Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kọrinti 8

Oúnjẹ tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà

1Ní ìsinsin yìí, nípa tí oúnjẹ ti a fi rú ẹbọ sí òrìṣà, a mọ̀ pé gbogbo wa ni a ní ìmọ̀. Imọ̀ a máa fẹ́ mu ní gbéraga, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ní gbé ni ró. Bí ẹnikẹ́ni bá ró pé òun mọ ohun kan, kò tí ì mọ̀ bí ó ti yẹ kí ó mọ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn Ọlọ́run nítòótọ́, òun ni ẹni tí Ọlọ́run mọ.

Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ kí a jẹ àwọn oúnjẹ ti a fi rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà bí? Láìṣe àní àní, gbogbo wá mọ̀ pé àwọn ère òrìṣà kì í ṣe Ọlọ́run rárá, ohun asán ni wọn ni ayé. A sì mọ̀ dájúdájú pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ní ń bẹ, kò sì ṣí ọlọ́run mìíràn bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, à ní ọ̀pọ̀ ọlọ́run kéékèèkéé mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé (gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” ṣe wa náà ní ọ̀pọ̀ “olúwa” wa). Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan ṣoṣo Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀.

Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn lo mọ èyí: Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn tí ó ti ń bọ̀rìṣà lọ́jọ́ tó ti pẹ́ títí di ìsinsin yìí jẹ ẹ́ bí ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà; àti ẹ̀rí ọkàn wọn tí ó ṣe àìlera sì di aláìmọ́. Ṣùgbọ́n oúnjẹ kò mú wa súnmọ́ Ọlọ́run, nítorí pé kì í ṣe bí àwa bá jẹun ni àwa burú jùlọ tàbí nígbà tí a kò jẹ ni àwa dára jùlọ.

Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsi ara gidigidi nípa ìlò òmìnira yín kí ẹ má ba à mú kí àwọn arákùnrin mìíràn tí í ṣe onígbàgbọ́, tí ọkàn wọn ṣe aláìlera, ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. 10 Ẹ kíyèsára, nítorí bi ẹnìkan ba rí i ti ìwọ ti o ni ìmọ̀ bá jókòó ti oúnjẹ ní ilé òrìṣà, ǹjẹ́ òun kò ha ni mú ọkàn le, bi ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá ṣe aláìlera, láti jẹ oúnjẹ tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà? 11 Nítorí náà, nípa ìmọ̀ rẹ ni arákùnrin aláìlera náà yóò ṣe ṣègbé, arákùnrin ẹni tí Kristi kú fún. 12 Bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀ sí arákùnrin rẹ̀ tí ẹ sì ń pa ọkàn àìlera wọn lára, ẹ̀yìn ǹ dẹ́ṣẹ̀ sí Kristi jùlọ. 13 Nítorí nà án, bí oúnjẹ bá mú arákùnrin mi kọsẹ̀, èmi kì yóò sì jẹ ẹran mọ́ títí láé, kí èmi má ba à mú arákùnrin mi kọsẹ̀.

New Russian Translation

1 Corinthians 8

О пище, принесенной в жертву идолам

1Теперь к вопросу о пище, принесенной в жертву идолам.

Мы знаем, что «все из нас обладают знанием», но знание делает людей гордыми, а любовь назидает. 2Тот, кто думает, что он что-то знает, на самом деле еще не знает так, как ему следовало бы знать. 3Но кто любит Бога, тот познан Им.

4Итак, о пище, принесенной в жертву идолам. Всем нам известно, что идолы, которым мир поклоняется, ничего не значат, и что нет другого Бога, кроме Единого. 5И хотя есть так называемые «боги», будь то на небе или на земле (а в мире действительно много разных «богов» и «господ»), 6но для нас есть только один Бог – Отец, Которым все было сотворено и для Которого мы и живем, и только один Господь – Иисус Христос, через Которого все было сотворено и через Которого мы получили жизнь. 7Но не всем еще это известно. Некоторые настолько привыкли к идолам, что, когда они едят такую пищу, они до сих пор думают о ней, как о жертве, принесенной идолам, и при этом их слабая совесть внушает им, что они нечисты. 8Но пища не помогает приблизиться к Богу. Мы не становимся хуже, если мы не едим чего-то, и не становимся лучше, если мы едим.

9Смотрите, однако, чтобы ваша свобода в выборе пищи не стала камнем преткновения для слабых. 10Потому что если кто-то увидит, что ты при всем твоем знании ешь в языческом храме, то и он со своей слабой совестью вслед за тобой станет есть пищу, принесенную в жертву идолам. 11А значит, твое знание погубит слабого брата, за которого умер Христос. 12Согрешая таким образом против братьев и раня их слабую совесть, вы согрешаете против Христа. 13Поэтому, если из-за моей пищи может согрешить мой брат, то я лучше не буду есть мяса вообще, чтобы этим не ввести брата в грех.