Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 1

Ọ̀rọ̀ ìṣáájú

1Ìfihàn ti Jesu Kristi, tí Ọlọ́run fi fún un, láti fihàn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ohun tí kò le ṣàìṣẹ ní lọ́ọ́lọ́ọ́; ó sì ránṣẹ́, ó sì fi í hàn láti ọwọ́ angẹli rẹ̀ wá fún Johanu, ìránṣẹ́ rẹ̀: Ẹni tí ó jẹ́rìí ohun gbogbo tí ó rí—èyí ì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti ẹ̀rí ti Jesu Kristi. Ẹni ìbùkún ni ẹni tí ń kà, àti àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, tí ó sì ń pa nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́: nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.

Ọ̀rọ̀ ìkíni àti ìyìn

Johanu,

Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Asia:

Oore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá; àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀; àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí olóòtítọ́, àkọ́bí nínú àwọn òkú, àti aláṣẹ àwọn ọba ayé.

Ẹni tí ó fẹ́ wa, ẹni tí ó gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí ó sì ti fi wá jẹ ọba àti àlùfáà láti sin Ọlọ́run àti Baba rẹ; tirẹ̀ ni ògo àti ìjọba láé àti láéláé. Àmín.

Kíyèsi i, o ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀;
    gbogbo ojú ni yóò sì rí i,
àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú;
    àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ni! Àmín.

“Èmi ni Alfa àti Omega,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, alágbára.”

Ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí Ọmọ ènìyàn

Èmi, Johanu, arákùnrin yín àti alábápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jesu, wà ní erékúṣù tí a ń pè ní Patmo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jesu Kristi. 10 Mo wà nínú Ẹ̀mí ní ọjọ́ Olúwa, mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ́yìn mi, bí ìró ìpè, 11 Ó ń wí pé, “Kọ́ ìwé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje; sí Efesu, àti sí Smirna, àti sí Pargamu, àti sí Tiatira, àti sí Sardi, àti sí Filadelfia, àti sí Laodikea.”

12 Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo yípadà, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà méje; 13 àti láàrín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnìkan tí ó dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí a wọ̀ ní aṣọ tí ó kanlẹ̀ dé ẹsẹ̀, tí a sì fi àmùrè wúrà dì ní ẹ̀gbẹ́. 14 Orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó funfun bí yìnyín; ojú rẹ̀ sì dàbí, ọwọ́ iná; 15 Ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀. 16 Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde: Ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn.

17 Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn. 18 Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsi i, èmi sì ń bẹ láààyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò òkú lọ́wọ́.

19 “Kọ̀wé nítorí náà ohun tí ìwọ ti rí, àti ti ohun tí ń bẹ, àti ti ohun tí yóò hù lẹ́yìn èyí; 20 ohun ìjìnlẹ̀ tí ìràwọ̀ méje náà tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ọ̀pá wúrà fìtílà méje náà. Ìràwọ̀ méje ni àwọn angẹli ìjọ méje náà: àti ọ̀pá fìtílà méje náà ní àwọn ìjọ méje.

Chinese Union Version (Simplified)

啟 示 錄 1

1耶 稣 基 督 的 启 示 , 就 是 神 赐 给 他 , 叫 他 将 必 要 快 成 的 事 指 示 他 的 众 仆 人 。 他 就 差 遣 使 者 晓 谕 他 的 仆 人 约 翰 。

约 翰 便 将 神 的 道 和 耶 稣 基 督 的 见 证 , 凡 自 己 所 看 见 的 都 证 明 出 来 。

念 这 书 上 预 言 的 和 那 些 听 见 又 遵 守 其 中 所 记 载 的 , 都 是 有 福 的 , 因 为 日 期 近 了 。

约 翰 写 信 给 亚 西 亚 的 七 个 教 会 。 但 愿 从 那 昔 在 、 今 在 、 以 後 永 在 的 神 , 和 他 宝 座 前 的 七 灵 ,

并 那 诚 实 作 见 证 的 、 从 死 里 首 先 复 活 、 为 世 上 君 王 元 首 的 耶 稣 基 督 , 有 恩 惠 、 平 安 归 与 你 们 ! 他 爱 我 们 , 用 自 己 的 血 使 我 们 脱 离 ( 有 古 卷 作 : 洗 去 ) 罪 恶 ,

又 使 我 们 成 为 国 民 , 作 他 父 神 的 祭 司 。 但 愿 荣 耀 、 权 能 归 给 他 , 直 到 永 永 远 远 。 阿 们 !

看 哪 , 他 驾 云 降 临 ! 众 目 要 看 见 他 , 连 刺 他 的 人 也 要 看 见 他 ; 地 上 的 万 族 都 要 因 他 哀 哭 。 这 话 是 真 实 的 。 阿 们 !

主 神 说 : 我 是 阿 拉 法 , 我 是 俄 梅 戛 , ( 阿 拉 法 , 俄 梅 戛 : 是 希 利 尼 字 母 首 末 二 字 ) , 是 昔 在 、 今 在 、 以 後 永 在 的 全 能 者 。

我 ─ 约 翰 就 是 你 们 的 弟 兄 , 和 你 们 在 耶 稣 的 患 难 、 国 度 、 忍 耐 里 一 同 有 分 , 为 神 的 道 , 并 为 给 耶 稣 作 的 见 证 , 曾 在 那 名 叫 拔 摩 的 海 岛 上 。

10 当 主 日 , 我 被 圣 灵 感 动 , 听 见 在 我 後 面 有 大 声 音 如 吹 号 , 说 :

11 你 所 看 见 的 当 写 在 书 上 , 达 与 以 弗 所 、 士 每 拿 、 别 迦 摩 、 推 雅 推 喇 、 撒 狄 、 非 拉 铁 非 、 老 底 嘉 、 那 七 个 教 会 。

12 我 转 过 身 来 , 要 看 是 谁 发 声 与 我 说 话 ; 既 转 过 来 , 就 看 见 七 个 金 灯 ? 。

13 灯 ? 中 间 有 一 位 好 像 人 子 , 身 穿 长 衣 , 直 垂 到 脚 , 胸 间 束 着 金 带 。

14 他 的 头 与 发 皆 白 , 如 白 羊 毛 , 如 雪 ; 眼 目 如 同 火 焰 ;

15 脚 好 像 在 炉 中 ? 炼 光 明 的 铜 ; 声 音 如 同 众 水 的 声 音 。

16 他 右 手 拿 着 七 星 , 从 他 口 中 出 来 一 把 两 刃 的 利 剑 ; 面 貌 如 同 烈 日 放 光 。

17 我 一 看 见 , 就 仆 倒 在 他 脚 前 , 像 死 了 一 样 。 他 用 右 手 按 着 我 , 说 : 不 要 惧 怕 ! 我 是 首 先 的 , 我 是 末 後 的 ,

18 又 是 那 存 活 的 ; 我 曾 死 过 , 现 在 又 活 了 , 直 活 到 永 永 远 远 ; 并 且 拿 着 死 亡 和 阴 间 的 钥 匙 。

19 所 以 你 要 把 所 看 见 的 , 和 现 在 的 事 , 并 将 来 必 成 的 事 , 都 写 出 来 。

20 论 到 你 所 看 见 、 在 我 右 手 中 的 七 星 和 七 个 金 灯 ? 的 奥 秘 , 那 七 星 就 是 七 个 教 会 的 使 者 , 七 灯 ? 就 是 七 个 教 会 。