Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Peteru 1

1Simoni Peteru, ìránṣẹ́ àti aposteli Jesu Kristi,

Sí àwọn tí ó gba irú iyebíye ìgbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú wá nínú òdodo Ọlọ́run wa àti ti Jesu Kristi Olùgbàlà.

Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sí i fún yín nínú ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jesu Olúwa wa.

Mímú kí ìpè àti yíyàn ẹni dájú

Bí agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀. Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wa: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.

Àti nítorí ìdí èyí, ẹ máa ṣe àìsimi gbogbo, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ kún ìwà rere; àti àìrékọjá kún ìmọ̀; àti sùúrù kún àìrékọjá; àti ìwà-bí-Ọlọ́run kún sùúrù. Àti ìfẹ́ ọmọnìkejì kún ìwà-bí-Ọlọ́run; àti ìfẹ́ni kún ìfẹ́ ọmọnìkejì. Nítorí bí ẹ̀yin bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè, ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́.

10 Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsimi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú: nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò ṣubú. 11 Nítorí báyìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀lọpọ̀ láti wọ ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.

Àsọtẹ́lẹ̀ ti ọrọ̀ Ọlọ́run

12 Nítorí náà, èmi ó máa rán yin létí àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti mọ̀ wọ́n, tí ẹsẹ̀ yín sì múlẹ̀ nínú òtítọ́ tí ẹ ní báyìí. 13 Èmi sì rò pé ó tọ́ láti máa mú wọn wá sí ìrántí yín, níwọ̀n ìgbà tí èmí ba ń bẹ nínú àgọ́ ara yìí. 14 Bí èmi ti mọ̀ pé, bíbọ́ àgọ́ ara mi yìí sílẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, àní, bí Olúwa wa Jesu Kristi ti fihàn mí. 15 Èmi ó sì máa ṣaápọn pẹ̀lú, kí ẹ̀yin lè máa rántí nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo lẹ́yìn ikú mi.

16 Nítorí kì í ṣe bí ẹni tí ó ń tọ ìtàn asán lẹ́yìn tí a fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n là sílẹ̀, nígbà tí àwa sọ fún yín ní ti agbára àti wíwá Jesu Kristi Olúwa, ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí ọláńlá rẹ̀ ni àwa jẹ́. 17 Nítorí tí Ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, nígbà tí irú ohùn yìí fọ̀ sí i láti inú ògo ńlá náà wá pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.” 18 Àwa pẹ̀lú sì gbọ́ ohun yìí tí ó ti ọ̀run wá nígbà tí àwa wà pẹ̀lú rẹ̀ ní orí òkè mímọ́ náà.

19 Àwa sì ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì dunjúdunjú sí i, èyí tí ó yẹ kí ẹ kíyèsi gẹ́gẹ́ bí fìtílà tó ń mọ́lẹ̀ níbi tí òkùnkùn gbé wà, títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóò sì yọ lọ́kàn yín. 20 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kí ẹ ní òye yìí pé kò sí àsọtẹ́lẹ̀ ìwé mímọ́ kankan tí ó wáyé nípa ìtumọ̀ wòlíì fún rara rẹ̀. 21 Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipá ìfẹ́ ènìyàn wá rí; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí a ti ń darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá.

Chinese Union Version (Simplified)

彼 得 後 書 1

1作 耶 稣 基 督 仆 人 和 使 徒 的 西 门 。 彼 得 写 信 给 那 因 我 们 的 神 和 ( 有 古 卷 没 有 和 字 ) 救 主 耶 稣 基 督 之 义 , 与 我 们 同 得 一 样 宝 贵 信 心 的 人 。

愿 恩 惠 、 平 安 , 因 你 们 认 识 神 和 我 们 主 耶 稣 , 多 多 的 加 给 你 们 。

神 的 神 能 已 将 一 切 关 乎 生 命 和 虔 敬 的 事 赐 给 我 们 , 皆 因 我 们 认 识 那 用 自 己 荣 耀 和 美 德 召 我 们 的 主 。

因 此 , 他 已 将 又 宝 贵 又 极 大 的 应 许 赐 给 我 们 , 叫 我 们 既 脱 离 世 上 从 情 欲 来 的 败 坏 , 就 得 与 神 的 性 情 有 分 。

正 因 这 缘 故 , 你 们 要 分 外 地 殷 勤 ; 有 了 信 心 , 又 要 加 上 德 行 ; 有 了 德 行 , 又 要 加 上 知 识 ;

有 了 知 识 , 又 要 加 上 节 制 ; 有 了 节 制 , 又 要 加 上 忍 耐 ; 有 了 忍 耐 , 又 要 加 上 虔 敬 ;

有 了 虔 敬 , 又 要 加 上 爱 弟 兄 的 心 ; 有 了 爱 弟 兄 的 心 , 又 要 加 上 爱 众 人 的 心 ;

你 们 若 充 充 足 足 的 有 这 几 样 , 就 必 使 你 们 在 认 识 我 们 的 主 耶 稣 基 督 上 不 至 於 ? 懒 不 结 果 子 了 。

人 若 没 有 这 几 样 , 就 是 眼 瞎 , 只 看 见 近 处 的 , 忘 了 他 旧 日 的 罪 已 经 得 了 洁 净 。

10 所 以 弟 兄 们 , 应 当 更 加 殷 勤 , 使 你 们 所 蒙 的 恩 召 和 拣 选 坚 定 不 移 。 你 们 若 行 这 几 样 , 就 永 不 失 脚 。

11 这 样 , 必 叫 你 们 丰 丰 富 富 的 得 以 进 入 我 们 主 ─ 救 主 耶 稣 基 督 永 远 的 国 。

12 你 们 虽 然 晓 得 这 些 事 , 并 且 在 你 们 已 有 的 真 道 上 坚 固 , 我 却 要 将 这 些 事 常 常 提 醒 你 们 。

13 我 以 为 应 当 趁 我 还 在 这 帐 棚 的 时 候 提 醒 你 们 , 激 发 你 们 。

14 因 为 知 道 我 脱 离 这 帐 棚 的 时 候 快 到 了 , 正 如 我 们 主 耶 稣 基 督 所 指 示 我 的 。

15 并 且 , 我 要 尽 心 竭 力 , 使 你 们 在 我 去 世 以 後 时 常 记 念 这 些 事 。

16 我 们 从 前 将 我 们 主 耶 稣 基 督 的 大 能 和 他 降 临 的 事 告 诉 你 们 , 并 不 是 随 从 乖 巧 捏 造 的 虚 言 , 乃 是 亲 眼 见 过 他 的 威 荣 。

17 他 从 父 神 得 尊 贵 荣 耀 的 时 候 , 从 极 大 荣 光 之 中 有 声 音 出 来 , 向 他 说 : 「 这 是 我 的 爱 子 , 我 所 喜 悦 的 。 」

18 我 们 同 他 在 圣 山 的 时 候 , 亲 自 听 见 这 声 音 从 天 上 出 来 。

19 我 们 并 有 先 知 更 确 的 预 言 , 如 同 灯 照 在 暗 处 。 你 们 在 这 预 言 上 留 意 , 直 等 到 天 发 亮 , 晨 星 在 你 们 心 里 出 现 的 时 候 , 才 是 好 的 。

20 第 一 要 紧 的 , 该 知 道 经 上 所 有 的 预 言 没 有 可 随 私 意 解 说 的 ;

21 因 为 预 言 从 来 没 有 出 於 人 意 的 , 乃 是 人 被 圣 灵 感 动 , 说 出 神 的 话 来 。