Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kọrinti 1

1Paulu aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti Timotiu arákùnrin wá, sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọrinti pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní gbogbo Akaia:

Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Jesu Kristi Olúwa.

Ọlọ́run gbogbo ìtùnú

Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo; Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa pẹ̀lú lè máa tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Nítorí pé bí àwa ti pín nínú ìjìyà Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ̀ pẹ̀lú nípa Kristi. Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbí bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù láti mú yin ní irú ìfaradà ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́. Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹ̀yin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú.

Arákùnrin àti arábìnrin, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Asia, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́. Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde: 10 Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá; òun ní àwa gbẹ́kẹ̀lé pé yóò sí máa gbà wá síbẹ̀síbẹ̀, 11 bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ń fi àdúrà yín ràn wá lọ́wọ́. Àti pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò dúpẹ́ nítorí wa fún oore-ọ̀fẹ́ ojúrere tí a rí gbà nípa ìdáhùn sí àdúrà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.

Paulu yí ìpinnu rẹ̀ padà

12 Nítorí èyí ní ìṣògo wá, ẹ̀rí láti inú ọkàn wa pẹ̀lú si jẹ́rìí wí pé àwa ń gbé ìgbésí ayé tí ó ní ìtumọ̀ pàápàá jùlọ nínú ìbágbépọ̀ wa pẹ̀lú yín, nínú ìwà mímọ́ àti òtítọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Kì í ṣe nípa ọgbọ́n ti ara ni àwa ń ṣe èyí bí kò ṣe nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. 13 Nítorí pé àwa kò kọ̀wé ohun tí eyín kò lè kà àti ni mòye rẹ̀ sí yín. Mo sì tún ní ìrètí wí pé. 14 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ní ìmọ̀ nípa wa ní apá kan, bákan náà ni ẹ ó ní ìmọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́ tí ẹ ó sì fi wá yangàn, bí àwa pẹ̀lú yóò ṣe fi yín yangàn ní ọjọ́ Jesu Olúwa.

15 Nítorí mo ní ìdánilójú yìí wí pé, mo pinnu láti kọ́kọ́ bẹ̀ yín wò kí ẹ lè jẹ àǹfààní ìgbà méjì. 16 Mo pinnu láti bẹ̀ yín wò ní ìrìnàjò mi sí Makedonia àti láti tún bẹ̀ yín wò nígbà tí mo bá ń padà bọ̀ láti Makedonia àti wí pé kí ẹ̀yin kí ó lè rán mi láti ọ̀dọ̀ yín ní ìrìnàjò mi sí Judea. 17 Nítorí náà nígbà tí èmi ń gbèrò bẹ́ẹ̀, èmi ha ṣiyèméjì bí? Tàbí àwọn ohun tí mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹ́gẹ́ bí ti ará bí, pé kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ ní, bẹ́ẹ̀ ní” àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ kọ́”?

18 Ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run tí jẹ́ olóòtítọ́, ọ̀rọ̀ wa fún yín kí í ṣe bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́. 19 Nítorí pé Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí a tí wàásù rẹ̀ láàrín yín nípasẹ̀ èmí àti Silfanu àti Timotiu, kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nínú rẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ ní. 20 Nítorí tí gbogbo ìlérí Ọlọ́run dí bẹ́ẹ̀ ni nínú Kristi. Nítorí ìdí èyí ní a ṣe ń wí pé “Àmín” nípasẹ̀ rẹ̀ sí ògo Ọlọ́run. 21 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Ọlọ́run ni ó fi ẹsẹ̀ wa múlẹ̀ pẹ̀lú yín nínú Kristi, Òun ni ó ti fi ààmì òróró yàn wá, 22 ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì wá pẹ̀lú, ó sì tí fi Ẹ̀mí rẹ́ sí wa ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ó ń bọ̀.

23 Mo sì pe Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí ọkàn mi pé nítorí àti dá yín sí ní èmi kò ṣe padà sí Kọrinti. 24 Kì í ṣe nítorí tí àwa jẹ gàba lórí ìgbàgbọ́ yín: ṣùgbọ́n àwa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú yín fún ayọ̀ yín nítorí nípa ìgbàgbọ́ ni ẹ̀yin dúró ṣinṣin.

En Levende Bok

2 Korintierne 1

Hilsen

1Hilsen fra Paulus, som ved Guds vilje er utsending[a] for Jesus Kristus[b]. Min medarbeider Timoteus er med og sender sin hilsen.

Til Guds menighet i Korint, og til alle de troende rundt om i provinsen Akaia. Jeg ber at Gud, vår Far, og Herren Jesus Kristus vil vise dere godhet og fylle dere med fred.

