Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Johanu

Alàgbà,

Sì àyànfẹ́ obìnrin ọlọ́lá àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ ní òtítọ́, kì í sì í ṣe èmi nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó mọ òtítọ́ pẹ̀lú; nítorí òtítọ́ tí ń gbé inú wa, yóò sì bá wa gbé títí.

Oore-ọ̀fẹ́, àánú, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, Ọmọ Baba, yóò wà pẹ̀lú wa nínú òtítọ́ àti nínú ìfẹ́.

Mo yọ̀ gidigidi pé mo rí nínú àwọn ọmọ rẹ tí ń rìn nínú òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí Baba ti pa àṣẹ fún wa. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, mo bẹ̀ ọ́, obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe bí ẹni pé èmi ń kọ̀wé òfin tuntun kan sí ọ, bí kò ṣe èyí ti àwa tí ní ní àtètèkọ́ṣe, pé kí àwa fẹ́ràn ara wa. Èyí sì ni ìfẹ́, pé, kí àwa máa rin nípa òfin rẹ̀, èyí ni òfin náà, àní bí ẹ ti gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé, kí ẹ̀yin rìn nínú rẹ̀.

Nítorí ẹlẹ́tàn púpọ̀ ti jáde wa sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá nínú ara. Èyí ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi. Ẹ kíyèsára yín, kí ẹ má ba à sọ iṣẹ́ tí ẹ tí ṣe nù, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè rí èrè kíkún gbà. Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń rú òfin tí kò si dúró nínú ẹ̀kọ́ Kristi, kò mọ Ọlọ́run. Ẹni tí ó bá dúró nínú ẹ̀kọ́, òun ni ó mọ Baba àti Ọmọ. 10 Bí ẹnikẹ́ni bá tọ̀ yín wá, tí kò sì mu ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé, kí ẹ má sì ṣe kí i kú ààbọ̀. 11 Nítorí ẹni tí ó bá kí kú ààbọ̀, ó ní ọwọ́ nínú iṣẹ́ búburú rẹ̀.

12 Bí mo tilẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti ṣe alábápín pẹ̀lú yín, síbẹ̀ èmi kò fẹ́ lo ìwé ìkọ̀wé àti jẹ́lú ìkọ̀wé. Ṣùgbọ́n èmi ní ìrètí láti tọ̀ yín wá àti láti bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín bá à le è kún.

13 Àwọn ọmọ arábìnrin rẹ àyànfẹ́ kí ọ.

Nkwa Asem

Yohane II

Me, Ɔpanyin, mekyerɛw kɔma Awuraa a wɔayi no ne ne mma a medɔ wɔn yiye no. Ɛnyɛ me nko, na mmom wɔn a wonim nokware no nyinaa dɔ wo, efisɛ, nokware no te yɛn mu na ɛbɛtena yɛn mu akosi daa daa. Adom, mmɔborɔhunu ne asomdwoe mfi Agya Nyankopɔn ne Awurade Yesu Kristo, Agya no Ba no, nkyɛn mmra yɛn so nokware ne ɔdɔ mu.

Nokware ne ɔdɔ

M’ani gyei sɛ mihui sɛ mo mma no bi te nokware mu sɛnea Agya no hyɛɛ yɛn no.

Enti mereka akyerɛ wo, Awuraa se, momma yɛnnodɔ yɛn ho. Eyi nyɛ mmara foforo a merehyɛ ama wo. Ɛyɛ mmara a wɔahyɛ ama yɛn fi mfitiase. Saa ɔdɔ a mereka ho asɛm yi kyerɛ sɛ, momma yɛntena ase na yɛnyɛ osetie mma Onyankopɔn. Mmara a mote fii mfitiase no kyerɛ sɛ mo nyinaa, montena ase ɔdɔ mu.

Adaadaafo a wɔmpae mu nka se Yesu Kristo bae ɔhonam mu no abu so wiase. Saa onipa a ɔte saa no yɛ ɔdaadaafo na ɔyɛ Kristo tamfo nso. Monhwɛ mo ho so yiye na moanhwere nea moayɛ ho adwuma na moanya mo akatua wɔ mu. Obiara a ɔmfa Kristo nkyerɛkyerɛ na ɔtra no, nni Onyankopɔn. Na nea ɔfa nkyerɛkyerɛ no wɔ Agya no ne Ɔba no.

10 Sɛ obi ba mo nkyɛn na wamfa saa nkyerɛkyerɛ yi ammrɛ mo a, munnnye no wɔ mo fi, na monnka nso se, “Asomdwoe nka wo.” 11 Efisɛ, obiara a ɔbekyia no asomdwoe nka no no ka bɔne a ɔyɛ no ho.

Nsɛm a etwa to

12 Mewɔ nsɛm pii ka kyerɛ mo, nanso meremfa krataa ne kyerɛwduru so nka. Na mmom, mɛba nipadua so abɛkasa akyerɛ mo, na moani agye.

13 Wo nuabea a wɔayi no no mma no kyia wo.