàgbà gidigidi, àti ìfẹ́ olúkúlùkù yín sí ara yín ń di púpọ̀. Nítorí náà, àwa tìkára wa ń fi yín ṣògo nínú ìjọ Ọlọ́run, nítorí sùúrù àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti wàhálà yín tí ẹ̀yin náà ń fi ara dà.

Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé òdodo ni ìdájọ́ Ọlọ́run àti pé nítorí èyí ni a ó kà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, nítorí èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe ń jìyà. Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú, Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì ṣe nígbà ìfarahàn Jesu Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn angẹli alágbára. Òun yóò fi ìyà jẹ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ń ṣe àìgbọ́ràn sí ìhìnrere Jesu Olúwa wa. A ó fi ìparun àìnípẹ̀kun jẹ wọ́n ní yà, a ó sì ṣe wọn mọ̀ kúrò níwájú Olúwa àti inú ògo agbára rẹ̀ 10 Ní ọjọ́ tí yóò jẹ́ ẹni tí a ó yìn lógo nínú àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àti ẹni àwòyanu ní àárín gbogbo àwọn tí ó ti gbàgbọ́. Èyí kò yọ yín sílẹ̀, nítorí ẹ ti gba ẹ̀rí tí a jẹ́ sí yín gbọ́.

11 Nítorí èyí, àwa pẹ̀lú ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọ́run wa kí ó lè kà yín yẹ fún ìpè rẹ̀, àti pé nípa agbára rẹ̀, òun yóò mú gbogbo èrò rere yín ṣẹ àti gbogbo ohun tí ìgbàgbọ́ bá rú jáde. 12 Wọ̀nyí ni àdúrà wa, kí orúkọ Jesu Olúwa wa lè di yíyìn lógo nínú yín àti ẹ̀yin nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti ti Jesu Kristi Olúwa.

Amplified Bible

2 Thessalonians 1

Thanksgiving for Faith and Perseverance

1Paul, Silvanus (Silas), and Timothy,

To the church of the Thessalonians in God our Father and the Lord Jesus Christ: Grace to you and peace [inner calm and spiritual well-being] from God the Father and the Lord Jesus Christ.

We ought always and indeed are morally obligated [as those in debt] to give thanks to God for you, [a]brothers and sisters, as is fitting, because your faith is growing ever greater, and the [unselfish] [b]love of each one of you toward one another is continually increasing. Therefore, we speak of you with pride among the churches of God for your steadfastness [your unflinching endurance, and patience] and your firm faith in the midst of all the persecution and [crushing] distress which you endure. This is a positive proof of the righteous judgment of God [a sign of His fair verdict], so that you will be considered worthy of His kingdom, for which indeed you are suffering. For after all it is only just for God to repay with distress those who distress you, and to give relief to you who are so distressed and to us as well when the Lord Jesus is revealed from heaven with His mighty angels in a flame of fire, dealing out [full and complete] vengeance to those who do not [seek to] know God and to those who ignore and refuse to obey the gospel of our Lord Jesus [by choosing not to respond to Him]. These people will pay the penalty and endure the punishment of [c]everlasting destruction, banished from the presence of the Lord and from the glory of His power, 10 when He comes to be glorified in His saints on that day [that is, glorified through the changed lives of those who have accepted Him as Savior and have been set apart for His purpose], and to be marveled at among all who have believed, because our testimony to you was believed and trusted [and confirmed in your lives]. 11 With this in view, we constantly pray for you, that our God will count you worthy of your calling [to faith] and with [His] power fulfill every desire for goodness, and complete [your] every work of faith, 12 so that the name of our Lord Jesus will be glorified in you [by what you do], and you in Him, according to the [precious] grace of our God and the Lord Jesus Christ.

Notas al pie

  1. 2 Thessalonians 1:3 Lit brethren, includes all born-again believers.
  2. 2 Thessalonians 1:3 The key to understanding this and other statements about love is to know that this love (the Greek word agape) is not so much a matter of emotion as it is of doing things for the benefit of another person, that is, having an unselfish concern for another and a willingness to seek the best for another.
  3. 2 Thessalonians 1:9 Not annihilation, but the loss of all meaningful things.