Gud trøster og oppmuntrer

La oss hylle Gud, han som er Far til vår Herre Jesus Kristus. All trøst og oppmuntring har jo sitt utspring i Gud. Han trøster og oppmuntrer oss i alle våre vanskeligheter, slik at vi selv kan gi trøst og oppmuntring videre til andre som har det vanskelig. Jo mer vi må lide for Kristi skyld, desto mer trøst og oppmuntring får vi gjennom vårt fellesskapet med Kristus. Når jeg og mine medarbeidere møter vanskeligheter, er det altså til det beste, slik at dere skal bli frelst for evig. Gjennom den trøst og oppmuntring vi selv får når vi har det vanskelig, kan vi styrke og oppmuntre dere, slik at dere ikke forlater troen når dere må gå gjennom de samme lidelsene. Vi er sikre på at dere virkelig vil holde fast ved troen, etter som Gud trøster og oppmuntrer dere når dere må lide, akkurat som han gjør med oss.

Jeg vil at dere skal vite, kjære søsken[c], hvilke enorme vanskeligheter jeg måtte gå gjennom i provinsen Asia[d]. Jeg var så ille ute at jeg ikke hadde noen krefter igjen og faktisk trodde at min siste time var kommet. Ja, det kjentes ut som om jeg allerede hadde fått min dødsdom. Men gjennom dette skulle jeg lære å ikke stole på min egen kraft, men bare på Gud, han som kan vekke opp døde. 10 Gud reddet meg virkelig fra den visse død, og han vil gjøre det igjen etter som jeg stoler på ham. 11 Husk på å hjelpe meg ved at dere ber for meg, slik at vi alle kan takke Gud for at han svarte på bønnene våre og reddet meg.

Paulus forandrer reiseplanene

12 Jeg er stolt over ærlig å kunne si at jeg alltid har handlet rett mot dere, akkurat som jeg med Guds hjelp forsøker å handle rett mot alle mennesker. Jeg har ikke blitt styrt av menneskelig visdom og har ikke skjult noe, men har alltid vært ærlig og fulgt Guds vilje. 13-14 Mine brev har vært åpne og rett på sak. Det finnes ingen skjulte motiv, men alt er skrevet slik at dere enkelt og greit skal kunne forstå det jeg mener. Jeg håper også at dere snart fullt og helt skal forstå det som dere inntil nå bare har forstått enkelte deler av. Når vår Herre Jesus kommer igjen, kan dere være like stolte over meg som jeg er over dere.

15-16 Etter som jeg er sikker på at dere virkelig har tillit til meg, hadde jeg tenkt å glede dere, ikke bare med ett, men med to besøk. Jeg hadde tenkt å besøke dere først på veien til Makedonia, og så på returen hjem igjen. Da ville dere sikkert kommet meg til hjelp med det jeg trengte for min reise til Judea.

17 Men nå ble det altså ikke slik, og dere mener kanskje at jeg forandret planene mine litt vel lettvint. At jeg kanskje sier en ting og gjør noe annet? Nesten som om et ja fra meg kan bety et nei? 18 Absolut ikke! Gud, som selv holder løftene sine, kan vitne om at jeg alltid står for det jeg sier. 19 Jesus Kristus, Guds sønn, som jeg, Silvanus og Timoteus har undervist dere om, sa heller aldri ja til noe uten at han holdt sitt ord. Gjennom Jesus har Gud sagt sitt ja til menneskene. 20 Alt det som Gud har lovet, vil bli oppfylt gjennom Jesus. Derfor har vi som nå tilhører Gud, sagt vårt ja til ham og lever for å ære ham. 21 Det er han som har utrustet oss med sin Ånd, og som hjelper både dere og meg til å holde fast ved troen på Kristus. 22 Ånden som bor i vårt indre, er et tegn på at vi tilhører Gud, og garantien for at han en dag skal innfri løftet sitt og frelse oss for evig. 23 Gud selv kan vitne om at det jeg nå sier, er sant: Den eneste grunnen til at jeg ikke besøkte dere slik jeg først hadde tenkt, var at jeg ikke ville komme for å irettesette dere. 24 Ikke se på meg og mine medarbeidere som autoriteter som vil bestemme over hva dere skal tro. Nei, vi vil bare hjelpe dere til å være glade for troen på Jesus som dere allerede har. Det er den som gjør dere sterke.

Notas al pie

  1. 1:1 Kalles også apostel.
  2. 1:1 ”Kristus” betyr ”den salvede” på gresk. Blant Israels folk ble konger, prester og profeter salvet med olje før de begynte oppgaven sin. Gud hadde ved profetene lovet å sende en salvet konge som skulle herske over alle folk. Det hebraisk ordet ”Messias” betyr også ”den salvede”.
  3. 1:8 På gresk: brødre. Samme tolkning blir brukt gjennom hele brevet.
  4. 1:8 Provinsen Asia var en romersk provins i nåværende Tyrkia.